ORÍ KẸRIN
Báwo Ni O Ṣe Lè Bójú Tó Agbo Ilé?
1. Èé ṣe tí bíbójú tó agbo ilé fi lè nira tó bẹ́ẹ̀ lónìí?
“ÌRÍSÍ ìran ayé yii ń yípadà.” (1 Korinti 7:31) A kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní èyí tí ó lé ní 1,900 ọdún sẹ́yìn, ẹ sì wo bí wọ́n ti jẹ́ òtítọ́ tó lónìí! Àwọn nǹkan ń yí padà, ní pàtàkì ní ti ìgbésí ayé ìdílé. Púpọ̀ nǹkan tí a kà sí apá kan ìgbésí ayé tàbí àṣà ìbílẹ̀ ní 40 tàbí 50 ọdún sẹ́yìn ni kò ṣètẹ́wọ́gbà mọ́ lónìí. Nítorí èyí, bíbójú tó agbo ilé lọ́nà aláṣeyọrí lè gbé àwọn ìpèníjà ńlá dìde. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, o lè kojú àwọn ìpèníjà wọ̀nyẹn.
ṢE BÍ O TI MỌ
2. Àwọn ipò ìṣúnná owó wo ní ń fa másùnmáwo nínú ìdílé?
2 Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ìgbésí ayé oníwọ̀ntunwọ̀nsì, onídìílé kò tẹ́ lọ́rùn mọ́. Bí ayé ìṣòwò ti ń mú àwọn ọjà jáde, tí ó sì ń lo àwọn ìpolówó rẹ̀ láti gbìyànjú láti fa àwùjọ mọ́ra, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ bàbá àti ìyá ń lo àkókò gígùn lẹ́nu iṣẹ́, kí wọ́n lè ra àwọn ọjà wọ̀nyí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ń ṣe làálàá lójoojúmọ́ láti wá ohun tí ẹnu ó jẹ kiri. Wọ́n ní láti lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́, ju bí ó ti ń rí tẹ́lẹ̀ lọ, bóyá nípa pípa iṣẹ́ méjì pọ̀, kìkì láti lè rówó bójú tó àwọn ohun kòṣeémánìí. Inú àwọn mìíràn yóò dùn láti wulẹ̀ ní iṣẹ́ lọ́wọ́, níwọ̀n bí àìníṣẹ́lọ́wọ́ ti jẹ́ ìṣòro tí ó kárí ayé. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbésí ayé kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún ìdílé òde òní, ṣùgbọ́n àwọn ìlànà Bibeli lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nínú ipò tí wọ́n bá ara wọn.
3. Ìlànà wo ni aposteli Paulu ṣàlàyé, báwo sì ni fífi í sílò ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí sí rere nínú bíbójú tó agbo ilé?
3 Aposteli Paulu ní ìṣòro ìṣúnná owó. Ní mímójú tó wọn, ó kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan, tí ó ṣàlàyé nínú lẹ́tà tí ó kọ sí Timoteu, ọ̀rẹ́ rẹ̀. Paulu kọ̀wé pé: “A kò mú nǹkankan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nitori naa, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró ati ìbora, awa yoo ní ìtẹ́lọ́rùn-ọkàn pẹlu nǹkan wọnyi.” (1 Timoteu 6:7, 8) Ní tòótọ́, ohun tí ìdílé nílò ju oúnjẹ àti aṣọ lọ. Ó tún nílò ibùgbé. Àwọn ọmọ ní láti kàwé. Owó ìtọ́jú ìṣègùn àti àwọn ìnáwó mìíràn sì wà níbẹ̀. Síbẹ̀, ìlànà tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ Paulu ṣeé mú lò. Bí a bá ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú kíkájú àwọn ohun kòṣeémánìí wa, dípò títẹ́ àwọn ohun tí ó wù wa lọ́rùn, ìgbésí ayé yóò túbọ̀ rọrùn.
4, 5. Báwo ni ìrònú ṣáájú àti ìwéwèé ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú bíbójú tó agbo ilé?
