Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń lé Òkùnkùn Dà Nù!
“Jèhófà . . . ni ó mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.”—2 SÁMÚẸ́LÌ 22:29.
1. Báwo ni ìmọ́lẹ̀ ṣe tan mọ́ ìwàláàyè?
“ỌLỌ́RUN sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: ‘Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.’ Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ wá wà.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:3) Àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyẹn nínú ìtàn ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ló fi hàn pé Jèhófà ni orísun ìmọ́lẹ̀, tó jẹ́ pé láìsí i, ìwàláàyè kò ní ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà tún ni orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, tó ṣe pàtàkì fún ṣíṣamọ̀nà wa nínú ìgbésí ayé. (Sáàmù 43:3) Dáfídì Ọba fi ìbáratan tó wà láàárín ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí àti ìwàláàyè hàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwa fi lè rí ìmọ́lẹ̀.”—Sáàmù 36:9.
2. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, ìmọ́lẹ̀ ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú kí ni?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ìtàn ìṣẹ̀dá kan náà yẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn àkókò Dáfídì. Nígbà tó ń kọ̀wé sí ìjọ Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé: ‘Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn.’” Pọ́ọ̀lù wá fi hàn pé ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìmọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá nígbà tó fi kún un pé: “Ó sì ti tàn sí ọkàn-àyà wa láti fi ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run tànmọ́lẹ̀ sí i nípasẹ̀ ojú Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 4:6) Báwo ni ìmọ́lẹ̀ yìí ṣe ń dé ọ̀dọ̀ wa?
Bíbélì Ló Ń Ta Àtaré Ìmọ́lẹ̀ Náà
3. Ìmọ́lẹ̀ wo ni Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Bíbélì?
3 Olórí ohun tí Jèhófà ń lò láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí. Nítorí náà, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń gba ìmọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sínú ọkàn wa, ńṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn wọnú ọkàn wa. Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sórí àwọn ète rẹ̀, ó sì ń sọ bí a ó ṣe ṣe ìfẹ́ rẹ̀ fún wa nípasẹ̀ Bíbélì. Èyí ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa ní ète nínú, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ́ àìní wa nípa tẹ̀mí lọ́rùn. (Oníwàásù 12:1; Mátíù 5:3) Jésù tẹnu mọ́ ọn pé a gbọ́dọ̀ bìkítà nípa àìní wa nípa tẹ̀mí. Ó tẹnu mọ́ èyí nígbà tó tọ́ka sí Òfin Mósè tó sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’”—Mátíù 4:4; Diutarónómì 8:3.
4. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé”?
4 Jésù ni a mọ̀ sí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Àní, ó pe ara rẹ̀ ní “ìmọ́lẹ̀ ayé,” ó sì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòhánù 8:12) Gbólóhùn yìí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ipa pàtàkì tí Jésù kó nínú sísọ òtítọ́ Jèhófà fún aráyé. Bí a bá fẹ́ yàgò fún òkùnkùn kí a sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ fetí sí gbogbo ohun tí Jésù sọ, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú Bíbélì.
5. Ẹrù iṣẹ́ wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní lẹ́yìn ikú rẹ̀?
5 Ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, ó tún pe ara rẹ̀ ní ìmọ́lẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ìmọ́lẹ̀ yóò wà láàárín yín fún ìgbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn má bàa borí yín; ẹni tí ó bá sì ń rìn nínú òkùnkùn kò mọ ibi tí òun ń lọ. Nígbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ náà, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, láti lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (Jòhánù 12:35, 36) Àwọn tó di ọmọ ìmọ́lẹ̀ kọ́ “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tó wà nínú Bíbélì. (2 Tímótì 1:13, 14) Lẹ́yìn náà, wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera wọ̀nyí fa àwọn olóòótọ́ ọkàn jáde látinú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run.
6. Òtítọ́ pọ́ńbélé wo la rí nípa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn nínú 1 Jòhánù 1:5?
6 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀, kò sì sí òkùnkùn kankan rárá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Jòhánù 1:5) Kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn níhìn-ín. Ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, òkùnkùn tẹ̀mí kò sí ní sàkáání rẹ̀ rárá. Ta wá ni orísun òkùnkùn náà?
