Wọ́n Yan Ohun Tó Sàn Jù Ṣé Wàá Fara Wé Wọn?
ILÉ iṣẹ́ tó ń ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì fáwọn tó máa ń lọ sí gbalasa òfuurufú ni Arákùnrin Marc ti ń ṣiṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Kánádà. Iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ló ń ṣe níbẹ̀, ó sì tún ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá rẹ̀ fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. Ipò tuntun yìí máa gba àkókò Marc, àmọ́, ó máa bẹ̀rẹ̀ sí gba owó gọbọi. Kí ni Marc wá ṣe?
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Amy, lórílẹ̀ èdè Philippines, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ ṣe tán nílé ẹ̀kọ́ gíga. Lẹ́yìn tó gboyè jáde, ó ríṣẹ́ kan tó máa gbà á lákòókò, àmọ́ owó tó jọjú ni wọ́n á máa san. Kí ni Amy pinnu láti ṣe?
Ohun tí Marc àti Amy yàn láti ṣe ò dọ́gba rárá, àbájáde ohun tí wọ́n yàn sì fi hàn pé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì bọ́gbọ́n mu gan-an ni. Ó sọ pé: “Kí . . . àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—1 Kọ́r. 7:29-31.
Má Ṣe Lo Ayé Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ká tó mọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀ sí Marc àti Amy, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ayé” (tàbí koʹsmos lédè Gíríìkì) tí Pọ́ọ̀lù lò nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, “koʹsmos” túmọ̀ sí ètò àwọn nǹkan tó yí wa ká, ìyẹn àwùjọ àwa èèyàn lápapọ̀, tó fi mọ́ àwọn ohun kòṣeémáàní, irú bí ilé, oúnjẹ àti aṣọ. Ká tó lè ní àwọn ohun kòṣeémáàní wọ̀nyí, àfi ká níṣẹ́ lọ́wọ́. Ká sòótọ́, kò sí ọ̀nà àbùjá kankan, àfi ká lo àwọn nǹkan tó wà nínú ayé láti fi bójú tó ara wa àti ìdílé wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ. (1 Tím. 5:8) Bó ti wù kó rí, a ò ní gbàgbé pé “ayé ń kọjá lọ.” (1 Jòh. 2:17) Nítorí náà, a máa lo àwọn ohun tí ayé lè fún wa dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ kì í ṣe “dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—1 Kọ́r. 7:31.
Nítorí Bíbélì sọ pé ká má ṣe lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti tún èrò ara wọn pa, tí wọ́n ti dín àkókò tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù, tí wọn ò sì ṣe jura wọn lọ. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá rí i pé àwọn ti yan ohun tó sàn jù lóòótọ́, torí pé wọ́n wá ń ní àkókò tó pọ̀ sí i láti fi gbọ́ ti ìdílé wọn àti láti fi sin Jèhófà. Síwájú sí i, bí wọn ò ṣe wayé máyà yìí ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbára lé Jèhófà dípò kí wọ́n máa gbára lé ayé yìí. Ṣé wàá fara wé wọn? Ìyẹn ni pé kí ìwọ náà má ṣe wayé máyà kó o ba lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Mát. 6:19-24, 33.
“A Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”
Marc tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká má ṣe lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Kò gba ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, èyí tó lè sọ ọ́ dọlọ́rọ̀ lọ́sàn-án kan òru kan. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà ni ọ̀gá rẹ tún wá fi owó tabua kún owó tí wọ́n fẹ́ máa san fún un tẹ́lẹ̀ kó ba lè gbà láti ṣiṣẹ́ ní ipò tuntun náà. Marc sọ pé: “Àdánwò ìgbàgbọ́ ló jọ lójú mi, àmọ́ mo tún sọ pé mi ò ṣe.” Marc wá ṣàlàyé ìdí tóun tún fi kọ̀ ọ́, ó ní: “Èmi àti ìyàwó mi, Paula, fẹ́ fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ìdí nìyẹn tá a fi pinnu pé a ò ní ṣe jura wa lọ. A gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa lọ́gbọ́n kọ́wọ́ wa lè tẹ ohun tá a fojú sùn, a sì dá ọjọ́ kan pàtó tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo ara gbárùkù ti iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.”
Paula ṣàlàyé pé: “Ọjọ́ mẹ́ta lọ́sẹ̀ ni mo fi ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ní ọsibítù kan, mo sì ń gba owó oṣù tó tó ná. Mo tún ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́, bíi ti Marc, èmi náà fẹ́ lo àkókò tó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà níbikíbi tí wọ́n bá ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Nígbà tí mo kọ̀wé pé mo fẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀ lọ̀gá mi wá sọ fún mi pé mo tóótun fún ipò akọ̀wé àgbà tí wọ́n ń wá èèyàn fún. Ká sòótọ́, ipò yẹn ni ipò akọ̀wé tó lówó lórí jù lọ ní ọsibítù yẹn, àmọ́ mi ò tìtorí ìyẹn yí ìpinnu mi padà. Nígbà tí mo ṣàlàyé ìdí tí mo fi kọ̀ láti ṣiṣẹ́ akọ̀wé àgbà fún ọ̀gá mi, ó gbóríyìn fún mi torí ìgbàgbọ́ tí mo ní.”