4 A tún rí ìlànà míràn tí ó ṣèrànwọ́ nínú ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe Jesu. Ó sọ pé: “Ta ni ninu yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì gbéṣiròlé ìnáwó naa, lati rí i bí oun bá ní tó lati parí rẹ̀?” (Luku 14:28) Níhìn-ín, Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa ríronú ṣáájú, wíwéwèé ṣáájú. A ti rí bí èyí ti ṣàǹfààní nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin kan bá ń ronú àtifẹ́ ara wọn, nínú ọ̀kan lára àwọn orí tí ó ṣáájú. Lẹ́yìn ìgbéyàwó pẹ̀lú, ó tún ṣàǹfààní nínú bíbójú tó agbo ilé. Ríronú ṣáájú ní agbègbè yìí ní í ṣe pẹ̀lú níní ìwéwèé ètò ìnáwó, wíwéwèé ṣáájú láti lo àwọn ohun ìní wa lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání jù lọ. Lọ́nà yìí, ìdílé lè bójú tó àwọn ìnáwó rẹ̀, ní yíya àwọn owó tí a óò ná lórí àwọn ohun ṣíṣe kókó sọ́tọ̀, lójoojúmọ́ tàbí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí a má sì ṣe ná ju iye yẹn lọ.
5 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, irú ìwéwèé ètò ìnáwó bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí gbígbógun ti ìsúnniṣe láti yá owó èlé rẹpẹtẹ láti ra àwọn ohun tí kò pọn dandan. Níbòmíràn, ó lè túmọ̀ sí bíbójú tó bí a ti ń lo káàdì ìrajà àwìn. (Owe 22:7) Ó tún lè túmọ̀ sí gbígbógun ti ríra ohun tí a kò wéwèé fún tẹ́lẹ̀—ríra ohun kan lójú ẹsẹ̀, láìro ìwúlò àti ìyọrísí rẹ̀. Síwájú sí i, ìwéwèé ètò ìnáwó yóò mú kí ó ṣe kedere pé fífi ìmọtara-ẹni-nìkan náwó dà nù sórí tẹ́tẹ́ títa, sìgá mímu, àti ọtí àmuyíràá, ń kó bá ipò ìṣúnná owó ìdílé, ó sì tún ta ko àwọn ìlànà Bibeli.—Owe 23:20, 21, 29-35; Romu 6:19; Efesu 5:3-5.
6. Àwọn òtítọ́ Ìwé Mímọ́ wo ni ó ń ran àwọn tí wọ́n bá ara wọn nínú ipò òṣì lọ́wọ́?
6 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí a fipá mú láti gbé nínú ipò òṣì ńkọ́? Fún ohun kan, ó lè tù wọ́n nínú láti mọ̀ pé ìṣòro tí ó kárí ayé yìí kì yóò wà pẹ́ títí. Nínú ayé tuntun, tí ń yára sún mọ́lé, Jehofa yóò mú ipò òṣì àti gbogbo ibi yòókù, tí ń kó òṣì àti àre bá aráyé, kúrò. (Orin Dafidi 72:1, 12-16) Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn Kristian tòótọ́ kò gbékú tà, bí wọ́n tilẹ̀ tòṣì paraku, nítorí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Jehofa náà pé: “Dájúdájú emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.” Nítorí èyí, onígbàgbọ́ kan lè fi pẹ̀lú ìgbọ́kànlé sọ pé: “Jehofa ni olùrànlọ́wọ́ mi; emi kì yoo fòyà.” (Heberu 13:5, 6) Ní àwọn ọjọ́ líle koko wọ̀nyí, Jehofa ń ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́yìn ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Ìjọba rẹ̀ ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. (Matteu 6:33) Púpọ̀ nínú wọ́n lè jẹ́rìí sí i, ní sísọ ọ́, ní ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pé: “Ninu ohun gbogbo ati ninu àyíká ipò gbogbo mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó ati bí a ti ń wà ninu ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu ati bí a ti ń jẹ́ aláìní. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni naa tí ń fi agbára fún mi.”—Filippi 4:12, 13.
JÍJỌ GBÉ ẸRÙ NÁÀ
7. Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu wo ni yóò ṣèrànwọ́ nínú bíbójú tó agbo ilé lọ́nà yíyọrí sí rere, bí a bá fi sílò?
