Awọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun—Awọn Ènìyàn Aláyọ̀ Tí Wọn Wà Létòlétò
“Aláyọ̀ ni awọn ènìyàn naa tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun wọn!”—ORIN DAFIDI 144:15, NW.
1, 2. (a) Èéṣe tí Jehofa fi ní ẹ̀tọ́ lati gbé awọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n kalẹ̀ fún awọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí ni méjì lára awọn àmì ànímọ́ Jehofa tí ó ṣe pàtàkì pé kí a fẹ́ lati ṣàfarawé rẹ̀?
JEHOFA ni Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, Ọlọrun Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá. (Genesisi 1:1; Orin Dafidi 100:3) Nitori ìdí èyí, ó ní ẹ̀tọ́ lati gbé awọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n ìwàhíhù kalẹ̀ fún awọn ìránṣẹ́ rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti mọ ohun tí ó dára jùlọ fún wọn. (Orin Dafidi 143:8) Oun sì ni Olórí Àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn tí o yẹ fún wọn lati ṣàfarawé awọn ànímọ́ rẹ̀. Aposteli kan kọ̀wé pé, “Ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọrun bí awọn ọmọ ọ̀wọ́n.”—Efesu 5:1.
2 Àmì ànímọ́ kan tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tí ó yẹ fún wa lati ṣàfarawé nííṣe pẹlu ìṣètòjọ rẹ̀. Oun “kìí ṣe Ọlọrun ohun rúdurùdu.” (1 Korinti 14:33) Nígbà tí a ba fẹ̀sọ̀ kíyèsí ohun tí Ọlọrun ti dá, a ń sún wa lati wá sí ìparí èrò naa pé oun ni Ẹni-Sàràkí tí ó wà létòlétò jùlọ lágbàáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, àmì ànímọ́ mìíràn tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tí ó fẹ́ kí awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣàfarawé ni ayọ̀, nitori pé oun jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀.” (1 Timoteu 1:11, NW) Nipa bayii, agbára ìṣètò rẹ̀ ni a mú wàdéédéé pẹlu ayọ̀. Ọ̀kan kò tayọ lọ́nà tí ó lè ṣèpalára fún èkejì.
3. Bawo ni ojú ọ̀run tí ó kún fún awọn ìràwọ̀ ṣe ṣàṣefihàn agbára ìṣètò Ọlọrun?
3 Gbogbo ohun tí Jehofa ti ṣe, lati orí èyí tí ó tóbi jùlọ títí lọ dé orí èyí tí ó kéré jùlọ fi ẹ̀rí hàn pé oun jẹ́ Ọlọrun ètò. Fún àpẹẹrẹ, ṣe àgbéyẹ̀wò àgbáyé tí a lè fojúrí. Ninu rẹ̀ ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún billion ìràwọ̀ wà. Ṣugbọn gbogbo iwọnyi kò fọ́n káàkiri lọ́nà wúruwùru. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbangba ojúde òfúúrufú George Greenstein ṣàkíyèsí pé “ọ̀nà kan ni a gbà ṣètò awọn ìràwọ̀.” A ṣètò wọn sí ìdìpọ̀ tí a ń pè ní galaxy (ìṣùpọ̀ awọn ìràwọ̀), tí awọn kan sì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún billion ìràwọ̀ ninu. A sì díwọ̀n rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ billion ìṣùpọ̀ awọn ìràwọ̀ ní ń bẹ! A tún ṣètò ìṣùpọ̀ awọn ìràwọ̀ pẹlu, iye kan lára wọn (lati nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún díẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún) ni a kójọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣùjọ ìṣùpọ̀ awọn ìràwọ̀. Ìṣùjọ ìṣùpọ̀ awọn ìràwọ̀ ni a sì tún wòye pé a ṣètò wọn sí awọn ẹ̀ka ìpín tí ó túbọ̀ tóbi tí a ń pè ní ìṣùjọ gbẹ̀ǹgbẹ̀ awọn ìràwọ̀.—Orin Dafidi 19:1; Isaiah 40:25, 26.
4, 5. Fúnni ni awọn àpẹẹrẹ ìṣètò láàárín awọn ẹ̀dá abẹ̀mí lórí ilẹ̀-ayé.
