Maṣe Jẹ́ Ki Ẹnikẹni Ba Ìwà Rere Rẹ Jẹ́
“Ki a má tàn yin jẹ: ẹgbẹ́ buburu ba ìwà rere jẹ́.”—1 KORINTI 15:33.
1, 2. (a) Imọlara wo ni aposteli Paulu ni nipa awọn Kristian ará Korinti, eesitiṣe? (b) Imọran wo ni pataki ni a o gbeyẹwo?
Ẹ WO iru ero-imọlara alagbara ti ifẹ òbí sí ọmọ jẹ́! O ń sún awọn òbí lati fi ọpọlọpọ nǹkan rubọ nitori awọn ọmọ wọn, lati kọ́ wọn ati lati gbà wọn niyanju. Aposteli Paulu lè má ti jẹ́ baba nipa ti ibimọ, ṣugbọn o kọwe si awọn Kristian ni Korinti pe: “Nitori bi ẹyin tilẹ ní ẹgbaarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹyin kò ni baba pupọ: nitori pe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí yin.”—1 Korinti 4:15.
2 Ṣaaju, Paulu ti rinrin-ajo lọ si Korinti, nibi ti o ti waasu fun awọn Ju ati Griki. O ṣeranlọwọ lati dá ijọ ti o wà ní Korinti silẹ. Ninu lẹta miiran Paulu fi aájò rẹ̀ wé ti abiyamọ kan, ṣugbọn oun dabii baba fun awọn ará Korinti. (1 Tessalonika 2:7) Gẹgẹ bi baba onifẹẹ gidi kan ti ń ṣe, Paulu gba awọn ọmọ rẹ̀ nipa ti ẹmi niyanju. Iwọ lè janfaani lati inu imọran bii ti baba yii si awọn Kristian ni Korinti: “Ki a má tan yin jẹ: ẹgbẹ́ buburu ba ìwà rere jẹ́.” (1 Korinti 15:33) Eeṣe ti Paulu fi kọ iyẹn si awọn ará Korinti? Bawo ni awa ṣe lè fi imọran naa silo?
Imọran fun Wọn ati fun Wa
3, 4. Ki ni a mọ̀ nipa Korinti ti ọrundun kìn-ín-ní ati iye awọn olugbe inu rẹ̀?
3 Ní ọrundun kìn-ín-ní, onimọ-ijinlẹ nipa irisi oju-ilẹ ọmọ ilu Griki naa Strabo kọwe pe: “Korinti ni a pè ní ‘ọlọ́rọ̀’ nitori ìṣòwò rẹ̀, niwọn bi o ti jẹ́ pe a fidii rẹ̀ kalẹ lori Isthmus ti o sì jẹ́ ọ̀gá lori ebute-ọkọ-okun meji, eyi ti ọ̀kan ninu rẹ̀ lọ si Asia ni taarata, ati ekeji si Italy; o sì mu ki paṣipaarọ iṣowo lati orilẹ-ede mejeeji rọrùn.” Ní ọdun meji meji Eré-àṣedárayá ti Isthmus ti a mọ̀ bi ẹni mowó naa ń fa èrò gan-an wá si Korinti.
4 Ki ni nipa ti awọn eniyan ti wọn wà ninu ilu yii ti o jẹ́ ikorita fun ọla-aṣẹ ijọba ati ijọsin onifẹẹkufẹẹ ti abo-ọlọrun ifẹ ti ilẹ Griki? Ọjọgbọn T. S. Evans ṣalaye pe: “O ṣeeṣe ki o [jẹ́] pe iye awọn olugbe ibẹ jẹ́ nǹkan bii 400,000. Awujọ naa [jẹ́] ti aláṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ lọna giga, ṣugbọn o dẹra niti iwarere, ani lọna wiwuwo paapaa. . . . Awọn ara ilẹ Griki ti Akaia ni a sàmì sí pẹlu aisinmi niti imọ-ori ati fifi igbonara ṣàfẹ́rí awọn ohun titun. . . . Igbera-ẹni-larugẹ wọn lè tètè ru ìyapa-ẹgbẹ́ soke.”
