Ẹ Duro Ṣinṣin Fun Ominira Ti Ọlọrun Fi Funni!
“Fun irú ominira bẹẹ ni Kristi dá wa silẹ lominira. Nitori naa, ẹ duro ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ kí a tún sé yin mọ́ inú àjàgà oko ẹrú mọ́.”—GALATIA 5:1, NW.
1, 2. Bawo ni a ṣe padanu ominira ti Ọlọrun fi funni?
AWỌN eniyan Jehofa wà lominira. Ṣu gbọn wọn kò wá ominira kuro lọdọ Ọlọrun, nitori pe iyẹn yoo tumọsi ìsìnrú fun Satani. Wọn ṣikẹ ipo ibatan timọtimọ wọn pẹlu Jehofa wọn sì yọ̀ ninu ominira ti o fifun wọn.
2 Awọn obi wa akọkọ, Adamu ati Efa, padanu ominira ti Ọlọrun fifun wọn nipasẹ dídẹ́ṣẹ̀ ati didi ẹrú ẹṣẹ, iku, ati Eṣu. (Jẹnẹsisi 3:1-19; Roomu 5:12) Họwu, Satani fi gbogbo ayé soju ọna ẹ̀ṣẹ̀ si iparun! Ṣugbọn awọn wọnni ti ń duro ṣinṣin fun ominira ti Ọlọrun fi funni ń rìn loju ọna ìyè ayeraye.—Matiu 7:13, 14; 1 Johanu 5:19.
Ominira Kuro Ninu Ìdè Ìsìnrú
3. Ireti wo ni Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ jade ni Edẹni?
3 Ète Jehofa ni pe awọn eniyan ti ń bọla fun orukọ rẹ̀ yoo wà lominira kuro ninu ìdè ìsìnrú Satani, ẹṣẹ, ati iku. Ireti yẹn ni a nawọ́ rẹ̀ jade nigba ti Ọlọrun sọ fun ejo ti Satani lò ni Edẹni pe: “Emi yoo sì fi ọ̀tá saaarin iwọ ati obinrin naa, ati saaarin iru-ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: oun yoo fọ́ ọ ni ori, iwọ yoo sì pa á ni gìgìísẹ̀.” (Jẹnẹsisi 3:14, 15) Jesu Kristi, Iru-Ọmọ naa lati inu eto-ajọ Jehofa ti ọrun, niriiri pípa ni gìgìísẹ̀ nigba ti ó kú lori opo igi, ṣugbọn Ọlọrun tipa bayii pese ẹbọ irapada kan lati dá araye onigbagbọ silẹ lominira kuro lọwọ ẹṣẹ ati iku. (Matiu 20:28; Johanu 3:16) Bi akoko ti ń lọ, Jesu yoo fọ́ ori Satani, Ejo ipilẹṣẹ naa.—Iṣipaya 12:9.
4. Ominira wo ni Aburahamu gbadun, kí sì ni Jehofa ṣeleri fun un?
4 Ni nǹkan bii 2,000 ọdun lẹhin ti a ti funni ni ileri naa ni Edẹni, “ọ̀rẹ́ Jehofa” Aburahamu ṣegbọran si Ọlọrun ó sì fi ilu Uri silẹ lọ si ibomiran. (Jakobu 2:23, NW; Heberu 11:8) Ó tipa bayii gba ominira ti Ọlọrun fi funni kò sì gbé gẹgẹ bi ẹrú ayé Satani ti isin èké, oṣelu oniwa ibajẹ, ati iṣowo oniwọra mọ́. Ni isopọ pẹlu asọtẹlẹ ti Edẹni, Ọlọrun ṣe afikun awọn ileri pe gbogbo awọn idile ati orilẹ-ede yoo bukun araawọn nipasẹ Aburahamu ati Iru-Ọmọ rẹ̀. (Jẹnẹsisi 12:3; 22:17, 18) Aburahamu wà lominira kuro ninu idalẹbi nitori pe ‘o ni igbagbọ ninu Oluwa [“Jehofa,” NW], ẹni ti o kà á si ododo fun un.’ (Jẹnẹsisi 15:6) Lonii, ipo ibatan timọtimọ kan pẹlu Jehofa bakan naa mú ominira ti Ọlọrun fi funni wá kuro ninu idalẹbi ati kuro ni oko ẹrú si ayé ti o wà labẹ agbara Satani.
