Títù—“Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún Ire Yín”
LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN, ìṣòro máa ń dìde nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní. Wọ́n ní láti yanjú àwọn ìṣòro náà, wọ́n sì nílò ìgboyà àti ìgbọràn láti ṣe èyí. Ọkùnrin kan tí ó kojú irú ìpèníjà púpọ̀ bẹ́ẹ̀, tí ó sì ṣàṣeyọrí ni Títù. Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó ti bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ pọ̀, ó sapá gan-an láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe nǹkan bí Jèhófà ṣe fẹ́. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì pé, Títù jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ire wọn.’—2 Kọ́ríńtì 8:23.
Ta ni Títù? Ipa wo ló kó nínú yíyanjú ìṣòro? Báwo ni a sì ṣe lè jàǹfààní nínú gbígbé ọ̀ràn rẹ̀ yẹ̀ wò?
Ọ̀ràn Ìdádọ̀dọ́
Gíríìkì aláìdádọ̀dọ́ ni Títù. (Gálátíà 2:3)a Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti pè é ní “ojúlówó ọmọ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a ṣàjọpín ní àpapọ̀,” ó ṣeé ṣe kí Títù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ àpọ́sítélì náà nípa tẹ̀mí. (Títù 1:4; fi wé 1 Tímótì 1:2.) Títù wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, Bánábà, àti àwọn mìíràn tí wọ́n gbéra láti Áńtíókù, Síríà, nígbà tí wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Tiwa láti jíròrò ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́.—Ìṣe 15:1, 2; Gálátíà 2:1.
Àwọn ènìyàn sọ pé níwọ̀n bí ìjíròrò ti ń lọ lọ́wọ́ nípa yíyí àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ lọ́kàn padà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n mú Títù dání láti fi hàn pé àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù lè rí ojú rere Ọlọ́run yálà wọ́n dádọ̀dọ́ tàbí wọn kò dádọ̀dọ́. Àwọn kan nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù tí wọ́n jẹ́ Farisí kí wọ́n tó gba ìsìn Kristẹni sọ pé àwọn Kèfèrí tí a yí lọ́kàn padà wà lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti dádọ̀dọ́, kí wọ́n sì máa pa Òfin mọ, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan tako ọ̀rọ̀ náà. Fífipá mú Títù àti àwọn Kèfèrí mìíràn láti dádọ̀dọ́ yóò túmọ̀ sí sísọ pé ìgbàlà kò sinmi lórí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà àti lórí ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi bí kò ṣe lórí ṣíṣe ohun tó wà nínú Òfin. Yóò tún jẹ́ ṣíṣàìtẹ́wọ́gba ẹ̀rí náà pé àwọn Kèfèrí, tàbí àwọn ènìyàn ayé, ti gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.—Ìṣe 15:5-12.
A Rán An Lọ sí Kọ́ríńtì
Nígbà tí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ yanjú, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gba àṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láti wàásù fún àwọn orílẹ̀-èdè. Lákòókò kan náà, wọ́n tún gbìyànjú láti fi àwọn òtòṣì sọ́kàn. (Gálátíà 2:9, 10) Ní gidi, nígbà tí a tún fi máa mẹ́nu kan Títù nínú àkọsílẹ̀ tí a mí sí ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, Kọ́ríńtì ló wà bí aṣojú Pọ́ọ̀lù, tó sì ń ṣètò kíkó nǹkan jọ fún àwọn ẹni mímọ́. Àmọ́, bí Títù ti ń ṣe iṣẹ́ yìí lọ́wọ́, ó tún bá ara rẹ̀ nínú ipò mìíràn tí kò fararọ.
Ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì fi hàn pé ó kọ́kọ́ kọ̀wé sí wọ́n láti “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbèrè.” Ó wí fún wọn pé kí wọ́n mú alágbèrè kan tí kò ronú pìwà dà kúrò láàárín wọn. Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé tó lágbára sí wọn, “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé.” (1 Kọ́ríńtì 5:9-13; 2 Kọ́ríńtì 2:4) Láàárín àkókò náà, a rán Títù lọ sí Kọ́ríńtì láti ṣèrànwọ́ nínú ètò ìkó-nǹkan-jọ tó ń lọ lọ́wọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn Kristẹni ará Jùdíà tí wọ́n jẹ́ aláìní. Ó tún lè jẹ́ pé a rán an láti lọ wo bí àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe gba lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí.—2 Kọ́ríńtì 8:1-6.
