ORÍ KEJÌ
Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
1, 2. (a) Báwo ni Jesu ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwéwèé? (b) Ní àgbègbè wo ní pàtàkì ni ìwéwèé tí ṣe kókó?
KÍKỌ́ ilé ń béèrè fún ìmúrasílẹ̀ dáradára. Ṣáájú kí a tó fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, a ní láti ra ilẹ̀, kí a sì yàwòrán ilé. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan tún ṣe kókó. Jesu sọ pé: “Ta ni ninu yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì gbéṣiròlé ìnáwó naa, lati rí i bí oun bá ní tó lati parí rẹ̀?”—Luku 14:28.
2 Ohun tí ó bá kíkọ́ ilé bá kíkọ́ ìgbéyàwó aláṣeyọrí pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ ń sọ pé: “Mo fẹ́ ṣègbéyàwó.” Ṣùgbọ́n, ẹni mélòó ní ń sinmẹ̀dọ̀ láti gbé ohun tí yóò ná an yẹ̀ wò? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bibeli sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ìgbéyàwó, ó tún pe àfiyèsí sórí àwọn ìpèníjà tí ìgbéyàwó máa ń mú wá. (Owe 18:22; 1 Korinti 7:28) Nítorí náà, àwọn tí ń wéwèé láti ṣègbéyàwó ní láti ní ojú ìwòye bí nǹkan ṣe rí gán-an nípa àwọn ìbùkún ìgbéyàwó àti àwọn ohun tí ń náni.
3.Èé ṣe tí Bibeli fi jẹ́ àrànṣe ṣíṣeyebíye fún àwọn tí ń wéwèé láti ṣègbéyàwó, àwọn ìbéèrè mẹ́ta wo ni yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn?
3 Bibeli lè ṣèrànwọ́. Jehofa Ọlọrun, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, ni ó mí sí àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀. (Efesu 3:14, 15; 2 Timoteu 3:16) Ní lílo àwọn ìlànà tí ó wà nínú ìwé atọ́nisọ́nà ògbólógbòó, ṣùgbọ́n tí ó bá ìgbà mu yìí, ẹ jẹ́ kí a pinnu (1) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè mọ̀ bí òún bá ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó? (2) Àwọn ànímọ́ wo ni ó yẹ kí a wá lára alábàáṣègbéyàwó kan? àti (3) Báwo ni a ṣe lè mú kí ìfẹ́sọ́nà ní ọlá?
O HA TI ṢE TÁN LÁTI ṢÈGBÉYÀWÓ BÍ?
4.Kí ni kókó pàtàkì kan ní bíbá ìgbéyàwó aláṣeyọrí nìṣó, èé sì ti ṣe?
4 Kíkọ́ ilé kan lè gba ìnáwó púpọ̀, ṣùgbọ́n bíbójú tó o lẹ́yìn náà gba ìnáwó púpọ̀ bákan náà. Bí ó ṣe rí pẹ̀lú ìgbéyàwó nìyẹn. Ṣíṣègbéyàwó fúnra rẹ̀ jẹ́ ìpènijà ńlá; bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ gbé bíbá ipò ìbátan ìgbéyàwó nìṣó láti ọdún dé ọdún yẹ̀ wò bákan náà. Kí ni bíbá irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ nìṣó ní nínú? Ẹ̀jẹ́ àdéhùn àtọkànwá jẹ́ kókó pàtàkì kan. Bí Bibeli ṣe ṣàpèjúwe ipò ìbátan ìgbéyàwó nìyí: ‘Ọkùnrin yóò máa fi bàbá òun ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀: Wọn óò sì di ara kan.’ (Genesisi 2:24) Jesu Kristi pèsè ìdí kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fi lélẹ̀ fún ìkọ̀sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn—“àgbèrè,” ìyẹn ni, ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu lẹ́yìn òde ìgbéyàwó. (Matteu 19:9) Ní àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí lọ́kàn, bí o bá ń wéwèé láti ṣègbéyàwó. Bí o kò bá tí ì ṣe tán láti wọnú ẹ̀jẹ́ àdéhùn mímọ́ yìí, nígbà náà, o kò tí ì ṣe tán láti ṣègbéyàwó.—Deuteronomi 23:21; Oniwasu 5:4, 5.
