“Àwọn Tí A Ń Pè Ní ‘Ọlọ́run’”
NÍ LÍSÍRÀ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú ọkùnrin kan tó yarọ lára dá, àwọn èèyàn pariwo pé: “Àwọn ọlọ́run ti dà bí ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ wá wá!” Wọ́n pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, wọ́n sì pe Bánábà ẹni kejì rẹ̀ ní Súúsì. (Ìṣe 14:8-14) Ní Éfésù, Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé bí wọ́n bá gba Pọ́ọ̀lù láyè láti máa bá ìwàásù rẹ̀ lọ, “tẹ́ńpìlì ńlá ti abo ọlọ́run Átẹ́mísì pẹ̀lú ni a ó kà sí asán.”—Ìṣe 19:24-28.
Ní ọ̀rúndún kìíní àwọn èèyàn máa ń jọ́sìn “àwọn tí a ń pè ní ‘ọlọ́run’ . . . , yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé,” bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣe lónìí. Kódà, Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ‘ọlọ́run’ àti ọ̀pọ̀ ‘olúwa’” ló wà. Àmọ́, ó tún ṣàlàyé pé: “Fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba,” “Olúwa kan ni ó sì ń bẹ, Jésù Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 8:5, 6.
Ǹjẹ́ Wọ́n Pe Jésù Pẹ̀lú Ní Ọlọ́run?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò fìgbà kan rí sọ pé Ọlọ́run lòun, gẹ́gẹ́ bí alákòóso tí Jèhófà yàn, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nínú Bíbélì pè é ní “Ọlọ́run Alágbára Ńlá” àti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ Aládé,” ìyẹn ọmọ Jèhófà, Ọba Ńlá tó ń fọba jẹ, Jésù yóò jẹ Alákòóso ìjọba ọ̀run ti “Ọlọ́run Olódùmarè.”—Ẹ́kísódù 6:3.
Síbẹ̀ ẹnì kan lè béèrè pé ‘Lọ́nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Ọlọ́run Alágbára Ńlá,” àti pé ṣebí àpọ́sítélì Jòhánù ṣáà sọ pé Jésù fúnra rẹ̀ ni Ọlọ́run?’ Nínú ìtumọ̀ Bíbélì Mímọ́, Jòhánù 1:1 kà pé: “Li àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.” Iyàn táwọn kan máa ń jà ni pé ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé “Ọ̀rọ na,” tí obìnrin kan bí sáyé tó di Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè fúnra rẹ̀. Ṣé lóòótọ́ ni?
Tá a bá sọ pé ìtumọ̀ ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè, ìyẹn á ta ko gbólóhùn tó ṣáájú gbólóhùn náà pé, “Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun.” Tá a bá sọ pé ẹnì kan wà “pẹ̀lú” ẹlòmíràn, onítọ̀hún ò tún lè jẹ́ ẹni tí wọ́n jọ wà. Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn méjèèjì, tó fi lè ṣe kedere pé Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tá a ṣàyẹ̀wò sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ Ọlọ́run kan,” “ọlọ́run kan ni Ọ̀rọ̀ náà,” àti “ará ọ̀run ni Ọ̀rọ̀ náà.”a
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ẹ̀hun ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tó wà nínú wọn jọra pẹ̀lú èyí tó wà ní Jòhánù 1:1 lo ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́run kan.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èrò ń sábà Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní, wọ́n pariwo pé, ‘ọlọ́run kan ló ń sọ̀rọ̀.’ Bákan náà, nígbà tí ejò olóró kan bu Pọ́ọ̀lù ṣán tí Pọ́ọ̀lù kò sì kú, àwọn èèyàn sọ pé, “ọlọ́run kan ni.” (Ìṣe 12:22; 28:3-6) Ó bá gírámà èdè Gíríìkì àti Bíbélì mu láti sọ pé Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ “ọlọ́run kan,” kì í ṣe Ọlọ́run.—Jòhánù 1:1.