7 Ní apá òpin iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jesu sọ pé: “Iwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Matteu 22:39) Fífi ìmọ̀ràn yìí sílò nínú ìdílé ń ṣèrànwọ́ gidigidi nínú bíbójú tó agbo ilé. Ó ṣe tán, àwọn wo ni àwọn aládùúgbò tí ó sún mọ́ wa jù lọ, tí ó sì ṣọ̀wọ́n fún wa jù lọ, bí kì í bá ṣe àwọn tí a jọ ń gbé inú ilé—ọkọ àti aya, àwọn òbí àti àwọn ọmọ? Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn?
8. Báwo ni a ṣe lè fi ìfẹ́ hàn láàárín ìdílé?
8 Ọ̀nà kan ni fún mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kan láti ṣe ipa bíbójú mu tirẹ̀ nínú iṣẹ́ ilé. Nípa báyìí, a ní láti kọ́ àwọn ọmọ láti dá àwọn ohun tí a lò padà sí àyè wọn, ì báà jẹ́ aṣọ tàbí àwọn ohun ìṣiré. Ó lè gba àkókò àti ìsapá láti tẹ́ bẹ́ẹ̀dì láràárọ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá nínú bíbójú tó agbo ilé. Dájúdájú, a kò lè fẹ́ wúruwùru díẹ̀ kù, ṣùgbọ́n gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣiṣẹ́ pọ̀ láti rí i pé inú ilé wà ní mímọ́ tónítóní, títí kan pípalẹ̀ mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Ìwà ọ̀lẹ, ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́, àti ẹ̀mí ìlọ́tìkọ̀, ìtàdísẹ́yìn, ń ní ipa búburú lórí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé. (Owe 26:14-16) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí ọ̀yàyà, ìmúratán, ń gbé ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ ró. “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Korinti 9:7.
9, 10. (a) Ẹrù ìnira wo ni ó sábà máa ń já lé ìyálé ilé léjìká, báwo ni a sì ṣe lè mú èyí fúyẹ́? (b) Ojú ìwòye tí ó wà déédéé wo nípa iṣẹ́ ilé ni a dábàá?
9 Ìgbatẹnirò àti ìfẹ́ yóò ṣèrànwọ́ láti bẹ́gi dínà ipò kan tí ó jẹ́ ìṣòro ńlá nínú àwọn agbo ilé kan. Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn ìyá ti jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà nínú ilé. Wọ́n ti ṣètọ́jú àwọn ọmọ, tọ́jú ilé, fọ aṣọ gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé, ra àwọn ohun èlò, wọ́n sì ti gbọ́ oúnjẹ. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn obìnrin tún ti ṣiṣẹ́ nínú oko, ta àwọn irè oko lọ́jà, tàbí ṣiṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà míràn láti mú owó wọlé fún ìdílé. Àní ní àwọn ibi tí èyí kì í ti í ṣe àṣà tẹ́lẹ̀ pàápàá, àwọn ipò nǹkan ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn abilékọ wá iṣẹ́ síta. Aya àti ìyá kan tí ń ṣiṣẹ́ kára ní onírúurú agbègbè wọ̀nyí yẹ fún ìyìn. Bí “obìnrin oníwà rere” tí a ṣàpèjúwe nínú Bibeli, òṣìṣẹ́ kára ni. ‘Kò jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.’ (Owe 31:10, 27) Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀ sí pé obìnrin nìkan ṣoṣo ni ó lè ṣiṣẹ́ nínú ilé. Lẹ́yìn tí ọkọ àti aya ti ṣiṣẹ́ látàárọ̀ dalẹ́ níta, ǹjẹ́ aya nìkan ni ó yẹ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé, nígbà tí ọkọ àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù jókòó tẹtẹrẹ? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́. (Fi wé 2 Korinti 8:13, 14.) Nítorí náà, fún àpẹẹrẹ, bí ìyá bá fẹ́ẹ́ gbọ́ oúnjẹ, ó lè mọrírì rẹ̀ bí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù bá ṣèrànwọ́ nínú ṣíṣètò rẹ̀ nípa gbígbé oúnjẹ sórí tábìlì, lílọ ra díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí a nílò, tàbí títún ilé ṣe díẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé ni ó lè ṣàjọpín ẹrù iṣẹ́ náà.—Fi wé Galatia 6:2.