5. Ewu wo ni awọn ará ni Korinti dojukọ?
5 Bi akoko ti ń lọ, ani ijọ naa tilẹ di eyi ti awọn kan tí wọn ṣì ni itẹsi sipa ìméfò onigbeeraga pín si ọtọọtọ. (1 Korinti 1:10-31; 3:2-9) Iṣoro kan pato ni pe awọn kan ń sọ pe: “Ajinde òkú kò si.” (1 Korinti 15:12; 2 Timoteu 2:16-18) Ohun yoowu ki o jẹ igbagbọ (tabi ṣaigbagbọ) wọn niti gidi, Paulu nilati tọ́ wọn sọ́nà pẹlu ẹ̀rí kedere pe Kristi ni a “ti jinde kuro ninu oku.” Nipa bayii, awọn Kristian lè ni igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo fun wọn ni ‘iṣẹgun nipasẹ Oluwa wa Jesu Kristi.’ (1 Korinti 15:20, 51-57) Bi o bá jẹ́ pe iwọ wà nibẹ, o ha lè ṣeeṣe ki ẹmi iyapa naa ti nipa lori rẹ bi?
6. Imọran Paulu ninu 1 Korinti 15:33 ṣeé fisilo ni pataki fun ta ni?
6 Nigba ti o ń pese ẹ̀rí ti o fẹsẹmulẹ pe awọn oku ni a o jinde, Paulu sọ fun wọn pe: “Ki a má tan yin jẹ: ẹgbẹ́ buburu ba ìwà rere jẹ́.” Koko imọran yii kan awọn ti wọn ń darapọ mọ ijọ naa ti wọn kò fohunṣọkan lori ẹkọ ajinde. Wọn ha wulẹ ṣaini idaniloju nipa koko kan ti wọn kò lóye ni bi? (Fiwe Luku 24:38.) Bẹẹkọ. Paulu kọwe pe ‘awọn kan laaarin yin wi pe kò si ajinde,’ nitori naa awọn tí ọ̀rọ̀ kàn ń fi aifohunṣọkan hàn, ni títẹ̀ siha ipẹhinda. Paulu mọ daradara pe wọn lè ba ìwà rere ati ironu awọn yooku jẹ́.—Iṣe 20:30; 2 Peteru 2:1.
7. Ki ni iru ayika ipo kan ninu eyi ti a lè fi 1 Korinti 15:33 silo?
7 Bawo ni a ṣe lè fi ikilọ Paulu nipa awọn ibakẹgbẹ silo? Oun kò ní i lọkan pe a gbọdọ yẹra lati ran ẹnikan ti kò rọrun fun lati loye ẹsẹ Bibeli tabi ẹkọ kan lọwọ ninu ijọ. Niti gidi, Juda 22, 23 rọ̀ wá lati fi iranlọwọ alaaanu fun awọn ọlọkan mímọ́ ti wọn ni iru iyemeji bẹẹ. (Jakọbu 5:19, 20) Bi o ti wu ki o ri, imọran bii ti baba ti Paulu funni niti gidi ni a gbọdọ fi silo bi ẹnikan bá ń fiyatọ si ohun ti a mọ̀ gẹgẹ bi otitọ Bibeli tabi ti o ń sọ awọn ọ̀rọ̀ ti o dabi ti alainigbagbọ tabi eyi ti o jẹ òdì. A nilati wà lojufo lodisi ibakẹgbẹpọ pẹlu iru ẹni bẹẹ. Lotiitọ, bi ẹnikan bá di apẹhinda patapata, awọn oluṣọ-agutan nipa tẹmi yoo nilati gbé igbesẹ lati daabobo agbo.—2 Timoteu 2:16-18; Titu 3:10, 11.
