Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kọ́ríńtì Kìíní àti Ìkejì
Ọ̀RỌ̀ bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìjọ Kọ́ríńtì wà lórí ẹ̀mí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó ti gbọ́ pé ìyapa wà láàárín àwọn ará tó wà níbẹ̀. Wọ́n sì ń fàyè gba ìṣekúṣe. Àwọn ará ìjọ yẹn sì tún kọ̀wé sí Pọ́ọ̀lù láti bi í ní ìbéèrè lórí àwọn ọ̀ràn kan. Torí ìdí èyí, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nílùú Éfésù ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, ní ìrìn àjò kẹta tó rìn lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó kọ àkọ́kọ́ nínú lẹ́tà méjì tó kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì.
Lẹ́tà rẹ̀ kejì jẹ́ àfikún lẹ́tà àkọ́kọ́, kò sì lè ju nǹkan bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn tó kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ tó fi kọ ti èkejì yìí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní nílùú Kọ́ríńtì àti nínú ìjọ tó wà níbẹ̀ ló jọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí, nítorí náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù méjèèjì yìí wúlò fún wa gan-an ni.—Héb. 4:12.
‘Ẹ WÀ LÓJÚFÒ, Ẹ DÚRÓ GBỌN-IN GBỌN-IN, Ẹ DI ALÁGBÁRA ŃLÁ’
Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé: “Kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan.” (1 Kọ́r. 1:10) Kò sí orí “ìpìlẹ̀ èyíkéyìí mìíràn” téèyàn lè kọ́ àwọn ànímọ́ Kristẹni lé, àyàfi “Jésù Kristi.” (1 Kọ́r. 3:11-13) Alágbèrè kan wà nínú ìjọ wọn tí Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn nípa rẹ̀ pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.” (1 Kọ́r. 5:13) Ó fi kún un pé: “Ara kò wà fún àgbèrè, bí kò ṣe fún Olúwa.”—1 Kọ́r. 6:13.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fèsì lórí “àwọn ohun tí [wọ́n] kọ̀wé nípa rẹ̀,” ó fún wọn ní ìmọ̀ràn tó múná dóko lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó àti wíwà ní àpọ́n. (1 Kọ́r. 7:1) Lẹ́yìn tó ti sọ̀rọ̀ nípa ipò orí láàárín àwọn Kristẹni, ó sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ létòlétò nínú ìpàdé àti bí àjíǹde ṣe dájú, ó wá gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, ẹ di alágbára ńlá.”—1 Kọ́r. 16:13.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:21—Ṣé Jèhófà ń lo “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” láti fi gba àwọn tó ń gbà gbọ́ là ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ayé nípasẹ̀ ọgbọ́n tirẹ̀ kò mọ Ọlọ́run,” ohun tí Ọlọ́run fi ń gba àwọn èèyàn là lè dà bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú aráyé.—Jòh. 17:25.
5:5—Kí ló túmọ̀ sí láti “fi [ẹni burúkú] lé Sátánì lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara, kí a bàa lè gba ẹ̀mí là”? Nígbà tí wọ́n bá yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ nítorí pé ó ti sọ ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì dàṣà, tí kò sì ronú pìwà dà, ṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ padà di ara ayé burúkú ti Sátánì yìí. (1 Jòh. 5:19) Ìyẹn la fi lè sọ pé wọ́n ti fi í lé Sátánì lọ́wọ́. Yíyọ tí wọ́n yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ ń mú àkóbá tí ìwà rẹ̀ lè ṣe fún ìjọ kúrò, tàbí ká sọ pé wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ mú ohun tó lè ṣàkóbá fún ìjọ kúrò. Èyí á sì yọrí sí pípa ẹ̀mí ìjọ, ìyẹn ìwà rere tó gbilẹ̀ nínú ìjọ, mọ́.—2 Tím. 4:22.
7:33, 34—Kí ni “àwọn ohun ti ayé,” tí ọkùnrin tàbí obìnrin tó ti ṣègbéyàwó máa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Àwọn nǹkan tara tó yẹ káwọn Kristẹni tó bá ti ṣègbéyàwó máa ṣàníyàn nípa rẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí. Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni oúnjẹ, aṣọ àti ilé, àmọ́ kì í ṣàwọn ohun búburú ayé yìí táwọn Kristẹni ní láti sá fún ló ń sọ o.—1 Jòh. 2:15-17.
11:26—Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà “nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí,” “títí” dìgbà wo ló sì ń sọ? Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ní ká máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lemọ́lemọ́ o. Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a lò fún “nígbàkúùgbà” túmọ̀ sí ni “gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá.” Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé gbogbo ìgbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá ń jẹ ohun tó ṣàpẹẹrẹ ara Olúwa tí wọ́n sì ń mu ohun tó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ṣe ni wọ́n “ń pòkìkí ikú Olúwa.” Wọ́n á máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ “títí yóò fi dé,” ìyẹn títí dìgbà tó máa gbà wọ́n sọ́run nípasẹ̀ àjíǹde.—1 Tẹs. 4:14-17.