Awokẹkọọ Iṣapẹẹrẹ Kan Ti Ó Gbàfiyèsí
5. Ìbí Isaaki ni a sopọ mọ́ awọn ipo wo?
5 Ki Aburahamu baà lè ni iru-ọmọ kan, Sera, aya rẹ̀ ti ó yàgàn, fi Hagari, ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin fun un, gẹgẹ bi ẹni ti yoo bí ọmọ kan. Nipasẹ rẹ̀, Aburahamu bí Iṣimaẹli, ṣugbọn Ọlọrun kò yàn án gẹgẹ bi Iru-Ọmọ ti a ṣeleri naa. Kaka bẹẹ, nigba ti Aburahamu jẹ́ ẹni 100 ọdun tí Sera sì jẹ́ 90, Jehofa mú ki ó ṣeeṣe fun wọn lati ní ọmọkunrin kan ti a pe ni Isaaki. Nigba ti Iṣimaẹli fi Isaaki ṣẹlẹ́yà, Hagari ati ọmọkunrin rẹ̀ ni a lé lọ, ni fifi ọmọkunrin Aburahamu nipasẹ obinrin ominira naa Sera silẹ gẹgẹ bi iru-ọmọ Aburahamu ti kò ṣee jáníkoro. Bii Aburahamu, Isaaki tún mú igbagbọ lò ó sì gbadun ominira ti Ọlọrun fi funni.—Jẹnẹsisi 16:1-16; 21:1-21; 25:5-11.
6, 7. Ki ni awọn olukọ èké ti mú dá awọn Kristẹni diẹ loju ni Galatia, ki sì ni Pọọlu ṣalaye?
6 Awọn iṣẹlẹ wọnyi jẹ́ ojiji iṣaaju fun awọn ohun ti o ṣe pataki fun awọn olùfẹ́ ominira ti Ọlọrun fi funni. Eyi ni a ṣakiyesi ninu lẹta ti apọsiteli Pọọlu kọ si awọn ijọ Galatia ni nǹkan bii 50 si 52 C.E. Nigba yẹn ẹgbẹ́ oluṣakoso ti pinnu pe ìkọlà ni a kò beere lọwọ awọn Kristẹni. Ṣugbọn awọn olukọ èké ti yí diẹ lara awọn ará Galatia lero pada pe ó jẹ ìhà ṣiṣekoko kan ninu isin Kristẹni.
7 Pọọlu sọ fun awọn ara Galatia pe: Ẹnikan ni a polongo ni olododo nipasẹ igbagbọ ninu Kristi, kii ṣe nipasẹ awọn iṣẹ Ofin Mose. (1:1–3:14) Ofin naa kò fi ẹsẹ ileri ominira ti a sopọ mọ majẹmu ti Aburahamu mulẹ ṣugbọn ó fi awọn ìrékọjá han ó sì ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọni ti ń ṣamọna sí Kristi. (3:15-25) Nipa iku rẹ̀, Jesu dá awọn wọnni ti wọn wà labẹ Ofin silẹ, ni mímú ki o ṣeeṣe fun wọn lati di ọmọkunrin Ọlọrun. Fun idi yii, pipada sí iṣeto kan ti kikiyesi awọn ọjọ, oṣu, ìgbà, ati ọdun yoo tumọsi pipada lọ si oko ẹrú. (4:1-20) Pọọlu kọwe lẹhin naa pe:
8, 9. (a) Ni ọrọ tirẹ funraarẹ, ṣalaye ohun ti Pọọlu sọ ni Galatia 4:21-26 ni ṣoki. (b) Ninu awokẹkọọ iṣapẹẹrẹ yii, ta ni tabi ki ni Aburahamu ati Sera ṣapẹẹrẹ, ta sì ni Iru-Ọmọ ti a ṣeleri naa?
