Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
“Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 16:14.
1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn òbí nígbà tí wọ́n bá bímọ tuntun?
Ọ̀PỌ̀ òbí ló máa gbà pé ọ̀kan lára ohun tó ń múnú ẹni dùn jù lọ láyé ni kéèyàn bímọ tuntun. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Aleah sọ pé: “Bí mo ṣe ń wo ọmọbìnrin tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí báyìí, ṣe ni ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún mi. Ńṣe ló dà bíi pé òun lọ́mọ tuntun tó rẹwà jù lọ tí mo tíì rí rí.” Àmọ́ irú àkókò aláyọ̀ báyẹn tún lè kó àníyàn bá àwọn òbí. Ọkọ Aleah sọ pé: “Mò ń ronú bí mo ṣe lè tọ́ ọmọ mi lọ́nà táá fi lè ṣàṣeyọrí nínú gbogbo wàhálà ayé.” Ọ̀pọ̀ abiyamọ ló máa ń ṣe irú àníyàn bẹ́ẹ̀ wọ́n sì mọ̀ dájú pé àwọn ní láti kọ́ àwọn ọmọ àwọn tìfẹ́tìfẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni tó ń wù láti kọ́ àwọn ọmọ wọn tìfẹ́tìfẹ́ á kojú àwọn ìṣòro kan. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro yẹn?
2. Àwọn ìṣòro wo ló ń kojú àwọn òbí?
2 A ti sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan ìsinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn tí ò nífẹ̀ẹ́ ló kún inú ayé tá a wà yìí. Kódà láàárín ìdílé, àwọn èèyàn kì í lo “ìfẹ́ àdánidá” wọn sì ti ya “aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò.” (2 Tímótì 3:1-5) Bó ṣe jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni nǹkan ń dà wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń hu irú ìwà wọ̀nyí, ó lè mú káwọn tó wà nínú ìdílé Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í hu irú àwọn ìwà yẹn síra wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí náà ní àìpé tiwọn tí wọ́n jogún, èyí tí wọ́n ń bá yí, ó sì lè mú káwọn náà ṣàìlo ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà míì, tí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé á fi jábọ́ lẹ́nu wọn tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan míì láìronújinlẹ̀.—Róòmù 3:23; Jákọ́bù 3:2, 8, 9.
3. Báwo làwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi láyọ̀?
3 Lójú gbogbo ìṣòro yìí, àwọn òbí ṣì lè tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà táwọn ọmọ náà á fi láyọ̀ tí wọ́n á sì sún mọ́ Ọlọ́run. Báwo ni wọ́n á ṣe ṣe é? Bí wọ́n bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́” ni. (1 Kọ́ríńtì 16:14) Ìfẹ́ tá a sì ń sọ yìí “jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun mẹ́ta tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìfẹ́ nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ká sì wá jíròrò báwọn òbí ṣe lè lo ìfẹ́ yìí nínú bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn.—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.
Ó Yẹ́ Káwọn Òbí Ní Ìpamọ́ra
4. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí máa ní ìpamọ́ra?
4 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìpamọ́ra” túmọ̀ sí sùúrù àti àìtètè bínú. Kí nìdí táwọn òbí fi ní láti ní ìpamọ́ra? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí òbí tá a máa bi tí ò ní rí ọ̀pọ̀ nǹkan sọ. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ ná. Àwọn ọmọ máa ń ránnu mọ́ ohun tí wọ́n bá fẹ́. Kódà lẹ́yìn táwọn òbí bá ti jẹ́ kó yé àwọn ọmọ pé kò ṣeé ṣe, àwọn ọmọ á ṣì máa yọ wọ́n lẹ́nu nírètí pé àwọn òbí á gbà fáwọn tó bá yá. Àwọn ọ̀dọ́ lè máa jiyàn lọ pẹrẹu láti lè fi yé òbí wọn pé ó yẹ kó gbà wọ́n láyè láti ṣe ohun kan tí òbí náà mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu fún wọn láti ṣe. (Òwe 22:15) Ohun kàn sì wà tó ń ṣe gbogbo wa tó sì máa ń ṣe àwọn ọmọdé náà, ohun náà ni pé wọ́n lè máa ṣe àwọn àṣìṣe kan léraléra.—Sáàmù 130:3.
