Ẹ Máa Wo Ọ̀dọ̀ Jèhófà Fún Ìtùnú
“Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—RÓÒMÙ 15:5.
1. Èé ṣe tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fi ń mú kí nínílò tí a nílò ìtùnú túbọ̀ máa pọ̀ sí i?
BÍ ỌJỌ́ kọ̀ọ̀kan ti ń kọjá ni nínílò tí a nílò ìtùnú túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Bíbélì kan ṣe sọ ní èyí tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Ní àkókò wa “kíkérora” àti “ìrora” ti pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, aráyé ti jìyà yánpọnyánrin kan tẹ̀ lé òmíràn lọ́nà ti ogun, ìwà ọ̀daràn, àti àwọn jàm̀bá ti ìṣẹ̀dá tí ó sábà máa ń jẹ mọ́ lílò tí ènìyàn ti ṣi ilẹ̀ ayé lò.—Ìṣípayá 11:18.
2. (a) Ta ni ó jẹ̀bi jù lọ fún àwọn ègbé tí ó dé bá aráyé nísinsìnyí? (b) Òkodoro òtítọ́ wo ni ó fún wa ní ìdí fún ìtùnú?
2 Èé ṣe tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní àkókò wa? Ní ṣíṣàpèjúwe lílé Sátánì kúrò ní ọ̀run lẹ́yìn ìbí Ìjọba náà ní ọdún 1914, Bíbélì dáhùn pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òún ní.” (Ìṣípayá 12:12) Ẹ̀rí ṣíṣe kedere nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn túmọ̀ sí pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé òpin ìṣàkóso búburú ti Sátánì. Ẹ wo bí ó ti ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé láìpẹ́, ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé yóò padà sí ipò alálàáfíà tí ó wáyé kí Sátánì tó ti àwọn òbí wa àkọ́kọ́ sínú ìṣọ̀tẹ̀!
3. Nígbà wo ni ẹ̀dá ènìyàn ṣàìnílò ìtùnú?
3 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, Ẹlẹ́dàá ènìyàn pèsè ọgbà ẹlẹ́wà kan bí ibùgbé fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Ó wà ní agbègbè tí a ń pè ní Édẹ́nì, tí ó túmọ̀ sí “Ìdùnnú” tàbí “Ìgbádùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Síwájú sí i, Ádámù àti Éfà gbádùn ìlera pípé, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ṣíṣàìkú láéláé. Ṣáà ronú ná nípa ọ̀pọ̀ agbègbè tí wọn ì bá ti mú agbára ìṣe wọn dàgbà—níní ọgbà ọ̀gbìn, iṣẹ́ ọnà, ìkọ́lé, orin kíkọ. Ronú, pẹ̀lú, nípa gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí wọn ì bá ti kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe ń mú iṣẹ́ àṣẹ wọn ṣẹ láti ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì sọ ọ́ di párádísè kan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ní tòótọ́, ìgbésí ayé Ádámù àti Éfà ì bá ti kún fún ìgbádùn àti ìdùnnú, kì í ṣe ìkérora àti ìrora. Ní kedere, wọn kì bá tí nílò ìtùnú.
4, 5. (a) Èé ṣe tí Ádámù àti Éfà fi fìdí rẹmi nínú ìdánwò ìgbọ́ràn? (b) Báwo ni aráyé ṣe di ẹni tí ó nílò ìtùnú?
4 Ṣùgbọ́n, ohun tí Ádámù àti Éfà nílò jẹ́ láti mú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìmọrírì dàgbà fún Bàbá wọn ọ̀run onínúure. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ì bá ti sún wọn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run lábẹ́ gbogbo àyíká ipò. (Fi wé Jòhánù 14:31.) Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, àwọn òbí wa ìpilẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì kùnà láti ṣègbọràn sí ẹni tí ó fi ẹ̀tọ́ jẹ́ Ọba Aláṣẹ wọn, Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yọ̀ọ̀da ara wọn láti wá sábẹ́ ìṣàkóso búburú áńgẹ́lì kan tí a ti rẹ̀ sílẹ̀, Sátánì Èṣù. Sátánì ni ó tan Éfà láti dẹ́ṣẹ̀, kí ó sì jẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, Ádámù dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí òun pẹ̀lú jẹ nínú èso igi tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ ní kedere pé: “Ní ọjọ́ tí ìwọ́ bá jẹ nínú rẹ̀ kíkú ni ìwọ óò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:17.