10 Àwọn kan lè sọ pé: “Níbi tí mò ń gbé, kì í ṣe ẹrù iṣẹ́ ọkùnrin láti ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.” Ìyẹ́n lè jóòótọ́, ṣùgbọ́n, kò ha ní dára láti gba ọ̀ràn yìí rò bí? Nígbà tí Jehofa Ọlọrun dá ìdílé sílẹ̀, kò pa á láṣẹ pé àwọn obìnrin nìkan ṣoṣo ni ó gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ kan pàtó. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ pàtàkì láti ọ̀dọ Jehofa bẹ Abrahamu, ọkùnrin olùṣòtítọ́ nì wò, òun fúnra rẹ̀ ṣàjọpín nínú gbígbọ́ oúnjẹ àti gbígbé e kalẹ̀ síwájú àwọn àlejò náà. (Genesisi 18:1-8) Bibeli gbani nímọ̀ràn pé: “Ó yẹ kí awọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ awọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara awọn fúnra wọn.” (Efesu 5:28) Bí ó bá rẹ ọkọ lẹ́yìn iṣẹ́, tí ó sì fẹ́ láti sinmi, kò ha ṣeé ṣe kí ó rí bákan náà fún ìyàwó, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá? (1 Peteru 3:7) Nígbà náà, kò ha ní bójú mu, kí ó sì jẹ́ ìwà onífẹ̀ẹ́ fún ọkọ náà láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ilé bí?—Filippi 2:3, 4.
11. Ọ̀nà wo ni Jesu gbà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú agbo ilé?
11 Jesu ni àpẹẹrẹ tí ó dára jù lọ, ti ẹnì kan tí ó mú inú Ọlọrun dùn, tí ó sì mú ayọ̀ wá fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Bí Jesu kò tilẹ̀ ṣègbéyàwó, ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ọkọ, títí kan aya àti àwọn ọmọ pẹ̀lú. Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Ọmọkùnrin ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bíkòṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́,” ìyẹn ni pé, láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn. (Matteu 20:28) Ẹ wo bí àwọn ìdílé tí gbogbo mẹ́ḿbà rẹ̀ mú irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ dàgbà ti ń láyọ̀ tó!
ÌMỌ́TÓTÓ—ÈÉ ṢE TÍ Ó FI ṢE PÀTÀKÌ TÓ BẸ́Ẹ̀?
12. Kí ni Jehofa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn ín?
12 A rí ìlànà Bibeli míràn, tí ó lè ṣèrànwọ́ nínú bíbójú tó agbo ilé, nínú 2 Korinti 7:1. A kà níbẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran-ara ati ti ẹ̀mí.” Jehofa, tí ń béèrè “ìjọsìn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin,” tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí. (Jakọbu 1:27) Agbo ilé wọn sì ń rí àwọn àǹfààní tí ó ń bá a rìn gbà.
13. Èé ṣe tí ìmọ́tótó fi ṣe pàtàkì nínú bíbójú tó agbo ilé?
13 Fún àpẹẹrẹ, Bibeli mú un dá wa lójú pé ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí àrùn àti àìsàn yóò pòórá. Ní àkókò yẹn, “kò sí olùgbé ibẹ̀ tí yóò wí pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Isaiah 33:24, NW; Ìṣípayá 21:4, 5) Bí ó ti wù kí ó rí, títí di ìgbà yẹn, gbogbo ìdílé ní láti kojú àìsàn láti ìgbà dé ìgbà. Àní Paulu àti Timoteu pàápàá ṣàìsàn. (Galatia 4:13; 1 Timoteu 5:23) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ògbógi nínú ìṣègùn sọ pé, a lè dènà ọ̀pọ̀ jù lọ àìsàn. Àwọn ìdílé tí ó gbọ́n ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn àrùn kan tí ó ṣeé dènà, bí wọ́n bá yẹra fún àwọn ẹ̀gbin ti ara àti tẹ̀mí. Ẹ jẹ́ kí a gbé bí a ṣe lè ṣe èyí yẹ̀ wò.—Fi wé Owe 22:3.