Nígbà tó yá, Marc àti Paula di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìjọ kékeré tó wà ní àdádó kan báyìí lórílẹ̀-èdè Kánádà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Marc sọ pé: “Ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí lẹ́yìn tí mo fi iṣẹ́ tó ń mówó wọlé dáadáa tí mo ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún sílẹ̀, àmọ́ Jèhófà bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A ní ayọ̀ jaburata téèyàn máa ń ní tó bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run. Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sì tún mú kí ìgbéyàwó wa láyọ̀ sí i. Ìjíròrò wa máa ń dá lórí àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Ìyẹn àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. A túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” (Ìṣe 20:35) Paula fi kún un pé: “Téèyàn bá fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ìtura tó ń rí ní ibùgbé tó ti mọ́ ọn lára sílẹ̀, àfi kó fọkàn tán Jèhófà pátápátá. Ohun tá a ṣe gan-an nìyẹn, Jèhófà sì bù kún wa. Àwọn ará tó wà nínú ìjọ wa tuntun jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wa, àti pé a wúlò fáwọn. Mo ti wá ń lo okun tí mo máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tẹ́lẹ̀ láti máa fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run. Ìdùnnú wá ṣubú layọ̀ fún mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yìí.”
‘Mo Rí Towó Ṣe àmọ́ Mi Ò Láyọ̀’
Ọ̀tọ̀ lohun tí Amy tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan yẹn ṣe ní tiẹ̀. Ó gbà láti ṣe iṣẹ́ olówó gegere, tó ń gba àkókò, tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yẹn. Ó sọ pé: “Lọ́dún àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yẹn, mi ò kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ lọ̀rọ̀ ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà mí lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ. Wọ́n fi àwọn ipò lọ́gàálọ́gàá tó ṣòro láti kọ̀ lọ̀ mí; mo gbà á, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti túbọ̀ máa gun àkàbà ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. Ojúṣe mi tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i níbi iṣẹ́ ò jẹ́ kí n fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Nígbà tó yá mi ò tiẹ̀ wàásù mọ́ rárá.”
Nígbà tó ronú padà sẹ́yìn, Amy ṣàlàyé pé: “Mo rí towó ṣe lóòótọ́. Mo máa ń rìnrìn àjò gan-an, mo sì ń jẹ̀gbádùn ipò ọlá tí mo wà torí mo mọ iṣẹ́ tí mò ń ṣe dunjú. Síbẹ̀ mi ò láyọ̀. Owó tí mo ní bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kò tán ìṣòro mi tó lọ jàáǹtìrẹrẹ. Ohun tó wá ń ṣẹlẹ̀ ò yé mi mọ́. Nígbà tó yá ni mo wá rí i pé, ipò ọlá tí mò ń lé nínú ayé ti jẹ́ kí n fẹ́rẹ̀ ‘ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́.’ Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, mò ń jẹ ‘ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora.’”—1 Tím. 6:10.
Kí ni Amy wá ṣe? Ó sọ pé: “Mo sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ kí n lè padà sún mọ́ Ọlọ́run, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé. Lọ́jọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí sunkún nígbà tá à ń kọrin lọ́wọ́. Mo rántí bínú mi ṣe máa ń dùn tó ní gbogbo ọdún márùn-ún tí mo fi wàásù gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lówó lọ́wọ́ nígbà yẹn. Mo wá rí i pé, kò yẹ kí n máa fàkókò mi ṣòfò nítorí àtidi olówó ọ̀sán gangan, àti pé ó yẹ kí n fàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Mo wá ní kí wọ́n fi mí sípò tó rẹlẹ̀ níbi iṣẹ́, èyí tó já sí pé owó oṣù mi ò ní máa ju ìdajì ti tẹ́lẹ̀ lọ mọ́, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wàásù.” Inú Amy dùn láti sọ pé: “Mo láyọ̀ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mélòó kan. Mo ti wá ní irú ìfọ̀kànbalẹ̀ tí mi ò ní nígbà tí mo ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò mi ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.”
Ṣé ìwọ náà á tún ọ̀ràn ara ẹ yẹ̀ wò, kó o má sì ṣe ju bó o ti mọ lọ? Tó o bá wá ń lo àkókò tó máa yọ sílẹ̀ fún ẹ láti ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ, ìwọ náà ti yan ohun tó sàn jù nìyẹn.—Òwe 10:22.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Ṣé ìwọ náà á tún ọ̀ràn ara ẹ yẹ̀ wò, kó o má sì ṣe ju bó o ti mọ lọ?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
“Mo Ti Ń Gbádùn Ẹ̀ Gan-an!”
Ó wu Arákùnrin David, tó jẹ́ alàgbà níjọ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, pé kóun náà máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé bíi ti ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. Ó wá ṣètò nílé iṣẹ́ tó ti ń ṣiṣẹ́ pé kí wọ́n dín wákàtí tóun fi ń ṣiṣẹ́ kù, èyí sì jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ṣé David yan ohun tó sàn jù báyìí? Nínú lẹ́tà tó kọ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ lóṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ní: “Kò sí nǹkan míì tó fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn máa fi gbogbo àkókò ẹ̀ sin Jèhófà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Mo rò pé ó máa gbà mí lákòókò díẹ̀ kíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó mọ́ mi lára ni, àmọ́ mo ti ń gbádùn ẹ̀ gan-an! Ó tù mí lára púpọ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Marc àti Paula rèé lóde ẹ̀rí