8 “Ẹ wí fun mi, ẹyin ti ń fẹ́ wà labẹ ofin, ẹ kò ha gbọ́ ofin? Nitori a ti kọ ọ́ pe, Aburahamu ní ọmọ ọkunrin meji, ọ̀kan [Iṣimaẹli] lati ọdọ ẹrúbìnrin [Hagari], ati ọ̀kan [Isaaki] lati ọdọ ominira obinrin [Sera]. Ṣugbọn a bi eyi tii ṣe ti ẹrúbìnrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti ominira obinrin ni a bí nipa ileri. Nǹkan wọnyi jẹ́ apẹẹrẹ: nitori pe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeeji; ọ̀kan [majẹmu Ofin] lati ori Oke Sinai [nibi ti Ọlọrun ti dá majẹmu yẹn silẹ pẹlu awọn ọmọ Isirẹli] wá, ti o bimọ ni oko ẹrú, ti i ṣe Hagari. [Majẹmu keji ni eyi ti a ṣe pẹlu Aburahamu nipa Iru-Ọmọ rẹ̀.] Nitori Hagari yii ni oke Sinai Arabia, ti o si duro bii Jerusalẹmu ti ó wà nisinsinyi, ti o sì wà ni oko ẹrú pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ [awọn iran atẹle Aburahamu, Isaaki, ati Jakọbu]. Ṣugbọn Jerusalẹmu ti oke jẹ́ ominira, eyi ti i ṣe ìyá wa.”—Galatia 4:21-26.
9 Ninu awokẹkọọ iṣapẹẹrẹ yii, Aburahamu duro fun Jehofa. “Ominira obinrin,” Sera, ṣapẹẹrẹ “obinrin” Ọlọrun, tabi eto-ajọ mímọ́ agbaye. Ó mú Kristi jade, Iru-Ọmọ obinrin iṣapẹẹrẹ yẹn ati ti Aburahamu Gigaju. (Galatia 3:16) Lati fi ọna idasilẹ kuro ninu ijọsin àìmọ́, ẹṣẹ, ati Satani han awọn eniyan, Jesu kọni ni otitọ ó sì tudii aṣiiri isin èké, ṣugbọn Jerusalẹmu ati awọn ọmọ rẹ̀ ń baa lọ ninu ìdè ìsìnrú isin nitori pe wọn kọ̀ ọ́. (Matiu 23:37, 38) Awọn Juu ọmọlẹhin Jesu di ominira kuro ninu Ofin, eyi ti o fi ìsìnrú wọn fun aipe, ẹṣẹ, ati iku han. Nitootọ ni gbogbo awọn eniyan tí wọn gba Jesu gẹgẹ bi Ẹni naa ti a mú jade nipasẹ “obinrin” Ọlọrun lati jẹ́ Mesaya Ọba naa ati Oludasilẹ tí ń ‘polongo idasilẹ fun awọn òǹdè,’ ti di ominira!—Aisaya 61:1, 2; Luuku 4:18, 19.
Yẹra fun Àjàgà Ẹrú
10, 11. Kuro ninu àjàgà ẹrú wo ni Kristi dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ silẹ lominira, ìbádọ́gba wo ni a sì lè ri lonii?
10 Si awọn wọnni ti wọn parapọ di iru-ọmọ Aburahamu pẹlu Kristi, Isaaki Gigaju naa, Pọọlu sọ pe: “Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ ominira, oun sì ni ìyá wa. . . . Ẹyin, ará, awa jẹ́ ọmọ ileri gẹgẹ bi Isaaki ti jẹ́. Ṣugbọn gan-an gẹgẹ bí eyi ti a bí nigba naa ní iru ọ̀nà ti ẹran-ara [Iṣimaẹli] ti bẹrẹ sii ṣe inunibini si eyi ti a bí ní iru ọna ti ẹmi [Isaaki], bẹẹ naa tun ni nisinsinyi. . . . Awa jẹ́ ọmọ, ki i ṣe ti iranṣẹbinrin, bikoṣe ti ominira obinrin. Fun irú ominira bẹẹ [kuro ninu Ofin] ni Kristi dá wa silẹ lominira. Nitori naa ẹ duro ṣinṣin, ẹ má sì jẹ́ ki á tun se yin mọ́ inú àjàgà oko-ẹrú mọ́.”—Galatia 4:26–5:1, NW.
11 Eyikeyii ninu awọn ọmọlẹhin Jesu ni à bá ti há mọ́ inu àjàgà ẹrú bi wọn bá ti juwọsilẹ fun Ofin. Isin èké ni àjàgà ẹrú isinsinyi, Kristẹndọmu sì baradọgba pẹlu Jerusalẹmu igbaani ati awọn ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn awọn ẹni ami ororo ni ọmọ Jerusalẹmu ti òkè, eto-ajọ ọrun olominira ti Ọlọrun. Awọn ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ni ireti ti ilẹ̀-ayé kii ṣe apakan ayé yii wọn kò sì sí ninu ìsìnrú fun Satani. (Johanu 14:30; 15:19; 17:14, 16) Bi a ti jẹ ẹni ti a ti dasilẹ lominira nipasẹ otitọ ati nipasẹ ẹbọ Jesu, ẹ jẹ ki a duro ṣinṣin fun ominira ti Ọlọrun fifun wa.
