Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
26 Ágírípà+ sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “A gbà ọ́ láyè láti rojọ́ ara rẹ.” Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ara rẹ̀, ó ní:
2 “Lórí gbogbo ohun tí àwọn Júù fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí,+ Ọba Ágírípà, mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni màá ti gbèjà ara mi lónìí yìí, 3 ní pàtàkì, torí pé ọ̀jáfáfá ni ọ́ nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn àwọn Júù. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ pé kí o fi sùúrù gbọ́rọ̀ mi.
4 “Ní tòótọ́, irú ìgbésí ayé tí mo gbé láti ìgbà èwe mi láàárín àwọn èèyàn* mi àti ní Jerúsálẹ́mù ni gbogbo àwọn Júù mọ̀ dáadáa,+ 5 ìyẹn àwọn tó ti mọ̀ mí tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ìgbé ayé Farisí ni mo gbé+ ní ìlànà ẹ̀ya ìsìn tí kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá,+ ti ọ̀nà ìjọsìn wa. 6 Àmọ́ ní báyìí, torí pé mò ń retí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wa+ ni mo ṣe ń jẹ́jọ́; 7 ìlérí yìí kan náà ni àwọn ẹ̀yà méjìlá (12) wa ń retí pé kó ṣẹ bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru. Ìrètí yìí ló mú kí àwọn Júù fẹ̀sùn kàn mí o,+ Ọba.
8 “Kí nìdí tí ẹ fi kà á sí* ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ láàárín yín pé Ọlọ́run ń jí òkú dìde? 9 Ní tèmi, mo gbà tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ àtakò dìde sí orúkọ Jésù ará Násárẹ́tì. 10 Ohun tí mo sì ṣe gẹ́lẹ́ ní Jerúsálẹ́mù nìyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni mímọ́ ni mo tì mọ́ inú ẹ̀wọ̀n,+ torí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà;+ nígbà tí wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n, mo dìbò pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. 11 Bí mo ṣe ń fìyà jẹ wọ́n léraléra ní gbogbo sínágọ́gù, mo fipá mú wọn láti fi ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀; torí pé inú wọn ń bí mi gidigidi, mo bá a débi pé mo ṣe inúnibíni sí wọn ní àwọn ìlú tó wà lẹ́yìn òde pàápàá.
12 “Ẹnu èyí ni mo wà nígbà tí mò ń rìnrìn àjò lọ sí Damásíkù pẹ̀lú àṣẹ àti agbára látọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, 13 lójú ọ̀nà ní ọ̀sán gangan, ìwọ Ọba, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tó ju ìtànṣán oòrùn, tó kọ mànà láti ọ̀run yí mi ká àti yí àwọn tí a jọ ń rìnrìn àjò ká.+ 14 Nígbà tí gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi lédè Hébérù pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí ló dé tí ò ń ṣe inúnibíni sí mi? Tí o bá ń tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́,* ó máa nira fún ọ.’ 15 Àmọ́ mo sọ pé: ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Olúwa sì fèsì pé: ‘Èmi ni Jésù, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. 16 Ní báyìí, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Ìdí tí mo fi fara hàn ọ́ ni pé, mo fẹ́ yàn ọ́ ṣe ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí àwọn ohun tí o ti rí àti àwọn ohun tí màá mú kí o rí nípa mi.+ 17 Màá sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn yìí àti lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá rán ọ sí+ 18 láti la ojú wọn,+ láti mú wọn kúrò nínú òkùnkùn+ wá sínú ìmọ́lẹ̀+ àti láti mú wọn kúrò lábẹ́ àṣẹ Sátánì+ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ kí wọ́n sì rí ogún láàárín àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ti sọ wọ́n di mímọ́.’
19 “Nítorí náà, Ọba Ágírípà, mi ò ṣàìgbọràn sí ìran àtọ̀runwá náà, 20 àmọ́ mo jẹ́ iṣẹ́ náà fún àwọn tó wà ní Damásíkù+ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù + àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà àti fún àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yíjú sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.+ 21 Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì fẹ́ pa mí.+ 22 Àmọ́ torí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mò ń jẹ́rìí nìṣó títí di òní yìí fún ẹni kékeré àti ẹni ńlá, mi ò sì sọ nǹkan kan tó yàtọ̀ sí ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀,+ 23 pé Kristi máa jìyà+ àti pé bó ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí a máa jí dìde kúrò nínú ikú,+ ó máa kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn yìí àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.”+
24 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí láti gbèjà ara rẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì kígbe pé: “Orí ẹ ti ń dà rú, Pọ́ọ̀lù! Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ẹ́ lórí rú!” 25 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe pé orí mi ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ọlọ́lá Jù Lọ, òótọ́ ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání ni mò ń sọ. 26 Ká sòótọ́, ọba tí mò ń bá sọ̀rọ̀ ní fàlàlà gan-an mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí dáadáa; ó dá mi lójú pé kò sí ìkankan nínú wọn tí kò mọ̀ nípa rẹ̀, torí kò sí ìkankan nínú wọn tó ṣẹlẹ̀ ní kọ̀rọ̀.+ 27 Ọba Ágírípà, ṣé o gba àwọn Wòlíì gbọ́? Mo mọ̀ pé o gbà wọ́n gbọ́.” 28 Àmọ́ Ágírípà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò díẹ̀ sí i, wàá sọ mí* di Kristẹni.” 29 Ni Pọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ohun tí mò ń bẹ Ọlọ́run ni pé ì báà jẹ́ ní àkókò kúkúrú tàbí ní àkókò gígùn, kó má ṣe jẹ́ ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tó ń gbọ́rọ̀ mi lónìí náà dà bíi tèmi, àmọ́ láìsí nínú ìdè ẹ̀wọ̀n yìí.”
30 Lẹ́yìn náà, ọba dìde, gómìnà àti Bẹ̀níìsì pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n jọ jókòó sì dìde. 31 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń fi ibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn sọ̀rọ̀, pé: “Ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó yẹ fún ikú tàbí ìdè ẹ̀wọ̀n.”+ 32 Ágírípà wá sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “À bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ ká ní kò ké gbàjarè sí Késárì.”+