Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Rán Kíláàsì Rẹ̀ Ọgọ́rùn-ún Jáde
ILÉ ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti kó ipa pàtàkì nínú ìpolongo Ìjọba Ọlọrun kárí ayé ní òde òní. Láti ìgbà tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ti bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ ní 1943, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege rẹ̀ ti ṣiṣẹ́ sìn ní ilẹ̀ tí ó lé ní 200. Ní March 2, 1996, kíláàsì rẹ̀ ọgọ́rùn-ún kẹ́kọ̀ọ́ yege.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní àkókò tí òjò dídì tí ó ga ju mítà méjì lọ ti rọ̀ sí agbègbè Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower ní Patterson, New York. Kò yani lẹ́nu pé, òjò dídì rọ̀ ní ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, gbọ̀ngàn àpéjọ náà kún fọ́fọ́, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwùjọ olùgbọ́ sì fetí sílẹ̀ ní Patterson, Wallkill, àti Brooklyn—àpapọ̀ 2,878 ènìyàn.
Theodore Jaracz, mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ni alága. Lẹ́yìn kíkí àwọn àlejò tí ó wá láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ó ké sí gbogbo wọn láti dìde dúró kọ orin 52. Gbọ̀ngàn àpéjọ náà ń hó yèè fún ìyìn sí Jehofa, bí wọ́n ti ń kọ orin “Orukọ Baba Wa,” láti inú ìwé náà, Kọrin Ìyìn sí Jehofah. Orin yẹn, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ alága nípa lílo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti yin Jehofa, ru èrò ìmọ̀lára sókè fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí yóò tẹ̀ lé e.
Ìmọ̀ràn Tí A Gbé Karí Ìwé Mímọ́ Látẹnu Àwọn Àgbà Ọkùnrin
Apá àkọ́kọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé ṣókí fún kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà, látẹnu mélòó kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jehofa fún ìgbà pípẹ́. Richard Abrahamson, mẹ́ḿbà orílé-iṣẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rẹ̀ ní 1940, rọ kíláàsì náà pé: “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Jíjẹ́ Kí A Tọ́ Yín Sọ́nà.” Ó rán wọn létí pé wọ́n ti ní ìrírí onírúurú sáà ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristian, títí kan oṣù márùn-ún tí wọ́n fi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní Gilead. Nítorí náà, èé ṣe tí wọ́n fi ní láti máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ kí a tọ́ wọn sọ́nà?
Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé, gbólóhùn náà tí aposteli Paulu lò ní 2 Korinti 13:11 “túmọ̀ sí ìgbésẹ̀ onítẹ̀síwájú, bíbá a nìṣó láti jọ̀wọ́ ara ẹni fún ohun tí Jehofa fẹ́ fi wá ṣe tàbí àtúnṣe rẹ̀, títún wa ṣe dé ìwọ̀n gíga jù lọ, kí a baà lè kúnjú òṣùwọ̀n ohun tí Jehofa ń béèrè lọ́wọ́ wa.” Nínú iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ilẹ̀ òkèèrè, kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege yóò dojú kọ àwọn ìpènijà tuntun sí ìgbàgbọ́ wọn. Wọn yóò ní láti kọ́ èdè tuntun, kí wọ́n mú ara wọn bá àṣà ìbílẹ̀ àti ipò ìgbésí ayé tuntun mu, kí wọ́n sì mú ara wọn ba oríṣiríṣi agbègbè ìpínlẹ̀ mu. Wọn yóò tún máa kojú onírúurú àkópọ̀ ìwà nínú ilé míṣọ́nnárì wọn àti nínú ìjọ wọn tuntun. Bí wọn yóò bá fara balẹ̀ fi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú gbogbo ipò wọ̀nyí, pẹ̀lú ẹ̀mí ìmúratán láti jẹ́ kí a tọ́ wọn sọ́nà, nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti kọ̀wé, wọ́n lè “máa bá a lọ lati máa yọ̀.”