Mímú Iduro fun Ominira ti Ọlọrun Fi Funni
12. Ipa-ọna wo ni awọn onigbagbọ tọ̀, kí sì ni a o jiroro nisinsinyi?
12 Araadọta-ọkẹ ń gbadun ominira tootọ nisinsinyi gẹgẹ bi Awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa. Ikẹkọọ Bibeli ni a ń ṣe pẹlu araadọta-ọkẹ miiran, tí ọpọlọpọ ninu wọn “ní itẹsi ọkàn titọ fun ìyè ainipẹkun.” Nigba ti wọn bá di onigbagbọ, wọn yoo mú iduro fun ominira ti Ọlọrun fi funni nipa gbigba iribọmi. (Iṣe 13:48, NW; 18:8) Ṣugbọn awọn igbesẹ wo ni ó ṣaaju bamtisimu Kristẹni?
13. Ibatan wo ni ó wà laaarin ìmọ̀ ati bamtisimu?
13 Ṣaaju gbigba iribọmi, ẹnikan gbọdọ gbà ki ó sì gbegbeesẹ lori ìmọ̀ pipeye ti Iwe Mímọ́. (Efesu 4:13) Nipa bayii, Jesu sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ lọ ki ẹ si sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa bamtisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mímọ́, ki ẹ maa kọ́ wọn lẹkọọ lati fiṣọra kiyesi ohun gbogbo ti mo ti paṣẹ fun yin.”—Matiu 28:19, 20, NW.
14. Didi ẹni ti a bamtisi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ beere fun ìmọ̀ wo?
14 Jíjẹ́ ẹni ti a bamtisi ni orukọ Baba tumọsi lati mọ ipo ati aṣẹ Jehofa daju gẹgẹ bi Ọlọrun, Ẹlẹdaa, ati Ọba-Alaṣẹ Agbaye. (Jẹnẹsisi 17:1; 2 Ọba 19:15; Iṣipaya 4:11) Bamtisimu ni orukọ Ọmọkunrin, beere fun dídá ipo ati aṣẹ Kristi mọ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi ti a gbé ga, Ọba Mesaya naa, ati ẹni naa nipasẹ ẹni ti Ọlọrun ti pese “irapada ti o ṣe deedee kan.” (1 Timoti 2:5, 6, NW; Daniẹli 7:13, 14; Filipi 2:9-11) Ẹnikan ti a bamtisi ní orukọ ẹmi mímọ́ mọ̀ pe ó jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ tí Ọlọrun lò ninu iṣẹda ati ninu mímí sí awọn onkọwe Bibeli, ati ni awọn ọna miiran bakan naa. (Jẹnẹsisi 1:2; 2 Peteru 1:21) Nitootọ, pupọpupọ sii ni o ṣì wà lati mọ̀ nipa Ọlọrun, Kristi, ati ẹmi mímọ́.
15. Eeṣe ti ẹnikan fi nilati lo igbagbọ ṣaaju ki o to di ẹni ti a bamtisi?
15 Ṣaaju bamtisimu, ẹnikan gbọdọ lo igbagbọ ti a gbekari ìmọ̀ pipeye. “Laisi igbagbọ kò ṣeeṣe lati wu [Jehofa] daradara.” (Heberu 11:6, NW) Ẹni kan ti ń lo igbagbọ ninu Ọlọrun, Kristi, ati ète atọrunwa yoo fẹ́ lati jẹ́ ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ní gbigbe ni ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun ati nini ajọpin ti o nitumọ ninu wiwaasu ihinrere. Oun yoo sọrọ nipa ogo ipo-ọba Jehofa.—Saamu 145:10-13; Matiu 24:14.
