Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MAY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 4-6
“A Kò Juwọ́ Sílẹ̀”
Ó Ń Rẹ̀ Wá Àmọ́ A Kì í Ṣàárẹ̀
16 Bíbójútó ìlera wa nípa tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan-an. Tí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run bá gún régé, bó tiẹ̀ rẹ̀ wá nípa tara, ìjọsìn rẹ̀ kò ní sú wa láé. Jèhófà ni ẹni tí “ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.” (Aísáyà 40:28, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí òun fúnra rẹ̀ rí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kọ̀wé pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—2 Kọ́ríńtì 4:16.
17 Kíyè sí gbólóhùn yẹn “láti ọjọ́ dé ọjọ́.” Èyí túmọ̀ sí pé ká lo àǹfààní ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa lójoojúmọ́. Obìnrin míṣọ́nnárì kan tó ti fi òtítọ́ sìn fún ọdún mẹ́tàlélógójì kojú àwọn àkókò kan tó rẹ̀ ẹ́ nípa tara tó sì tún rẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú. Àmọ́ kò ṣàárẹ̀ nípa tẹ̀mí. Obìnrin náà sọ pé: “Mo ti sọ ọ́ dàṣà mi láti máa tètè jí kí n lè gbàdúrà sí Jèhófà kí n sì ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ èyíkéyìí tí mo bá fẹ́ ṣe. Ohun tí mo ń ṣe lójoojúmọ́ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa fara da ipò tí kò rọgbọ títí di ìsinsìnyí.” A lè gbára lé agbára tí Jèhófà fi ń gbéni ró tá a bá ń gbàdúrà sí i “láti ọjọ́ dé ọjọ́” tá a sì ń ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ gíga rẹ̀ àtàwọn ìlérí rẹ̀ déédéé.
it-1 724-725
Ìfaradà
Ó ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni máa ronú lórí ìrètí tá a ní, ìyẹn ìrètí láti wà láàyè títí láé, tá a sì máa di ẹni pípé. Kódà tí àwọn tó ń takò wá bá tiẹ̀ gbẹ̀mí wa, wọn ò lè gba ìrètí yìí lọ́wọ́ wa. (Ro 5:4, 5; 1Tẹ 1:3; Ifi 2:10) Ìyà tá à ń jẹ nísinsìnyí máa di ohun ìgbàgbé nígbà tí ìrètí àgbàyanu tá à ń fojú sọ́nà fún yìí bá nímùúṣẹ. (Ro 8:18-25) Tá a bá fi àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun wé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa báyìí, a máa rí i pé ìyà tá à ń jẹ báyìí jẹ́ “fún ìgbà díẹ̀, kò sì lágbára.” (2Kọ 4:16-18) Tí Kristẹni kan bá ń rántí pé àwọn ìyà tá à ń jẹ báyìí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, tó sì di ìrètí tó ní yìí mú ṣinṣin, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní máa kárí sọ, á sì máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Mú Inú Jèhófà Dùn”
Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé àkòrí yìí tó wá látinú Ìwé Mímọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Kí ni ìṣúra yìí? Ṣé ìmọ̀ ni tàbí ọgbọ́n? Olùbánisọ̀rọ̀ náà dáhùn pé: “Rárá o. Ìṣúra tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí,’ ìyẹn ni, ‘fífi òtítọ́ hàn kedere.’ ” (2 Kọ́ríńtì 4:1, 2, 5) Arákùnrin Splane rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé oṣù márùn-ún tí wọ́n fi kẹ́kọ̀ọ́ ti múra wọn sílẹ̀ fún àkànṣe iṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ojú pàtàkì ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi wo iṣẹ́ náà.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé “àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe” dúró fún ara èèyàn. Ó sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe àti èyí tí a fi wúrà ṣe. Àwọn ohun èlò tí a fi wúrà ṣe kì í sábà wà fún iṣẹ́. Àmọ́, iṣẹ́ ni àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe wà fún. Bí a bá fi ìṣúra kan sínú ohun èlò tí a fi wúrà ṣe, ojú iyebíye tí a fi ń wo ìṣura náà la máa fi wo ohun èlò tí a fi wúrà ṣe náà. Arákùnrin Splane wá sọ pé: “Kí ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ má ṣe pe àfiyèsí sí ara yín. Bí ẹ ṣe ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni kí ẹ dárí àwọn èèyàn sí. Ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe ni yín, ẹ mọ̀wọ̀n ara yín.”
Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní Fáwọn Ará Máa Pọ̀ Sí I
7 Àwa ńkọ́? Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ ará wa ‘gbòòrò sí i’? Ó máa ń rọrùn fáwọn tí ọjọ́ orí wọn sún mọ́ra tàbí tí wọ́n jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí ọmọ ìlú kan náà láti máa bá ara wọn rìn. Bákan náà, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí irú eré ìnàjú kan náà sábà máa ń jọ rìn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó da àwa àtàwọn Kristẹni kan pọ̀ ti ń mú ká máa yẹra fáwọn míì, ó yẹ ká “gbòòrò síwájú.” Ó bọ́gbọ́n mu ká bi ara wa léèrè pé: ‘Ṣé ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń bá àwọn tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dà wá pọ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kí n bá wọn ṣeré jáde? Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣé mo máa ń dọ́gbọ́n yẹra fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wa, torí mo gbà pé ó yẹ kó pẹ́ díẹ̀ kí n tó sọ wọ́n di ọ̀rẹ́? Ǹjẹ́ tọmọdétàgbà nínú ìjọ ni mo máa ń kí?’
Bíbélì Kíkà
MAY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 7-10
“Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe”
“Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì nípa àwọn ará Makedóníà, tí wọ́n sakun lọ́nà títayọ láti ṣe àkójọ náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà ìdánwò ńlá lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ yanturu ìdùnnú wọn àti ipò òṣì paraku wọn mú kí ọrọ̀ ìwà ọ̀làwọ́ wọn pọ̀ gidigidi.” Kò di ìgbà tí a ti àwọn ará Makedóníà kí wọ́n tó ṣiṣẹ́. Ní ìdàkejì, Pọ́ọ̀lù wí pé, “àwọn, láti inú ìdánúṣe àwọn fúnra wọn, ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.” Ìwà ọ̀làwọ́ ọlọ́yàyà tí àwọn ará Makedóníà hù túbọ̀ gbàfiyèsí, nígbà tí a bá ro ti pé àwọn fúnra wọn wà ní “ipò òṣì paraku.”—2 Kọ́ríńtì 8:2-4.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
NÍ NǸKAN bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni, ìyàn mú gan-an nílẹ̀ Jùdíà. Oúnjẹ ò tó nǹkan, ìwọ̀nba tó sì wà gbówó lórí débi pé àwọn Júù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi pàápàá ò fi bẹ́ẹ̀ rówó rà á. Ebi fẹ́rẹ̀ẹ́ lè yọ ojú wọn! Àṣé wọ́n máa tó rọ́wọ́ Jèhófà lára wọn ní irú ọ̀nà tí kò ṣẹlẹ̀ sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi rí. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
4 Nínú ìwé kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé fún wọn pé ọ̀nà méjì ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni pín sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ló darí ìwé náà sí, ọ̀rọ̀ tó sọ kan “àwọn àgùntàn mìíràn” tí Kristi sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Jòh. 10:16) Apá àkọ́kọ́ tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,” ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (2 Kọ́r. 5:18-20; 1 Tím. 2:3-6) Apá kejì jẹ mọ́ ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́’ tí Pọ́ọ̀lù sọ, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a fi ń ṣe ìrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 8:4) Ní ti gbólóhùn méjèèjì náà “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” àti ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,’ ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “iṣẹ́ òjíṣẹ́” lédè Yorùbá wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà, ìyẹn di·a·ko·niʹa. Kí nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?