John Barr, ọ̀kan nínú àwọn Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso márùn-ún, tí wọ́n kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, mú ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti inú 1 Korinti 4:9. Ó rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí pé, àwọn Kristian jẹ́ ìran àpéwò fún àwọn áńgẹ́lì àti fún àwọn ènìyàn. Ó wí pé: “Mímọ èyí ń fi kún ìjẹ́pàtàkì ipa ọ̀nà ìgbésí ayé Kristian kan, ní pàtàkì nígbà tí ó bá mọ̀ pé nípa ohun tí òún ń sọ àti ohun tí òún ń ṣe, òún lè ní ipa lílágbára lórí àwọn tí ń wo òun, àwọn tí òun kò rí àti àwọn tí òún rí. Mo gbà gbọ́ pé èyí yóò jẹ́ ohun kan tí ó dára fún ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n ti kíláàsì Gilead ọgọ́rùn-ún láti máa rántí bí ẹ ti ń lọ sí orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.”
Arákùnrin Barr rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 48 náà, bí wọ́n ti ń ran àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, láti fi sọ́kàn pé “ìdùnnú-ayọ̀ . . . máa ń sọ láàárín awọn áńgẹ́lì Ọlọrun lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.” (Luku 15:10) Ní títọ́ka sí 1 Korinti 11:10, ó fi hàn pé kì í ṣe kìkì àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí a lè fojú rí nìkan ni ìṣarasíhùwà ẹnì kan sí ìṣètò ìṣàkóso Ọlọrun ń nípa lé lórí, ṣùgbọ́n ó ń nípa lórí àwọn áńgẹ́lì tí a kò fojú rí pẹ̀lú. Ẹ wo bí ó ṣe ṣàǹfààní tó láti ní ojú ìwòye gbígbòòrò yìí lọ́kàn!
Mẹ́ḿbà míràn ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, Gerrit Lösch, tí òun alára jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́yege Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, jíròrò irú ẹsẹ Iwé Mímọ́ bí Orin Dafidi 125:1, 2; Sekariah 2:4, 5; àti Orin Dafidi 71:21 láti fi hàn pé Jehofa “yí àwọn ènìyàn rẹ̀ ká.” Ó ń dáàbò bò wọ́n ní gbogbo ìhà. Kìkì ìgbà ìpọ́njú ńlá nìkan ni Ọlọrun yóò ha pèsè irú ààbò bẹ́ẹ̀ bí? Olùbánisọ̀rọ̀ náà dáhùn pé: “Rárá, nítorí pé Jehofa ti jẹ́ ‘odi iná,’ ààbò kan fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ọdún ẹ̀yìn ogun, 1919, rí àṣẹ́kù Israeli nípa tẹ̀mí tí ń hára gàgà láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà káàkiri àgbáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Wọ́n jẹ́ aṣojú Jerusalemu ìṣàpẹẹrẹ tí ń bẹ ní ọ̀run. Jehofa mú ààbò àtọ̀runwá dájú fún àwọn aṣojú wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan ní àkókò òpin. Nígbà náà, ta ni ó lè kẹ́sẹ járí nínú dídá wọn dúró? Kò sí olúwa rẹ̀.” Ẹ wo bí ó ti fi àwọn àti gbogbo àwọn tí ń bá wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun lọ́kàn balẹ̀ tó!
Ulysses Glass, àgbà mẹ́ḿbà olùdarí ilé ẹ̀kọ́, fún kíláàsì náà níṣìírí láti ‘parí wíwá àyè fún ara wọn nínú ètò àjọ àgbáyé Jehofa.’ Àyè ni ipò kan tàbí ìgbòkègbodò kan tí ó bá agbára tàbí ìwà ẹnì kan mu. Ó polongo pé: “Ẹ̀yin míṣọ́nnárì lọ́la ti rí àyè yín nínú ètò àjọ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣeyebíye tó nísinsìnyí, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni èyí nínú ìgbésí ayé yín gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì.” Wọn yóò ní láti fi ara wọn fún lílo agbára wọn dáradára, kí wọ́n sì bá iṣẹ́ àyànfúnni àrà ọ̀tọ̀ tí Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀ ti fi lé wọn lọ́wọ́ mu.
Wallace Liverance, tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà olùdarí Gilead, tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọdún 17 ní Bolivia, ni ó sọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kẹ́yìn nínú apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Ó béèrè lọ́wọ́ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ẹ̀yin yóò ha dán Ọlọrun wò bí?” Báwo ni wọn yóò ṣe ṣe ìyẹn? Orílẹ̀-èdè Israeli dán Ọlọrun wò lọ́nà òdì. (Deuteronomi 6:16) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ní kedere, dídán Ọlọrun wò nípa ṣíṣàròyé tàbí kíkùn tàbí bóyá nípa fífi àìnígbàgbọ́ hàn nínú ọ̀nà tí ó gbà ń yanjú ọ̀ràn kò tọ́.” Ó rọ̀ wọ́n pé: “Nígbà tí ẹ bá dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni yín tuntun, ẹ dènà ìtẹ̀sí yẹn.” Nígbà náà, ọ̀nà wo ni ó tọ́ láti dán Ọlọrun wò? Arákùnrin Liverance ṣàlàyé pé: “Ó jẹ́ nípa gbígba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, nípa ṣíṣe ohun tí ó bá sọ gẹ́lẹ́, kí a sì fi àbájáde rẹ̀ sílẹ̀ fún un.” Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i ní Malaki 3:10 (NW), Jehofa ké sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dán mi wò.” Ó ṣèlérí pé bí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ mú ìdámẹ́wàá wọn wá sínú tẹ́ḿpìlì, òun yóò bù kún wọn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà béèrè pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi fi irú ojú kan náà wo iṣẹ́ àyànfúnni yín? Jehofa fẹ́ kí ẹ ṣàṣeyọrí nínú rẹ̀, nítorí náà ẹ dán an wò. Ẹ rọ̀ mọ́ iṣẹ́ àyànfúnni yín. Ẹ ṣe àtúnṣe tí ó bá fẹ́ kí ẹ ṣe. Ẹ ní ìfaradà. Ẹ wò ó bóyá yóò bù kún yín tàbí kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” Ẹ wo ìmọ̀ràn àtàtà tí èyí jẹ́ fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sin Jehofa!
Lẹ́yìn orin kan, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yí padà láti orí ọ̀rọ̀ àsọyé sí ọ̀wọ́ àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò gbígbádùn mọ́ni.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Gbígbéṣẹ́ Láti Inú Pápá
Mark Noumair, mẹ́ḿbà tuntun ti olùdarí Gilead, ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní àkókò tí wọ́n fi wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Èyí tẹnu mọ́ ìníyelórí lílo àtinúdá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì fún àwùjọ náà ní àwọn èrò gbígbéṣẹ́ tí wọ́n lè lò.
Nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ wọn ń lọ lọ́wọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Gilead yìí jàǹfààní ní pàtàkì nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti ilẹ̀ 42, tí àwọn pẹ̀lú wá gba àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Patterson. Púpọ̀ nínú wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gilead ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń lọ lọ́wọ́, a fọ̀rọ̀ wá àwọn aṣojú láti kíláàsì kẹta, ìkarùn-ún, ìkọkànléláàádọ́ta, àti ìkejìléláàádọ́rùn-ún, àti láti ibi Ìmúgbòòrò Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ní Germany lẹ́nu wò. Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí wọn ti ṣàǹfààní tó!
Wọ́n sọ bí ìmọ̀lára àwọn míṣọ́nnárì ṣe rí nígbà tí wọ́n rí iye àwọn olùyin Jehofa tí ń pọ̀ sí i ní àwọn ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn, láti orí iye kéréje sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá. Wọ́n sọ nípa bí wọ́n ṣe nípìn-ín nínú mímú ìhìn rere náà lọ sí àwọn ibùgbé jíjìnnà síra ní Àwọn Òke Andes àti àwọn abúlé ní orísun Odò Amazon. Wọ́n jíròrò jíjẹ́rìí fún àwọn púrúǹtù. Wọ́n sọ nípa akitiyan tiwọn fúnra wọn láti kọ́ èdè tuntun àti ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege lè máa retí ní ti gidi nípa bí ó ṣe lè tètè yá tó fún wọn láti jẹ́rìí, kí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ àsọyé ní èdè kan bíi Chinese. Àní wọ́n ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè Spanish àti Chinese pàápàá. Wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn míṣọ́nnárì máa ń túbọ̀ jáfáfá nígbà tí kì í bá ṣe èdè àwọn ènìyàn nìkan ni wọ́n kọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n tún kọ́ ìrònú wọn. Wọ́n sọ nípa ipò ìgbésí ayé líle koko ní àwọn ilẹ̀ òtòṣì, wọ́n sì sọ pé: “Àwọn míṣọ́nnárì ní láti mọ̀ pé ipò yìí sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ìkóninífà. Míṣọ́nnárì kan yóò ṣe rere jù bí ó bá lè nímọ̀lára bíi ti Jesu—àánú àwọn ènìyàn ṣe é, àwọn tí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”
Lẹ́yìn orin kan, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń bá a nìṣó pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwíyé látẹnu A. D. Schroeder, mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ó ní àǹfààní láti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead nígbà tí a dá a sílẹ̀ ní 1943. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àsọparí tí ó bá a mu fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó jíròrò kókó ẹ̀kọ́ náà “Kíkókìkí Jehofa Gẹ́gẹ́ Bí Oluwa Ọba Aláṣẹ.” Ìjíròrò agbàfíyèsí tí Arákùnrin Schroeder sọ nípa Orin Dafidi ìkẹrìnlélógún wú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìjókòó lórí, nípa bí ó ṣe jẹ́ àǹfààní kíkọyọyọ tó láti kókìkí Jehofa gẹ́gẹ́ bí Oluwa Ọba Aláṣẹ.
Lẹ́yìn pípín ìwé ẹ̀rí, àti kíkọ orin ìparí, Karl Klein ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso mú un wá sí òpin pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá. Ẹ wo irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbéṣẹ́, tí ó sì tuni lára nípa tẹ̀mí tí èyí jẹ́!
Ní àwọn ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, àwọn mẹ́ḿbà 48 ti kíláàsì ọgọ́rùn-ún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síbi iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì wọn ní ilẹ̀ 17. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n ti ní àkọsílẹ̀ rẹpẹtẹ ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian alákòókò kíkún tẹ́lẹ̀. Nígbà tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ ní Gilead, ní ìpíndọ́gba, wọ́n jẹ́ ẹni ọdún 33, wọ́n sì ti lo èyí tí ó lé ní ọdún 12 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn kan lára wọn ti jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé Beteli àgbáyé ti Watch Tower Society. Àwọn mìíràn ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn àjò. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti nípìn-ín nínú oríṣi iṣẹ́ ìsìn kan ní ilẹ̀ òkèèrè—ní Áfíríkà, Europe, Gúúsù America, àwọn erékùṣù òkun, àti àwọn àwùjọ tí ń sọ èdè àjèjì ní orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ àwọn míṣọ́nnárì míràn tí inú wọn ti dùn láti sọ pé, ‘Àwa yóò ṣiṣẹ́ sìn níbikíbi tí a bá ti nílò wa lágbàáyé.’ Ìfẹ́ ọkàn àtọkànwá wọn ni láti lo ìgbésí ayé wọn láti gbé Jehofa ga.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì:
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 8
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yanni sí: 17
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33.75
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 17.31
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.06
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Ọgọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Nínú orúkọ tí ó wà nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ḿbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì kọ orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Shirley, M.; Grundström, M.; Genardini, D.; Giaimo, J.; Shood, W.; Phair, P.; Buchanan, C.; Robinson, D. (2) Pine, C.; Kraus, B.; Racicot, T.; Hansen, A.; Beets, T.; Berg, J.; Garcia, N.; Fleming, K. (3) Whinery, L.; Whinery, L.; Harps, C.; Giaimo, C.; Berg, T.; Mann, C.; Berrios, V.; Pfeifer, C. (4) Randall, L.; Genardini, S.; Kraus, H.; Fleming, R.; D’Abadie, S.; Shirley, T.; Stevenson, G.; Buchanan, B. (5) Robinson, T.; Garcia, J.; Harps, P.; Racicot, D.; D’Abadie, F.; Phair, M.; Stevenson, G.; Shood, D. (6) Beets, L.; Pfeifer, A.; Berrios, M.; Pine, J.; Mann, L.; Randall, P.; Grundström, J.; Hansen, G.