5 Lọ́nà yìí, tọkọtaya ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Nígbà tí ó ń dájọ́ ikú, Ọlọ́run tún sọ fún Ádámù pé: “A fi ilẹ̀ bú nítorí rẹ; ní ìpọ́njú ni ìwọ óò máa jẹ nínú rẹ̀ ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo; ẹ̀gún òun òṣùṣú ni yóò máa hù jáde fún ọ, ìwọ óò sì máa jẹ ewéko ìgbẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:17, 18) Nípa báyìí, Ádámù àti Éfà pàdánù ìfojúsọ́nà ti sísọ ilẹ̀ ayé tí a kò tí ì ro di párádísè kan. Níwọ̀n bí a ti lé wọn kúrò ní Édẹ́nì, wọ́n gbọ́dọ̀ lo agbára wọn láti rí oúnjẹ tí a ń làágùn kí a tó rí, láti inú ilẹ̀ tí a ti fi bú. Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn, níwọ̀n bí wọ́n ti jogún ipò kíkú, ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í nílò ìtùnú gidigidi.—Róòmù 5:12.
Ìlérí Kan Tí Ń Tuni Nínú Ní Ìmúṣẹ
6. (a) Ìlérí tí ń tuni nínú wo ni Ọlọ́run ṣe lẹ́yìn tí aráyé ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ìtùnú ni Lámékì sọ?
6 Nígbà tí ó ń dájọ́ fún ẹni tí ó súnná sí ìṣọ̀tẹ̀ ènìyàn, Jèhófà fẹ̀rí jíjẹ́ ‘Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú’ hàn. (Róòmù 15:5) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣèlérí láti rán “irú-ọmọ” kan tí yóò dá àwọn ọmọ Ádámù nídè lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí oníjàm̀bá tí ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù ní. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Láìpẹ́, Ọlọ́run tún pèsè àrítẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè yìí. Fún àpẹẹrẹ, ó mí sí Lámékì, àtọmọdọ́mọ Ádámù kan tí ó jìnnà sí i, tí Sẹ́ẹ̀tì ọmọkùnrin rẹ̀ bí, láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí ọmọkùnrin Lámékì yóò ṣe pé: “Eléyìí ni yóò tù wá ní inú ní iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí OLÚWA ti fi bú.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:29) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí yìí, a sọ ọmọdékùnrin náà ní Nóà, èyí tí a lóye sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.”
7, 8. (a) Ipò wo ni ó mú kí Jèhófà banú jẹ́ nítorí dídá tí ó dá ènìyàn, kí sì ni Ó pète láti ṣe ní ìhùwàpadà? (b) Báwo ni Nóà ṣe gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀?
7 Lọ́wọ́ kan náà, Sátánì ń rí àwọn ọmọlẹ́yìn láàárín àwọn kan lára àwọn áńgẹ́lì tí ń bẹ ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyí gbé ẹran ara wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì mú àwọn obìnrin tí wọ́n jojú ní gbèsè, tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù, ṣe aya. Irú ìdàpọ̀ tí kò bá ti ẹ̀dá mu bẹ́ẹ̀ túbọ̀ sọ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn dìbàjẹ́, ó sì mú ìran àwọn Néfílímù, “àwọn agbéniṣánlẹ̀” aláìmọ-Ọlọ́run jáde, àwọn tí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2, 4, 11; Júúdà 6) “Ọlọ́run sì rí i pé ìwà búburú ènìyàn di púpọ̀ ní ayé . . . Inú OLÚWA sì bàjẹ́ nítorí tí ó dá ènìyàn sí ayé, ó sì dùn ún dé ọkàn rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6.
8 Jèhófà pète láti fi ìkún omi kárí ayé pa ayé búburú yẹn run, ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, ó mú kí Nóà kan ọkọ̀ láti gba ẹ̀mí là. Nípa báyìí, a gba ìran ènìyàn àti ọ̀wọ́ àwọn ẹranko là. Ẹ wo bí ara yóò ti tu Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó lẹ́yìn Ìkún Omi náà bí wọ́n ti ń jáde kúrò nínú ọkọ̀ sínú ilẹ̀ ayé tí a fọ̀ mọ́ tónítóní! Ẹ wo bí yóò ti tù wọ́n nínú tó pé a ti mú ègún tí ń bẹ lórí ilẹ̀ kúrò, ní mímú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn gidigidi! Ní tòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Lámékì já sóòótọ́, Nóà sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, Nóà jẹ́ irinṣẹ́ ní mímú “ìtùnú” wá fún aráyé títí dé ìwọ̀n àyè kan. Bí ó ti wù kí ó rí, agbára ìdarí búburú ti Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò dópin pẹ̀lú Ìkún Omi náà, aráyé sì ń bá a nìṣó láti máa kérora lábẹ́ ẹrù ìnira ti ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú.
Ẹnì Kan Tí Ó Tóbi Ju Nóà
9. Báwo ni Jésù Kristi ṣe já sí olùrànlọ́wọ́ àti olùtùnú fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn onírònúpìwàdà?
9 Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ní òpin nǹkan bí 4,000 ọdún ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, Irú-Ọmọ ìlérí náà fara hàn. Bí ìfẹ́ lílágbára fún aráyé ti sún un, Jèhófà Ọlọ́run rán Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ilẹ̀ ayé láti kú gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ìran ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jòhánù 3:16) Jésù Kristi ń mú ìtura púpọ̀ wá fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ olùrònúpìwàdà tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ikú ìrúbọ rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, tí wọ́n ti ṣe batisí máa ń rí ìtura àti ìtùnú wíwà pẹ́ títí gbà. (Mátíù 11:28-30; 16:24) Láìka àìpé wọn sí, wọ́n ń rí ìdùnnú jíjinlẹ̀ nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ tónítóní. Ẹ wo bí yóò ti tù wọ́n nínú tó láti mọ̀ pé bí wọ́n bá ń bá a nìṣó láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, a óò san èrè ìyè àìnípẹ̀kun fún wọn! (Jòhánù 3:36; Hébérù 5:9) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan nítorí àìlera, nígbà náà, wọ́n ní olùrànlọ́wọ́, tàbí olùtùnú, ìyẹn ni Olúwa tí a jí dìde, Jésù Kristi. (Jòhánù Kìíní 2:1, 2) Nípa jíjẹ́wọ́ irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu láti yẹra fún jíjẹ́ olùfi-ẹ̀ṣẹ̀-ṣèwàhù, wọ́n ń rí ìtura gbà, ní mímọ̀ pé ‘Ọlọ́run jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì.’—Jòhánù Kìíní 1:9; 3:6; Òwe 28:13.
10. Kí ni a rí kọ́ láti inú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tí ó fi wà lórí ilẹ̀ ayé?
10 Nígbà tí ó fi wà lórí ilẹ̀ ayé, Jésù tún mú ìtura wá nípa títú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù sílẹ̀, nípa wíwo gbogbo onírúurú àìsàn sàn, àti nípa jíjí àwọn olùfẹ́ tí ó ti kú dìde sí ìyè. Lóòótọ́, irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní tí kò wà pẹ́ títí, níwọ̀n bí àwọn tí a tipa bẹ́ẹ̀ bù kún ti darúgbó, tí wọ́n sì kú lẹ́yìn ìgbà náà. Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù tipa bẹ́ẹ̀ tọ́ka sí àwọn ìbùkún ọjọ́ ọ̀la wíwà pẹ́ títí tí òun yóò tú dà sórí gbogbo aráyé. Nísinsìnyí tí òún jẹ́ Ọba alágbára ti ọ̀run, láìpẹ́ òun yóò ṣe ohun tí ó ju wíwulẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lọ fíìfíì. Òun yóò jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú aṣáájú wọn, Sátánì, nínú ipò àìlètapútú. Lẹ́yìn náà, Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ológo ti Kristi yóò bẹ̀rẹ̀.—Lúùkù 8:30, 31; Ìṣípayá 20:1, 2, 6.
11. Èé ṣe tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní “Olúwa sábáàtì”?
11 Jésù sọ pé òun ni “Olúwa sábáàtì,” ó sì ṣe ọ̀pọ̀ lára àwọn ìmúláradá rẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì. (Mátíù 12:8-13; Lúùkù 13:14-17; Jòhánù 5:15, 16; 9:14) Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Tóò, Sábáàtì jẹ́ ara Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Hébérù 10:1) Ọjọ́ mẹ́fà fún iṣẹ́ ṣíṣe láàárín ọ̀sẹ̀ ń rán wa létí nípa 6,000 ọdún tí ó ti kọjá tí ènìyàn ti fi sìnrú lábẹ́ ìṣàkóso aninilára ti Sátánì. Ọjọ́ Sábáàtì ní òpin ọ̀sẹ̀ ń ránni létí ìsinmi tí ń tuni nínú tí aráyé yóò rí gbà nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ti Nóà Títóbi Jù náà, Jésù Kristi.—Fi wé Pétérù Kejì 3:8.
12. Ìrírí tí ń tuni nínú wo ni a lè fojú sọ́nà fún?
12 Ẹ wo ìtura tí àwọn ọmọ-abẹ́ ìṣàkóso Kristi, tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé yóò ní, nígbà tí wọ́n bá rí ara wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín, tí wọ́n ti yè bọ́ pátápátá kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí búburú ti Sátánì! Ìtùnú síwájú sí i yóò dé bí wọ́n ti ń nírìírí ìwòsàn àrùn wọn nípa ti ara, ní ti èrò ìmọ̀lára, àti ní ti ọpọlọ. (Aísáyà 65:17) Lẹ́yìn náà, ṣáà ronú ná nípa ayọ̀ àgbàyanu tí wọn yóò ní, bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kí àwọn olùfẹ́ wọn káàbọ̀ láti inú ikú! Ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 21:4) Bí a ti ń ṣàmúlò àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, àwọn onígbọràn ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò dàgbà dé ìjẹ́pípé, ní yíyè bọ́ pátápátá kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ìdarí búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ní. (Ìṣípayá 22:1-5) Lẹ́yìn náà, a óò dá Sátánì sílẹ̀ “fún ìgbà díẹ̀.” (Ìṣípayá 20:3, 7) A óò fí ìyè àìnípẹ̀kun san èrè fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ gbé ipò ọba aláṣẹ tí ó fi ẹ̀tọ́ jẹ́ ti Jèhófà lárugẹ. Finú wòye ìdùnnú àti ìtura tí kò ṣeé fi ẹnu sọ ti níní ‘ìdásílẹ̀ lómìnira’ pátápátá “kúrò nínú ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́”! Nípa báyìí, aráyé onígbọràn yóò gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
13. Èé ṣe tí gbogbo Kristẹni tòótọ́ fi nílò ìtùnú tí Ọlọ́run ń pèsè?
13 Níwọ̀n àkókò yìí ná, a ń bá a nìṣó láti wà lábẹ́ ìkérora àti ìrora tí ó wọ́pọ̀ fún gbogbo àwọn tí ń gbé láàárín ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì. Ìbísí nínú àìsàn nípa ti ara àti ìṣiṣẹ́gbòdì nípa ti èrò ìmọ̀lára ń nípa lórí gbogbo onírúurú ènìyàn, títí kan àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́. (Fílípì 2:25-27; Tẹsalóníkà Kìíní 5:14) Ní àfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a sábà máa ń jìyà ìfiniṣẹlẹ́yà àti inúnibíni tí kò tọ́ tí Sátánì ń rọ́ lù wá nítorí ‘ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò sí àwọn ènìyàn.’ (Ìṣe 5:29) Nípa báyìí, bí a óò bá fara dà á nìṣó ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run títí dé òpin ayé Sátánì, a nílò ìtùnú, ìrànwọ́, àti okun tí Òun ń pèsè.
Ibi Tí A Óò Ti Rí Ìtùnú
14. (a) Ìlérí wo ni Jésù ṣe ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀? (b) Kí ni ó ṣe pàtàkì bí a óò bá jàǹfààní ní kíkún láti inú ìtùnú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run?
14 Ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù mú un ṣe kedere sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé òun yóò fi wọ́n sílẹ̀ láìpẹ́, òun yóò sì padà sọ́dọ̀ Bàbá òun. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì bà wọ́n nínú jẹ́. (Jòhánù 13:33, 36; 14:27-31) Ní mímọ àìní wọn fún ìtùnú tí ń bá a nìṣó, Jésù ṣèlérí pé: “Èmi óò béèrè lọ́wọ́ Bàbá òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.” (Jòhánù 14:16, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Jésù níhìn-ín tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tí a tú dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní 50 ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀.a Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ẹ̀mí Ọlọ́run tù wọ́n nínú nígbà ìdánwò wọn, ó sì fún wọn lókun láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 4:31) Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gbọdọ̀ wo irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí í ṣàdédé wá. Láti jàǹfààní nínú rẹ̀ ní kíkún, Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní gbígbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ tí ń tuni nínú, tí Ọlọ́run ń pèsè nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Lúùkù 11:13.
15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń pèsè ìtùnú fún wa?