5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà yìí, ńṣe ló fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù wé irú àwọn iṣẹ́ òjíṣẹ́ míì tá à ń ṣe nínú ìjọ Kristẹni. Ó ti kọ́kọ́ sọ fún wọn pé: “Onírúurú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ní ń bẹ, síbẹ̀ Olúwa kan náà ni ó wà; onírúurú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ sì ní ń bẹ, . . . Ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ìṣiṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀mí kan ṣoṣo náà ń mú ṣe.” (1 Kọ́r. 12:4-6, 11) Kódà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọ Ọlọ́run jẹ́ “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.” (Róòmù 12:1, 6-8) Abájọ tó fi kà á sí ohun pàtàkì láti yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ kó lè fi “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́”!—Róòmù 15:25, 26.
6 Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yé àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì pé iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nígbà ìṣòro jẹ́ ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìjọsìn wọn sí Jèhófà. Pọ́ọ̀lù gbà pé Kristẹni tó bá ń ṣèrànwọ́ fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń fi hàn pé òun ní “ẹ̀mí ìtẹríba fún ìhìn rere nípa Kristi.” (2 Kọ́r. 9:13) Nítorí náà, Kristẹni tó bá ń fi ẹ̀kọ́ Kristi sílò kò ní ṣàì ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ohun tí àwọn ará ń ṣe yìí jẹ́ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá.” (2 Kọ́r. 9:14; 1 Pét. 4:10) Tó bá di ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn ará wa tó wà nínú ìṣòro, tó fi mọ́ iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, Ile-Iṣọ Na June 1, 1976 sọ pé: “Àwa kò gbọ́dọ̀ ṣiyè méjì pé Jèhófà àti Jésù ka irú iṣẹ́ báyìí sí nǹkan pàtàkì.” Ó dá wa lójú ní tòótọ́ pé irú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kan tó ṣeyebíye ni iṣẹ́ ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́.—Róòmù 12:1, 7; 2 Kọ́r. 8:7; Héb. 13:16.
Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
10 Àkọ́kọ́, à ń ṣe ọrẹ àtinúwá torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà a sì fẹ́ láti ṣe “àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.” (1 Jòh. 3:22) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an bí ẹni tó ń sìn ín bá ń fínnúfíndọ̀ ṣètọrẹ látọkàn wá. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bó ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni máa fúnni. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Ẹní bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́ tìkọ̀ láti fúnni, a kì í sì í fipá mú un kó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fúnni torí pé ó ti “pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀” pé òun máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ni pé ó máa ń ronú lórí ohun tó ń fẹ́ àbójútó àti ohun tí òun lè ṣe nípa rẹ̀, lẹ́yìn náà lá wá ṣe ohun tó yẹ. Jèhófà máa ń ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n, torí pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fẹ́ràn láti máa fúnni.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Jẹ́ Kí ‘Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Aláìṣeé-Ṣàpèjúwe’ Ti Ọlọ́run Mú Ẹ Lọ́ranyàn
2 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹbọ ìràpadà Jésù ló jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe máa nímùúṣẹ. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:20.) Èyí túmọ̀ sí pé ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ ti Ọlọ́run ní nínú, ẹbọ ìràpadà Jésù, gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún wa àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ń fi hàn sí wa. Kò sí bá a ṣe ṣàlàyé ẹ̀bùn pàtàkì yìí tó, tó máa yé àwa èèyàn yékéyéké. Báwo ló ṣe yẹ kí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí rí lára wa? Báwo ni ẹ̀bùn tá a ní yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe lọ́jọ́ Wednesday, March 23, 2016?
Ǹjẹ́ Ó Lòdì Láti Yangàn?
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà kau·khaʹo·mai, táa tú sí “fi yangàn, yọ ayọ̀ ńláǹlà, ṣògo,” lọ́nà rere àti lọ́nà búburú. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé a lè “máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, lórí ìpìlẹ̀ ìrètí ògo Ọlọ́run.” Ó tún gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.” (Róòmù 5:2; 2 Kọ́ríńtì 10:17) Èyí túmọ̀ sí ṣíṣògo nínú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wa, èrò tó lè jẹ́ ká máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí orúkọ rere àti ìfùsì rẹ̀.