Orísun Òkùnkùn Tẹ̀mí
7. Ta ni orísun òkùnkùn tẹ̀mí tó bo ayé, ipa wo ló sì ní?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” Sátánì Èṣù ló ní lọ́kàn nínú gbólóhùn tó lò yẹn. Ó tún sọ pé ẹni yìí “ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ọ̀pọ̀ ló sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́; síbẹ̀ iye tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i lára wọn ni kò gbà pé Èṣù wà. Kí nìdí? Wọn ò fẹ́ gbà pé ẹ̀mí búburú kan, tí agbára rẹ̀ ju ti ẹ̀dá lè wà tó ń darí ìrònú àwọn. Àmọ́ wọ́n gbà tàbí wọn ò gbà, Èṣù wà, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, òun ni kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́. Agbára tí Sátánì ní láti darí ìrònú àwọn èèyàn la rí nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tá a sọ nípa rẹ̀, pé òun ni “ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Nítorí ìgbòkègbodò Sátánì, ipò tí wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ti wá nímùúṣẹ lórí gbogbo aráyé báyìí, àyàfi àwọn tó ń sin Jèhófà nìkan. Ó sọ pé: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.”—Aísáyà 60:2.
8. Báwo làwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí ṣe ń fi hàn pé ọkàn àwọn pòrúurùu?
8 Kò sí béèyàn ṣe lè rí ohunkóhun nínú òkùnkùn biribiri. Kíá lèèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí táràrà kiri tàbí kí ọkàn olúwarẹ̀ tiẹ̀ pòrúurùu. Bákan náà làwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí kì í ríran, tí ọkàn wọn kì í sì í pẹ́ pòrúurùu nípa tẹ̀mí. Wọ́n lè dẹni tí kò mọ ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ àti èké mọ́, tí wọn ò sì ní mọ rere yàtọ̀ sí búburú. Wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà nínú irú òkùnkùn bẹ́ẹ̀ nígbà tó kọ̀wé pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára, àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn, àwọn tí ń fi ohun kíkorò dípò dídùn àti ohun dídùn dípò kíkorò!” (Aísáyà 5:20) Ọlọ́run òkùnkùn, ìyẹn Sátánì Èṣù ló ń darí àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí, ìdí sì nìyẹn tí wọ́n fi kẹ̀yìn sí orísun ìmọ́lẹ̀ àti ìyè.—Éfésù 4:17-19.
Ìṣòro Tó Wà Nínú Títi Inú Òkùnkùn Bọ́ Sínú Ìmọ́lẹ̀
9. Ṣàlàyé báwọn oníwà àìtọ́ ṣe nífẹ̀ẹ́ sí òkùnkùn gidi àti òkùnkùn tẹ̀mí.
9 Jóòbù olóòótọ́ nì mẹ́nu kan bí àwọn tí ń hùwà àìtọ́ ṣe nífẹ̀ẹ́ sí òkùnkùn gidi, nígbà tó sọ pé: “Ní ti ojú panṣágà, ó dúró de òkùnkùn alẹ́, ó wí pé, ‘Kò sí ojú tí yóò rí mi!’ Ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀.” (Jóòbù 24:15) Àwọn tí ń hùwà àìtọ́ tún wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí, irú òkùnkùn yẹn sì lè borí ẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìwà pálapàla takọtabo, olè jíjà, ìwọra, ìmutípara, ìkẹ́gàn, àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó wà nínú òkùnkùn yẹn. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá wá sínú ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí padà. Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ ní kedere pé irú ìyípadà yẹn ṣeé ṣe nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ló ń ṣe iṣẹ́ òkùnkùn tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
10, 11. Báwo ni Jésù ṣe gba ti ọkùnrin afọ́jú tó wò sàn rò? (b) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi yan ìmọ́lẹ̀?
