Ṣé Èmi Ni Jésù Kú fún Lóòótọ́?
ÀWỌN ọ̀rọ̀ àtọkànwá táwọn èèyàn tó nímọ̀lára “bíi tiwa” sọ ló kúnnú Bíbélì. (Jém. 5:17) Bí àpẹẹrẹ, kò ṣòro fún wa láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó sọ ohun tó wà nínú Róòmù 7:21-24, pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi. . . . Èmi abòṣì èèyàn!” Táwa náà bá ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá jà, ọkàn wa balẹ̀ pé a rẹ́ni fi jọ.
Pọ́ọ̀lù tún sọ ọ̀rọ̀ míì tó tọkàn ẹ̀ wá. Nínú Gálátíà 2:20, ó fi ìdánilójú sọ pé Jésù ‘nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún òun.’ Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀.
Tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan torí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn, ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó ti dárí jì wá. Yàtọ̀ síyẹn, a lè máa wò ó pé kì í ṣe irú àwa ni ẹ̀bùn ìràpadà wà fún. Ṣé Jésù fẹ́ ká ka ìràpadà tó san sí ẹ̀bùn pàtàkì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lá jẹ́ ká lè máa fojú tó tọ́ wo ìràpadà náà? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìbéèrè méjì yìí.
OJÚ TÍ JÉSÙ FI WO ÌRÀPADÀ TÓ SAN
Kò sí àní-àní pé Jésù fẹ́ ká ka ìràpadà náà sí ẹ̀bùn tó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí ló máa jẹ́ ká gbà bẹ́ẹ̀? Fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Lúùkù 23:39-43. Ọkùnrin kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù tí wọ́n kàn mọ́ igi, ó sì gbà pé ìyà tó tọ́ sí òun lòun ń jẹ. Ó ní láti jẹ́ pé ìwà ọ̀daràn tó hù burú gan-an torí pé àwọn ọ̀daràn paraku ni wọ́n máa ń firú ìyà yìí jẹ. Nǹkan tojú sú ọkùnrin yẹn, ló bá bẹ Jésù pé: “Rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.”
Báwo ni Jésù ṣe dá ọkùnrin náà lóhùn? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń jẹ̀rora, ó tiraka láti wojú ọkùnrin náà. Ó mirí, ó sì sọ fún ọkùnrin náà pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Tí Jésù bá fẹ́, ó kàn lè sọ fún un pé ‘Ọmọ èèyàn wá kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.’ (Mát. 20:28) Àmọ́, ńṣe ni Jésù mú kí ọkùnrin náà rí i pé ikú òun máa ṣe é láǹfààní. Bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “mo” àti “ọ” dà bí ìgbà téèyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bákan náà ló sì rí nígbà tó ṣèlérí fún ọkùnrin náà pé ó máa wà pẹ̀lú òun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
Ó ṣe kedere pé Jésù fẹ́ kí ọkùnrin yẹn mọ̀ pé ẹ̀bùn pàtàkì ni ikú ìrúbọ òun jẹ́ fún un. Bí Jésù bá lè fi ọ̀daràn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn balẹ̀, mélòómélòó Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run? Torí náà, kí lá jẹ́ ká lè máa fojú tó tọ́ wo ara wa bí Jésù ṣe fẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dẹ́ṣẹ̀ sẹ́yìn?
KÍ LÓ RAN PỌ́Ọ̀LÙ LỌ́WỌ́?
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù gbé fún Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó dá a lójú pé òun gan-an ni Jésù kú fún. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jésù Olúwa wa, tó fún mi lágbára, torí ó kà mí sí olóòótọ́ ní ti pé ó fún mi ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.” (1 Tím. 1:12-14) Jésù gbé iṣẹ́ fún Pọ́ọ̀lù láìka gbogbo ohun tí Pọ́ọ̀lù ti ṣe tẹ́lẹ̀ sí, èyí sì jẹ́ kó mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jésù nífẹ̀ẹ́ òun, ó fọkàn tán òun, ó sì ń fàánú hàn sóun. Lọ́nà kan náà, Jésù ti gbé iṣẹ́ ìwàásù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Mát. 28:19, 20) Ǹjẹ́ iṣẹ́ yìí lè mú ká gbà bíi ti Pọ́ọ̀lù pé àwa gan-an ni Jésù kú fún?
Arákùnrin Albert tó ṣẹ̀ṣẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) tí wọ́n ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Mi ò lè gbàgbé àwọn nǹkan burúkú tí mo ti ṣe sẹ́yìn. Àmọ́, tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, mo gbà pé Jésù gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan fún mi bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ohun tó ń fún mi láyọ̀ nìyẹn, kì í jẹ́ kí n ro ara mi pin. Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, pé mo ṣì wúlò fún Jèhófà, ìgbésí ayé mi sì nítumọ̀.”—Sm. 51:3.
Arákùnrin Allan tó jẹ́ ọ̀daràn àti oníjàgídíjàgan kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sọ pé: “Tí mo bá ń rántí gbogbo aburú tí mo ti ṣe fáwọn èèyàn, inú mi máa ń bà jẹ́. Ṣùgbọ́n, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ bíi tèmi máa wàásù ìhìn rere fáwọn míì. Tí mo bá ń rí bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe, ó máa ń jẹ́ kí n rí i pé ẹni rere ni Jèhófà, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Mo mọ̀ pé ó ń lò mí láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń gbé irú ìgbésí ayé témi náà ti gbé rí.”
Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ rere là ń ṣe, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká ní èrò tó tọ́. Ó máa ń jẹ́ ká rí bí Jésù ṣe ń fàánú hàn sí wa, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì fọkàn tán wa.
JÈHÓFÀ JU ỌKÀN WA LỌ
Títí dìgbà tí Jèhófà máa pa ayé Sátánì yìí run, ọkàn wa ṣì lè máa dá wa lẹ́bi torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn. Kí ló máa jẹ́ ká borí irú èrò bẹ́ẹ̀?
Arábìnrin Jean máa ń dá ara ẹ̀ lẹ́bi torí irú ìgbésí ayé burúkú tó gbé nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó wá sọ pé: “Inú mi dùn pé ‘Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ.’ ” (1 Jòh. 3:19, 20) Táwa náà bá ń fi sọ́kàn pé Jèhófà àti Jésù lóye wa, wọ́n sì mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ọkàn wa máa balẹ̀. Rántí pé kì í ṣe àwọn èèyàn pípé ni Jèhófà àti Jésù pèsè ìràpadà náà fún, bí kò ṣe àwa ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a ti ronú pìwà dà.—1 Tím. 1:15.
Tó o bá ń fara balẹ̀ ronú nípa bí Jésù ṣe hùwà sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó gbé fún wa, ó máa dá ẹ lójú pé ìwọ gan-an ni Jésù kú fún. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: ‘Jésù nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’