13:13—Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ gbà tóbi ju ìgbàgbọ́ àti ìrètí lọ? Nígbà tí “àwọn ohun tí a ń retí” bá ti tẹ̀ wá lọ́wọ́, tóhun tá à ń fi “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú” dúró dè bá sì ti ṣẹlẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ìrètí ti parí iṣẹ́ wọn lórí ọ̀ràn yẹn. (Héb. 11:1) Ìfẹ́ tóbi ju ìgbàgbọ́ àti ìrètí lọ ní ti pé ìfẹ́ wà títí láé.
15:29—Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe “batisí fún ète jíjẹ́ òkú”? Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń sọ pé àwọn alààyè ní láti ṣe batisí torí àwọn tí kò ṣe batisí kí wọ́n tó kú o. Ohun tó ń sọ ni pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ri ara wọn bọ inú ìgbésí ayé kan tí wọ́n ti gbọ́dọ̀ máa pa ìwà títọ́ wọn mọ́ títí dìgbà tí wọ́n á fi kú tí wọ́n á sì jíǹde sí ìyè gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:26-31; 3:3-9; 4:7. Tá a bá ń ṣògo nínú Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀, tá ò máa ṣògo nínú ara wa, a ó máa fi kún àlàáfíà ìjọ.
2:3-5. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù nílùú Kọ́ríńtì níbi tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ Gíríìkì ti gbilẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máa ṣàníyàn nípa ọ̀nà táá fi lè yí àwọn tó ń wàásù fún lérò padà. Àmọ́ kò jẹ́ kí àìlera tàbí ìbẹ̀rù kankan dí i lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Táwa náà bá bá ara wa nínú ipò kan tá ò rírú ẹ̀ rí, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ṣèdíwọ́ fún wa láti polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. A ní láti fọkàn balẹ̀, ká máa wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe.
2:16. Níní “èrò inú ti Kristi,” túmọ̀ sí pé ká mọ bó ṣe ń ronú àti ìdí tó fi ń ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀, káwa náà sì máa ronú nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ká mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ dáadáa ká sì máa fi wọ́n ṣèwà hù. (1 Pét. 2:21; 4:1) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù dáadáa!
3:10-15; 4:17. Ó yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa ká lè mọ bá a ṣe jáfáfá tó lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti sísọni-dọmọ-ẹ̀yìn, ká sì tún máa wá ọ̀nà tá a fi máa mú kó sunwọ̀n sí i. (Mát. 28:19, 20) Tá ò bá kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ wa dáadáa, ó lè kùnà nígbà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ bá dé, àdánù yẹn sì lè dùn wá débi pé ìgbàlà tiwa fúnra wa á dà bí “ẹní la iná já.”
6:18. Láti “sá fún àgbèrè” túmọ̀ sí pé a ní láti yẹra fún gbogbo ohun tá a lè kà sí por·neiʹa. Kì í ṣèyẹn nìkan o, ó tún kan pé ká yẹra fún àwọn àwòrán tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, ìwà àìmọ́, ríronú lórí ìṣekúṣe, títage àti ohunkóhun míì tó bá lè súnni dédìí àgbèrè.—Mát. 5:28; Ják. 3:17.
7:29. Kò yẹ káwọn tọkọtaya jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àárín ara wọn kó sí wọn lórí débi tí wọn ò fi ní lè fọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ mọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.
10:8-11. Inú bí Jèhófà gan-an nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn lòdì sí Mósè àti Áárónì. Táwa náà bá gbọ́n, ṣe ló yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa di ẹni táá máa kùn.
16:2. Tá a bá ṣètò ọrẹ tá a ń ṣe fún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run dáadáa, tá a sì ń fọgbọ́n ṣe é, ọrẹ náà á máa ṣe déédéé.
‘Ẹ MÁA GBA ÌTỌ́SỌ́NÀPADÀ’
Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n ‘fi inú rere dárí ji’ oníwà àìtọ́ tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tó ti ronú pìwà dà, ‘kí wọ́n sì tù ú nínú.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sí wọn bà wọ́n nínú jẹ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé inú òun dùn torí pé ó bà wọ́n “nínú jẹ́ sí ríronúpìwàdà.”—2 Kọ́r. 2:6, 7; 7:8, 9.
Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú pé ‘gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ gidigidi nínú ohun gbogbo, kí wọ́n pọ̀ gidigidi nínú ìfúnni.’ Lẹ́yìn tó ti dá àwọn alátakò rẹ̀ lóhùn tán, ó fún gbogbo wọn ní ìmọ̀ràn tó kẹ́yìn yìí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, ní gbígba ìtọ́sọ́nàpadà, ní gbígba ìtùnú, ní ríronú ní ìfohùnṣọ̀kan, ní gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà.”—2 Kọ́r. 8:7; 13:11.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:15, 16—Báwo la ṣe jẹ́ “òórùn dídùn Kristi”? Ohun tó mú ká jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé a ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ a sì ń wàásù rẹ̀. Irú “òórùn ìtasánsán” yẹn lè jẹ́ ohun ìríra fáwọn aláìṣòótọ́, àmọ́ òórùn tó ń dùn mọ́ Jèhófà àtàwọn olóòótọ́ ọkàn nínú ni.
5:16—Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò gbà “mọ ènìyàn kankan nípa ti ẹran ara”? Wọn kì í fojú ẹlẹ́ran ara wo àwọn èèyàn, ìyẹn ni pé wọn kì í ṣojúsàájú láàárín àwọn èèyàn torí ọlá tí wọ́n ní, ẹ̀yà tàbí ìran tí wọ́n ti wá, tàbí orílẹ̀-èdè wọn. Ohun tó ṣe pàtàkì lójú wọn ni àjọṣe tẹ̀mí tó wà láàárín àwọn àti àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
11:1, 16; 12:11—Ǹjẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò jọ tẹni tí kò lọ́gbọ́n nínú? Rárá, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ o. Àmọ́, lójú àwọn kan, ó lè dà bí ẹni tó ń ṣògo àti ẹni tí kò lọ́gbọ́n nínú torí ohun tó pọn dandan fún un pé kó sọ nígbà tó ń fún wọn ní ẹ̀rí pé àpọ́sítélì lòun lóòótọ́.
12:1-4—Ta ni “ẹni tí a gbà lọ” “sínú párádísè”? Níwọ̀n bí Bíbélì kò ti sọ̀rọ̀ nípa ẹlòmíì tó rí irú ìran bẹ́ẹ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá dé ibẹ̀ yẹn ni ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí tó fi hàn pé àpọ́sítélì lòun, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìrírí ara rẹ̀ gan-an ló ń sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Párádísè tẹ̀mí táwọn ará ìjọ Kristẹni ń gbádùn ní “àkókò òpin” yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran.—Dán. 12:4.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
3:5. Ìlànà tó wà nínú ẹsẹ yìí ni pé Jèhófà ló ń mú káwa Kristẹni tóótun tẹ́rùntẹ́rùn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn ohun tó sì ń lò ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ àti apá ti orí ilẹ̀ ayé nínú ètò rẹ̀. (Jòh. 16:7; 2 Tím. 3:16, 17) Ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, bákan náà ni àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, ó sì yẹ ká máa gbàdúrà lemọ́lemọ́ pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, ká sì máa lọ sípàdé déédéé, ká tún máa kópa nínú rẹ̀.—Sm. 1:1-3; Lúùkù 11:10-13; Héb. 10:24, 25.
4:16. Níwọ̀n bí Jèhófà ti ‘ń sọ ẹni tá a jẹ́ nínú dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́,’ ó yẹ ká máa lo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti pèsè fún wa, ká má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá lọ láìjẹ́ pé a ṣàyẹ̀wò nǹkan tẹ̀mí.
4:17, 18. Tá a bá ń rántí pé ‘ìpọ́njú ìsinsìnyí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ó sì fúyẹ́,’ yóò jẹ́ ká lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó nígbà ìṣòro.
5:1-5. Àbẹ́ ò rí i pé ọ̀nà tó fani mọ́ra ni Pọ́ọ̀lù gbà sọ̀rọ̀ nípa ojú táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi ń wo ìrètí tí wọ́n ní láti gba ìyè ti ọ̀run!
10:13. Ó yẹ ká fi ìlànà yìí sọ́kàn pé tí kì í bá ṣe pé wọ́n dìídì yàn wá pé ká lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ níbi tí wọ́n bá ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i, ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n bá pín fún ìjọ wa ló yẹ ká ti máa ṣiṣẹ́.
13:5. Láti lè ‘dán ara wa wò bóyá a ṣì wà nínú ìgbàgbọ́,’ ó yẹ ká máa fi ohun tá à ń kọ́ látinú Bíbélì yẹ ara wa wò. Láti lè ‘wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́,’ ó yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò bí àjọṣe àwa àti Ọlọ́run ṣe dán mọ́rán tó, ká sì máa ṣàyẹ̀wò bí “agbára ìwòye” wa àti iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wa ṣe pọ̀ tó. (Héb. 5:14; Ják. 1:22-25) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àtàtà Pọ́ọ̀lù yìí, a ó máa bá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà òtítọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà “nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí”?—1 Kọ́r. 11:26