10 Nígbà tẹ́nì kan bá tinú òkùnkùn biribiri bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kó gba àkókò díẹ̀ kí ìmọ́lẹ̀ náà tó bá a lójú mu. Jésù wo ọkùnrin afọ́jú kan sàn ní Bẹtisáídà, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ló rọra ń ṣe é. “Ó . . . di ọwọ́ ọkùnrin afọ́jú náà mú, ó mú un jáde sẹ́yìn òde abúlé náà, àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́ sí ojú rẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ìwọ ha rí ohunkóhun bí?’ Ọkùnrin náà sì gbé ojú sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: ‘Mo rí àwọn ènìyàn, nítorí mo ṣàkíyèsí àwọn ohun tí ó jọ igi, ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn káàkiri.’ Lẹ́yìn náà, ó tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkùnrin náà, ọkùnrin náà sì ríran kedere, a sì mú un padà bọ̀ sípò, ó sì ń rí ohun gbogbo ní ketekete.” (Máàkù 8:23-25) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kí ìtànṣán oòrùn má bàa wọ ọkùnrin náà lójú ló jẹ́ kí Jésù rọra máa la ojú rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. A lè fojú inú wo bí ayọ̀ ọkùnrin náà ṣe pọ̀ tó nígbà tó ṣeé ṣe fún un láti ríran.
11 Bó ti wù kó rí, kékeré ni ayọ̀ tí ọkùnrin yẹn ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn tá a ràn lọ́wọ́ láti tinú òkùnkùn tẹ̀mí jáde díẹ̀díẹ̀ bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ òtítọ́. Nígbà tá a bá rí i bí ayọ̀ wọn ṣe pọ̀ tó, a lè máa ṣe kàyéfì nípa ìdí táwọn púpọ̀ sí i kò fi wá sínú ìmọ́lẹ̀. Jésù sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ fún wa pé: “Èyí ni ìpìlẹ̀ fún ìdájọ́, pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí pé àwọn iṣẹ́ wọn burú. Nítorí ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa fi ìbáwí tọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà.” (Jòhánù 3:19, 20) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ ló nífẹ̀ẹ́ sí fífi “ohun búburú” ṣe ìwà hù—bí ìwà pálapàla, ìninilára, irọ́ pípa, lílu jìbìtì, àti olè jíjà—inú òkùnkùn tẹ̀mí Sátánì sì ni àyè ti gbà wọ́n láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.
Títẹ̀ Síwájú Nínú Ìmọ́lẹ̀
12. Báwo la ṣe jàǹfààní nínú wíwá tá a wá sínú ìmọ́lẹ̀?
12 Látìgbà tá a ti wá sínú ìmọ́lẹ̀ náà, àwọn ìyípadà wo la ti rí nínú ara wa? Ó sábà máa ń dára láti bojú wẹ̀yìn ká sì wo ìlọsíwájú tá a ti ní nípa tẹ̀mí. Àwọn ìwà búburú wo la ti pa tì? Àwọn ìṣòro wo la ti yanjú nínú ìgbésí ayé wa? Báwo làwọn ìwéwèé wa fún ọjọ́ iwájú ṣe yí padà? Ní agbára Jèhófà, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, a lè máa bá a lọ láti yí àkópọ̀ ìwà wa àti ọ̀nà tí a gbà ń ronú padà lọ́nà tí yóò fi hàn pé à ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ náà. (Éfésù 4:23, 24) Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà báyìí pé: “Ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ nísinsìnyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa. Ẹ máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀, nítorí pé èso ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo onírúurú ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ nínú.” (Éfésù 5:8, 9) Bí a bá jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ Jèhófà máa darí wa, a óò ní ìrètí àti ète, á sì fi ayọ̀ kún ìgbésí ayé àwọn tó yí wa ká. Ẹ sì wo bí ṣíṣe tí à ń ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ ṣe ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀ tó!—Òwe 27:11.
13. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún ìmọ́lẹ̀ Jèhófà, kí la sì nílò láti lè tọ irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀?
