“Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
JÈHÓFÀ jẹ́ àpẹẹrẹ ìwà ọ̀làwọ́. Ní tòótọ́, Bíbélì sọ pé òun ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Ó ṣẹ̀dá oúnjẹ tó ládùn, kì í ṣe àtẹ́ lásán; àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère, kì í ṣe aláwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀ lásán; àrímáleèlọ gbáà ni bí oòrùn ṣe ń wọ̀, kì í ṣe ohun tí kì í wuni. Ní tòótọ́, gbogbo ẹ̀ka ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀rí ìfẹ́ àti ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ hàn. (Sáàmù 19:1, 2; 139:14) Síwájú sí i, Jèhófà jẹ́ Olùfúnni ọlọ́yàyà. Ó máa ń dunnú sí ṣíṣe ohun rere fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 84:11; 149:4.
A pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣàgbéyọ ìwà ọ̀làwọ́ Ọlọ́run nínú bí wọ́n ṣe ń hùwà sí ara wọn. Mósè sọ fún wọn pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sé ọkàn-àyà rẹ le tàbí kí ó háwọ́ sí arákùnrin rẹ tí ó jẹ́ òtòṣì. Kí o fi fún un lọ́nàkọnà, kí ọkàn-àyà rẹ má sì ṣahun.” (Diutarónómì 15:7, 10) Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ dùn sí híhu ìwà ọ̀làwọ́ nítorí pé fífúnni ń wá láti inú ọkàn-àyà.
A fún àwọn Kristẹni ní ìṣítí tó jọ èyí tí a mẹ́nu kàn. Ní gidi, Jésù sọ pé “ayọ̀” wà “nínú fífúnni.” (Ìṣe 20:35) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ta yọ ní ti ìfúnni ọlọ́làwọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ròyìn pé, àwọn tó di onígbàgbọ́ ní Jerúsálẹ́mù “ń ta àwọn ohun ìní àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó ohun tí a tà fún gbogbo wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní olúkúlùkù bá ṣe rí.”—Ìṣe 2:44, 45.
Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀làwọ́ ará Jùdíà wọ̀nyí wá tòṣì lẹ́yìn náà. Bíbélì kò sọ ohun tó fa ìṣòro wọn ní pàtó. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyàn tí a tọ́ka sí nínú Ìṣe 11:28, 29 ló fà á. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni ará Jùdíà ṣe aláìní gidigidi, Pọ́ọ̀lù sì fẹ́ rí i dájú pé, a bójú tó àìní wọn. Báwo ló ṣe ṣe bẹ́ẹ̀?
Àkójọ Tí Ó Wà fún Àwọn Aláìní
Pọ́ọ̀lù béèrè pé kí àwọn ìjọ tó wà títí dé Makedóníà ṣèrànwọ́, ó sì ṣètò àkójọ kan nítorí àwọn Kristẹni ará Jùdíà tí àìní ń bá fínra náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Bí mo ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin tìkára yín ṣe pẹ̀lú. Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí.”a—1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.
Ète Pọ́ọ̀lù ni pé kí a tètè kó owó yìí ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n àwọn ará Kọ́ríńtì kò tètè ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fún wọn. Èé ṣe? Ṣe ọ̀rọ̀ ìṣòro àwọn arákùnrin wọn ní Jùdíà kò ká wọn lára ni? Ó tì o, nítorí pé, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn ará Kọ́ríńtì “pọ̀ gidigidi nínú ohun gbogbo, nínú ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ àti gbogbo ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan.” (2 Kọ́ríńtì 8:7) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn nǹkan mìíràn tí Pọ́ọ̀lù kọ sínú lẹ́tà rẹ̀ kìíní sí wọn, tí wọ́n ń bójú tó, ló mú kí ọwọ́ wọn dí. Àmọ́ ipò tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe kánjúkánjú báyìí. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọ̀ràn náà nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará Kọ́ríńtì.
Ìpè fún Ìwà Ọ̀làwọ́
Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì nípa àwọn ará Makedóníà, tí wọ́n sakun lọ́nà títayọ láti ṣe àkójọ náà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà ìdánwò ńlá lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ yanturu ìdùnnú wọn àti ipò òṣì paraku wọn mú kí ọrọ̀ ìwà ọ̀làwọ́ wọn pọ̀ gidigidi.” Kò di ìgbà tí a ti àwọn ará Makedóníà kí wọ́n tó ṣiṣẹ́. Ní ìdàkejì, Pọ́ọ̀lù wí pé, “àwọn, láti inú ìdánúṣe àwọn fúnra wọn, ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.” Ìwà ọ̀làwọ́ ọlọ́yàyà tí àwọn ará Makedóníà hù túbọ̀ gbàfiyèsí, nígbà tí a bá ro ti pé àwọn fúnra wọn wà ní “ipò òṣì paraku.”—2 Kọ́ríńtì 8:2-4.
Ṣé Pọ́ọ̀lù ń gbìyànjú láti dá ẹ̀mí ìbánidíje sílẹ̀ láàárín àwọn ará Kọ́ríńtì, nípa yíyin àwọn ará Makedóníà ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí pé ó mọ̀ pé èyí kì í ṣe ọ̀nà yíyẹ láti súnni ṣiṣẹ́. (Gálátíà 6:4) Síwájú sí i, ó mọ̀ pé, kò di ìgbà tí a bá dójú ti àwọn ará Kọ́ríńtì kí wọ́n tó ṣe ohun tó bá yẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá a lójú pé, àwọn ará Kọ́ríńtì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wọn, ará Jùdíà, ní tòótọ́, wọ́n sì fẹ́ láti kópa nínú ìsapá ṣíṣe ìpèsè náà. Ó sọ fún wọn pé: “Láti ọdún kan sẹ́yìn ni ẹ ti bẹ̀rẹ̀, kì í ṣe ṣíṣe nìkan ṣùgbọ́n fífẹ́ láti ṣe pẹ̀lú.” (2 Kọ́ríńtì 8:10) Ní tòótọ́, ní àwọn apá mìíràn nínú ètò ìpèsè náà, àwọn ará Kọ́ríńtì fúnra wọn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Mo mọ ìmúratán èrò inú yín, èyí tí mo fi ń ṣògo nípa yín fún àwọn ará Makedóníà,” ó fi kún un pé: “Ìtara yín sì ti ru ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sókè.” (2 Kọ́ríńtì 9:2) Síbẹ̀síbẹ̀, ní báyìí, ó pọn dandan pé kí àwọn ará Kọ́ríńtì fi ìtara àti ìmúratán èrò inú wọn hàn.
Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Nítorí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń fẹ kì í ṣe láti mú àwọn ará Kọ́ríńtì nípá, nítorí pé, kò ṣeé ṣe kí ẹni tí a mú nípá jẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà. Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù gbà pé ìsúnniṣe yíyẹ ti wà, olúkúlùkù sì ti pinnu tán láti fúnni. Láfikún sí i, Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Kọ́ríńtì 8:12) Òtítọ́ ni, nígbà tí ìmúratán bá wà—tí ìfẹ́ bá ń súnni ṣiṣẹ́—ohun tí a bá mú wá yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ó ti wù kí ó jọ pé ó kéré tó.—Fi wé Lúùkù 21:1-4.
Àwọn Olùfúnni Ọlọ́yàyà Lónìí
Ìsapá láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn Kristẹni ará Jùdíà yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ fún wa lónìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dáwọ́ lé ìgbòkègbodò wíwàásù kárí ayé, wọ́n ń mú oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ lọ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa. (Aísáyà 65:13, 14) Wọ́n ń ṣe èyí ní ìgbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
Mímú àṣẹ yìí ṣẹ kò rọrùn rárá. Lára rẹ̀ ni bíbójútó àwọn ilé àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn ilé ẹ̀ka iṣẹ́ tó lé lọ́gọ́rùn-ún kárí ayé. Lára rẹ̀ náà tún ni kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ, kí àwọn olùsin Jèhófà lè ní ibi tó dára láti máa pàdé pọ̀, kí wọ́n sì máa fún ara wọn ní ìṣírí. (Hébérù 10:24, 25) Nígbà mìíràn pẹ̀lú, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pèsè ìrànwọ́ ní àwọn àgbègbè tí àjálù lọ́nà ti ẹ̀dá bá ti ṣẹlẹ̀.
Tún ronú lórí ìnáwó gọbọi ti títẹ àwọn ìwé. Ní ìpíndọ́gba, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó lé ní 22,000,000 àti nǹkan bí 20,000,000 ẹ̀dà Jí! la ń tẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Láfikún sí ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí a ń ṣe déédéé yìí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́, àti kásẹ́ẹ̀tì amóhùnmáwòrán tí a ń ṣe jáde lọ́dọọdún.
Báwo ni a ṣe ń ṣètìlẹyìn fún gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí? Nípasẹ̀ ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ni. A ń ṣe ọrẹ wọ̀nyí láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ, kì í ṣe láti di olókìkí tàbí nítorí èrò onímọtara-ẹni-nìkan. Nítorí náà, irú ìfúnni bẹ́ẹ̀ ń fún ẹni tó ń fúnni náà ní ayọ̀ àti ìbùkún Ọlọ́run. (Málákì 3:10; Mátíù 6:1-4) Kódà, àwọn ọmọdé pàápàá láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn pé àwọn jẹ́ ọ̀làwọ́, olùfúnni ọlọ́yàyà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Allison, ọmọ ọdún mẹ́rin, gbọ́ nípa ìbàjẹ́ tí ìjì líle ṣe ní apá kan United States, ó dá dọ́là méjì. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo owó tí mo ní nínú àpótí tí mo ń fi owó pa mọ́ sí nìyí. Mo mọ̀ pé àwọn ọmọdé tí ọ̀ràn náà kàn pàdánù gbogbo ohun ìṣeré àti ìwé wọn. Bóyá ẹ ó lè fi owó yìí ra ìwé kan fún ọmọbìnrin kékeré kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ dọ́gbà pẹ̀lú tèmi.” Maclean, ọmọ ọdún mẹ́jọ, kọ̀wé pé inú òun dùn pé kò sí arákùnrin kan tó kú sínú ìjì náà. Ó fi kún un pé: “Nígbà tí mo ń bá baba mi ta ìdérí irin táyà ọkọ̀, mo jèrè dọ́là 17. Nǹkan kan ni mo fẹ́ fi owó náà rà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n mo wá ronú nípa àwọn arákùnrin náà.”—Tún wo àpótí tó wà lókè.
Dájúdájú, inú Jèhófà ń dùn láti rí tèwetàgbà tí ń fi ire Ìjọba rẹ̀ sí ipò kìíní nípa ‘fífi àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún un.’ (Òwe 3:9, 10) Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó lè ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ Jèhófà di ọlọ́rọ̀, nítorí pé òun ló ni ohun gbogbo. (1 Kíróníkà 29:14-17) Ṣùgbọ́n títi iṣẹ́ náà lẹ́yìn jẹ́ ojúrere kan tí ń fún olùjọsìn láǹfààní láti fi ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà hàn. A dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ọkàn-àyà wọn sún wọn ṣiṣẹ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù “pa àṣẹ ìtọ́ni,” èyí kò túmọ̀ sí pé ó lànà àwọn ohun àfidandanlé kalẹ̀ ní àdábọwọ́ ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ ń ṣe kòkárí àkójọ náà, tó kan ọ̀pọ̀ ìjọ, ni. Láfikún sí i, Pọ́ọ̀lù sọ pé, kí olúkúlùkù, “ní ilé ara rẹ̀,” mú wá, “bí ó ti lè máa láásìkí.” Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, ìdáwó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí òun nìkan mọ̀, tó sì fínnú fíndọ̀ ṣe. A kò fipá mú ẹnikẹ́ni.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Àwọn Ọ̀nà Tí Àwọn Kan Yàn Láti Gbà Ṣe Ìfúnni Ìtọrẹ fún Iṣẹ́ Yíká Ayé
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a kọ: “Contributions to Society [Id̀áwó fún Society]” sí lára. Lóṣooṣù ni àwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti àdúgbò.
O tún lè fi ìtọrẹ owó tí o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn tọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
Ìṣètò Ìtọrẹ Onípò Àfilélẹ̀
A lè fún Watch Tower Society ní owó lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún olùtọrẹ náà, nígbà tí ó bá ti nílò rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí a kọ sókè yìí.
Fífúnni Tí A Wéwèé
Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ìtọrẹ onípò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba kárí ayé wà. Lára wọn ni:
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìlànà ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí ìwéwèé owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báǹkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báǹkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí kí a ṣètò láti mú kí ó ṣeé san fún Society bí ẹni tó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báǹkì àdúgbò bá béèrè fún.
Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá, tàbí lábẹ́ ìṣètò kan, níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeé tà, tọrẹ fún Watch Tower Society, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn pátápátá, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Ẹnì kan ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Ìfisíkàáwọ́-Ẹni: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, a sì lè kọ orúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìwé àdéhùn fífi nǹkan sí ìkáwọ́ ẹni. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni tí ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.
Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “fífúnni tí a wéwèé,” irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé díẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń fẹ́ láti ṣe Society láǹfààní nípasẹ̀ irú ọ̀nà ìfúnni tí a wéwèé kan, Society ti mú ìwé pẹlẹbẹ kan jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Planned Giving to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà ní ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí Society ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní àfisíkàáwọ́-ẹni. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni wíwúlò nípa ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú. A sì pète rẹ̀ láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà ní United States, tí ń wéwèé láti fún Society ní ẹ̀bùn àkànṣe nísinsìnyí, tàbí tí ń fẹ́ fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tó bá kú, kí wọ́n lè yan ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní jù, tí ó sì gbéṣẹ́ jù láti ṣe bẹ́ẹ̀, ní gbígbé àyíká ipò ìdílé àti ti ara wọn yẹ̀ wò.
Lẹ́yìn tí àwọn kan ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ Planned Giving Desk, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún Society, kí wọ́n sì mú kí àǹfààní owó orí pọ̀ sí i nígbà kan náà, fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ìṣètò wọ̀nyí tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka iṣẹ́ Planned Giving Desk létí, kí a sì fún wọn ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá tan mọ́ ọn. Kí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ yìí, tàbí tí wọ́n fẹ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò fífúnni tí a wéwèé wọ̀nyí kàn sí ẹ̀ka iṣẹ́ Planned Giving Desk, nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tí a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí títẹ àdírẹ́sì náà láago, tàbí kí wọ́n kàn sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn.
Planned Giving Desk
Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
100 Watchtower Drive, Patterson, New York 12563-9204
Tẹlifóònù: (914) 878-7000
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn Ọmọdé Pẹ̀lú Jẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyÀ!
Mo fẹ́ fún yín lówó yìí kí ẹ fi ṣe ìwé sí i fún wa. Mo kó o jọ nípa ríran baba mi lọ́wọ́. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún iṣẹ́ àṣekára tí ẹ ń ṣe.—Pamela, ọmọ ọdún méje.
Mo ń fi dọ́là 6.85 ránṣẹ́ sí yín láti fi kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i. Nígbà tí mo ń ta ohun mímu olómi ọsàn nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí ni mo pa owó náà.—Selena, ọmọ ọdún mẹ́fà.
Mo sin àgbébọ̀ adìyẹ kan tó pa àkùkọ kan àti àgbébọ̀ mìíràn fún mi. Mo ya èyí tó kẹ́yìn sọ́tọ̀ fún Jèhófà. Níkẹyìn, ó pa àgbébọ̀ mẹ́ta, tí mo tà. Mo fi owó rẹ̀ ránṣẹ́ fún iṣẹ́ Jèhófà.—Thierry, ọmọ ọdún mẹ́jọ.
Gbogbo owó tí mo ní nìyí! Ẹ jọ̀wọ́ fi ọgbọ́n ná an. Kò rọrùn láti kó o jọ. Ó jẹ́ dọ́là 21.—Sarah, ọmọ ọdún mẹ́wàá
Mo gba ẹ̀bùn ipò kìíní nínú iṣẹ́ àyànfúnni kan nílé ìwé, nítorí náà, mo lọ ṣe ìdíje ẹlẹ́kùnjẹkùn ìjọba ìbílẹ̀. Níbẹ̀ pẹ̀lú, mo gba ipò kìíní, mo sì tún wá gba ipò kejì ní àṣekágbá ti àgbègbè. Mo gba ẹ̀bùn owó fún gbogbo ìwọ̀nyí. Mo fẹ́ láti fún Society nínú owó náà. Mo rò pé, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti gba àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí nítorí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo ti gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Ọkàn mí balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà tí mo ń ṣàgbékalẹ̀ ohun tí mo kọ níwájú àwọn adájọ́ náà.—Amber, ọmọ oníwèé kẹfà.
Mo fẹ́ láti fi èyí fún Jèhófà nípasẹ̀ yín. Ẹ bi í léèrè ohun tó yẹ kí ẹ fi ṣe. Ó mọ ohun gbogbo.—Karen, ọmọ ọdún mẹ́fà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
A ń ti iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn ọrẹ àtinúwá