4 Ìṣètò gígalọ́lá ti awọn ìṣẹ̀dá Ọlọrun ni a ń rí níbi gbogbo, kìí ṣe lójú ọ̀run tí a lè fojúrí nìkan ni ṣugbọn lórí ilẹ̀-ayé pẹlu, pẹlu ẹgbàágbèje awọn ẹ̀dá abẹ̀mí inú rẹ́. Paul Davies, ọ̀jọ̀gbọ́n ninu ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ physics, kọ̀wé nipa gbogbo èyí pé “ọláńlá ati ìṣètò dídíjú ti àgbáyé tí ó ṣeé fojúrí” mú kí “ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ mú” awọn tí ń ṣàkíyèsí rẹ̀.—Orin Dafidi 104:24.
5 Gbé awọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò nipa “ìṣètò dídíjú” tí a rí ninu awọn ẹ̀dá abẹ̀mí. Oníṣẹ́-abẹ awọn iṣan ìmọ̀lára Joseph Evans sọ nipa ọpọlọ ènìyàn ati okùn ògóóró ẹ̀yìn pé: “Ìjótìítọ́ ìṣètò ńláǹlà naa fẹ́rẹ̀ẹ́ bonimọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá.” Nipa ti awọn sẹ́ẹ̀lì abẹ̀mí kíkéré bín-tín, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa awọn kòkòrò bacteria, H. J. Shaughnessy wí pé: “Ìdíjú ati ìṣètò rírẹwà ti ètò-ìgbékalẹ̀ awọn ẹ̀dá kòkòrò bacteria ni a ṣe lọ́nà yíyanilẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi farahàn bí ẹni pé ó jẹ́ apákan ètò-ìgbékalẹ̀ kan tí a pinnuyàn látọ̀runwá.” Onímọ̀ ẹ̀kọ́ nipa awọn ẹ̀dá akéréjojú Michael Denton sì sọ nipa àkójọ-òfin apilẹ̀-àbùdá (DNA) tí ń bẹ ninu sẹ́ẹ̀lì kan pé: “Ó gbéṣẹ́ gan-an débi pé gbogbo ìsọfúnni . . . tí ó pọndandan lati fìyàtọ̀ sí ìṣètò gbogbo irú-ọ̀wọ́ ẹ̀dá alààyè tí ó tíì wà rí lórí planẹti . . . ni a lè kó sínú ṣíbí kékeré kan tí àyè yoo sì tún ṣẹ́kù fún gbogbo ìsọfúnni naa ninu olúkúlùkù ìwé tí a tíì kọ rí.”—Wo Orin Dafidi 139:16.
6, 7. Ìṣètò wo ni a fihàn láàárín awọn ẹ̀dá ẹ̀mí, bawo sì ni wọn ṣe fi ìmọrírì hàn fún Olùṣẹ̀dá wọn?
6 Kìí ṣe kìkì awọn ẹ̀dá ti ara tí Jehofa dá nìkan ni ó ṣètò, ó tún ṣètò awọn ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀ tí ń bẹ ní ọ̀run pẹlu. Danieli 7:10 fi tó wa létí pé awọn angẹli tí iye wọn tó ‘ẹgbẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún ń dúró níwájú Jehofa.’ Ọgọ́rùn-ún million awọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tí wọn pésẹ̀ ṣíbáṣíbá, tí a sì yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí àyè iṣẹ́ tirẹ̀ tí ó yẹ kí ó ṣe! Lati ronú nipa òye-iṣẹ́ tí ó ti níláti béèrè fún lati ṣètò irú iye tabua bẹ́ẹ̀ ń múnitagọ̀ọ́gọ̀ọ́. Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, Bibeli sọ pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Oluwa, ẹyin angẹli rẹ̀, tí ó pọ̀ ní ipá tí ń ṣe òfin rẹ̀, tí ń fi etí sí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Oluwa, ẹyin [angẹli] ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.”—Orin Dafidi 103:20, 21; Ìfihàn 5:11.
