Orin 3
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run ìfẹ́ ńpè wá pé,
‘Bá mi rìn, fẹ́ ọ̀nà mi.’
Báa nífẹ̀ẹ́ Jáà àti èèyàn,
Ire ṣáá la ó máa ṣe.
Ìgbé ayé ire nìyẹn;
Ìgbé ayé tí a ńfẹ́.
Ìfẹ́ bíi Kristi kìí kùnà.
Ìfẹ́ yìí yóò sì máa hàn.
2. Ìfẹ́ òtítọ́ ńdarí wa;
Ìfẹ́ Jáà ńmú wa nífẹ̀ẹ́.
Táa bá ṣubú òun yóò gbé wa;
Okun rẹ̀ laó fi dìde.
Mímọ́ nìfẹ́ kìí sìí jowú;
Ó nínúure òun sùúrù.
Ká ní ìfẹ́ àwọn ará.
Ká jadùn ìfẹ́ tòótọ́.
3. Má fàyè gba ìkórìíra;
Má ṣe jẹ́ kó sún mọ́ ọ.
Wo Jáà yóò sì tọ́ ọ sọ́nà;
Yóò kọ́ ọ ní àṣẹ yìí:
Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtèèyàn,
Mọ bí ìfẹ́ ṣe jẹ́ gan-an.
Ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì,
Ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni.
(Tún wo Máàkù 12:30, 31; 1 Kọ́r. 12:31–13:8; 1 Jòh. 3:23.)