-
Àjíǹde Dájú!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | December
-
-
12. Kí ni 1 Pétérù 3:18, 22 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde Jésù yàtọ̀ sí àwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú tiẹ̀?
12 Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run “ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú.” Àjíǹde Jésù sàn ju àwọn àjíǹde tó ti wáyé ṣáájú tiẹ̀ torí pé àwọn ẹni yẹn tún pa dà kú lẹ́yìn tí wọ́n jí wọn dìde. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ àkọ́so? Òun lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, òun náà sì lẹni àkọ́kọ́ tó lọ sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde.—1 Kọ́r. 15:20; Ìṣe 26:23; ka 1 Pétérù 3:18, 22.
-
-
Àjíǹde Dájú!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | December
-
-
16. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó pe Jésù ní “àkọ́so”?
16 Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti gbé Kristi dìde, òun sì ni “àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.” Ká rántí pé Ọlọ́run ti jí àwọn míì bíi Lásárù dìde ṣáájú Jésù. Àmọ́, Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí tó sì fún ní ìyè àìnípẹ̀kun. A lè fi wé àkọ́so nínú ìkórè táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi rúbọ sí Ọlọ́run. Bákan náà, bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe Jésù ní “àkọ́so” fi hàn pé Ọlọ́run máa jí àwọn míì náà dìde sí ọ̀run, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tí wọ́n wà “nínú Kristi.” Tó bá yá, Ọlọ́run máa jí àwọn náà dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí lọ sí ọ̀run bíi ti Jésù.
-