7 Ẹ wo bí awọn iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ti wà létòlétò lọ́nà pípinmirin ati bí wọn ṣe gbéṣẹ́ tó! Abájọ nígbà naa tí awọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni ilẹ̀-àkóso ti ọ̀rún fi ń polongo lọ́nà tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ati pẹlu ìtẹríba pé: “Oluwa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbára: nitori pé iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ìfẹ́-inú rẹ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”—Ìfihàn 4:11.
8. Awọn àpẹẹrẹ wo ni ó fihàn pé Jehofa ṣètò awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé?
8 Jehofa ṣètò awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé pẹlu. Nígbà tí ó mú Ìkún-Omi wá sórí ayé Noa ní 2370 B.C.E., Noa ati awọn méje mìíràn la Ìkún-Omi naa já gẹ́gẹ́ bí ètò-àjọ ìdílé kan. Nígbà Ìjádelọkúrò ti ọdún 1513 B.C.E., Jehofa mú ọ̀pọ̀ àádọ́ta-ọ̀kẹ́ awọn ènìyàn rẹ̀ jáde kúrò lábẹ́ ìsìnrú ní ilẹ̀ Egipti ó sì fún wọn ni kúlẹ̀kúlẹ̀ àkójọpọ̀ awọn òfin lati fi ṣètò awọn àlámọ̀rí ati ìjọsìn wọn ojoojúmọ́. Láìpẹ́ lẹ́yìn naa, ní Ilẹ̀ Ìlérí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá lára wọn ni a ṣètòjọ fún àkànṣe iṣẹ́-ìsìn ní tẹ́ḿpìlì. (1 Kronika 23:4, 5) Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, awọn ìjọ Kristian ni a ṣètòjọ lábẹ́ ìdarí àtọ̀runwá: “Ó sì fi awọn kan fúnni bí aposteli; ati awọn mìíràn, bíi wòlíì; ati awọn mìíràn bíi ẹfangelisti, ati awọn mìíràn bíi olùṣọ́-àgùtàn ati olùkọ́ni; fún àṣepé awọn ènìyàn mímọ́ fún iṣẹ́-ìránṣẹ́.”—Efesu 4:11, 12.
A Ṣètò Awọn Ìránṣẹ́ ti Òde-Òní Pẹlu
9, 10. Bawo ni Jehofa ṣe ṣètò awọn ènìyàn rẹ̀ ní àkókò tiwa?
9 Bákan naa, Jehofa ti ṣètò awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti òde-òní kí wọn baà lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní ọjọ́ tiwa—wíwàásù ìhìnrere Ìjọba rẹ̀ ṣáájú kí ó tó mú ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan aláìwà-bí-Ọlọ́run ti ìsinsìnyí wá sí òpin. (Matteu 24:14) Ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó wémọ́ iṣẹ́ kárí-ayé yii ati bí ìṣètòjọ rere ti ṣe pàtàkì tó. Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ awọn ọkùnrin, obìnrin, ati awọn ọmọdé ni a ti ń fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ lati fi awọn òtítọ́ Bibeli kọ́ awọn ẹlòmíràn. Lati ṣètìlẹ́yìn fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yii, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ awọn Bibeli ati awọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli ni a ti tẹ̀. Họ́wù, ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà kọ̀ọ̀kan ni a ti ń tẹ̀ jáde nísinsìnyí ní iye tí ó jú million 16 lọ ni awọn èdè 118, ti Jí! sì jẹ́ nǹkan bíi million 13 ní èdè 73. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìtẹ̀jáde naa ni a ń tẹ̀ ní àkókò kan naa kí ó lè jẹ́ pé níti tòótọ́ ni gbogbo awọn ìránṣẹ́ Jehofa ń rí ìsọfúnni kan naa gbà ní àkókò kan naa.
10 Ní àfikún síi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí-ayé tí iye ìjọ wọn jú 73,000 lọ ni a ṣètòjọ lati pàdépọ̀ déédéé fún ìtọ́ni Bibeli. (Heberu 10:24, 25) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún awọn ìpéjọpọ̀ ńláńlá sì tún wà—awọn àpéjọ àyíká ati àpéjọpọ̀ àgbègbè—lọ́dọọdún. Iṣẹ́-ìkọ́lé aládàá-ńlá ti awọn Gbọ̀ngàn Ìjọba titun tàbí èyí tí a ń mú sunwọ̀n síi, awọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, awọn ilé Beteli, ati awọn ilé-lílò fún títẹ awọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kò sì tún gbẹ́yìn. Awọn ilé-ẹ̀kọ́ ń bẹ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gbígbépẹ́ẹ́lí fún awọn ti ń fi Bibeli kọ́ni, irú bíi Watchtower Bible School of Gilead fún awọn míṣọ́nnárì ati Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà, tí a ń ṣe káàkiri awọn ilẹ̀ yíká-ayé.