Ẹ̀yin ẹ wo bí Jòhánù ṣe fi ẹni tí “Ọ̀rọ̀ náà” jẹ́ hàn nínú orí kìíní Ìhìn Rere rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara, ó sì gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, ògo kan [tí kì í ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe] irú èyí tí ó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo láti ọ̀dọ̀ baba kan.” Fún ìdí èyí àwọn èèyàn rí “Ọ̀rọ̀ náà,” tó di elẹ́ran ara, tó sì gbé láyé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jésù. Ìdí tí kò fi lè jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè nìyẹn nítorí Jòhánù sọ nípa rẹ̀ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.”—Jòhánù 1:14, 18.
Ẹlòmíì tún lè béèrè pé: ‘Ó dáa nígbà náà, kí ló dé tí Tọ́másì fi sọ pé “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”’ nígbà tó rí Jésù tó ti jínde? Bá a ṣe sọ sáájú ọlọ́run kan ni Jésù nítorí pé ará ọ̀run ni, ṣùgbọ́n kì í ṣe òun ni Baba. Kò tíì pẹ́ sígbà yẹn tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Màríà Magidalénì pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” Ẹ má sì gbàgbé ìdí tí Jòhánù fi kọ Ìhìn Rere rẹ̀ o. Ní ẹsẹ kẹrin sí ẹsẹ tí Jòhánù ti sọ̀rọ̀ Tọ́másì, ó ṣàlàyè pé ìdí tóun fi kọ̀wé Ìhìn Rere òun ni torí káwọn èèyàn lè “gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run,” kì í ṣe Ọlọ́run.—Jòhánù 20:17, 28, 31.
Ta Ni “Ọlọ́run Ayé Yìí”?
Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ọlọ́run ló wà. A ti rí i pé wọ́n dárúkọ àwọn kan lára wọn nínú Bíbélì. Àmọ́, àwọn tí wọ́n fojú rí agbára Jèhófà láyé àtijọ́ pariwo pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” (1 Àwọn Ọba 18:39) Ṣùgbọ́n ọlọ́run míì wà tó lágbára ṣá o. Bíbélì sọ pé, “ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju.”—2 Kọ́ríńtì 4:4, Bíbélì Mímọ́.
Lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ló kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ọlọ́run yìí, ó pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí.” Jésù sọ pé olùṣàkóso tó lágbára yìí tàbí ọlọ́run, “ni a óò lé jáde.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11) Ta ni ọlọ́run yìí, orí ayé wo sì ló jẹ olùṣàkóso lé?
Ẹyẹ méjì kì í jẹ́ àṣà, áńgẹ́lì tó dìtẹ̀ yẹn náà ni, ìyẹn Sátánì Èṣù. Báwo la ṣe mọ̀? Bíbélì ṣàlàyé pé nígbà tí Sátánì ń dán Jésù wò, Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’” (Mátíù 4:8, 9) A ò lè pe ìyẹn ní àdánwò tó bá jẹ́ pé Sátánì kọ́ ló ni ohun tó fi lọ Jésù. Àní, àpọ́sítélì Jòhánù là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.
Ẹ rántí pé Jésù ṣèlérí pé, “olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.” (Jòhánù 12:31) Kódà, ayé yìí, tàbí ètò àwọn nǹkan, tó fi mọ́ alákòóso rẹ̀ yóò dàwátì, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nígbà tó wí pé: “Ayé ń kọjá lọ.” Àmọ́ Jòhánù tún fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jọ wo ohun ológo tí Ọlọ́run tóòtọ́ kan ṣoṣo náà fẹ́ ṣe àti bá a ṣe lè fi ṣèrè jẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn Bíbélì wọ̀nyí lédè Gẹ̀ẹ́sì: The New Testament, látọwọ́ James L. Tomanek; The Emphatic Diaglott, tó ní èdè Gíríìkì nínú, látọwọ́ Benjamin Wilson; The Bible—An American Translation, látọwọ́ J.M.P. Smith àti E. J. Goodspeed.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Àwọn èèyàn Lísírà ti fẹ́ máa pe Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Jésù sọ fún Màríà Magidalénì pé: ‘Mo ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run rẹ’