Báwo ni àwọn ará Kọ́ríńtì yóò ṣe gba ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí? Bóyá nítorí pé Pọ́ọ̀lù ń ṣàníyàn láti mọ̀ ló ṣe rán Títù láti Éfésù lọ sí Kọ́ríńtì ní ìsọdá Òkun Aegean, ó sì ní kí ó padà wá jábọ̀ bí ó bá ṣe lè yá tó. Bí Títù bá parí iṣẹ́ yẹn kí ọkọ̀ tó yé rin òkun nítorí ìgbà òtútù tí ń bọ̀ (ní nǹkan bí àárín November), ó lè wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Tíróásì tàbí kí ó fẹsẹ̀ rin ọ̀nà Hellespont tí ó túbọ̀ jìnnà. Ó lè jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti tètè dé ibi tí wọ́n ṣàdéhùn láti pàdé ní Tíróásì, níwọ̀n bí ìjà ìgboro tí àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà dá sílẹ̀ ti jẹ́ kí ó tètè kúrò ní Éfésù ṣáájú ìgbà tí ó ní lọ́kàn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró ní Tíróásì tó sú u, ó ronú pé kì í ṣe ọkọ̀ òkun ni Títù ń wọ̀ bọ̀. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ rìn lọ pẹ̀lú èrò pé òun yóò pàdé rẹ̀ lọ́nà. Tí Pọ́ọ̀lù bá dé ilẹ̀ Yúróòpù, yóò gba Via Egnatia, ó sì pàdé Títù ní Makedóníà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ohun tó mú kí ara tu Pọ́ọ̀lù, kí ó sì láyọ̀ gan-an ni pé ìròyìn rere ló gbọ́ láti Kọ́ríńtì. Ìjọ náà gba ìmọ̀ràn àpọ́sítélì náà tọwọ́tẹsẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 2:12, 13; 7:5-7.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nípa bí wọn óò ṣe gba àwọn aṣojú rẹ̀, Ọlọ́run ran Títù lọ́wọ́ láti jíṣẹ́ tí a rán an. Wọ́n gba Títù pẹ̀lú “ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (2 Kọ́ríńtì 7:8-15) Tí a bá sọ ọ́ bí alálàyé náà, W. D. Thomas, ṣe sọ ọ́: “A lè gbà pé láìsọ ìbániwí Pọ́ọ̀lù di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, [Títù] fi òye àti ọgbọ́n ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ará Kọ́ríńtì; ó sì mú un dá wọn lójú pé ire tẹ̀mí wọn ló jẹ Pọ́ọ̀lù lọ́kàn tó fi sọ̀rọ̀ bó ṣe sọ̀rọ̀ yẹn.” Lásìkò tí èyí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, Títù ti wá nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì nítorí ẹ̀mí ìgbọràn tí wọ́n ní àti ìyípadà dáradára tí wọ́n ṣe. Ìṣarasíhùwà dáadáa tí wọ́n ní ló jẹ́ orísun ìṣírí fún un.
Ohun kejì ńkọ́, èyí tó gbé Títù lọ sí Kọ́ríńtì—kíkó nǹkan jọ fún àwọn ẹnì mímọ́ ní Jùdíà? Títù ń ṣiṣẹ́ lórí ìyẹn pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú 2 Kọ́ríńtì. Ó lè jẹ́ pé Makedóníà ni a ti kọ lẹ́tà yẹn, nígbà ìwọ́wé ọdún 55 Sànmánì Tiwa, ní kété lẹ́yìn tí Títù àti Pọ́ọ̀lù pàdé. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé a rán Títù, tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkó nǹkan jọ náà, padà sí wọn pẹ̀lú àwọn olùrànlọ́wọ́ méjì tí a kò dárúkọ láti wá parí iṣẹ́ náà. Níwọ̀n bí ìfẹ́ àwọn ará Kọ́ríńtì ti jẹ Títù lọ́kàn gan-an, kò lọ́ra láti padà lọ rárá. Ó lè jẹ́ pé Títù mú lẹ́tà onímìísí kejì ti Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì dání nígbà tí ó ń padà lọ sí Kọ́ríńtì.—2 Kọ́ríńtì 8:6, 17, 18, 22.
Kì í ṣe pé Títù mọ ètò ṣíṣe dáradára nìkan ni, ó tún jẹ́ ẹni tí a lè fa iṣẹ́ tí ó gbẹgẹ́ nínú àwọn ipò tí kò rọgbọ lé lọ́wọ́. Ó ní ìgboyà, ó dàgbà dénú, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù ka Títù sí ẹni tó dáńgájíá láti kojú àwọn ìṣòro gbígbàfiyèsí tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí àwọn “àpọ́sítélì . . . adárarégèé” ń dá sílẹ̀ ní Kọ́ríńtì. (2 Kọ́ríńtì 11:5) Ẹ̀rí wà pé irú èèyàn yìí ni Títù jẹ́ nítorí ibi tí orúkọ rẹ̀ tún ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, nínú iṣẹ́ mìíràn tí ó gbomi mu.