Bíbélì Kíkà
MAY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 11-13
“Ẹ̀gún Nínú Ara Pọ́ọ̀lù”
A Lè Jẹ́ Alágbára Láìfi Àìlera Wa Pè
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tóun náà jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, bẹ Jèhófà pé kó bá òun mú ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ẹran ara’ òun kúrò, ìyẹn ìṣòro kan tó ń yọ ọ́ lẹ́nu nígbà gbogbo. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó mú ìṣòro náà kúrò. Ohun yòówù kí ìṣòro náà jẹ́, ńṣe ló ń yọ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ṣáá bí ìgbà tí ẹ̀gún há sí i lára, èyí tó jẹ́ pé ó lè paná ayọ̀ rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó sọ pé ìṣòro náà dà bí ìgbà tí wọ́n ń gbáni lábàrá ṣáá. Kí wá ni Jèhófà sọ? Ó ní: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Jèhófà kò mú ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara Pọ́ọ̀lù kúrò. Ó wá di dandan kó máa bá a yí. Síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:7-10) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?
Jèhófà Ń fi “Ẹ̀mí Mímọ́ Fún Àwọn Tí Ń béèrè Lọ́wọ́ Rẹ̀”
17 Nígbà tí Ọlọ́run máa dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, ó sọ fún un pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́.” (2 Kọ́ríńtì 12:9; Sáàmù 147:5) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù rí i pé Ọlọ́run tipa Kristi da ààbò rẹ̀ tó nípọn bo òun bí àgọ́. Bákan náà lónìí, bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa jọ ìyẹn. Ó máa ń da ààbò rẹ̀ tó nípọn bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí àgọ́.
18 Lóòótọ́, àgọ́ tàbí ilé tó ní òrùlé kò lè dá òjò dúró kó má rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò lè da ìjì dúró kó má jà, àmọ́ kò ní jẹ́ kí òjò pa ẹni tó bá sá sábẹ́ rẹ̀ yóò sì tún dáàbò bò ó lọ́wọ́ ìjì. Bákan náà, “agbára Jésù” tó dà bí àgọ́ tàbí ilé kò ní káwa ìránṣẹ́ Jèhófà má ní ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni kò dá àwọn èèyàn dúró kí wọ́n má kó ìṣòro bá wa. Àmọ́, ó ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé kì í jẹ́ kí ohunkóhun bá àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ nínú ayé yìí, ó sì ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ Sátánì tí ń ṣàkóso ayé. (Ìṣípayá 7:9, 15, 16) Torí náà, bí ìṣòro kan bá tilẹ̀ ń bá ọ fínra, tí ìṣòro ọ̀hún ò ‘kúrò lára rẹ,’ kí ó dá ọ lójú pé Jèhófà rí gbogbo bó o ṣe ń tiraka àti pé ó ń ṣe nǹkan kan nípa “igbe ẹkún rẹ.” (Aísáyà 30:19; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13; Fílípì 4:6, 7.
“Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
8 Ka Aísáyà 40:30. Bó ti wù ká ní òye tàbí ìrírí tó, ó lójú ohun tá a lè dá ṣe. Kókó pàtàkì nìyí, ó sì yẹ ká máa fi í sọ́kàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ohun tó wù ú láti ṣe ló ṣe torí pé ẹlẹ́ran ara lòun náà. Nígbà tó sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Ohun tí Ọlọ́run sọ yé Pọ́ọ̀lù dáadáa, abájọ tó fi sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:7-10) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?