16. Ki ni ironupiwada, bawo ni o sì ṣe tan mọ bamtisimu Kristẹni?
16 Ironupiwada jẹ́ ohun abeerefun miiran fun bamtisimu. Lati ronupiwada tumọsi lati “yí ọkàn ara-ẹni pada nipa iṣesi atijọ (tabi ti a ní lọkan), tabi ìwà, nitori ìkábàámọ̀ tabi ainitẹẹlọrun,” tabi lati “nimọlara ìkábàámọ̀, ìròbìnújẹ́, tabi ìgúnni-ọkàn fun ohun ti ẹnikan ti ṣe tabi gbàgbé lati ṣe.” Awọn Juu ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní nilati ronupiwada kuro ninu awọn ẹṣẹ wọn lodisi Jesu Kristi. (Iṣe 3:11-26) Awọn onigbagbọ kan ni Kọrinti ronupiwada kuro ninu agbere, ibọriṣa, panṣaga, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, olè jíjà, iwọra, imutipara, ṣiṣe ẹlẹ́yà, ati ìlọ́nilọ́wọ́gbà. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, a ‘fọ̀ wọn mọ́’ ninu ẹ̀jẹ̀ Jesu, a ‘sọ wọn di mímọ́’ gẹgẹ bi awọn wọnni ti a yà sọtọ fun iṣẹ-isin Jehofa, a sì ‘polongo wọn gẹgẹ bi olododo’ ni orukọ Jesu Kristi ati pẹlu ẹmi Ọlọrun. (1 Kọrinti 6:9-11) Nitori naa ironupiwada jẹ́ igbesẹ kan siha ẹ̀rí ọkàn rere ati ominira ti Ọlọrun fi funni kuro ninu ẹ̀bi lori ẹṣẹ ti ń dani laamu.—1 Peteru 3:21.
17. Ìyílọ́kànpadà tumọsi ki ni, ki ni o sì beere fun lọwọ ẹni ti ń wewee lati gba iribọmi?
17 Ìyílọ́kànpadà tun gbọdọ ṣẹlẹ ṣaaju ki ẹnikan tó lè di ẹni ti a bamtisi gẹgẹ bi ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìyílọ́kànpadà ẹnikan ti o ronupiwada wáyé lẹhin ti o pa ipa-ọna àìtọ́ rẹ̀ tì tí ó sì pinnu lati ṣe ohun ti o tọ́. Ọrọ-iṣe Heberu ati Giriiki ti o tanmọ ìyílọ́kànpadà tumọsi “yí pada sẹhin, sẹ́rí pada, tabi pada.” Nigba ti a bá lò ó ni itumọ tẹmi ti o dara, eyi tọka sí yiyipada sí Ọlọrun kuro ni ọna ti kò tọ́. (1 Ọba 8:33, 34, NW) Ìyílọ́kànpadà beere fun “awọn iṣẹ ti ó yẹ sí ironupiwada,” pe ki a ṣe ohun ti Ọlọrun pa ni aṣẹ, pa isin èké tì, ki a sì dari ọkan-aya wa láìyàbàrá si Jehofa ki a baà lè ṣiṣẹsin oun nikanṣoṣo. (Iṣe 26:20; Deutaronomi 30:2, 8, 10; 1 Samuẹli 7:3) Eyi beere fun “ọkan-aya titun ati ẹmi titun,” fun ironu, itẹsi-ọkan, ati gongo ti a yipada ninu igbesi-aye. (Esikiẹli 18:31) Animọ titun ti o yọrisi fi awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun rọ́pò awọn animọ iwa alaiwa-bi-Ọlọrun. (Kolose 3:5-14) Bẹẹni, ironupiwada tootọ ń fa ẹnikan lati “sẹ́rí padà” niti gidi.—Iṣe 3:19, NW.
18. Eeṣe ti a fi nilati ṣe ìyàsímímọ́ si Ọlọrun ninu adura, ki sì ni ijẹpataki igbesẹ yii?
18 Ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun ninu adura gbọdọ wá ṣaaju bamtisimu. (Fiwe Luuku 3:21, 22.) Ìyàsímímọ́ tumọsi yíyàsọ́tọ̀ fun ète mímọ́. Igbesẹ yii ṣe pataki gan-an debi pe a gbọdọ sọ fun Ọlọrun ninu adura ipinnu wa lati fun un ni ifọkansin àyàsọ́tọ̀ gédégbé ki a sì ṣiṣẹsin in titilae. (Deutaronomi 5:8, 9; 1 Kironika 29:10-13) Àmọ́ ṣáá o, ìyàsímímọ́ wa kii ṣe sí iṣẹ kan bikoṣe sí Ọlọrun funraarẹ. Koko yẹn ni a mu ṣe kedere nibi ààtò isinku ààrẹ Watch Tower Society akọkọ, Charles Taze Russell. Ni akoko yẹn ni 1916, W. E. Van Amburgh ti ó jẹ́ akọwe ati akápò Society sọ pe: “Iṣẹ ńláǹlà yíká ayé yii kii ṣe iṣẹ ẹnikanṣoṣo. O tobi gan-an ju iyẹn lọ. Iṣẹ Ọlọrun ni tí kìí sìí yipada. Ọlọrun ti lo ọpọlọpọ awọn iranṣẹ ni akoko ti o ti kọja kò sì sí iyemeji pe Oun yoo lo ọpọlọpọ ni ọjọ-iwaju. Ìyàsímímọ́ wa kii ṣe fun eniyan kan, tabi fun iṣẹ eniyan kan, ṣugbọn lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, gẹgẹ bi Oun yoo ṣe ṣipaya rẹ̀ si wa nipasẹ Ọrọ ati ìṣamọ̀nà Rẹ̀ lati ọrun wa. Ọlọrun ṣì wà ni ipo idari.” Ṣugbọn kí tún ni a gbọdọ ṣe nipa ìyàsímímọ́ si Ọlọrun?
19. (a) Bawo ni awọn ẹnikọọkan ṣe ń funni ni ẹ̀rí itagbangba nipa ìyàsímímọ́ si Jehofa? (b) Ki ni bamtisimu inu omi jẹ́ iṣapẹẹrẹ fun?
19 Ẹ̀rí itagbangba ti ìyàsímímọ́ si Jehofa ni a pese nigba ti a bá bamtisi ẹnikan. Bamtisimu jẹ́ iṣapẹẹrẹ kan ti ń tọka sii pe ẹni naa tí ń niriiri iribọmi ninu omi ti ṣe ìyàsímímọ́ ti a kò gbékarí ipò afilelẹ kan si Jehofa Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi. (Fiwe Matiu 16:24.) Nigba ti a bá ri olunaga fun anfaani iribọmi kan sabẹ omi ti a sì fà á jade lẹhin naa, ó kú lọna afiṣapẹẹrẹ si ipa-ọna igbesi-aye rẹ̀ ti iṣaaju a sì jí i dide si ọna igbesi-aye titun kan, nisinsinyi lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun lọna àìkùsíbìkankan. (Fiwe Roomu 6:4-6.) Nigba ti a bamtisi Jesu, ó mú araarẹ wá siwaju Baba rẹ̀ ọrun ni ọna aláìkùsíbìkankan. (Matiu 3:13-17) Iwe Mímọ́ sì fihan leralera pe awọn onigbagbọ ti o tootun gbọdọ ṣe iribọmi. (Iṣe 8:13; 16:27-34; 18:8) Nitori naa, lati di ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii, ẹni kan gbọdọ jẹ́ onigbagbọ ti ó ń lo igbagbọ nitootọ ti o sì gba iribọmi.—Fiwe Iṣe 8:26-39.
Ẹ Duro Ṣinṣin!
20. Ki ni awọn apẹẹrẹ Bibeli diẹ ti o fihan pe a bukun fun wa fun mímú iduro fun ominira ti Ọlọrun fi funni gẹgẹ bi Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a ti bamtisi?
20 Bi iwọ bá ti mú iduro ṣinṣin fun ominira ti Ọlọrun fi funni nipa didi Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a ti bamtisi, oun yoo bukun ọ gẹgẹ bi o ti bukun awọn iranṣẹ rẹ̀ ni ìgbà atijọ. Fun apẹẹrẹ, Jehofa bukun Aburahamu ati Sera arúgbó pẹlu ọmọkunrin olubẹru Ọlọrun kan, Isaaki. Nipa igbagbọ wolii Mose yàn pe ki a hu ìwà ìkà si oun pẹlu awọn eniyan Ọlọrun “ju ati jẹ faaji ẹṣẹ fun igba diẹ; o ka ẹ̀gàn Kristi [tabi Ẹni Ami ororo Ọlọrun, nitori tí oun jẹ́ iru ti atijọ kan] si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Ijibiti lọ.” (Heberu 11:24-26) Mose ni anfaani jíjẹ́ ẹni ti a lò nipasẹ Jehofa lati ṣaaju awọn ọmọ Isirẹli jade kuro ninu ìdè ìsìnrú awọn ará Ijibiti. Ju bẹẹ lọ, nitori pe o ṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu iṣotitọ, a o jí i dide yoo sì ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ọ̀kan lara “awọn ọmọ aládé ni gbogbo ilẹ̀-ayé” labẹ Mose Gigaju naa, Jesu Kristi.—Saamu 45:16, NW; Deutaronomi 18:17-19.
21. Awọn apẹẹrẹ afunni niṣiiri wo ni a fi funni nipa awọn obinrin oniwa-bi-Ọlọrun akoko igbaani?
21 Awọn Kristẹni oluṣeyasimimọ lonii ni a tun lè fun niṣiiri nipa gbigbe awọn obinrin ti wọn di ominira ati alayọ nitootọ yẹwo. Lara wọn ni Ruutu ara Moabu, ẹni ti o niriiri irora ọkàn jíjẹ́ opó ati ayọ ominira tí Ọlọrun fi funni kuro ninu isin èké. Ni fifi awọn eniyan rẹ̀ ati awọn ọlọrun rẹ̀ silẹ, ó dirọ mọ Naomi, ìyakọ rẹ̀ ti o jẹ́ opo. “Ibi ti iwọ bá lọ, ni emi yoo lọ,” ni Ruutu sọ, “ibi ti iwọ bá sì wọ̀, ni emi yoo wọ̀: awọn eniyan rẹ ni yoo ma ṣe eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yoo si maa ṣe Ọlọrun mi.” (Ruutu 1:16) Gẹgẹ bi iyawo Boasi, Ruutu di ìyá Obẹdi babanla Dafidi. (Ruutu 4:13-17) Eeṣe, Jehofa fi “ẹ̀san kíkún” fun obinrin onirẹlẹ ti kii ṣe ará Isirẹli yii nipa yiyọnda fun un lati di ìyáńlá Jesu Mesaya naa! (Ruutu 2:12) Inu Ruutu yoo ti dun tó nigba ti a bá jí i dide ti o sì mọ̀ pe oun ti ni iru anfaani kan bẹẹ! Kò si iyemeji pe ayọ ti o farajọ eyi yoo kún ọkan-aya Rahabu kárùwà tẹlẹri naa, ẹni ti a sọ dominira kuro ninu iwa palapala ati ijọsin èké, ati bakan naa Batiṣeba ẹlẹṣẹ ṣugbọn ti o ronupiwada, nitori pe awọn pẹlu yoo mọ pe Jehofa yọnda wọn lati di ìyáńlá Jesu Kristi.—Matiu 1:1-6, 16.
22. Ki ni a o gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti yoo tẹle e?
22 Agbeyẹwo awọn olùgba ominira ti Ọlọrun fi funni lè maa baa lọ siwaju ati siwaju. Fun apẹẹrẹ, iye wọn ní awọn ọkunrin ati obinrin onigbagbọ ti a mẹnukan ni Heberu ori 11 ninu. Wọn jiya ipọnju ati ìwà ìkà, “ayé kò sì yẹ fun wọn.” Afikun si iye wọn ni awọn ọmọlẹhin Kristi aduroṣinṣin ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ati awọn oluṣotitọ miiran lati ìgbà naa wá, papọ pẹlu araadọta-ọkẹ ti ń ṣiṣẹsin Jehofa nisinsinyi gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Gẹgẹ bi awa yoo ti rí i tẹle, bi iwọ bá ti mú iduro pẹlu wọn fun ominira ti Ọlọrun fi funni, iwọ ni ọpọlọpọ idi fun ayọ.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ireti wo ni Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ jade nigba ti ominira tí Ọlọrun fi funni di eyi ti a padanu?
◻ Lati inu “àjàgà ẹrú” wo ni Kristi ti dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ silẹ?
◻ Awọn igbesẹ wo ni o ṣaaju bamtisimu gẹgẹ bi ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
◻ Awọn apẹẹrẹ ti o bá Iwe Mímọ́ mu wo ni o fihan pe a o bukun wa fun mímú iduro fun ominira ti Ọlọrun fi funni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Iwọ ha mọ awọn igbesẹ ti o ṣaaju bamtisimu gẹgẹ bi ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bi?