8. Bawo ni a ṣe lè fi imoye huwa nigba ti ẹnikan kò bá fohunṣọkan lori ẹkọ Bibeli kan?
8 A tun lè fi ọ̀rọ̀ Paulu bii ti baba ti o wà ninu 1 Korinti 15:33 silo nigba ti o ba kan ti awọn ti wọn wà ni òde ijọ ti wọn ń gbe isin èké larugẹ. Bawo ni a ṣe lè fà wà sinu ibakẹgbẹpọ pẹlu wọn? Ó lè ṣẹlẹ bi a kò bá fi aala saaarin awọn wọnni ti a lè ranlọwọ lati kẹkọọ otitọ ati awọn wọnni ti wọn wulẹ ń gbe ariyanjiyan dide lati lè gbé ẹkọ èké larugẹ. Fun apẹẹrẹ, ninu iṣẹ́ ijẹrii wa, a lè bá ẹnikan ti kò gbà lori awọn koko kan pade ṣugbọn ti o muratan lati jiroro rẹ̀ siwaju sii. (Iṣe 17:32-34) Iyẹn ninu ararẹ̀ kò yẹ ki o gbé iṣoro dide, nitori pe a ń fi idunnu ṣalaye otitọ Bibeli fun ẹnikẹni ti o bá fẹ́ lati mọ iru nǹkan bẹẹ pẹlu àìṣẹ̀tàn, ani ti a tilẹ ń pada lọ lati pese awọn ẹ̀rí ti ń yíniléròpadà. (1 Peteru 3:15) Sibẹ, awọn kan lè má ni ọkàn-ìfẹ́ ninu wíwá otitọ Bibeli niti gidi.
9. Bawo ni a ṣe nilati huwapada si awọn ipenija si igbagbọ wa?
9 Ọpọ awọn eniyan yoo jiyàn fun ọpọ wakati, ni ọsọọsẹ, ṣugbọn kìí ṣe nitori pe wọn ń wá otitọ. Wọn wulẹ fẹ́ lati pa igbagbọ ẹlomiran run ni bí wọn ti ń fẹ́ lati ṣaṣefihan ẹkọ ti o dabi ẹni pe wọn ní ninu ede Heberu, Griki, tabi imọ-ijinlẹ ẹfoluṣọn. Nigba ti a bá bá wọn pade, awọn Ẹlẹ́rìí diẹ ti nimọlara ipenija gẹgẹ bi abajade rẹ̀ wọn ti ń ní ibakẹgbẹpọ ti a mu gbooro sii eyi ti a gbé ka ori igbagbọ isin èké, imọ-ọran, tabi awọn aṣiṣe onimọ-ijinlẹ. O hàn gbangba pe Jesu kò jẹ́ ki iyẹn ṣẹlẹ si oun, bi o tilẹ jẹ pe kì bá ti bori ijiyan pẹlu awọn olori isin ti wọn kawe ni ilana ti Heberu tabi Griki. Nigba ti wọn pè é nija, Jesu dahunpada ni ṣoki lẹhin naa o sì yí afiyesi rẹ̀ pada si awọn onirẹlẹ, awọn agutan gidi.—Matteu 22:41-46; 1 Korinti 1:23–2:2.