5. Bí ẹ̀jẹ́ àdéhùn ìgbéyàwó tilẹ̀ ń já àwọn kan láyà, èé ṣe tí àwọn tí ó fẹ́ẹ́ ṣègbéyàwó fi ní láti mọyì rẹ̀ gidigidi?
5 Èrò ẹ̀jẹ́ àdéhùn mímọ́ ń já ọ̀pọ̀ ènìyàn láyà. Ọ̀dọ́kùnrin kan jẹ́wọ́ pé: “Ní mímọ̀ pé a ti so àwa méjèèjì pọ̀ títí lọ gbére, mú kí n nímọ̀lára pé a ti ká mi lọ́wọ́ kò, a ti dè mí mọ́lẹ̀, a sì ti sé mi mọ́ pátápátá.” Ṣùgbọ́n, bí o bá nífẹ̀ẹ́ ẹni tí o fẹ́ẹ́ fẹ́ ní tòótọ́, ẹ̀jẹ́ àdéhùn kì yóò dà bí ẹrù ìnira. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń fọkàn ẹni balẹ̀. Òye ẹ̀jẹ́ àdéhùn nínú ìgbéyàwó yóò jẹ́ kí tọkọtaya kan fẹ́ láti wà pọ̀ nígbà dídùn àti nígbà kíkan, àti láti ti ara wọn lẹ́yìn, láìka ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí. Kristian aposteli Paulu kọ̀wé pé, ìfẹ́ tòótọ́ “a máa mú ohun gbogbo mọ́ra,” a sì “máa farada ohun gbogbo.” (1 Korinti 13:4, 7) Obìnrin kan sọ pé: “Ẹ̀jẹ́ àdéhùn ìgbéyàwó túbọ̀ fọkàn mi balẹ̀. Mo fẹ́ràn ìtùnú tí jíjẹ́wọ́ fún ara wa àti fún aráyé pé, a ní in lọ́kàn láti wà pọ̀ tímọ́tímọ́, ń mú wá.”—Oniwasu 4:9-12.
6. Èé ṣe tí kò fi dára láti sáré kó wọnú ìgbéyàwó ní kékeré?
6 Mímú irú ẹ̀jẹ́ àdéhùn bẹ́ẹ̀ ṣẹ ń béèrè ìdàgbàdénú. Nítorí èyí, Paulu gbani nímọ̀ràn pé, àwọn Kristian ṣe dáradára láti má ṣègbéyàwó títí tí wọ́n yóò fi “rékọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” àkókò tí ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ ń lágbára, tí ó sì lè da ènìyàn lọ́kàn rú. (1 Korinti 7:36) Àwọn ọ̀dọ́ máa ń tètè yí padà, bí wọ́n ti ń dàgbà. Ọ̀pọ̀ tí ó ṣègbéyàwó nígbà tí wọ́n kéré púpọ̀, rí i pé, ìfẹ́ ọkàn àti àìní wọn, àti ti alábàáṣègbéyàwó wọn, ti yí padà lẹ́yìn iye ọdún díẹ̀ péré. Ìṣirò ṣí i payá pé, ó ṣeé ṣe púpọ̀ pé kí àwọn ọ̀dọ́langba, tí ó ṣègbéyàwó máà láyọ̀, kí wọ́n sì wá ọ̀nà àtikọ ara wọn sílẹ̀, ju àwọn tí ó dúró díẹ̀ sí i lọ. Nítorí náà, má ṣe sáré kó wọnú ìgbéyàwó. Ọdún díẹ̀ tí o bá lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, àgbà àpọ́n, lè mú kí o nírìírí tí ó ṣeyebíye, tí yóò mú kí o túbọ̀ dàgbà dénú dáradára sí i, kí o sì túbọ̀ tóótun láti jẹ́ alábàáṣègbéyàwó yíyẹ wẹ́kú. Sísún ìgbéyàwó síwájú tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ara rẹ—ohun kan tí ó pọn dandan bí ìwọ yóò bá mú ìbátan aláṣeyọrí dàgbà nínú ìgbéyàwó rẹ.
KỌ́KỌ́ MỌ ARA RẸ NÁ
7. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn tí ń wéwèé láti ṣègbéyàwó kọ́kọ́ yẹ ara wọn wò ná?