11. Awọn àǹfààní ọjọ́-ọ̀la wo ni yoo jẹyọ lati inú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìṣètò dáradára nísinsìnyí?
11 Ẹ sì wo bí Jehofa ti ṣètò awọn ènìyàn rẹ̀ dáradára tó lórí ilẹ̀-ayé lati ‘ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn ní kíkún,’ pẹlu ìtìlẹ́yìn awọn angẹli rẹ̀ tí ń ṣèrańṣẹ́! (2 Timoteu 4:5; Heberu 1:13, 14; Ìfihàn 14:6) Nipa fífi ìṣètò lọ́nà dídára kọ́ awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí, Ọlọrun ń ṣe àṣepé ohun mìíràn kan. A ń múra awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ dáradára kí ó baà lè jẹ́ pé nígbà tí wọn bá ré òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii kọjá, wọn yoo ti wà létòlétò lati bẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé ninu ayé titun naa. Nígbà naa, lọ́nà kan tí ó wà létòlétò lábẹ́ ìdarí Jehofa, wọn yoo bẹ̀rẹ̀ síí ṣe ìkọ́gbéró Paradise kárí ayé naa. Wọn yoo tún wà ní ìmúrasílẹ̀ dáradára lati fi kúlẹ̀kúlẹ̀ awọn ohun-àbéèrè-fún Ọlọrun tí ìwàláàyè sinmi lé lórí kọ́ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ awọn ènìyàn tí a óò jí dìde kúrò ninu ikú.—Isaiah 11:9; 54:13; Iṣe 24:15; Ìfihàn 20:12, 13.
Wọn Wà Létòlétò Síbẹ̀ Wọn Láyọ̀
12, 13. Èéṣe tí a fi lè sọ pé Jehofa fẹ́ kí awọn ènìyàn oun jẹ́ aláyọ̀?
12 Nígbà tí ó jẹ́ pé àgbàyanu òṣìṣẹ́ ati olùṣètò gígalọ́lá ni Jehofa, oun kìí ṣe adájúgbáú, tí kìí yípadà, tabi aláfaraṣe máfọkànṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, oun jẹ́ ọlọ́yàyà gan-an, ati aláyọ̀ Ẹni-Sàràkí tí ayọ̀ wa jẹlógún. Peteru kìn-ín-ní 5:7 (NW) polongo pé, “Ó ń bìkítà fún yin.” A lè rí ìbìkítà ati ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ pé kí awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyọ̀ ninu ohun tí ó ti ṣe fún awọn ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọrun dá ọkùnrin ati obìnrin pípé naa, ó fi wọn sínú paradise ìgbádùn. (Genesisi 1:26-31; 2:8, 9) Ó fún wọn ní ohun gbogbo tí wọn nílò lati mú kí wọn láyọ̀ lọ́nà gígalọ́lá. Ṣugbọn wọn tipasẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ pàdánù gbogbo rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a jogún àìpé ati ikú.—Romu 3:23; 5:12.
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá nísinsìnyí, awa ènìyàn ṣì lè rí ayọ̀ ninu ohun tí Ọlọrun ti ṣe. Awọn nǹkan pupọ ń bẹ tí ń mú ìgbádùn wá fún wá—awọn òkè-ńlá títóbilọ́lá, awọn adágún, odò, agbami-òkun ati awọn etíkun rírẹwà; awọn òdòdó olóòórùn dídùn, aláwọ̀ mèremère ati awọn ewéko-ìgbẹ́ mìíràn tí kò lóǹkà lónírúurú; ọ̀pọ̀ yanturu awọn oúnjẹ àjẹpọ́nnulá; wíwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ àrímálèlọ tí kìí sú wa bọ̀rọ̀; ojú ọ̀run tí ó kún fún ìràwọ̀ tí ó máa ń dùn mọ́ wa lati wò lọ́wọ́ alẹ́; ẹ̀dá awọn ẹranko tí wọn pọ̀ lọ jàra lónírúurú ati awọn ọmọ wọn fífanimọ́ra tí ń dábírà bí wọn bá ń ṣeré; ohun orin tí ń runisókè; iṣẹ́ gbígbádùnmọ́ni tí ó sì wúlò; awọn ọ̀rẹ́ rere. Ó ṣe kedere pé Ẹni naa tí ó ṣètò irúfẹ́ awọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláyọ̀ tí ó fẹ́ràn lati máa mú kí awọn ẹlòmíràn láyọ̀.