10. Eeṣe ti iṣọra fi yẹ fun awọn Kristian ti wọn ní ẹ̀rọ kọmputa ati ẹ̀tọ́ si ibi ìkósọfúnni si ninu kọmputa?
10 Awọn kọmputa igbalode ti ṣí awọn ọ̀nà miiran silẹ fun ẹgbẹ́ buburu. Awọn ilé-iṣẹ́ itaja kan mú ki o ṣeeṣe fun awọn ti ó sàn asansilẹ-owo ti wọn ń lo kọmputa ati tẹlifoonu lati fi isọfunni kan ranṣẹ si ibi ìkósọfúnni si ninu kọmputa; ẹnikan lè tipa bayii fi isọfunni kan ti o wà fun gbogbo awọn alasansilẹ-owo ranṣẹ sinu patako ibi ikosọfunni si. Eyi ti ṣamọna si ohun ti a ń fẹnu lasan pe ni ariyanjiya nipasẹ awọn ohun-eelo onina lori ọ̀ràn isin. A lè fa Kristian kan wọnu iru ijiyan bẹẹ o sì lè lo wakati pupọ pẹlu elérò apẹhinda kan ti a ti lè yọ lẹ́gbẹ́ kuro ninu ijọ. Itọsọna naa ti o wà ninu 2 Johannu 9-11 tẹnumọ imọran bii ti baba tí Paulu funni nipa yiyẹra fun ẹgbẹ́ buburu.a
Yẹra fun Dídi Ẹni ti A Ṣìlọ́nà
11. Ipo iṣowo ni Korinti pese anfaani wo?
11 Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi, Korinti jẹ́ ikorita iṣowo kan, pẹlu ọgọọrọ awọn ile-itaja ati iṣẹ́-ajé. (1 Korinti 10:25) Ọpọ awọn eniyan ti wọn wá fun Eré Isthmia yoo gbé ni àgọ́, ni akoko iṣẹlẹ yẹn sì niyi awọn oniṣowo yoo maa tajà ninu awọn àtíbàbà ti wọn ṣeégbékiri tabi awọn ìsọ̀. (Fiwe Iṣe 18:1-3.) Eyi mu ki o ṣeeṣe fun Paulu lati rí iṣẹ́ àgọ́ pípa nibẹ. Ó sì lè lo ibi iṣẹ́ naa lati mú ihinrere tẹsiwaju. Ọjọgbọn J. Murphy-O’Connor kọwe pe: “Lati inu ile itaja kan ninu ọjà ti o kun fun igbokegbodo . . . lọ si opopona kan ti o kun fun èrò ni Paulu lè wọ̀, kìí ṣe kiki dé ọ̀dọ̀ awọn alabaaṣiṣẹ ati awọn onibaara nikan ni, ṣugbọn iwọjọpọ awọn eniyan ti wọn wà ni ìta. Nigba miiran ti ọjà kò bá tà oun lè duro lẹnu ọ̀nà ki o sì maa dá awọn ti ó lero pe wọn lè tẹtisilẹ duro pẹlu ijiroro . . . Ó ṣoro lati ronuwoye pe animọ-iwa alagbara yii ati igbagbọ hán-ún-hán-ún rẹ̀ kò tètè sọ ọ́ di ‘ẹni ti igba-ojú-mọ̀’ ni adugbo, eyi yoo sì ti fa awọn ti wọn lọkan iṣewadii mọra, kìí wulẹ ṣe awọn afàkókòṣòfò ṣugbọn awọn wọnni ti ó jẹ pe nitootọ ni wọn ń wá isọfunni pẹlu. . . . Awọn abilékọ pẹlu awọn ọmọ-ọdọ wọn, ti wọn ti gbọ́ nipa rẹ̀, lè ṣe ibẹwo labẹ ìbòjú wíwá lati rajà. Ní awọn akoko idaamu, nigba ti iṣẹniniṣẹẹ tabi ihalẹmọni lasan bá halẹ mọ wọn, awọn onigbagbọ lè koju rẹ̀ gẹgẹ bi oníbàárà. Ilé-iṣẹ́ naa tun mú un wá si oju-ko-oju pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ń bojuto ilu.”
12, 13. Bawo ni a ṣe lè fi 1 Korinti 15:33 silo lọna ti o baa mu ni ibi iṣẹ́?
12 Bi o tilẹ ri bẹẹ, Paulu yoo ti mọ awọn ohun ti o lè di “ẹgbẹ́ buburu” ọjọ iwaju ní ibi iṣẹ́ naa. Awa pẹlu gbọdọ ṣe bẹẹ. Ni ọ̀nà ti o ṣe pataki, Paulu tọka si iwa kan ti o wọpọ laaarin awọn kan: “Ẹ jẹ́ ki a maa jẹ, ẹ jẹ́ ki a maa mu; ọla ni awa ó sá kú.” (1 Korinti 15:32) Ó yara fi imọran rẹ̀ ti o dabii ti baba kín iyẹn lẹhin pe: “Ki a má tan yin jẹ́: ẹgbẹ́ buburu ba ìwà rere jẹ́.” Bawo ni ibi iṣẹ́ ati wíwá igbadun ṣe lè ni isopọ pẹlu dídá ijamba ti ó ṣeeṣe ki o dide ni ọjọ iwaju silẹ?