14. Ní ọ̀nà wo ni mímọ́ tóní nínú ìwà ṣe lè dáàbò bo ìdílé lọ́wọ́ àìsàn?
14 Mímọ́ tóní nípa tẹ̀mí kan mímọ́ tóní nínú ìwà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ti mọ̀, Bibeli gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga fún ìwà rere lárugẹ, ó sì dẹ́bi fún gbogbo ìbálòpọ̀ èyíkéyìí lẹ́yìn òde ìgbéyàwó. “Kì í ṣe awọn àgbèrè, . . . tabi awọn panṣágà, tabi awọn ọkùnrin tí a pamọ́ fún awọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tabi awọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dàpọ̀, . . . ni yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (1 Korinti 6:9, 10) Pípa àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga wọ̀nyí mọ́ ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn Kristian tí ń gbé nínú ayé òde òní, tí ó ti bàjẹ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń dùn mọ́ Ọlọrun nínú, ó sì tún ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìdílé lọ́wọ́ àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, irú bí AIDS, rẹ́kórẹ́kó, àtọ̀sí, àti ìwúlé ojú ọ̀nà ìtọ̀.—Owe 7:10-23.
15. Fúnni ní àpẹẹrẹ àìmọ́tótó kan tí ó lè fa àrùn tí a lè ṣèdènà.
15 ‘Wíwẹ ara ẹni mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran-ara’ ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìdílé lọ́wọ́ àwọn àìsàn míràn. Àìmọ́tótó ń fa ọ̀pọ̀ àìsàn. Àṣa mímu sìgá jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì kan. Kì í ṣe kìkì pé sìgá mímu ń kó ìdọ̀tí bá ẹ̀dọ̀fóró, aṣọ, àti afẹ́fẹ́ àyíká nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń kó àìsàn bá ènìyàn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń kú lọ́dọọdún nítorí pé wọ́n ń mu sìgá. Ronú nípa rẹ̀ ná; lọ́dọọdún, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn kì bá tí ṣàìsàn, kí wọ́n sì kú láìtọ́jọ́, bí wọ́n bá ti yẹra fún “ẹ̀gbin ti ẹran-ara” yẹn!
16, 17. (a) Òfin tí Jehofa fifúnni wo ni ó dáàbò bo àwọn ọmọ Israeli lọ́wọ́ àwọn àrùn kan? (b) Báwo ni gbogbo agbo ilé ṣe lè fi ìlànà tí ó wà nínú Deuteronomi 23:12, 13 sílò?
16 Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn, Ọlọrun fún orílẹ̀-èdè Israeli ní Òfin rẹ̀ láti lè ṣètò ìjọsìn wọn àti, dé ìwọ̀n kan, láti ṣètò ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Òfin yẹn ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́ àrùn, nípa gbígbé àwọn òfin pàtàkì nípa àṣà ìmọ́tótó kalẹ̀. Ọ̀kan nínú irú òfin bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú pípalẹ̀ ìgbẹ́ ènìyàn mọ́ kúrò nílẹ̀, èyí tí a ní láti gbẹ́ kòtò, kí a sì bò mọ́lẹ̀ níbi tí ó jìnnà sí àgọ́, kí a má baà kó èérí bá ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé. (Deuteronomi 23:12, 13) Òfin àtijọ́ yẹn ṣì jẹ́ ìmọ̀ràn rere. Àní lónìí pàápàá, àwọn ènìyàn ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú, nítorí wọn kò tẹ̀ lé e.a
17 Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí ó wà nídìí òfin tí a fún àwọn ọmọ Israeli yẹn, ilé ìwẹ̀ àti ilé ìyàgbẹ́ tí ìdílé ń lò—ì báà jẹ́ láàárín ilé tàbí lẹ́yìnkùnlé ilé—gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, kí a sì da taniyá sí i. Bí a kò bá tọ́jú ilé ìyàgbẹ́ kí a sì bò ó, àwọn eṣinṣin yóò péjọ síbẹ̀, wọn yóò sì kó kòkòrò àrùn wọ àwọn ibi yòókù nínú ilé—àti sínú oúnjẹ tí a ń jẹ! Síwájú sí i, àwọn ọmọdé àti àgbà gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ wọn lẹ́yìn lílọ sí agbègbè ilé ìyàgbẹ́. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kó kòkòrò àrùn tí ó ti lẹ̀ mọ́ wọn lára wọlé. Gẹ́gẹ́ bí dókítà ọmọ ilẹ̀ Faransé kan ti sọ, fífọ ọwọ́ “ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí a lè fọwọ́ sọ̀yà pé ó lè ṣèdènà àwọn àkóràn kan tí ń ṣàkóbá fún dídà oúnjẹ, èémí tàbí awọ ara.”