Ní Erékùṣù Kírétè
Ó lè jẹ́ pé nígbà kan láàárín ọdún 61 sí 64 Sànmánì Tiwa, ni Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù, tó ń sìn ní erékùṣù Kírétè ní Mẹditaréníà nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù fi í sílẹ̀ níbẹ̀ kí ó lè “ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù,” kí ó sì lè “yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá.” Lápapọ̀, a mọ àwọn ará Kírétè ní “òpùrọ́ . . . ẹranko ẹhànnà tí ń ṣeni léṣe, . . . alájẹkì tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́.” Ìdí nìyẹn tí a óò tún fi ní kí Títù gbé ìgbésẹ̀ onígboyà àti onídùúróṣinṣin ní Kírétè. (Títù 1:5, 10-12) Iṣẹ́ bàǹtàbanta nìyẹn, nítorí ó lè wá jẹ́ ohun tí yóò pinnu bí ìgbésí ayé àwọn Kristẹni ní erékùṣù yẹn yóò ṣe rí lọ́jọ́ iwájú. Lábẹ́ ìmísí, Pọ́ọ̀lù ran Títù lọ́wọ́ nípa sísọ àwọn ohun pàtó tí yóò máa wò lára àwọn tí yóò wá di alábòójútó. Àwọn ẹ̀rí ìtóótun wọ̀nyẹn ni a ṣì ń gbé yẹ̀ wò tí a bá fẹ́ yan àwọn alàgbà Kristẹni.
Ìwé Mímọ́ kò sọ ìgbà tí Títù kúrò ní Kírétè. Ó pẹ́ níbẹ̀ débi tí Pọ́ọ̀lù fi ní kí ó pèsè fún Sénásì àti Àpólò, tí wọ́n yà níbẹ̀ nígbà ìrìn àjò kan tí wọ́n rìn ní ìgbà kan tí a kò mẹ́nu kàn. Àmọ́, Títù kò ní pẹ́ gan-an ní erékùṣù náà. Pọ́ọ̀lù ń ṣètò láti rán Átémásì tàbí Tíkíkọ́sì lọ síbẹ̀, lẹ́yìn náà, kí Títù sì lọ pàdé àpọ́sítélì náà ní Nikopólísì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìlú ńlá gbígbajúmọ̀ tí ń jẹ́ orúkọ yẹn tí ó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Gíríìsì.—Títù 3:12, 13.
Ní ibi tí a ti mẹ́nu kan Títù kẹ́yìn ní ṣókí, nínú Bíbélì, a gbọ́ pé bóyá Pọ́ọ̀lù tún rán an ní iṣẹ́ mìíràn ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa. Iṣẹ́ náà gbé e dé Damatíà, àgbègbè kan ní ìlà oòrùn Òkun Adriatic ní Croatia òde òní. (2 Tímótì 4:10) A kò rí ìsọfúnni nípa ohun tí Títù yóò ṣe níbẹ̀, àmọ́, a ronú pé bóyá a rán an láti lọ ṣàtúnṣe ọ̀ràn ìjọ ni, kí ó sì ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, irú iṣẹ́ tí Títù ṣe ní Kírétè ni yóò ṣe níbẹ̀.
A mà dúpẹ́ gan-an o, pé a ní irú àwọn Kristẹni alábòójútó bí Títù! Òye ṣíṣe kedere tí wọ́n ní nípa àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ àti bí wọ́n ṣe ń fi ìgboyà lò wọ́n ń dáàbò bo ipò tẹ̀mí ìjọ. Ẹ jẹ́ kí a fara wé ìgbàgbọ́ wọn, kí a sì dà bí Títù nípa kíkọ́wọ́ti ire tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—Hébérù 13:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gálátíà 2:3 sọ pe Gíríìkì (Helʹlen) ni Títù. Èyí lè túmọ̀ sí pé Gíríìkì ni orírun rẹ̀. Àmọ́, wọ́n sọ pé àwọn òǹkọ̀wé ará Gíríìkì kan lo èdè tí a ń lò fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà (Helʹle·nes) nígbà tí wọ́n ń tọ́ka sí àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì tí wọ́n ń sọ èdè Gíríìkì, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ó lè jẹ́ pé lọ́nà yìí ni Títù gbà jẹ́ Gíríìkì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Títù jẹ́ onígboyà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ire àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì àti àwọn ibòmíràn