5. Kí ló máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra?
5 Kí ló lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra kí wọ́n sì máa mú sùúrù fún àwọn ọmọ wọn? Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Ẹ̀ ẹ́ túbọ̀ lóye ìwà àwọn ọmọ yín dáadáa tẹ́yin òbí bá rántí pé ìgbà kan wà tẹ́yin náà máa ń “ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Ẹ̀yin òbí, ṣẹ́ ẹ lè rántí ìgbà tẹ́ ẹ wà lọ́mọdé, tẹ́ ẹ ń yọ màmá tàbí bàbá yín lẹ́nu pé kí wọ́n ṣe nǹkan kan fún yín? Nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́, ṣé ìgbà kan wà tẹ́ ẹ ń rò pé ẹ mọ ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe, pé ọ̀rọ̀ yín ò kàn yé àwọn òbí yín ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kẹ́yin náà mọ̀dí táwọn ọmọ yín fi ń ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe àti ìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ máa mú sùúrù fún wọn kẹ́ ẹ sì máa rán wọn létí ìpinnu yín lemọ́lemọ́. (Kólósè 4:6) Ẹ sì kíyè sí i pé ohun tí Jèhófà sọ fáwọn òbí lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni pé kí wọ́n máa ‘fi ìtẹnumọ́ gbin’ òfin òun sínú àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “fi ìtẹnumọ́ gbìn” túmọ̀ sí “láti tún un sọ,” “láti sọ ọ́ léraléra,” “láti tẹ̀ ẹ́ mọ́ni lọ́kàn.” Èyí fi hàn pé àwọn òbí ní láti sọ ohun kan náà lọ́pọ̀ ìgbà kó tó di pé àwọn ọmọ á dẹni tó ń tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀kọ́ míì wà nígbèésí ayé téèyàn ní láti tẹnu mọ́ lọ́nà yẹn kó tó lè yé wọn.
6. Kí nìdí tí ìpamọ́ra òbí kò fi ní kó gbàgbàkugbà?
6 Àmọ́ ṣá, pé òbí ní ìpamọ́ra kò sọ pé kó máa gbàgbàkugbà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ pé: “Ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” Kí irú ìyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, òwe kan náà yẹn sọ pé: “Ọ̀pá àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni ohun tí ń fúnni ní ọgbọ́n.” (Òwe 29:15) Nígbà míì, àwọn ọmọ lè máa rò pé àwọn òbí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá àwọn wí. Ṣùgbọ́n a ò lè sọ ọ̀rọ̀ agboolé Kristẹni di ọ̀rọ̀ ìjọba tiwa-n-tiwa, bíi pé àwọn òbí ò lẹ́tọ̀ọ́ àtibá ọmọ tó ṣẹ̀ wí láìṣe pé ọmọ fọwọ́ sí i. Dípò bẹ́ẹ̀, Jèhófà tó jẹ́ Olórí gbogbo ìdílé pátápátá ti fún àwọn òbí láṣẹ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì bá wọn wí tìfẹ́tìfẹ́. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 3:15; 6:1-4) Kódà, ìbáwí tún tan mọ́ apá míì nínú ìfẹ́, èyí tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà.
Béèyàn Ṣe Lè Bá Ọmọ Wí Tìfẹ́tìfẹ́
7. Kí nìdí táwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ á fi bá àwọn ọmọ wọn wí, kí sì nirú ìbáwí yẹn túmọ̀ sí?
7 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “ìfẹ́ a máa ní . . . inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn lóòótọ́ máa ń bá àwọn ọmọ wọn wí, wọ́n sì máa ń dúró lórí ọ̀rọ̀ wọn. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni wọ́n fìwà jọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.” Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kíyè sí i pé irú ìbáwí tí Bíbélì ń sọ nípa rẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ fífìyàjẹni o. Ó túmọ̀ sí kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Kí nìdí tá a fi máa ń fún èèyàn nírú ìbáwí bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:6, 11) Báwọn òbí bá ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wọn yẹn á mú kí wọ́n di ẹlẹ́mìí àlàáfíà wọ́n á sì jẹ́ ọmọlúwàbí èèyàn nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Táwọn ọmọ bá sì gba “ìbáwí Jèhófà,” wọ́n á ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀. Ogún tó ṣeyebíye ju fàdákà àti wúrà lọ sì làwọn ànímọ́ yìí.—Òwe 3:11-18.
8. Kí ló sábà máa ń tẹ̀yìn ẹ̀ yọ táwọn òbí kì í bá bọ́mọ wọn wí?
8 Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn òbí tó bá fi ọmọ wọn sílẹ̀ láìsí ìbáwí ò nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ náà. Jèhófà mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.” (Òwe 13:24) Báwọn òbí bá tọ́ ọmọ láìsí ìbáwí tó yẹ, ó ṣeé ṣe kí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ya ànìkànjọpọ́n àti òṣónú. Ní tàwọn òbí tó ń fọwọ́ ọ̀tún bọ́mọ wí láìgba gbẹ̀rẹ́ àmọ́ tí wọ́n tún ń fọwọ́ òsì fà á mọ́ra, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọ wọn máa ń ṣe dáadáa nílé ìwé, wọ́n sì máa ń lè bẹ́gbẹ́ pé, ìbànújẹ́ kì í sì í jọba lọ́kàn wọn. Torí náà, ó dájú pé àwọn òbí tó bá ń bá àwọn ọmọ wí ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn ni.
9. Kí làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, ojú wo sì ni àwọn ọmọ ní láti fi wo àwọn ìlànà wọ̀nyí?
9 Kí làwọn òbí ní láti ṣe tó máa fi hàn pé wọ́n ń fi ìfẹ́ bá ọmọ wí? Àwọn òbí ní láti máa ṣàlàyé fáwọn ọmọ wọn yékéyéké nípa ohun tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, láti kékeré làwọn Kristẹni ti máa ń kọ́ ọmọ wọn láwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kí wọ́n mọ̀ àti ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa kópa nínú onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Jèhófà. (Ẹ́kísódù 20:12-17; Mátíù 22:37-40; 28:19; Hébérù 10:24, 25) Ó yẹ káwọn ọmọ mọ̀ pé àwọn ohun tí Jèhófà ní ká ṣe yìí pọn dandan.
10, 11. Kì nìdí tó fi yẹ káwọn òbí máa gba tàwọn ọmọ rò nígbà tí wọ́n bá ń gbé òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé nínú ilé kalẹ̀?
10 Àmọ́ nígbà míì, àwọn òbí lè fẹ́ láti pe àwọn ọmọ wọn kí wọ́n jọ jíròrò nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé nínú ilé kalẹ̀. Báwọn ọ̀dọ́ bá lóhùn sí i nígbà tí wọ́n ń jíròrò òfin wọ̀nyẹn, wọ́n á túbọ̀ fẹ́ láti tẹ̀ lé irú òfin bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn. Bí àpẹẹrẹ, ká ní àwọn òbí pinnu láti dá gbèdéke lé aago tí wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ wọn máa wọlé, wọ́n lè yan aago kan tí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn ọmọ ti wà nínú ilé. Ẹ̀wẹ̀, ọ̀nà míì ni pé wọ́n lè ní káwọn ọmọ wọn dábàá iye aago kan kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò pé àkókò yẹn láwọn fẹ́ máa wọlé. Àwọn òbí náà wá lè sọ iye aago táwọn fẹ́ káwọn ọmọ náà ti wà nílé kí wọ́n sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi rò pé àkókò yẹn ló dáa jù. Ó ṣeé ṣe kí ìyàtọ̀ wà láàárín aago tó wu àwọn ọmọ àti aago táwọn òbí fẹ́, tó bá rí bẹ́ẹ̀ kí ni káwọn òbí ṣe? Láwọn ìgbà míì, àwọn òbí lè wò ó pé àwọn lè gba ohun táwọn ọmọ fẹ́ níwọ̀n bí kò bá ti ta ko ìlànà kankan nínú Bíbélì. Ṣéyẹn ò ní dà bíi pé àwọn ọmọ ló ń pàṣẹ fáwọn òbí?
11 Láti lè dáhùn ìbéèrè yẹn, wo ọ̀nà tí Jèhófà gbà lo àṣẹ rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́ nígbà tó fẹ́ pa Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn táwọn áńgẹ́lì ti sin Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ jáde kúrò ní Sódómù, wọ́n sọ fún un pé: “Sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá kí a má bàa gbá ọ lọ!” Àmọ́ Lọ́ọ̀tì fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀wọ́, Jèhófà!” Lọ́ọ̀tì wá dá àbá míì, ó ní: “Jọ̀wọ́, nísinsìnyí, ìlú ńlá yìí wà nítòsí láti sá lọ síbẹ̀, ó sì jẹ́ ohun kékeré. Jọ̀wọ́, ṣé kí n sá lọ síbẹ̀?” Kí wá ni Jèhófà fi dá a lóhùn? Jèhófà sọ fún un pé: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:17-22) Ṣé Jèhófà wá gbé àṣẹ rẹ̀ lé Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́ ni? Kò sóhun tó jọ ọ́! Síbẹ̀, ó gba ohun tí Lọ́ọ̀tì fẹ́, ó sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣe kọjá ohun tó yẹ kó ṣe fún Lọ́ọ̀tì. Bó o bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ àwọn ìgbà kan wà tó o lè gba tàwọn ọmọ rẹ rò nígbà tó o bá ń ṣe òfin tí ìdílé rẹ á máa tẹ̀ lé?
12. Kí ló máa mú kí ọkàn ọmọ balẹ̀?
12 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe òfin nìkan ló yẹ káwọn ọmọ mọ̀ o, ó tún yẹ kí wọ́n mọ ìyà tí wọ́n máa jẹ tí wọ́n bá rú òfin náà. Tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìyà tẹ́ni tó bá rúfin á jẹ, ẹ ní láti rí i pé ẹ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ yín. Káwọn òbí má ṣe rò pé ìfẹ́ làwọn ní sọ́mọ tó ń rúfin, tí wọ́n ń kìlọ̀ fún pé á jìyà, àmọ́ tí wọ́n ò jẹ́ kó jìyà ọ̀hún. Bíbélì sọ pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.” (Oníwàásù 8:11) Lóòótọ́, òbí lè máà fẹ́ bá ọmọ wí ní gbangba tàbí nígbà tó bá wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ torí kó má bàa dójú tì í. Àmọ́ ọkàn àwọn ọmọ á túbọ̀ balẹ̀, wọ́n á lè fún àwọn òbí wọn ní ọ̀wọ̀ púpọ̀ sí i, wọ́n á sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn sí i, báwọn òbí wọn bá jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” wọn jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, tí “Bẹ́ẹ̀ kọ́” wọn sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, kódà tó bá gba pé kí wọ́n bá wọn wí.—Mátíù 5:37.
13, 14. Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà lórí ọ̀ràn ọmọ títọ́?
13 Tí òbí bá fẹ́ bá ọmọ rẹ̀ wí tìfẹ́tìfẹ́, irú ìbáwí tó yẹ ọmọ náà ló yẹ kó fún un. Ìyá kan tó ń jẹ́ Pam sọ pé: “Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la máa ń gbà bá àwọn ọmọ wa méjèèjì wí. Bá a ṣe máa bá ọ̀kan wí táá gbọ́ yàtọ̀ sí bá a ṣe máa bá ìkejì wí.” Larry ọkọ ẹ̀ sọ pé: “Ohun tó bá ti wà nínú ọmọbìnrin wa àgbà ló máa ń fẹ́ ṣe, tá ò bá tíì fọwọ́ tó le mú un kò ní gbọ́. Àmọ́, ká tó bá àbúrò rẹ̀ obìnrin sọ̀rọ̀ báyìí, ó ti gbọ́; kódà béèyàn fojú bá a wí, ó ti yé e.” Torí náà, àwọn òbí tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn ní láti gbìyànjú kí wọ́n mọ irú ìbáwí tó yẹ ọmọ kọ̀ọ̀kan.
14 Àpẹẹrẹ Jèhófà ló yẹ káwọn òbí máa tẹ̀ lé, torí pé ó mọ ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti ń ṣe dáadáa àti ibi tó ti kù díẹ̀ káàtó fún wọn. (Hébérù 4:13) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jèhófà bá ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí, kì í ti àṣejù bọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í gbàgbàkugbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń bá wọn wí “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 30:11) Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀yin náà mọ ibi táwọn ọmọ yín ti lè ṣe dáadáa àti ibi tó ti kù díẹ̀ káàtó fún wọn? Ṣé ẹ máa ń fìyẹn sọ́kàn kẹ́ ẹ bàa lè tọ́ wọn sọ́nà bó ṣe yẹ? Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ yín.
Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Máa Sọ Tinú Wọn
15, 16. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa sọ òótọ́ tó wà lọ́kàn wọn, ọ̀nà wo làwọn òbí kan sì ti rí i pé ó dára láti gbà bójú tó ọ̀ràn yìí?
15 Apá míì tí ìfẹ́ ní ni pé “kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:6) Báwo làwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ ohun tó yẹ tó sì jẹ́ òtítọ́? Ohun pàtàkì kan tó yẹ kẹ́yin òbí máa ṣe ni pé kẹ́ ẹ máa rọ àwọn ọmọ yín láti máa sọ tinú wọn jáde, kódà bí ohun tí ọmọ yẹn sọ ò bá tiẹ̀ dùn mọ́ yín nínú. A mọ̀ pé inú àwọn òbí máa ń dùn nígbà táwọn ọmọ bá sọ èrò ọkàn wọn jáde tí ohun tí wọ́n sọ sì bá ìlànà òdodo Jèhófà mu. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ọmọ kan lè sọ ohun kan táá fi hàn pé èrò tí kò dáa kan wà lọ́kàn rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Kí ló yẹ kẹ́yin òbí ṣe nírú àkókò yẹn? Ó lè fẹ́ ṣe àwọn òbí bíi pé kí wọ́n bá ọmọ yẹn wí lójú ẹsẹ̀ torí ohun tó sọ yẹn. Àmọ́ táwọn òbí bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ò ní pẹ́ jágbọ́n pé káwọn máa sọ kìkì ohun tí wọ́n rò pé àwọn òbí àwọn á fẹ́ gbọ́. A gbà pé ó yẹ ká tètè tọ́ àwọn ọmọ wa sọ́nà tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tí ò dáa, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni kéèyàn kọ́ ọmọ pé ọ̀rọ̀ tó bójú mu ni kó máa sọ, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn má ṣe fún ọmọ lómìnira láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀.
16 Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ káwọn ọmọ máa sọ tinú wọn? Aleah tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Ohun tá a ṣe tó fi rọrùn fáwọn ọmọ wa láti máa sọ tinú wọn fún wa ni pé a kì í tètè bínú táwọn ọmọ wa bá sọ ohun kan tí kò bá wa lára mu.” Bàbá kan tó ń jẹ́ Tom sọ pé: “A rọ ọmọbìnrin wa láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wa, kódà tí èrò wa ò bá bá tiẹ̀ mu. A rí i pé tá a bá pa á lẹ́nu mọ́ tá a sì sọ pé kó fara mọ ohun tá a fẹ́ tipátipá, ọ̀rọ̀ wa yóò sú u, á sì jágbọ́n kó má máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ gan-an fún wa mọ́. Ṣùgbọ́n tá a bá ń fetí sí i, á jẹ́ kóun náà máa gbọ́ tiwa.” Kò sí àníàní, àwọn ọmọ ní láti gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu. (Òwe 6:20) Àmọ́ táwọn òbí bá fàyè gba àwọn ọmọ wọn láti máa sọ̀rọ̀ látọkàn wá, àwọn ọmọ á lè mọ inú rò. Vincent, tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́rin sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń bá àwọn ọmọ wa jíròrò àǹfààní àti ìṣòro tó wà nínú ọ̀ràn kan káwọn fúnra wọn lè rí ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ. Ìyẹn ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ inú rò.”—Òwe 1:1-4.
17. Kí ló yẹ káwọn òbí mọ̀ dájú?
17 Lóòótọ́ o, kò sí òbí tó lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọmọ títọ́ láìkù síbì kan. Síbẹ̀, mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ rẹ ń bọ̀ wá mọyì ìsapá rẹ, bó o ṣe ń fi ìpamọ́ra, inú rere àti ìfẹ́ tọ́ wọn. Jèhófà á sì kọ́ ẹ mọ̀ ọ́n ṣe. (Òwe 3:33) Ìdí pàtàkì tí gbogbo Kristẹni tó bímọ fi ń sapá ni pé káwọn ọmọ wọn lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà báwọn fúnra wọn ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwo wá làwọn òbí ṣe lè ṣe é tí ọmọ wọn á fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí á jíròrò ọ̀nà mélòó kan tí wọ́n lè gbà ṣe é.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra?
• Báwo ni ìbáwí ṣe fi hàn pé òbí nífẹ̀ẹ́?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí àtàwọn ọmọ máa bá ara wọn sọ tinú wọn kí wọ́n sì máa fetí sí ara wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ rántí ìgbà tẹ́ ẹ wà lọ́mọdé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ṣé ẹ máa ń rọ àwọn ọmọ yín láti sọ òótọ́ tó wà lọ́kàn wọn jáde?