14. Ìwàdéédéé wo ni Jehofa béèrè lọ́wọ́ wa ní ṣíṣàfarawé oun?
14 Nipa bayii, kìkì ìjáfáfá tí a mú wà létòlétò lásán kọ́ ni Jehofa ń fẹ́. Ó tún ń fẹ́ kí awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláyọ̀, bí oun gan-an ti jẹ́ aláyọ̀. Kò fẹ́ kí wọn máa fi ìgbónára ẹhànnà ṣètò awọn nǹkan débi tí wọn yoo fi pa ayọ̀ wọn lára. Awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ mú kí òye-iṣẹ́ ìṣètòjọ wọn ati ayọ̀ wàdéédéé, bí oun ti ń ṣe, nitori níbi tí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lílágbára bá wà, níbẹ̀ ni ayọ̀ wà pẹlu. Ní tòótọ́, Galatia 5:22 fihàn pé èkejì ninu èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun tí ń ṣiṣẹ́ lórí awọn ènìyàn rẹ̀ ni “ayọ̀.”
Ìfẹ́ Ń Mú Ayọ̀ Wá
15. Èéṣe tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì gan-an fún ayọ̀ wa?
15 Yoo dùn mọ́ wa gidigidi lati ṣàkíyèsí pé Bibeli sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.” (1 Johannu 4:8, 16, NW) Kò sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ ètò.” Ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ Ọlọrun, awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ ṣàfarawé rẹ̀. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí àkọ́kọ́ lára èso ẹ̀mí Ọlọrun tí a tòlẹ́sẹẹsẹ ní Galatia 5:22 fi jẹ́ “ìfẹ́,” tí “ayọ̀” sì tẹ̀lé e. Ìfẹ́ ń mú ayọ̀ wá. Nígbà tí a bá ṣàfarawé ìfẹ́ Jehofa ninu awọn ìbálò wa pẹlu awọn ẹlòmíràn, ayọ̀ máa ń tibẹ̀ wá, nitori pé awọn ènìyàn onífẹ̀ẹ́ jẹ́ ènìyàn aláyọ̀.
16. Bawo ni Jesu ṣe fi ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́ hàn?
16 Ìjẹ́pàtàkì ṣíṣàfarawé ìfẹ́ Ọlọrun ni a mú ṣe kedere ninu awọn ẹ̀kọ́ Jesu. Ó wí pé: “Bí Baba ti kọ́ mi, emi ń sọ nǹkan wọnyi.” (Johannu 8:28) Kí ni ohun naa gan-an ti a fi kọ́ Jesu, tí oun wá padà fi kọ́ awọn ẹlòmíràn? Ohun naa ni pé awọn àṣẹ títóbi jùlọ méjì naa jẹ́ lati nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun kí a sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. (Matteu 22:36-39) Jesu fi àpẹẹrẹ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Ó wí pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba,” ó sì fẹ̀rí rẹ̀ hàn nipa ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun títí dé ojú ikú. Ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún awọn ènìyàn nipa kíkú fún wọn. Aposteli Paulu sọ fún awọn Kristian ní Efesu pé: ‘Kristi nífẹ̀ẹ́ yín ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín.’ (Johannu 14:31, NW; Efesu 5:2, NW) Nipa bayii, Jesu sọ fún awọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.”—Johannu 15:12, 13, NW.