13 À ń fi ìmọrírì hàn fún ìgbésí ayé aláyọ̀ tá à ń gbádùn nípa gbígbé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yọ—sísọ ohun tí a ti kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́, àtàwọn aládùúgbò wa. (Mátíù 5:12-16; 24:14) Ìbáwí ni ìwàásù wa àti ìgbésí ayé àwòfiṣàpẹẹrẹ tó bá ìlànà Kristẹni mu tí à ń gbé jẹ́ fún àwọn tó kọ̀ láti fetí sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú; ẹ sì jáwọ́ nínú ṣíṣàjọpín pẹ̀lú wọn nínú àwọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, àní kí ẹ máa fi ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà.” (Éfésù 5:10, 11) Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fi òkùnkùn sílẹ̀ kí wọ́n sì yan ìmọ́lẹ̀ béèrè pé ká ní ìgboyà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gba pé ká ní ìyọ́nú, ká sì bìkítà fún àwọn ẹlòmíràn, ká sì ní ìfẹ́ àtọkànwá láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, fún àǹfààní wọn ayérayé.—Mátíù 28:19, 20.
Ṣọ́ra fún Ìmọ́lẹ̀ Ẹ̀tàn O!
14. Ní ti ọ̀ràn ìmọ́lẹ̀, ìkìlọ̀ wo la gbọ́dọ̀ kọbi ara si?
14 Kò sí ìmọ́lẹ̀ tí àwọn tó wà létíkun kì í gbá tẹ̀ lé nígbà tí òkùnkùn bá ṣú. Láyé àtijọ́, iná ni wọ́n máa ń dá sí àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ibi tí wọ́n ti lè rí ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì. Inú àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òkun máa ń dùn nígbà tí àwọn iná wọ̀nyí bá darí wọn láti gúnlẹ̀ sáwọn èbúté tí kò léwu. Àmọ́ àwọn iná kan wà tó ń tanni jẹ. Dípò tí wọn ì bá fi rí èbúté, ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ló ti ṣì lọ́nà, tí wọ́n sì ti rì sórí iyanrìn, níbi táwọn olè tí jí gbogbo ẹrù inú wọn kó lọ. Nínú ayé ẹ̀tàn yìí, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má bàa forí lé ibi tí ìmọ́lẹ̀ tí ń tanni jẹ wà, èyí tó lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa. A sọ fún wa pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” Bákan náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, títí kan àwọn apẹ̀yìndà jẹ́ “oníṣẹ́ ẹ̀tàn” tí àwọn “pẹ̀lú . . . ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo.” Tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí èrò òdì irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí mikàn nípa Bíbélì, Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Jèhófà, ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sì lè rì.—2 Kọ́ríńtì 11:13-15; 1 Tímótì 1:19.
15. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè?
15 Onísáàmù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà, Ọlọ́rùn wa onífẹ̀ẹ́, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” ti tan ìmọ́lẹ̀ rokoṣo sí ‘ojú ọ̀nà híhá tó lọ sínú ìyè.’ (Mátíù 7:14; 1 Tímótì 2:4) Fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò yóò dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ rírìn gbéregbère kúrò ní ojú ọ̀nà híhá yẹn lọ sí ojú ọ̀nà òkùnkùn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Bá a ṣe ń dàgbà nípa tẹ̀mí ni à ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa. A lè fi Ìwé Mímọ́ bá ara wa wí, tàbí kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ fi bá wa wí, bí a bá ṣe ohun tí ìbáwí fi tọ́ sí wa. Bákan náà la lè mú àwọn nǹkan tọ́, kí a sì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìbáwí nínú òdodo kí a lè máa bá a lọ ní rírìn ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè.
Fífi Ìmọrírì Rìn Nínú Ìmọ́lẹ̀
16. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu tí Jèhófà fún wa?