13 Awọn Kristian fẹ lati jẹ ẹni bi ọ̀rẹ́ pẹlu awọn alajọṣiṣẹ, iriri pupọ sì ṣaṣefihan bi eyi ṣe lè gbẹ́ṣẹ́ tó ní ṣiṣi ọ̀nà silẹ fun jijẹrii. Bi o ti wu ki o ri, oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ-ẹni kan lè ṣi jíjẹ́ ẹni bi ọ̀rẹ́ tumọ, gẹgẹ bi eyi ti ń wá ibakẹgbẹpọ lati lè jumọ gbadun. Ọkunrin tabi obinrin naa lè nawọ́ ikesini lasan fun ounjẹ ọ̀sán, iduro fun akoko diẹ lẹhin iṣẹ́ fun mimu ọtí lile, tabi eré itura diẹ ni opin ọsẹ. Ẹni yii lè farahan bi oninurere ati ẹni ti ọ̀wọ̀ yẹ, ikesini naa sì lè dabi eyi ti kò buru. Sibẹ, Paulu gbà wa nimọran pe: “Ki a má tan yin jẹ.”
14. Bawo ni a ti ṣe ṣi awọn Kristian kan lọna nipasẹ ibakẹgbẹ?
14 A ti tan awọn Kristian kan jẹ. Wọn mu iṣesi idẹrasilẹ ninu iṣarasihuwa niti ibakẹgbẹ pẹlu awọn alajọṣiṣẹ dagba. Boya o dagbasoke lati inu ìfẹ́-ọkàn wíwọ́pọ̀ ninu eré idaraya tabi iṣẹ́ afipawọ kan. Ó sì lè jẹ pe ẹni kan ti kìí ṣe Kristian ni ibi iṣẹ́ ni o jẹ́ oninurere ti o sì láájò lọna kan ti o ṣara-ọtọ, eyi ti o jalẹ sí lilo akoko ti ń pọ̀ sii pẹlu onítọ̀hún ani ti a tilẹ fẹ́ iru ibakẹgbẹ bẹẹ ju ti awọn kan ninu ijọ lọ. Nigba naa ibakẹgbẹ naa lè ṣamọna pipadanu kiki ipade kan. Ó lè tumọsi pípẹ́ ni òde ni alẹ́ ọjọ kan ki a sì ré ilana ṣiṣajọpin ninu iṣẹ-isin pápá ni owurọ kọja. Ó lè yọrisi wíwo iru sinima tabi fidio kan ti Kristian kan yoo kọ̀ gẹgẹ bi o ti yẹ ki o ri. ‘Óò, iyẹn kì yoo ṣẹlẹ si mi lae,’ ni awa lè ronu. Ṣugbọn pupọ awọn wọnni ti a ti tàn jẹ lè kọkọ ti dahunpada ni ọ̀nà yẹn. A nilati bi araawa leere pe, ‘Bawo ni mo ti pinnu tó lati fi imọran Paulu silo?’
15. Iṣarasihuwa ti o wà deedee wo ni a nilati ní si awọn aladuugbo?
15 Ohun ti a ṣẹṣẹ gbeyẹwo yii nipa ibi iṣẹ́ tun kan ibakẹgbẹ wa pẹlu awọn aladuugbo pẹlu. Dajudaju, awọn Kristian ni Korinti igbaani ní awọn aladuugbo. Ní awọn awujọ kan o baa mu lati jẹ́ ẹni bi ọ̀rẹ́ ti o sì ń ṣe itilẹhin fun awọn aladuugbo. Ní awọn agbegbe igberiko, awọn aladuugbo lè gbẹkẹle araawọn ẹnikinni keji nitori wíwà ní àdádó. Awọn ibatan idile lagbara ni pataki ninu awọn aṣa-iṣẹdalẹ kan, eyi ti ń gbé ọpọ ikesini si ounjẹ dide. Lọna ti o hàn gbangba, oju-iwoye ti o wà deedee ṣe pataki, gẹgẹ bi Jesu ti fihàn. (Luku 8:20, 21; Johannu 2:12) Ninu ajọṣepọ wa pẹlu awọn aladuugbo ati ibatan, a ha ni itẹsi lati maa baa lọ bi a ti ń ṣe ṣaaju ki a tó di Kristian bi? Kaka bẹẹ, kò ha yẹ ki a ṣatunyẹwo iru awọn ajọṣepọ bẹẹ ki a sì fi ironu pinnu ààlà ti o yẹ bi?
16. Bawo ni a ṣe nilati loye awọn ọ̀rọ̀ Jesu ninu Matteu 13:3, 4?
16 Ní ìgbà kan Jesu fi ọ̀rọ̀ Ijọba naa wé awọn irugbin ti ó “bọ́ si ẹ̀bá-ọ̀nà, awọn ẹyẹ sì wá, wọn si ṣà á jẹ.” (Matteu 13:3, 4, 19) Ni akoko yẹn, awọn erupẹ ti wọn wà ni ẹ̀bá-ọ̀nà maa ń le bi o ti jẹ́ pe ẹsẹ̀ pupọ ni o ń rìn lọ rìn bọ̀ lori rẹ̀. Bí o ti ri pẹlu awọn eniyan pupọ niyẹn. Igbesi-aye wọn kun fun awọn aladuugbo, awọn ibatan, ati awọn miiran ti wọn ń lọ ti wọn ń bọ̀, ti ó sì ń mu ki ọwọ́ wọn dí. Eyi, bi ọ̀ràn ti rí, ń tẹ erupẹ ọkan-aya wọn mọlẹ, ni mímú ki o le fun awọn eso otitọ lati fi idi mulẹ. Iru ìyigbì kan-naa lè gbèrú ninu ẹnikan ti o ti jẹ́ Kristian.
17. Bawo ni ibakẹgbẹ pẹlu awọn aladuugbo ati awọn ẹlomiran ṣe lè ni ipa lori wa?
17 Awọn aladuugbo ati awọn ibatan ti ayé kan lè jẹ́ ẹni bi ọ̀rẹ́ ti ń rannilọwọ, bi o tilẹ jẹ pe lati ìgbà de ìgbà ni wọn kò ti fi ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu awọn ohun ti ẹmi bẹẹ ni wọn kò fi ifẹ hàn fun òdodo. (Marku 10:21, 22; 2 Korinti 6:14) Dídi Kristian wa kò gbọdọ tumọsi pe ki a di alaijẹ bi ọ̀rẹ́, alainifẹẹ aladuugbo. Jesu gbà wá nimọran lati fi ifẹ gidi hàn ninu awọn ẹlomiran. (Luku 10:29-37) Ṣugbọn imọran Paulu naa ti a misi pe ki a ṣọra nipa awọn ibakẹgbẹ wa sì ṣe pataki bakan-naa. Bí a ti ń fi imọran iṣaaju naa silo, a kò gbọdọ gbagbe eyi ti o kẹhin. Bí a kò bá fi awọn ilana mejeeji naa sọkan, o lè nipa lori iwa wa. Bawo ni iwa rẹ ṣe rí niti ailabosi tabi ṣiṣegbọran si ofin Kesari ni ifiwera pẹlu ti awọn aladuugbo tabi awọn ibatan rẹ? Fun apẹẹrẹ, wọn lè nimọlara pe ni akoko owo-ori, ṣiṣai rohin owo ti ń wọle tabi èrè ninu iṣowo bojumu, ti o sì ṣe pataki fun lilaaja. Wọn lè sọrọ lọna ti ń yinileropada nipa oju-iwoye wọn lakooko ikorajọpọ ẹgbẹ-oun-ọgba alaijẹ-bi-aṣa tabi nigba ibẹwo ranpẹ kan. Bawo ni iyẹn ṣe lè ni ipa lori ironu ati awọn iwa ailaboosi rẹ? (Marku 12:17; Romu 12:2) “Ki a má tan yin jẹ: ẹgbẹ́ buburu ba ìwà rere jẹ́.”
Awọn Ìwà Èwe Pẹlu
18. Eeṣe ti 1 Korinti 15:33 ṣe kan awọn èwe?
18 Ohun ti awọn ọ̀dọ́ ń rí ti wọn si ń gbọ́ ní pataki ń ní ipa lori wọn. Iwọ kò ha ti ṣakiyesi awọn ọmọ ti awọn iṣesi tabi iwa wọn fi pupọpupọ dabii ti awọn òbí wọn tabi bii ti awọn arakunrin tabi arabinrin wọn bi? Kò yẹ ki o yà wa lẹnu, nigba naa, pe awọn alajumọṣerepọ tabi awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ wọn lè nipa lori awọn ọmọde lọna giga. (Fiwe Matteu 11:16, 17.) Bí ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ bá wà nitosi awọn èwe ti wọn ń sọrọ lọna ti kò ni ọ̀wọ̀ nipa awọn òbí wọn, eeṣe ti o fi ronuwoye pe eyi kì yoo ni ipa lori awọn ọmọ rẹ? Ki ni bi wọn bá saba maa ń gbọ́ awọn èwe miiran ti wọn ń lo awọn èdè àlùfààṣá? Ki ni bi awọn ojugba wọn ni ile-ẹkọ tabi ni adugbo bá ní irusoke-imọlara nipa iru bata tabi aṣa titun kan ninu ohun ìṣọ̀ṣọ́? Awa ha nilati ronu pe iru idari bẹẹ kì yoo lè ni ipa lori awọn ọ̀dọ́ Kristian bi? Paulu ha sọ pe 1 Korinti 15:33 kan kiki awọn ti wọn ti dé ọjọ-ori kan bi?
19. Oju-iwoye wo ni o yẹ ki awọn òbí gbiyanju lati fi si inu awọn ọmọ wọn?
19 Bi iwọ bá jẹ́ òbí, imọran yẹn ha ń jẹ ọ́ lọ́kàn, bi o ti ń ronu pẹlu awọn ọmọ rẹ ti o sì ń ṣe awọn ipinnu ti o niiṣe pẹlu wọn? Boya yoo ṣeranwọ bi iwọ bá gbà pe eyi kò tumọsi pe gbogbo awọn èwe ti awọn ọmọ rẹ wà nitosi wọn ni adugbo tabi ni ile-ẹkọ ni wọn kò dara. Awọn diẹ lara wọn lè wuni ki wọn sì wà letoleto, gẹgẹ bi awọn kan lara awọn aladuugbo, awọn ibatan, ati awọn alajumọṣiṣẹ rẹ ti jẹ́. Gbiyanju lati ran awọn ọmọ rẹ lọwọ lati rí eyi ati lati di oju-iwoye naa mú pe o wà deedee ninu fifi ti o ń fi imọran ọlọgbọn Paulu silo, ti o dabii ti òbí si awọn ará Korinti. Bi wọn ti ń fi òye mọ ọ̀nà ti iwọ gba ń mu awọn nǹkan baradọgba, ó lè ràn wọn lọwọ lati ṣafarawe rẹ.—Luku 6:40; 2 Timoteu 2:22.
20. Ẹyin èwe, awọn ipenija wo ni ẹ dojukọ?
