Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
8 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fún àwọn ìjọ tó wà ní Makedóníà.+ 2 Nígbà tí àdánwò ńlá pọ́n wọn lójú, ayọ̀ tó gba ọkàn wọn bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ òtòṣì paraku fi hàn pé wọ́n ní ọrọ̀ nípa tẹ̀mí, torí pé wọ́n lawọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.* 3 Bí agbára wọn ṣe gbé e tó ni,+ bẹ́ẹ̀ ni, mo jẹ́rìí sí i, kódà ó kọjá agbára wọn,+ 4 ṣe ni wọ́n lo ìdánúṣe, tí wọ́n ń bẹ̀ wá taratara pé kí a fún wọn láǹfààní láti ṣe ọrẹ, kí wọ́n lè ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+ 5 Kì í ṣe bí a ṣe retí nìkan, àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n fi ara wọn fún Olúwa àti fún àwa nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 Torí náà, a fún Títù+ ní ìṣírí pé, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí láàárín yín, kó parí gbígba àwọn ọrẹ yìí lọ́dọ̀ yín. 7 Síbẹ̀ náà, bí ẹ ṣe pọ̀ nínú ohun gbogbo, nínú ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ àti nínú fífi ìtara ṣe gbogbo nǹkan àti nínú ìfẹ́ tí a ní fún yín, kí ẹ pọ̀ nínú bí ẹ ṣe ń fúnni ní ọrẹ.+
8 Kì í ṣe láti pàṣẹ fún yín ni mo ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ó jẹ́ kí ẹ lè mọ bí àwọn míì ṣe ń fi ìtara ṣe nǹkan àti pé kí n lè dán ìfẹ́ yín wò láti mọ bó ṣe jinlẹ̀ tó. 9 Nítorí ẹ mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wa, pé bó tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó di aláìní nítorí yín,+ kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ àìní rẹ̀.
10 Mo sọ èrò mi lórí èyí pé:+ Àǹfààní yín ni èyí wà fún, bó ṣe jẹ́ pé lọ́dún kan sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan, ẹ tún fi hàn pé ó wù yín láti ṣe é. 11 Torí náà, ní báyìí, ẹ parí ohun tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀, kó lè jẹ́ pé bó ṣe yá yín lára nígbà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ náà ló ń yá yín lára títí ẹ ó fi parí rẹ̀, bí agbára yín ṣe gbé e tó. 12 Nítorí tó bá ti jẹ́ pé ó yá èèyàn lára, á túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tí èèyàn ní ló fi ṣe é,+ kì í ṣe ohun tí èèyàn kò ní. 13 Nítorí mi ò fẹ́ kó rọrùn fún àwọn míì, kó wá nira fún ẹ̀yin; 14 ṣùgbọ́n kí nǹkan lè dọ́gba, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ yín ní báyìí dí àìní wọn, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ wọn sì dí àìtó yín, ìyẹn á jẹ́ kí nǹkan lè dọ́gba. 15 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni tó ní púpọ̀, ohun tó ní kò pọ̀ jù, ẹni tó sì ní díẹ̀, ohun tó ní kò kéré jù.”+
16 Tóò, ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run tó fi irú ìtara tí a ní fún yín sínú ọkàn Títù,+ 17 torí pé ó ti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣírí tó rí gbà lóòótọ́, ó sì ń wù ú gan-an ni, kódà òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti wá sọ́dọ̀ yín. 18 Àmọ́ à ń rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni tí òkìkí rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìhìn rere ti kàn dé gbogbo ìjọ. 19 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àwọn ìjọ tún yàn án pé kó máa bá wa rìnrìn àjò bí a ṣe ń pín àwọn ọrẹ yìí fún ògo Olúwa, tí a sì ń fi ẹ̀rí hàn pé a múra tán láti ṣèrànwọ́. 20 Nípa báyìí, à ń kíyè sára kí ẹnikẹ́ni má bàa rí àléébù nínú wa lórí bí a ṣe ń pín ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn ṣe.+ 21 Nítorí à ‘ń fi òótọ́ inú ṣe ohun gbogbo, kì í ṣe níwájú Jèhófà* nìkan, àmọ́ níwájú àwọn èèyàn pẹ̀lú.’+
22 Yàtọ̀ síyẹn, à ń rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí a ti dán wò lọ́pọ̀ ìgbà, tí a sì ti rí i pé ó já fáfá nínú ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ ní báyìí, ó ti túbọ̀ já fáfá torí ìgbọ́kànlé tó lágbára tó ní nínú yín. 23 Tí ohunkóhun bá wà tó ń kọ yín lóminú nípa Títù, alábàákẹ́gbẹ́* mi ni, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire yín; tí ohunkóhun bá sì wà tó ń kọ yín lóminú nípa àwọn arákùnrin wa, àpọ́sítélì àwọn ìjọ ni wọ́n, wọ́n sì ń fi ògo fún Kristi. 24 Nítorí náà, ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn,+ kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ìjọ mọ ìdí tí a fi ń fi yín yangàn.