7 Ó ha rọrùn fún ọ láti to àwọn ànímọ́ tí o fẹ́ kí alábàáṣègbéyàwó rẹ ní lẹ́sẹẹsẹ bí? Ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ànímọ́ tìrẹ ńkọ́? Àwọn ànímọ́ wo ni o ní, tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi kún ìgbéyàwó aláṣeyọrí? Irú ọkọ tàbí aya wo ni ìwọ yóò jẹ́? Fún àpẹẹrẹ, o ha máa ń yára gba àṣìṣe rẹ, tí o sì ń gba ìmọ̀ràn, tàbí o ha máa ń fìgbà gbogbo jiyàn nígbà tí a bá tún ojú ìwòye rẹ ṣe? O ha jẹ́ ọlọ́yàyà àti olùfojúsọ́nà fún rere, tàbí o ha máa ń dijú koko, tí o sì máa ń tètè ṣàròyé bí? (Owe 8:33; 15:15) Rántí pé, ìgbéyàwó kì yóò yí ìwà rẹ padà. Bí o bá jẹ́ agbéraga, akanragógó tàbí ẹlẹ́mìí nǹkan yóò burú, nígbà tí o jẹ́ àpọ́n, bí o ṣe máa rí nìyẹn nígbà tí o bá ṣègbéyàwó. Níwọ̀n bí ó ti ṣòro láti rí ara wa bí àwọn ẹlòmíràn ti rí wa, èé ṣe tí o kò fi bi òbí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ kan tí o fọkàn tẹ̀ láti sọ bí o ṣe rí ní ti gidi fún ọ, kí ó sì gbà ọ́ nímọ̀ràn? Bí o bá mọ àwọn ibi tí o ti nílò àtúnṣe, ṣiṣẹ́ lórí àwọn wọ̀nyí ṣáájú gbígbégbèésẹ̀ láti ṣègbéyàwó.
8-10. Ìmọ̀ràn wo ní Bibeli fúnni tí yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó?
8 Bibeli rọ̀ wá láti jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun ṣiṣẹ́ nínú wa, ní mímú àwọn ànímọ́ bí “ìfẹ́, ìdùnnú-ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inúrere, ìwàrere, ìgbàgbọ́, ìwàtútù, ìkóra-ẹni-níjàánu” jáde. Ó tún sọ fún wa láti “di titun ninu ipá tí ń mú èrò-inú [wa] ṣiṣẹ́,” kí a sì “gbé àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin.” (Galatia 5:22, 23; Efesu 4:23, 24) Fífi ìmọ̀ràn yìí sílò nígbà tí o ṣì jẹ́ àpọ́n yóò dà bíi fífowó pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́sí—ohun kan tí yóò já sí iyebíye lọ́jọ́ iwájú, nígbà tí o bá ṣègbéyàwó.
9 Fún àpẹẹrẹ, bí o bá jẹ́ obìnrin, kọ́ láti túbọ̀ fiyè sí jíjẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” ju sórí ìrísí òde ara rẹ lọ. (1 Peteru 3:3, 4) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n, tí ó jẹ́ “adé ẹwà” ní tòótọ́. (Owe 4:9, NW; 31:10, 30; 1 Timoteu 2:9, 10) Bí o bá jẹ́ ọkùnrin, kọ́ láti fi inú rere àti ọ̀wọ̀ bá àwọn obìnrin lò. (1 Timoteu 5:1, 2) Bí o ti ń kọ́ láti ṣèpinnu àti láti gba ẹrù iṣẹ́, kọ́ láti jẹ́ olùmẹ̀tọ́mọ̀wà àti onírẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú. Níní ìṣarasíhùwà ìfipájẹgàba léni lórí yóò mú ìṣòro wá nínú ìgbéyàwó.—Owe 29:23; Mika 6:8; Efesu 5:28, 29.
10 Bí yíyí èrò inú wa padà ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí kò tilẹ̀ rọrùn, ó jẹ́ ohun tí gbogbo Kristian gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lé lórí. Yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ alábàáṣègbéyàwó tí ó sunwọ̀n.
ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÍ Ó YẸ KÍ O WÁ LÁRA ALÁBÀÁṢÈGBÉYÀWÓ KAN
11, 12. Báwo ni ẹni méjì ṣe lè wádìí bóyá wọ́n bára mu tàbí wọn kò bára mu?
11 Ó ha jẹ́ àṣà níbi tí o ń gbé fún ẹnì kan láti yan alábàáṣègbéyàwó fúnra rẹ̀ bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbésẹ̀ wo ni ó yẹ kí o gbé, bí ọkàn rẹ bá fà mọ́ ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà kejì? Lákọ̀ọ́kọ́, bi ara rẹ pé, ‘Mo ha ní in lọ́kàn láti fẹ́ ẹ ní ti gidi bí?’ Ó jẹ́ ìwà ìkà gbáà láti ru ìmọ̀lára ẹnì kan sókè lásán nípa gbígbọ́kàn rẹ̀ lórí òfo. (Owe 13:12) Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé, ‘Mo ha wà ní ipò láti ṣègbéyàwó bí?’ Bí o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ní sí ìbéèrè méjèèjì, àwọn ìgbésẹ̀ tí ìwọ yóò gbé tẹ̀ lé e yóò yàtọ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àdúgbò. Ní àwọn ilẹ̀ kan, lẹ́yìn kíkíyè sí ẹni náà fún àwọn àkókò kan, o lè tọ̀ ọ́ lọ, kí o sì sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ jáde láti túbọ̀ mọra dáradára sí i. Bí ó bá kọ̀, má ṣe ranrí mọ́ ọn débi tí ìwọ yóò fi di ẹlẹ́tẹ̀ẹ́. Rántí pé, ẹni tọ̀hún pẹ̀lú lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu lórí ọ̀ràn yìí. Àmọ́ ṣá o, bí ó bá gbà, ẹ lè ṣètò láti jọ lo àkókò pọ̀ nínú àwọn ìgbòkègbodò pípegedé. Èyí yóò ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún ọ láti rí i bóyá yóò bọ́gbọ́n mu láti fẹ́ ẹni yìí.a Kí ni ó yẹ kí o máa wá níbi tí ọ̀ràn dé yìí?
12 Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, finú yàwòrán ohun èèlò orin méjì kan, bóyá dùùrù àti gìtá. Bí a bá dá ìró wọn dáradára, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè nìkan mú orin dídára jáde. Síbẹ̀, kí ní ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá tẹ méjèèjì pa pọ̀? Ìró wọn gbọ́dọ̀ bára mú. Ó rí bákan náà pẹ̀lú ìwọ àti ẹni tí o wéwèé láti fẹ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan yín lè ti ṣiṣẹ́ kára láti “darí” ìwà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Ṣùgbọ́n ìbéèrè náà nísinsìnyí ni wí pé: Ẹ ha ṣe rẹ́gí bí? Ní ọ̀rọ̀ míràn, ẹ ha bára mu bí?
13. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti fẹ́ ẹni tí kì í ṣe onígbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú rẹ sọ́nà?
13 Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀yin méjèèjì ní ìgbàgbọ́ àti ìlànà kan náà. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba sopọ̀mọ́ra sábẹ́ àjàgà pẹlu awọn aláìgbàgbọ́.” (2 Korinti 6:14; 1 Korinti 7:39) Ṣíṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tí kò ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọrun, mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe pé kí ẹ máà ní ìṣọ̀kan rárá láàárín yín. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìfọkànsìn tí ẹ jọ ní sí Jehofa Ọlọrun ni ìpìlẹ̀ lílágbára jù lọ fún ìṣọ̀kan. Jehofa fẹ́ kí o láyọ̀, kí o sì gbádùn ìdè tí ó ṣe pẹ́kípẹ́kí jù lọ, tí ó ṣeé ṣe, pẹ̀lú ẹni tí o bá ṣègbéyàwó. Ó fẹ́ kí ẹ fi okùn ìfẹ́ oníkọ̀ọ́ mẹ́ta ṣe ara yín lọ́kan pẹ̀lú Òun àti pẹ̀lú ara yín.—Oniwasu 4:12.
14, 15. Níní ìgbàgbọ́ kan náà ha ni ohun kan ṣoṣo tí ń mú ìṣọ̀kan wá nínú ìgbéyàwó bí? Ṣàlàyé.
14 Nígbà tí jíjọ́sìn Ọlọrun pa pọ̀ jẹ́ apá pàtàkì jù lọ fún ìṣọ̀kan, ohun tí ó wé mọ́ ọn ju ìyẹn lọ. Láti bára mu, ìwọ àti ẹni tí o wéwèé láti fẹ́ gbọ́dọ̀ ní góńgó tí ó bára mu. Àwọn góńgó wo lẹ ní? Fún àpẹẹrẹ, kí ni èrò ẹ̀yin méjèèjì nípa ọmọ bíbí? Àwọn ohun wo ni ó gba ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé yín?b (Matteu 6:33) Nínú ìgbéyàwó aláṣeyọrí gidi, tọkọtaya jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà, wọ́n sì ń gbádùn jíjọ wà pa pọ̀. (Owe 17:17) Láti lè ṣe èyí, ìfẹ́ ọkàn wọ́n ní láti ṣọ̀kan. Ó ṣòro láti máa bá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ nìṣó—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ìgbéyàwó—bí ìfẹ́ ọkàn kò bá ṣọ̀kan. Síbẹ̀, bí ẹnì kejì rẹ lọ́la bá gbádùn ìgbòkègbodò pàtó kan, bíi rírìnrìn-in gbẹ̀fẹ́, tí ìwọ kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹ́n ha túmọ̀ sí pé, kò yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ ara yín? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Bóyá ẹ jọ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun mìíràn, tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, o lè mú ẹnì kejì rẹ lọ́la láyọ̀, nípa ṣíṣàjọpín nínú àwọn ìgbòkègbodò pípegedé nítorí ẹnì kejì rẹ gbádùn wọn.—Ìṣe 20:35.
15 Ní tòótọ́, dé ìwọ̀n gíga, a ń pinnu bí ẹ̀yin méjèèjì ṣe bára mu tó nípa bí ẹ ṣe mọwọ́ọ́ yí padà tó, kì í ṣe nípa bí ẹ ṣe ní ohun púpọ̀ ní ìjọra tó. Dípò bíbéèrè pé, “A ha máa ń fohùn ṣọ̀kan nínú gbogbo nǹkan bí?” àwọn ìbéèrè tí ó túbọ̀ dára jù lè jẹ́: “Kí ní ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a kò bá fohùn ṣọ̀kan? A ha máa ń yanjú ọ̀ràn ní pẹ̀lẹ́tù, ní fífi ọ̀wọ̀ àti iyì fún ara wa? Tàbí àwọn ìjíròrò wa ha máa ń yọrí sí ìjiyàn ńlá?” (Efesu 4:29, 31) Bí o bá fẹ́ láti ṣègbéyàwó, ṣọ́ra fún ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ agbéraga àti eléròo-tèmi-nìkan-ṣáá, tí kì í ṣe tán láti fohùn ṣọ̀kan, tàbí tí ń fìgbà gbogbo béèrè nǹkan ṣáá, tí ó sì ń pète láti ṣe nǹkan ní ọ̀nà tirẹ̀.
ṢÈWÁDÌÍ ṢÁÁJÚ
16, 17. Kí ni yẹ kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan máa wá lára ẹni tí ó ń wéwèé láti fẹ́?
16 Nínú ìjọ Kristian, a ní láti “kọ́kọ́ dán” àwọn tí a fún ní ẹrù iṣẹ́ “wò níti bí wọn ti yẹ sí.” (1 Timoteu 3:10) Ìwọ pẹ̀lú lè lo ìlànà yìí. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan lè béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni a mọ ọkùnrin yìí sí? Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ó ha ń fi ìkóra-ẹni-níjàánu hàn bí? Báwo ni ó ṣe ń hùwà sí àwọn àgbàlagbà? Irú ìdílé wo ni ó ti wá? Báwo ni ó ṣe ń bá wọn lò? Kí ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ nípa owó? Ó ha jẹ́ onímukúmu bí? Ó ha máa ń tètè bínú, tí ó sì máa ń fara ya pàápàá? Àwọn ẹrù iṣẹ́ wo ni ó ní nínú ìjọ, báwo ni ó sì ṣe ń bójú tó wọn? Mo ha lè ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un bí?”—Lefitiku 19:32; Owe 22:29; 31:23; Efesu 5:3-5, 33; 1 Timoteu 5:8; 6:10; Titu 2:6, 7.
17 Ọkùnrin kan lè béèrè pé, “Obìnrin yìí ha ń fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún Ọlọrun bí? Ó ha tóótun láti bójú tó ilé bí? Kí ni àwọn ìdílé rẹ̀ yóò retí lọ́dọ̀ wa? Ó ha jẹ́ ọlọgbọ́n, òṣìṣẹ́, ẹni tí ó mowó ṣún ná bí? Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń dá lé lórí? Ire àwọn ẹlòmíràn ha máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn ní ti gidi, tàbí anìkànjọpọ́n, alátojúbọ̀ ni? Ó ha ṣeé gbọ́kàn lé bí? Ó ha múra tán láti tẹrí ba fún ipò orí, tàbí olóríkunkun, ọlọ̀tẹ̀ paraku ni?”—Owe 31:10-31; Luku 6:45; Efesu 5:22, 23; 1 Timoteu 5:13; 1 Peteru 4:15.
18. Bí a bá kíyè sí àwọn àìlera tí kò tó nǹkan nígbà ìfẹ́sọ́nà, kí ni a ní láti gbé yẹ̀ wò?
18 Má ṣe gbàgbé pé aláìpé ọmọ Adamu ni o ń bá da nǹkan pọ̀, kì í ṣe akọni kan tí a hùmọ̀ nínú ìwé ìtàn eléré ìfẹ́. Gbogbo ènìyàn ni ó ní ìkùdíẹ̀-kí-à-tó tirẹ̀, a sì ní láti gbójú fo díẹ̀ lára ìwọ̀nyí dá—níhà tìrẹ àti níhà ẹnì kejì rẹ lọ́la. (Romu 3:23; Jakọbu 3:2) Síwájú sí i, àìlera kan tí a kíyè sí lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti dàgbà sí i. Fún àpẹẹrẹ, kí á sọ pé, ẹ jiyàn lórí ohun kan, nígbà tí ẹ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Ronú ná: Àní àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ fún ara wọn pàápàá, kì í fohùn ṣọ̀kan nígbà míràn. (Fi wé Genesisi 30:2; Ìṣe 15:39.) Ó ha lè jẹ́ pé, ẹ̀yin méjèèjì wulẹ̀ nílò láti túbọ̀ ‘ṣàkóso ara yín,’ kí ẹ sì kọ́ láti yanjú àwọn ọ̀ràn ní pẹ̀lẹ́tù ni bí? (Owe 25:28) Ẹni tí o ń wéwèé láti fẹ́ ha fi ìfẹ́ ọkàn hàn láti ṣàtúnṣe bí? Ìwọ ńkọ́? Ẹ ha lè kọ́ láti jẹ́ ẹni tí kì í kanra, tí kì í tètè bínú bí? (Oniwasu 7:9) Kíkọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro lè fìdí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláìlábòsí, tí ó ṣe kókó bí ẹ̀yin méjèèjì bá fẹ́ra yín, múlẹ̀.—Kolosse 3:13.
19. Ìgbésẹ̀ wo ni yóò bọ́gbọ́n mu láti gbé nígbà tí àwọn ìṣòro rírinlẹ̀ bá yọjú nígbà ìfẹ́sọ́nà?
19 Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá kíyè sí àwọn ohun tí ń yọ ọ́ lẹ́nu gan-an ńkọ́? Ó yẹ kí o gba àwọn iyè méjì náà yẹ̀ wò dáradára. Láìka bí òòfà ìfẹ́ rẹ ti ga tó, tàbí bí o ti ń hára gàgà láti ṣègbéyàwó tó sí, má ṣe pajú rẹ dé sí àwọn àléébù burúkú. (Owe 22:3; Oniwasu 2:14) Bí o bá ní ipò ìbátan pẹ̀lú ẹnì kan tí o kò nífẹ̀ẹ́ sí ìwà rẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu láti fòpin sí ipò ìbátan náà, kí o sì yẹra fún jíjẹ́jẹ̀ẹ́ àdéhùn mímọ́ pẹ̀lú ẹni náà.
Ẹ JẸ́ KÍ ÌFẸ́SỌ́NÀ YÍN LỌ́LÁ
20. Báwo ni ọkùnrin àti obìnrin tí ń fẹ́ra sọ́nà ṣe lè pa ìwà wọn mọ́ láìlẹ́gàn?
20 Báwo ni ẹ ṣe lè jẹ́ kí ìfẹ́sọ́nà yín lọ́lá? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ rí i dájú pé ẹ pa ìwà yín mọ́ láìlẹ́gàn. Ní ibi tí ẹ ń gbé, a ha ka dídi ọwọ́ mú, fífẹnu konu, tàbí gbígbáni mọ́ra sí ìwà tí ó bójú mu fún ọkùnrin àti obìnrin tí kò tí ì ṣègbéyàwó bí? Àní bí a kò bá tilẹ̀ dẹ́bi fún irú àwọn ìfìfẹ́hàn bẹ́ẹ̀ pàápàá, ẹ lè fi wọ́n hàn kìkì nígbà tí ipò ìbátan yín bá ti dé ibi ti ẹ ti ń wéwèé láti ṣègbéyàwó. Ẹ lo ìṣọ́ra, kí fífi ìfẹ́ hàn yín má baà yọrí sí ìwà àìmọ́ tàbí àgbèrè pàápàá. (Efesu 4:18, 19; fi wé Orin Solomoni 1:2; 2:6; 8:5, 9, 10.) Nítorí pé ọkàn-àyà ń tanni jẹ, ẹ̀yin méjèèjì yóò jẹ́ ọlọgbọ́n láti yẹra fún wíwà ní ẹ̀yin nìkan nínú ilé, níbi àdágbé, nínú ọkọ̀ tí a gbé kalẹ̀, tàbí níbikíbi mìíràn tí yóò ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti hùwà àìmọ́. (Jeremiah 17:9) Mímú kí ìwà rẹ wà ní mímọ́ nígbà tí ẹ ń fẹ́ra yín sọ́nà ń fi ẹ̀rí hàn kedere pé o ní ìkóra-ẹni-níjàánu àti pé o fi àníyàn aláìmọtara-ẹni-nìkan fún ire ẹnì kejì rẹ ṣáájú ìfẹ́ ọkàn tìrẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́sọ́nà mímọ́ tí kò lábàwọ́n yóò dùn mọ́ Jehofa Ọlọrun, tí ó pa á láṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti yẹra fún ìwà àìmọ́ àti àgbèrè, nínú.—Galatia 5:19-21.
21. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláìlábòsí wo ni a lè nílò láti lè pa ìfẹ́sọ́nà tí ó lọ́lá mọ́?
21 Ìkejì, ìfẹ́sọ́nà tí ó lọ́lá tún ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláìlábòsí nínú. Bí ìfẹ́sọ́nà yín ti ń tẹ̀ síwájú sí ìgbéyàwó, ẹ ní láti jíròrò àwọn ọ̀ràn kan láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Níbo ni ẹ óò gbé? Ṣé ẹ̀yin méjèèjì ni ẹ óò máa ṣiṣẹ́? Ṣé ẹ fẹ́ẹ́ bímọ? Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó dára kí ẹ mú àwọn ohun tí ó lè nípa lórí ìgbéyàwó yín, bóyá nípa ara yín ní àkókò tí ó ti kọjá, wá sójútáyé. Àwọn wọ̀nyí lè kan gbèsè ńlá tàbí ojúṣe tàbí ọ̀rọ̀ ìlera, irú bí àrùn tàbí ipò burúkú tí o lè ní. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ní àkóràn HIV (fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS) ni àmì àrùn náà kì í tètè hàn lára wọn, ó tọ̀nà fún ẹnì kan tàbí fún àwọn òbí tí ó bìkítà láti béèrè pé kí ẹnì kan tí ó ti fìgbà kan jẹ́ oníṣekúṣe tàbí tí ń gún ara rẹ̀ lábẹ́rẹ́ oògùn líle, lọ yẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò bóyá ó ní àrùn AIDS. Bí àyẹ̀wò náà bá fi hàn pé ó ní in, ẹni tí ó ní àkóràn náà kò gbọdọ̀ fagbára mú ẹni tí ó ń wéwèé láti fẹ́ náà láti máa bá ìbátan náà nìṣó, bí onítọ̀hún bá fẹ́ láti fòpin sí i. Lóòótọ́, ẹnì kan tí ó ti fìgbà kan jẹ́ oníṣekúṣe yóò ṣe dáradára láti finnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti lọ yẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò bóyá ó ní àrùn AIDS, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà.
WÍWÒ RÉ KỌJÁ ỌJỌ́ ÌGBÉYÀWÓ
22, 23. (a) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè sọ ojú ìwòye wíwà déédéé nù nígbà tí ó bá ń múra sílẹ̀ fún ayẹyẹ ìgbéyàwó? (b) Ojú ìwòye wíwà déédéé wo ni ó yẹ kí a dì mú nígbà tí a bá ń gbé ayẹyẹ ìgbéyàwó àti ìgbéyàwó yẹ̀ wò?
22 Ní àwọn oṣù tí ó kẹ́yìn sí ọjọ́ ìgbéyàwó yín, ó ṣeé ṣe kí ọwọ́ ẹ̀yin méjèèjì há gádígádí nítorí ìṣètò fún ọjọ́ ìgbéyàwó yín. Ẹ lè dín pákáǹleke náà kù nípa wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ayẹyẹ ìgbéyàwó pọ̀pọ̀ṣìnṣìn lè dùn mọ́ àwọn ìbátan àti àwọn aládùúgbò nínú, ṣùgbọ́n, ó lè mú kí ó tán tọkọtaya ọ̀ṣìngín àti àwọn ìdílé wọn lókun, kí ó sì gbọ́n àpò wọn gbẹ táútáú. Títẹ̀ lé àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan bọ́gbọ́n mu, ṣùgbọ́n títẹ̀ lé wọn bí ẹrú, àti bóyá fífẹ́ láti bẹ́gbẹ́ dọ́gba lè mú kí o sọ ète ìṣẹ̀lẹ̀ náà nù, ó sì lè fi ayọ̀ tí ó yẹ kí o ní dù ọ́. Bí ẹ tilẹ̀ ní láti gba ìmọ̀lára àwọn mìíràn yẹ̀ wò, ọkọ ìyàwó ni ó ni ẹrù iṣẹ́ náà ní pàtàkì láti pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ibi ayẹyẹ ìyàwó náà.—Johannu 2:9.