20 Ẹyin ti ẹ ṣi jẹ́ ọ̀dọ́, ẹ gbiyanju lati loye bi ẹ ṣe lè fi imọran Paulu naa silo, ni mímọ̀ pe o ṣe pataki fun gbogbo Kristian, lọ́mọdé ati lágbà. Eyi yoo beere isapa ati ipinnu nla, ṣugbọn eeṣe ti o kò fi muratan lati dojukọ ipenija naa? Mọ̀ pe kiki nitori pe o ti mọ diẹ lara awọn èwe wọnyẹn lati ìgbà ọmọde kò tumọsi pe wọn kò lè ni ipa lori iwa rẹ, pe wọn kò lè ba iwa ti iwọ ń mu dagba gẹgẹ bi èwe Kristian jẹ́.—Owe 2:1, 10-15.
Awọn Igbesẹ Titọna Lati Daabobo Ìwà Wa
21. (a) Aini wo ni a ní nipa ibakẹgbẹ? (b) Eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe awọn ibakẹgbẹ kan lè lewu?
21 Gbogbo wa nilo ibakẹgbẹ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, a nilati wà lojufo si otitọ naa pe awọn alabaakẹgbẹ wa lè ni ipa lori wa, si rere tabi buburu. Iyẹn jẹ́ otitọ pẹlu Adamu ati pẹlu gbogbo eniyan la ọpọ ọrundun kọja lati ìgbà naa wa. Fun apẹẹrẹ, Jehoṣafati, ọba rere kan ni Juda, gbadun ojurere ati ibukun Jehofa. Ṣugbọn lẹhin ti o faayegba ọmọkunrin rẹ̀ lati gbé ọmọbinrin Ọba Ahabu ti Israeli niyawo, Jehoṣafati bẹrẹ sii kẹgbẹ pẹlu Ahabu. Ibakẹgbẹ buburu yẹn fẹrẹẹ ná Jehoṣafati ni iwalaaye rẹ̀. (2 Ọba 8:16-18; 2 Kronika 18:1-3, 29-31) Bi a bá ṣe awọn yíyàn ti kò bọgbọnmu nipa ibakẹgbẹ wa, o lè lewu bẹẹ gẹlẹ.
22. Ki ni a nilati fi sọkan, eesitiṣe?
22 Nigba naa, ẹ jẹ́ ki a fi imọran onifẹẹ naa ti Paulu fun wa ninu 1 Korinti 15:33 sọkan. Iwọnyẹn kìí ṣe awọn ọ̀rọ̀ lasan ti a lè ti gbọ́ lati ìgbà de ìgbà debi pe a lè sọ wọn lori. Wọn ṣagbeyọ ifẹni bii ti baba tí Paulu ní fun awọn arakunrin ati arabinrin rẹ̀ ará Korinti, ati, nipa imugbooro, fun wa. Ati laisi iyemeji, wọn ní imọran tí Baba wa ọ̀run ń pese nitori pe oun fẹ́ ki awọn isapa wa yọrisi rere ninu.—1 Korinti 15:58.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ewu miiran ninu iru ibi ikosọfunni si bẹẹ ni idanwo lati ṣe adakọ iru awọn itolẹsẹẹsẹ tabi itẹjade ti a pamọ fiṣura bẹẹ sinu kọmputa wọn laigba àṣẹ ẹni ti o ni ẹ̀tọ́ tabi ti awọn tí wọn ṣe é, eyi ti yoo forigbari pẹlu awọn ofin ẹ̀tọ́ ipamọ-fiṣura jakejado awọn orilẹ-ede.—Romu 13:1.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Fun idi pataki wo ni Paulu ṣe kọ 1 Korinti 15:33?
◻ Bawo ni a ṣe lè fi imọran Paulu silo ni ibi iṣẹ́?
◻ Oju-iwoye wíwà deedee wo nipa awọn aladuugbo ni a nilati ní?
◻ Eeṣe ti 1 Korinti 15:33 fi jẹ́ imọran ti o baa mu ní pataki fun awọn èwe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Paulu lo ibi iṣẹ lati mú ihinrere naa tẹsiwaju
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Awọn èwe miiran lè ba iwa Kristian rẹ jẹ́