18, 19. Àwọn àbá wo ni a fúnni nípa mímú ilé wà ní mímọ́ tónítóní, àní ní àwọn àdúgbò akúrẹtẹ̀ pàápàá?
18 Ní tòótọ́, ìmọ́tótó jẹ́ ìpèníjà ní àwọn àdúgbò akúrẹtẹ̀. Ẹnì kan tí ó mọ irú àwọn àdúgbò bẹ́ẹ̀ dáradára sọ pé: “Oòrùn tí ń tani lára ń mú kí iṣẹ́ ìmọ́tótó túbọ̀ nira. Ekuru ń bo gbogbo inú ilé. . . . Iye ènìyàn tí ó túbọ̀ ń gbèrú nínú ìlú, àti ní àwọn àrọko kan, ń wu ìlera léwu pẹ̀lú. Àwọn kòtò omi ìdọ̀tí tí a kò bò, àwọn pàǹtírí gíga pelemọ, tí a kò kó, àwọn ilé ìyàgbẹ́ àjùmọ̀lò ẹlẹ́gbin, àwọn eku, aáyán, àti eṣinṣin, tí ń kó àrùn kiri, ti di ohun tí a ń rí lójoojúmọ́.”
19 Ó ṣòro láti jẹ́ afínjú nínú irú àwọn àyíká báyìí. Síbẹ̀, ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọṣẹ àti omi àti àfikún iṣẹ́ díẹ̀ sí i kò wọ́nwó tó egbòogi àti owó tí a óò san nílé ìwòsàn. Bí o bá ń gbé nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe, rí i pé ilé àti ẹ̀yìnkùnlé rẹ wà ní mímọ́ tónítóní, tí kò sì sí ìgbẹ́ ẹranko níbẹ̀. Bí pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ bá sábà máa ń wà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ, nígbà òjò, o kò ṣe da òkúta sí ojú ọ̀nà náà, kí a má baà kó pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ wọnú ilé? Ṣé ẹni tí ó wọ bàtà lè bọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà kí ó tó wọlé? O tún gbọ́dọ̀ rí i pé a kò kó èérí bá omi yín. A fojú díwọ̀n pé, ó kéré tán, ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ ènìyàn ní ń kú lọ́dọọdún nítorí àrùn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mímu omi ìdọ̀tí àti àìwà ní mímọ́ tónítóní.
20. Bí ilé yóò bá wà ní mímọ́ tónítóní, ta ni gbọ́dọ̀ gbé nínú ẹrù iṣẹ́ náà?
20 Níní ilé mímọ́ tónítóní sinmi lórí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé—ìyá, bàbá, àwọn ọmọ, àti àwọn àlejò pàápàá. Ìyá ọlọ́mọ mẹ́jọ kan ní Kenya sọ pé: “Gbogbo wọ́n ti kọ́ láti ṣe ojúṣe wọn.” Ilé mímọ́ tónítóní ń sọ dáradára nípa gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé. Òwe ilẹ̀ Spain kan sọ pé: “Àìlówólọ́wọ́ kò sọ pé ká yọ̀bùn.” Bóyá ènìyàn ń gbé nínú ilé ńlá ràgàjì, nínú ilé àdágbé kékeré, nínú ilé bínúkonú, tàbí nínú ahéré, ìmọ́tótó jẹ́ àṣírí ìdílé onílera.
ÌṢÍRÍ Ń MÚ WA ṢE DÁRADÁRA SÍ I
21. Ní ìbámu pẹ̀lú Owe 31:28, kí ni yóò ṣèrànwọ́ láti mú ayọ̀ wá fún agbo ilé?
21 Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin oníwà rere, ìwé Owe sọ pé: “Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní alábùkúnfún, àti baálé rẹ̀ pẹ̀lú, òun sì fi ìyìn fún un.” (Owe 31:28) Ìgbà wo ni o gbóríyìn fún mẹ́ḿbà kan nínú ìdílé rẹ kẹ́yìn? Ní ti gidi, a dà bí ewéko nígbà ìrúwé, tí ó ṣe tán láti yọ yẹtuyẹtu òdòdó, nígbà tí oòrùn àti òjò bá rọ̀ sí i. Ní ti wa, a nílò ìgbóríyìn ọlọ́yàyà. Ó ń mú kí aya mọ̀ pé ọkọ rẹ̀ mọrírì iṣẹ́ àṣekára àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àti pé ọkọ rẹ̀ kò ṣàìkà á sí. (Owe 15:23; 25:11) Ó sì dára bí aya bá gbóríyìn fún ọkọ rẹ̀, fún àwọn iṣẹ́ tí ó ń ṣe níta àti nínú ilé. Àwọn ọmọ pẹ̀lú ń ṣe dáradára sí i nígbà tí àwọn òbí wọn bá ń yìn wọ́n fún ìsapá wọn nínú ilé, ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí nínú ìjọ Kristian. Ẹ sì wo ire ńlá tí ìmoore díẹ̀ ń ṣàṣeparí rẹ̀! Kí ni ó ń náni láti sọ pé: “O ṣeun”? Kò tó nǹkan, síbẹ̀ ìwúrí tí ń mú wá fún ìdílé kì í ṣe kékeré.
22. Kí ni agbo ilé kan nílò láti lè “fìdí múlẹ̀ ṣinṣin,” báwo sì ni ọwọ́ ṣe lè tẹ èyí?
22 Fún ìdí púpọ̀, bíbójú tó agbo ilé kò rọrùn. Síbẹ̀, a lè ṣe é pẹ̀lú àṣeyọrí. Òwe Bibeli kan sọ pé: “Nípa ọgbọ́n a óò kọ́ agbo ilé, àti nípa ìfòyemọ̀ yóò fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.” (Owe 24:3, NW) A lè jèrè ọgbọ́n àti òye bí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé bá làkàkà láti kọ́ nípa ìfẹ́ inú Ọlọrun, kí wọ́n sì fi í sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Dájúdájú, ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ fún ìdílé aláyọ̀!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ìwé ìléwọ́ kan tí ń gbani nímọ̀ràn lórí bí a ṣe lè yẹra fún àrùn ìgbẹ́ gbuuru—àrùn wíwọ́pọ̀ kan tí ń yọrí sí ikú ọ̀pọ̀ ìkókó—Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Bí kò bá sí ṣáláńgá: má ṣe yàgbẹ́ sí itòsí ilé, àti sí itòsí ibi tí àwọn ọmọdé ti ń ṣeré, kí o sì fi, ó kéré tán, mítà 10 jìnnà sí ibi tí a ti ń pọnmi; fi erùpẹ̀ bo ìgbẹ́ náà.”
BAWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÌDÍLE KAN LÁTI BÓJÚ TÓ AGBO ILÉ WỌN?
Ó jẹ́ ìwà ọlọgbọ́n láti jẹ́ kí àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé tẹ́ wa lọ́rùn.—1 Timoteu 6:7, 8.
Jehofa kì yóò fi àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn ín sílẹ̀ láé.—Heberu 13:5, 6.
Ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ànímọ́ títayọ lọ́lá ti Kristian.—Matteu 22:39.
Àwọn Kristian ń wà ní mímọ́ tónítóní ní ti ara àti tẹ̀mí.—2 Korinti 7:1.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 45]
OMI MÍMỌ́ TÓNÍTÓNÍ, ÌLERA PÍPÉ
Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí rírí omi mímọ́ tónítóní ti lè nira, tí ilé ìyàgbẹ́ wọn kò sì bágbà mu.
“Pọn omi mímu sínú àmù tí ó mọ́ tónítóní. Bo àmù tí omi wà nínú rẹ̀ náà, má sì ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọdé tàbí ẹranko mu omi nínú rẹ̀. . . . Ìkéèmù oníga ńlá tí a fi ń bu omi nìkan ní kí o fi bu omi nínú rẹ̀. Lójoojúmọ́, da omi inu àmù náà nù, kí o sì fọ̀ ọ́.
“Se omi tí a óò lò láti fi gbọ́únjẹ tàbí láti fi po oúnjẹ fún àwọn ọmọdé. . . . Ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ péré ni a nílò láti fi se omi.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 42]
Títọ́jú agbo ilé jẹ́ ojúṣe ìdílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 47]
Jíjẹ́ kí àwọn nǹkan wà ní mímọ́ tónítóní kò wọ́nwó tó ríra egbòogi