23 Rántí pé ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ kò ju ọjọ́ kan lọ, ṣùgbọ́n ìgbéyàwó rẹ wà títí lọ gbére. Yẹra fún kíkó àfiyèsí púpọ̀ jù sórí ọjọ́ ìgbéyàwó. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbára lé Jehofa Ọlọrun fún ìtọ́sọ́nà, kí o sì wéwèé ṣáájú fún ìgbésí ayé lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó. Nígbà náà, ìwọ yóò ti múra sílẹ̀ dáradára fún ìgbéyàwó aláṣeyọrí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí yóò ṣeé fi sílò ní àwọn ilẹ̀ tí a ti ka bíbá ẹ̀yà kejì ròde sí ohun tí ó bójú mu fún Kristian.
b Ní àwọn ìjọ Kristian pàápàá, àwọn kan lè wà tí wọ́n jẹ́ afàwọ̀rajà, kí a sọ ọ́ ní ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Dípò jíjẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun tí ń sìn tọkàntara, àwọn ìṣarasíhùwà àti ìwà ayé lè ti nípa lórí wọn.—Johannu 17:16; Jakọbu 4:4.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ẸNÌ KAN LÁTI MÚRA SÍLẸ̀ FÚN ÌGBÉYÀWÓ ALÁṢEYỌRÍ?
Ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ wà pa pọ̀.—Genesisi 2:24.
Ẹni tí a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ìrísí òde lọ.—1 Peteru 3:3, 4.
“Ẹ máṣe fi àìdọ́gba sopọ̀mọ́ra sábẹ́ àjàgà.”—2 Korinti 6:14.
A sọ àwọn tí ìwà wọn kò mọ́ dàjèjì sí Ọlọrun.—Efesu 4:18, 19.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
ÀWỌN ÀṢÀ ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ ÀTI BIBELI
Owó Ìdána àti Dáórì: Ní àwọn ilẹ̀ kan, a retí pé kí àwọn ìdílé ọkọ fún àwọn ìdílé ìyàwó lówó (owó ìdána). Ní ìbomíràn, ìdílé ìyàwó ń fún ìdílé ọkọ lówó (dáórì). Ó lè máà sí ohun tí ó lòdì nípa àwọn àṣà ìbílẹ̀ wọ̀nyí, níwọ̀n bí wọ́n bá ti bá òfin mu. (Romu 13:1) Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ọ̀ràn èyíkéyìí nínú méjèèjì, ìdílé tí a ń fún lówó gbọ́dọ̀ yẹra fún fífi ìwọra béèrè fún owó tàbí ẹrù púpọ̀ sí i, ju bí ó ti bọ́gbọ́n mu lọ. (Owe 20:21; 1 Korinti 6:10) Síwájú sí i, a kò gbọ́dọ̀ túmọ̀ sísan owó ìdána sí pé aya jẹ́ ohun ìní tí a fowó rà; ọkọ kò sì gbọ́dọ̀ ronú pé ojúṣe kan ṣoṣo tí òún ní sí aya òun àti àwọn àna òun jẹ́ ti ìnáwó.
Ìkóbìnrinjọ: Àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan yọ̀ǹda kí ọkùnrin kan ní ju ìyàwó kan lọ. Ní irú àyíká bẹ́ẹ̀, a lè sọ ọkùnrin náà di baálẹ̀ dípò ọkọ àti bàbá. Síwájú sí i, ìkóbìnrinjọ máa ń ru ìdíje sókè láàárín àwọn aya. Fún àwọn Kristian, wíwà ní àpọ́n tàbí jíjẹ́ ọkọ aya kan nìkan ṣoṣo ni Bibeli fàyè gbà.—1 Korinti 7:2.
Ìgbéyàwó Jẹ́-Kí-A-Gbìyànjú-Rẹ̀-Wò-Ná: Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń fẹ́ra wọn ṣàwáwí pé gbígbé pọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó yóò ran àwọn lọ́wọ́ láti dán ìbáramu àwọn wò. Síbẹ̀, ìgbéyàwó jẹ́-kí-a-gbìyànjú-rẹ̀-wò-ná kì í dán ọ̀kan lára àwọn ohun ṣíṣe kókó jù lọ nínú ìgbéyàwó wò—ẹ̀jẹ́ àdéhùn. Kò sí ètò kankan tí ń fúnni ní irú ààbò àti ìfọkànbalẹ̀ kan náà tí ìgbéyàwó ń fi fún gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn—títí kan àwọn ọmọ tí ó lè tinú ìsopọ̀ náà wá. Ní ojú Jehofa Ọlọrun, gbígbé pọ̀ láìṣègbéyàwó jẹ́ àgbèrè.—1 Korinti 6:18; Heberu 13:4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Nígbà àpọ́n, mú àwọn ànímọ́, àṣà, àti agbára tí yóò ṣiṣẹ́ fún ọ dáradára nínú ìgbéyàwó dàgbà