17. Bawo ni Paulu ṣe fihàn pé fífi ìfẹ́ hàn sí awọn ẹlòmíràn ṣekókó?
17 Paulu sọ nipa bí ìfẹ́ Ọlọrun yii ti ṣekókó tó nipa sísọ pé: “Bí mo tilẹ̀ ń fọ onírúurú èdè ati ti angẹli, tí emi kò sì ní ìfẹ́, emi dàbí idẹ tí ń dún, tabi bíi kíḿbáálì olóhùn gooro. Bí mo sì ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, ati gbogbo ìmọ̀; bí mo sì ní gbogbo ìgbàgbọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí awọn òkè ńlá nípò, tí emi kò sì ní ìfẹ́, emi kò jẹ́ nǹkan. Bí mo sì ń fi gbogbo ohun-ìní mi bọ́ awọn tálákà, bí mo sì fi ara mi fúnni lati sùn, tí emi kò sì ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi. . . . Ìgbàgbọ́, ìrètí, ati ìfẹ́ ń bẹ, awọn mẹ́ta yii: ṣugbọn èyí tí ó tóbi jù ninu wọn ni ìfẹ́.”—1 Korinti 13:1-3, 13.
18. Ohun wo tí a lè retí lati ọ̀dọ̀ Jehofa ni ó ń fikún ayọ̀ wa?
18 Nígbà tí a bá ṣàfarawé ìfẹ́ Jehofa, a lè ní ìdánilójú ìfẹ́ rẹ̀ fún wa, kódà nígbà tí a bá ṣe awọn àṣìṣe, nitori tí oun jẹ́ “Ọlọrun aláàánú ati olóore-ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, ati ẹni tí ó pọ̀ ní oore ati òtítọ́.” (Eksodu 34:6) Bí a bá fi òtítọ́-inú ronúpìwàdà nígbà tí a bá ṣe awọn àṣìṣe, Ọlọrun kìí pa àkọsílẹ̀ ìwọ̀nyí mọ́ ṣugbọn ó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ dáríjì wá. (Orin Dafidi 103:1-3) Bẹ́ẹ̀ni, “Oluwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.” (Jakọbu 5:11) Mímọ èyí ń fikún ayọ̀ wa.
Ayọ̀ tí Ó Ní Ààlà Nísinsìnyí
19, 20. (a) Èéṣe tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ kò fi ṣeéṣe nísinsìnyí? (b) Bawo ni Bibeli ṣe fihàn pé a lè ní ayọ̀ tí ó ní ààlà ní àkókò yii?
19 Bí ó ti wù kí ó rí, ó ha ṣeéṣe lati láyọ̀ lónìí, níwọ̀n bí a ti ń gbé ninu awọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé tí ó kún fún ìwà-ọ̀daràn, oníwà-ipá, ati oníwà pálapàla tí ó wà lábẹ́ Satani yii, níbi tí àìsàn ati ikú ti ń dojúkọ wá? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè retí, a kò lè retí ìwọ̀n ayọ̀ tí yoo wà ninu ayé titun Ọlọrun nísinsìnyí, irú èyí tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọtẹ́lẹ̀ pé: “Sá wò ó, emi ó dá ọ̀run titun ati ayé titun: a kì yoo sì rántí awọn ti ìṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yoo wá sí àyà. Ṣugbọn kí ẹyin kí ó yọ̀, kí inú yin kí ó sì dùn títíláé ninu èyí tí emi ó dá.”—Isaiah 65:17, 18.
20 Ayọ̀ tí ó ní ààlà ni awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lè ní nísinsìnyí nitori pé wọn mọ ìfẹ́-inú rẹ̀ wọn sì ní ìmọ̀ pípéye nipa awọn ìbùkún àgbàyanu tí yoo wá láìpẹ́ ninu paradise ayé titun rẹ̀. (Johannu 17:3; Ìfihàn 21:4) Ìdí rẹ̀ niyẹn tí Bibeli fi lè sọ pé: “Oluwa awọn ọmọ-ogun, [ayọ̀, NW] ni fún olúwarẹ̀ naa tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,” “[ayọ̀, NW] ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Oluwa; tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀,” “aláyọ̀ ni awọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yoo ti jogún ilẹ̀-ayé.” (Orin Dafidi 84:12; 128:1; Matteu 5:5, NW) Nipa bayii, láìka awọn àyíká-ipò lílekoko tí a níláti bá wọ̀jà sí, a lè ní ayọ̀ tí ó pọ̀ tó. Àní nígbà tí awọn nǹkan búburú bá ṣẹlẹ̀ sí wa pàápàá, a kò ní banújẹ́ bí awọn wọnnì tí wọn kò mọ Jehofa tí wọn kò sì ní ìrètí ìye ayérayé ti ń ṣe.—1 Tessalonika 4:13.