15 Ọ̀nà míràn tí Ọlọ́run ń gbà pèsè ìtùnú jẹ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́ kí àwa lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Èyí fi àìní tí a ní hàn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kí a sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí a kọ sínú Bíbélì àti sínú àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì. A tún ní láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, níbi tí a ti ń ṣàjọpín àwọn èrò tí ń tuni nínú láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀kan nínú ète pàtàkì fún irú ìkórajọpọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ láti fún ẹnì kíní kejì níṣìírí.—Hébérù 10:25.
16. Kí ni àwọn ìpèsè Ọlọ́run tí ń tuni nínú yẹ kí ó sún wa láti ṣe?
16 Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ara Róòmù ń bá a nìṣó láti fi àbájáde rere tí a ń rí gbà nípa lílo àwọn ìpèsè Ọlọ́run tí ń tuni nínú hàn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní, pé pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan kí ẹ̀yin lè fi ẹnu kan yin Ọlọ́run àti Bàbá Olúwa wa Jésù Kristi lógo.” (Róòmù 15:5, 6) Bẹ́ẹ̀ ni, nípa lílo àwọn ìpèsè Ọlọ́run tí ń tuni nínú, dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́, a óò túbọ̀ dà bíi ti Aṣáájú wa onígboyà, Jésù Kristi. Èyí yóò sún wa láti máa bá a nìṣó ní lílo ẹnu wa láti yin Ọlọ́run lógo nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa, ní àwọn ìpàdé wa, nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ara ẹni pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, àti nínú àdúrà wa.
Ní Àkókò Ìdánwò Líle Koko
17. Báwo ni Jèhófà ṣe tu Ọmọkùnrin rẹ̀ nínú, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
17 Jésù “dààmú gidigidi,” ó sì “ní ẹ̀dùn ọkàn gidigidi” ní alẹ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀ onírora gógó. (Mátíù 26:37, 38) Nítorí náà, ó lọ jìnnà díẹ̀ sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sì gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. “A . . . gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Hébérù 5:7) Bíbélì ròyìn pé “áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara han [Jésù] ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:43) Ọ̀nà onígboyà àti alákíkanjú tí Jésù gbà kojú àwọn alátakò rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà tu Ọmọkùnrin rẹ̀ nínú ni èyí tí ó gbéṣẹ́ jù lọ.—Jòhánù 18:3-8, 33-38.
18. (a) Sáà wo nínú ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù ni ó kún fún àdánwò jù lọ? (b) Báwo ni a ṣe lè jẹ́ ìtùnú fún àwọn alàgbà oníyọ̀ọ́nú, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn?
18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú la àwọn sáà ìdánwò líle koko kọjá. Fún àpẹẹrẹ, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Éfésù ni “omijé àti àwọn àdánwò tí ó ṣẹlẹ̀ sí [i] nípasẹ̀ àwọn ìdìmọ̀lù àwọn Júù” bá rìn. (Ìṣe 20:17-20) Ní paríparí rẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi Éfésù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn alátìlẹ́yìn abo ọlọ́run Átẹ́mísì ti dá rògbòdìyàn sílẹ̀ ní ìlú náà nítorí ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀. (Ìṣe 19:23-29; 20:1) Bí Pọ́ọ̀lù ti dorí kọ àríwá láti lọ sí ìlú Tíróásì, ohun mìíràn mú kí ọkàn rẹ̀ dààmú. Ní àkókò kan ṣáájú rògbòdìyàn náà ní Éfésù, ó ti rí ìròyìn kan tí ń dani láàmú gbà. Ìpínyà ti wọnú ìjọ tuntun tí ó wà ní Kọ́ríńtì, ó sì ń fàyè gba ìwà àgbèrè. Fún ìdí èyí, láti Éfésù, Pọ́ọ̀lù ti kọ lẹ́tà ìbáwí lílágbára pẹ̀lú ìrètí ṣíṣàtúnṣe ipò náà. Èyí kì í ṣe ohun tí ó rọrùn fún un láti ṣe. Lẹ́yìn náà, ó sọ nínú lẹ́tà kejì pé: “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti làásìgbò ọkàn-àyà ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé.” (Kọ́ríńtì Kejì 2:4) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, kì í rọrùn fún àwọn alàgbà oníyọ̀ọ́nú láti fúnni ní ìmọ̀ràn àti ìbáwí atọ́nisọ́nà, lọ́nà kan nítorí pé wọ́n mọ àìlera ti àwọn fúnra wọn dáradára. (Gálátíà 6:1) Nígbà náà, ńjẹ́ kí a jẹ́ ìtùnú fún àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín wa nípa fífi ìmúratán dáhùn padà sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́, tí a gbé karí Bíbélì.—Hébérù 13:17.
19. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi lọ láti Tíróásì sí Makedóníà, báwo sì ni òún ṣe jèrè ìtura lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
19 Nígbà tí ó fi wà ní Éfésù, kì í ṣe kìkì pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún rán Títù láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ní fífún un ní iṣẹ́ àṣẹ láti fi ìròyìn ránṣẹ́ nípa ìhùwàpadà wọn sí lẹ́tà náà. Pọ́ọ̀lù retí láti pàdé Títù ní Tíróásì. Níbẹ̀, a fi àǹfààní rere ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bù kún Pọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n èyí kùnà láti fi òpin sí àníyàn rẹ̀ nítorí pé Títù kò tí ì dé síbẹ̀. (Kọ́ríńtì Kejì 2:12, 13) Nítorí náà, ó rìnrìn àjò lọ sí Makedóníà, ní ríretí láti pàdé Títù níbẹ̀. Àníyàn Pọ́ọ̀lù túbọ̀ pọ̀ sí i nítorí àtakò gbígbóná janjan sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a dé Makedóníà, ẹran ara wa kò ní ìtura àlàáfíà kankan, ṣùgbọ́n a ń bá a lọ lábẹ́ ìfìyà pọ́n wa lójú ní ọ̀nà gbogbo—ìjà wà lóde, ìbẹ̀rù wà nínú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń tu àwọn wọnnì tí a mú balẹ̀ nínú, tù wá nínú nípa wíwàníhìn-ín Títù.” (Kọ́ríńtì Kejì 7:5, 6) Ẹ wo ìtura tí ó jẹ́ nígbà tí Títù dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti sọ fún Pọ́ọ̀lù nípa bí àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe dáhùn padà lọ́nà rere sí lẹ́tà rẹ̀!
20. (a) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, kí ni ọ̀nà pàtàkì míràn tí Jèhófà fi ń pèsè ìtùnú? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e?
20 Ìrírí Pọ́ọ̀lù jẹ́ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, tí púpọ̀ lára wọn ń dojú kọ àwọn àdánwò pẹ̀lú, tí ó mú kí a “mú wọn balẹ̀,” tàbí “mú wọn sorí kọ́.” (Phillips) Bẹ́ẹ̀ ní, ‘Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú’ mọ àìní olúkúlùkù wa, ó sì lè lò wá láti jẹ́ ìtùnú fún ẹnì kíní kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe jèrè ìtùnú nípasẹ̀ ìròyìn Títù nípa ìṣarasíhùwà onírònúpìwàdà àwọn ará Kọ́ríńtì. (Kọ́ríńtì Kejì 7:11-13) Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí yóò tẹ̀ lé e, a óò gbé ìhùwàpadà ọlọ́yàyà ti Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì àti bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùṣàjọpín ìtùnú Ọlọ́run lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ lónìí yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀kan nínú iṣẹ́ pàtàkì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lórí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní jẹ́ láti yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbàṣọmọ ọmọkùnrin ẹ̀mí ti Ọlọ́run àti arákùnrin Jésù. (Kọ́ríńtì Kejì 1:21, 22) Èyí wà fún kìkì 144,000 ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣípayá 14:1, 3) Lónìí, ọ̀pọ̀ jaburata lára àwọn Kristẹni ni a ti fi inú rere fún ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fi ẹ̀mí yàn wọ́n, àwọn pẹ̀lú ń gba ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.
Ìwọ́ Ha Lè Dáhùn Bí?
◻ Báwo ni aráyé ṣe wá di ẹni tí ó nílò ìtùnú?
◻ Báwo ni Jésù ṣe fẹ̀rí hàn pé òún tóbi ju Nóà?
◻ Èé ṣe tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní “Olúwa sábáàtì”?
◻ Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pèsè ìtùnú lónìí?
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Pọ́ọ̀lù nírìírí ìtùnú gidigidi nípasẹ̀ ìròyìn Títù nípa àwọn ará Kọ́ríńtì
MAKEDÓNÍÀ
Fílípì
GÍRÍÌSÌ
Kọ́ríńtì
ÉṢÍÀ
Tíróásì
Éfésù