9 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé láìsí ìrànwọ́ Ọlọ́run, ó lójú ohun tí òun lè dá ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù ní agbára. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn nǹkan tó ju agbára òun fúnra rẹ̀ lọ. Bíi ti Pọ́ọ̀lù lọ̀rọ̀ tiwa náà rí. Tá a bá rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó dájú pé àwa náà máa ní agbára láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
“Ó ṣeé ṣe kí “ọ̀run kẹta” tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 12:2 tọ́ka sí Ìjọba Mèsáyà tí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣàkóso, ìyẹn sì ni Bíbélì pè ní “ọ̀run tuntun.”—2 Pét. 3:13.
Ó tún jẹ́ “ọ̀run kẹta” torí pé Ìjọba náà ga lọ́lá kò sì láfiwé.
Párádísè” tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran náà ṣeé ṣe kó jẹ́ (1) Párádísè tá à ń retí lórí ilẹ̀ ayé, (2) Párádísè tẹ̀mí tá a máa gbádùn nígbà yẹn, èyí táá gbòòrò ju Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí lọ àti (3) “párádísè Ọlọ́run” tó wà lọ́run lásìkò kan náà pẹ̀lú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
it-2 177
Ìfẹnukonu
“Ìfẹnukonu Mímọ́.” Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń fún ara wọn ní “ìfẹnukonu mímọ́” (Ro 16:16; 1Kọ 16:20; 2Kọ 13:12; 1Tẹ 5:26) tàbí “ìfẹnukonu ìfẹ́” (1Pe 5:14), bóyá láàárín ọkùnrin sí ọkùnrin àti obìnrin sí obìnrin. Àwọn Hébérù máa ń fẹnu ko ara wọn lẹ́nu láti kí ara wọn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àṣà yìí ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ lé. Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ fún wa nípa “ìfẹnukonu mímọ́” tàbí “ìfẹnukonu ìfẹ́” àmọ́ ìfẹnukonu yìí fi hàn pé ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ Kristẹni.—Jo 13:34, 35.
Bíbélì Kíkà
MAY 27–JUNE 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | GÁLÁTÍÀ 1-3
“Mo Ta Kò Ó Lójúkojú”
Ṣé Èrò Tí Jèhófà Ní Nípa Ìdájọ́ Òdodo Ni Ìwọ Náà Ní?
16 Ka Gálátíà 2:11-14. Ìbẹ̀rù èèyàn ló mú kí Pétérù ṣe àṣìṣe yìí. (Òwe 29:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù mọ̀ pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba àwọn tí kì í ṣe Júù, síbẹ̀ kò fẹ́ káwọn Júù tó wá láti ìjọ ní Jerúsálẹ́mù fojú burúkú wo òun, torí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn tí kì í ṣe Júù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà wà nípàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni lọ bá Pétérù, ó kò ó lójú, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìwà àgàbàgebè ló hù yẹn. (Ìṣe 15:12; Gál. 2:13) Kí làwọn Kristẹni tí Pétérù ń yẹra fún máa ṣe sí àìdáa tó ṣe sí wọn? Ṣé wọ́n á jẹ́ kíyẹn mú àwọn kọsẹ̀? Ṣé àṣìṣe yìí sì máa mú kí Pétérù pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?
‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
12 Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń mú kí Pétérù ṣe àṣìṣe nígbà míì. Síbẹ̀, kò kọ Jésù sílẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mẹ́ta ni Pétérù sọ pé òun kò mọ Jésù. (Lúùkù 22:54-62) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó mú kí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni rí ara wọn bíi pé wọ́n sàn ju àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni lọ. Ohun tí Pétérù ṣe yẹn kò dára, ó sì lè mú káwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú ìjọ. Torí náà, Pọ́ọ̀lù bá a wí gidigidi. (Gál. 2:11-14) Ṣé ìyẹn wá mú kí ìgbéraga ru bo Pétérù lójú débi tí kò fi sá eré ìje náà mọ́? Rárá o. Ńṣe ló ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó fara mọ́ ìbáwí náà, ó sì ń sá eré ìje náà nìṣó.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí
20 Kí la máa ṣe tí Sátánì bá gbéjà kò wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́? Bí àpẹẹrẹ, báwo la ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì? Ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tá a lè ṣe ni pé ká fara balẹ̀ ronú lórí ìràpadà. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn. Nígbà míì ó máa ń ṣe é bíi pé ó jẹ́ abòṣì èèyàn, ìyẹn ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ẹni pípé ni Jésù kú fún, bí kò ṣe, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Pọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Kódà, ó kọ̀wé pé: “Mo ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gál. 2:20) Pọ́ọ̀lù mọrírì ìràpadà. Ó mọ̀ pé ìràpadà náà dìídì ṣiṣẹ́ fún òun.
21 Tí ìwọ náà bá ń wo ìràpadà bí ẹ̀bùn tí Jèhófà dìídì fún ẹ, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àmọ́, èyí ò sọ pé ìrẹ̀wẹ̀sì máa pòórá lójú ẹsẹ̀ o. Dé ìwọ̀n àyè kan, ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú wa máa dojú kọ àtakò tí Sátánì ń gbé kò wá lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ títí ayé tuntun fi máa dé. Àmọ́ má gbàgbé pé: Àwọn tí kò bá juwọ́ sílẹ̀ ló máa gba èrè náà. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, a ti sún mọ́ ọjọ́ ológo náà tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà jọba, táá sì mú kí gbogbo olóòótọ́ èèyàn pa dà di ẹ̀dá pípé. Torí náà, pinnu pé wàá wọ Ìjọba Ọlọ́run, ì báà tiẹ̀ jẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú.
it-1 880
Lẹ́tà Sí Àwọn Ará Gálátíà
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà”! kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ẹ̀yà kan ní pàtó, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Gallic ní apá àríwá ìlú Gálátíà ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí. (Ga 3:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn kan nínú ìjọ ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí, àwọn wọ̀nyí gbà pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú káwọn Kristẹni jẹ́ olódodo ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, dípò kí wọ́n jẹ́ “olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́” bó ṣe wà nínú májẹ̀mú tuntun. (2:15–3:14; 4:9, 10) Oríṣiríṣi ẹ̀yà ló wà ní “àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà” (1:2), Júù wà nínú wọn àtàwọn tí kì í ṣe Júù, ìjọ yẹn sì ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí. Àwọn aláwọ̀ṣe Júù tó ti dádọ̀dọ́ náà wà láàárín wọn títí kan àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́, ó sì dájú pé àwọn míì nínú wọn ti fìgbà kan rí wà nínú ẹ̀sìn Celtic. (Iṣe 13:14, 43; 16:1; Ga 5:2) Gbogbo wọn pátá ni Pọ́ọ̀lù pè ní Kristẹni ará Gálátíà, ìdí sì ni pé Gálátíà ni wọ́n ń pe ibi tí gbogbo wọn ń gbé. Kókó tá a ní láti mọ̀ nípa lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ yìí ni pé, àwọn èèyàn tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń gbé ní ìpínlẹ̀ Gálátíà tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ló kọ ọ̀rọ̀ yìí sí. Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù ò dé apá àríwá rí, kò sì mọ àwọn tó wà níbẹ̀, torí náà àwọn kọ́ ló ń bá wí.
it-2 587 ¶3
Pọ́ọ̀lù
Ọ̀rọ̀ Ìdádọ̀dọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn, Pétérù wá sí Áńtíókù ti Síríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù. Àmọ́, nígbà táwọn Júù kan dé láti Jerúsálẹ́mù, ìbẹ̀rù èèyàn mú un, ò sì bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù, ohun tó ṣe yìí lòdì sí ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run, torí pé kì í ṣe ìdádọ̀dọ́ ló ń mú kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run. Kódà, Bánábà náà bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí èyí, ó fìgboyà bá Pétérù wí lójú gbogbo wọn, torí pé ohun tí Pétérù ṣe yẹn lè dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni.—Ga 2:11-14
Bíbélì Kíkà