21. Bawo ni yíyọ̀ǹda awọn ohun tí wọn ní ṣe ń fikún ayọ̀ awọn ìránṣẹ́ Jehofa?
21 Awọn ìránṣẹ́ Jehofa tún ń láyọ̀ nitori pé wọn ń lo àkókò, okun, ati awọn ohun àmúṣọrọ̀ ní fífi awọn òtítọ́ Bibeli kọ́ awọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì awọn ènìyàn tí wọn “ń kẹ́dùn, tí wọn sì ń kígbe nitori ohun ìríra” tí a ń ṣe ninu ayé Satani. (Esekieli 9:4) Bibeli sọ pé: “[Ayọ̀, NW] ni fún ẹni tí ń ro ti awọn aláìní, Oluwa yoo gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. Oluwa yoo pa á mọ́, yoo sì mú un wà láàyè; a ó sì bùkún fún un lórí ilẹ̀.” (Orin Dafidi 41:1, 2) Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ, “ati fúnni ó ní ìbùkún ju ati gbà lọ.”—Iṣe 20:35.
22. (a) Níti ayọ̀, fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ati awọn wọnnì tí wọn kò ṣiṣẹ́sìn ín hàn. (b) Fún àkànṣe ìdí wo ni a fi níláti retí lati láyọ̀?
22 Nitori naa nígbà tí ó jẹ́ pé awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun kò lè retí ayọ̀ gíga jùlọ ní àkókò tí a wà yí, wọn lè rí ayọ̀ tí awọn wọnnì tí wọn kò ṣiṣẹ́sin Ọlọrun kò ní. Jehofa polongo pé: “Kíyèsí i, awọn ìránṣẹ́ mi yoo kọrin fún inúdídùn, ṣugbọn ẹyin óò ké fún ìbànújẹ́ ọkàn, ẹyin ó sì hu fún ìròbìnújẹ́ ọkàn.” (Isaiah 65:14) Pẹ̀lúpẹ̀lù, awọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní àkànṣe ìdí fún ayọ̀ nísinsìnyí —wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tí “Ọlọrun fifún awọn tí ó gbọ́ tirẹ̀.” (Iṣe 5:32) Sì rántí pé, níbi tí ẹ̀mí Ọlọrun bá wà, ayọ̀ wà níbẹ̀.—Galatia 5:22.
23. Kí ni awa yoo gbéyẹ̀wò ninu ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tí yoo tẹ̀lé e?
23 Ninu ètò-àjọ awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lónìí, ipa pàtàkì kan ni “awọn àgbà ọkùnrin,” awọn alàgbà tí wọn ń mú ipò iwájú ninu awọn ìjọ ń kó, ní fífikún ayọ̀ awọn ènìyàn Jehofa. (Titu 1:5, NW) Ojú wo ni ó yẹ kí awọn wọnyi fi wo ẹrù-iṣẹ́ wọn ati ipò-ìbátan wọn pẹlu awọn arákùnrin ati arábìnrin wọn tẹ̀mí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa tí ó tẹ̀lé e yoo jíròrò èyí.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dáhùn?
◻ Bawo ni ìṣẹ̀dá ṣe jẹ́rìí sí ìwàlétòlétò Jehofa?
◻ Ní ọ̀nà wo ni Jehofa ti gbà ṣètò awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àtijọ́ ati nísinsìnyí?
◻ Ìwàdéédéé wo ni Jehofa ń fẹ́ kí a fihàn?
◻ Bawo ni ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó sí ayọ̀ wa?
◻ Irú ayọ̀ wo ni a lè retí ní àkókò wa?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Òkè: Ìyọ̀ọ̀da onínúure ti ROE/Anglo-Australian Observatory, a ya fọ́tò rẹ̀ lati ọwọ́ David Malin