16 Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu tí Jèhófà fún wa? Jòhánù orí kẹsàn-án sọ fún wa pé lẹ́yìn tí Jésù wo ọkùnrin tí a bí ní afọ́jú náà sán, inú ọkùnrin náà dùn, ó sì fi ìmọrírì rẹ̀ hàn. Lọ́nà wo? Ó gbà gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, ó sì là á mọ́lẹ̀ ní gbangba pé “wòlíì ni.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún fi ìgboyà sọ̀rọ̀ sí àwọn tó fẹ́ bẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. (Jòhánù 9:17, 30-34) Àpọ́sítélì Pétérù pe àwọn ẹni àmì òróró inú ìjọ Kristẹni ní “àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” Kí nìdí? Nítorí pé wọ́n ní ẹ̀mí ìmọrírì kan náà tí ọkùnrin tí a bí ní afọ́jú, tí ó sì rí ìwòsàn náà ní. Wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Olóore wọn, nípa ‘pípolongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè wọ́n jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.’ (1 Pétérù 2:9; Kólósè 1:13) Àwọn tó ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé ní ẹ̀mí ìmoore kan náà, wọ́n sì ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin wọn nínú pípolongo “ìtayọlọ́lá” Jèhófà ní gbangba. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni Jèhófà fún àwa ẹ̀dá aláìpé!
17, 18. (a) Kí ni ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? (b) Kí la rọ Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti yẹra fún, ní ṣíṣe àfarawé Tímótì?
17 Ó ṣe pàtàkì láti ní ìmọrírì àtọkànwá fún ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà. Rántí pé a kò bí ìmọ̀ òtítọ́ mọ́ ìkankan nínú wa. Àwọn kan ti dàgbà tán kí wọ́n tó mọ̀ ọ́n, kíákíá ni wọ́n sì rí i pé ìmọ́lẹ̀ dára ju òkùnkùn lọ. Àwọn mìíràn ní àǹfààní ńlá pé àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló tọ́ wọn dàgbà. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè má fọwọ́ dan-indan-in mú ìmọ́lẹ̀ náà. Ẹlẹ́rìí kan tí àwọn òbí rẹ̀ ti ń sin Jèhófà kí wọ́n tó bí i, sọ pé ó gba òun ní àkókò àti ìsapá gan-an kí òun tó lóye ìjẹ́pàtàkì òtítọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ òun láti ọmọ ọwọ́. (2 Tímótì 3:15) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, lọ́mọdé lágbà, ló gbọ́dọ̀ ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún òtítọ́ tí Jèhófà ti ṣí payá.
18 Láti ìgbà ọmọ ọwọ́ ni wọ́n ti fi “ìwé mímọ́” kọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà, Tímótì. Àmọ́ ìgbà tó wá fúnra rẹ̀ sapá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ló tó di Kristẹni tó dàgbà dénú. (2 Tímótì 3:15) Ìgbà yẹn ló tó tóótun láti di olùrànlọ́wọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tó gbà á níyànjú pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” Bíi ti Tímótì, ǹjẹ́ kí gbogbo wa yàgò fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè kó ìtìjú bá wa—tàbí tó lè dójú ti Jèhófà nítorí tiwa!—2 Tímótì 2:15.
19. (a) Bíi ti Dáfídì, kí ló yẹ kí gbogbo wa sọ? (b) Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Kò sídìí tí a ò fi ní yin Jèhófà lógo, ẹni tó fún wa ní ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ rẹ̀. Bíi ti Dáfídì Ọba, àwa náà sọ pé: “Ìwọ ni fìtílà mi, Jèhófà, Jèhófà sì ni ó mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 22:29) Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù, níwọ̀n bí èyí ti lè mú ká padà sínú òkùnkùn tá a ti mú wa jáde. Nítorí náà, àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò bí òtítọ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó nínú ìgbésí ayé wa.
Kí Ni O Ti Kọ́?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ìlàlóye tẹ̀mí?
• Ìpèníjà wo ni òkùnkùn tẹ̀mí tó yí wa ká ń gbé dìde?
• Àwọn ewu wo ló yẹ ká yẹra fún?
• Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn fún ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Jèhófà ni orísun ìmọ́lẹ̀ tí a lè rí àti ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bí Jésù ṣe wo ọkùnrin afọ́jú kan sàn díẹ̀díẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti jáde kúrò nínú òkùnkùn tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Dídi ẹni tí ìmọ́lẹ̀ èké Sátánì tàn jẹ lè mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì