‘Késí Awọn Àgbà Ọkunrin’
“Ẹnikẹni ṣe aisan ninu yin bi? ki o pe awọn àgbà ijọ.”—JAKỌBU 5:14.
1, 2. (a) Ninu ipo eléwu wo ni awọn iranṣẹ Jehofa bá araawọn nisinsinyi, bawo ni wọn sì ti lè nimọlara? (b) Awọn ibeere wo ni wọn beere fun idahun nisinsinyi?
“ÌGBÀ ewu” wà nihin-in. Awọn eniyan ń huwa lọna imọtara-ẹni-nikan, lọna ìfẹ́-ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, lọna igberaga, ti o sábà maa ń ru ipo ìdàrúdàpọ̀ soke ni “ikẹhin ọjọ” wọnyi. (2 Timoteu 3:1-5) Gẹgẹ bii awọn Kristian ti ń gbé ninu eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii, a rí araawa ti awọn ewu ńlá mẹta ń halẹ mọ wa: Satani Eṣu, ayé araye alaiwa-bi-Ọlọrun, ati awọn ìtẹ̀sí tiwa funraawa ti a jogunba.—Romu 5:12; 1 Peteru 5:8; 1 Johannu 5:19.
2 Bi awọn ewu wọnyi ti ń halẹ mọ wa, ó lè dabi ẹni pe wọn bò wá mọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá nigba miiran. Nibo, nigba naa, ni a ti lè rí itilẹhin ti yoo ràn wá lọwọ lati farada a pẹlu iṣotitọ? Ta ni a lè yiju si fun itọsọna nigba ti a bá dojukọ ipinnu nipa awọn igbokegbodo Kristian wa ati ijọsin wa?
Iranlọwọ Wà Larọọwọto
3. Lati ọ̀dọ̀ ta ni a ti lè jere ifọkanbalẹ onítùnú, bawo sì ni?
3 Ìmọ̀ pe Jehofa jẹ́ Orisun okun wa ń fun wa ni ifilọkanbalẹ onítìnú. (2 Korinti 1:3, 4; Filippi 4:13) Olorin naa Dafidi, ẹni ti o niriiri iranlọwọ atọrunwa, polongo pe: “Fi ọ̀nà rẹ lé Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; oun ó sì mú un ṣẹ.” “Kó ẹrù rẹ lọ si ara Oluwa, oun ni yoo sì mú ọ duro: oun kì yoo sì jẹ ki ẹsẹ̀ olódodo ki ó yẹ̀ lae.” (Orin Dafidi 37:5; 55:22) Bawo ni a ti gbọdọ kún fun imoore tó fun iru itilẹhin bẹẹ!
4. Bawo ni Peteru ati Paulu ṣe pese itunu?
4 A tun lè rí itunu lati inu ìmọ̀ naa pe a kò danikan wà ninu didojukọ awọn àdánwò ati ewu. Aposteli Peteru rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ẹni [Satani Eṣu] ti ki ẹyin ki o kọ oju ìjà sí pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ, ki ẹyin ki o mọ̀ pe ìyà kan-naa ni awọn ara yin ti ń bẹ ninu ayé ń jẹ.” (1 Peteru 5:9) Dajudaju, gbogbo awọn Kristian fẹ́ lati duro gbọnyingbọnyin ninu igbagbọ. Loootọ, niye ìgbà a lè nimọlara pe “a ń pọ́n wa loju niha gbogbo,” gẹgẹ bi a ti ṣe si aposteli Paulu. Sibẹ, oun ni “ara kò ni.” Bii tirẹ̀, a lè daamu wa “ṣugbọn a ko sọ ireti nù.” Àní bi a bá tilẹ ṣe inunibini si wa paapaa, “a kò kọ̀ wá silẹ.” Bi “a ń rẹ̀ wá silẹ,” a “kò . . . pa wá run.” Nitori eyi ni, “àárẹ̀ kò ṣe mú wa.” A ń lakaka lati maṣe “wo ohun ti a ń rí, bikoṣe ohun ti a kò rí.” (2 Korinti 4:8, 9, 16, 18) Bawo ni a ṣe lè ṣe eyi?
5. Aranṣe oniṣẹẹpo mẹta wo ni Jehofa pese?
5 Jehofa, ‘Olùgbọ́ adura,’ pese aranṣe onilọọpo mẹta. (Orin Dafidi 65:2; 1 Johannu 5:14) Ekinni, ó ń pese idari nipasẹ Ọ̀rọ̀ onimiisi rẹ̀, Bibeli. (Orin Dafidi 119:105; 2 Timoteu 3:16) Ekeji, ẹmi mimọ rẹ̀ ń fun wa ni agbara lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀. (Fiwe Iṣe 4:29-31.) Ati ẹẹkẹta, eto-ajọ Jehofa ti ori ilẹ̀-ayé wà ni sẹpẹ́ lati ràn wá lọwọ. Ki ni a gbọdọ ṣe lati rí itilẹhin gba?
“Ẹbun Ninu Awọn Ọkunrin”
6. Iranlọwọ wo ni Jehofa pese ni Tabera, bawo sì ni?
6 Iṣẹlẹ kan ni ọjọ wolii Mose ràn wá lọwọ lati mọriri idaniyan onifẹẹ Jehofa ni pipese iranlọwọ fun awọn iranṣẹ Rẹ̀. Ó ṣẹlẹ ni Tabera, ti o tumọsi “jíjó; iná titobi; ọwọ́-iná.” Ní ọgangan ibi yii ninu aginju Sinai, Ọlọrun mú kí iná jó awọn ọmọ Israeli ti ń ráhùn run. “Awọn eniyan” ti wọn tẹle awọn eniyan Israeli jade kuro ni Egipti ti darapọ mọ wọn ninu fifi ainitẹẹlọrun hàn lori ounjẹ ti a pese lati ọrun wa. Ní ṣiṣakiyesi ibinu Ọlọrun tí ẹrù-iṣẹ́ ti ó ní siha awọn eniyan naa ati aini wọn sì bò ó mọlẹ, Mose kigbe jade pe: “Emi nikan kò lè ru gbogbo awọn eniyan yii, nitori ti wọn wuwo ju fun mi. Ati bi bayii ni iwọ ó ṣe sí mi, emi bẹ̀ ọ́, pa mi kánkán, bi mo bá rí oore-ọfẹ ni oju rẹ; má sì ṣe jẹ ki emi rí òṣì mi.” (Numeri 11:1-15) Bawo ni Jehofa ṣe dahunpada? Ó yan “aadọrin ọkunrin ninu awọn àgbà Israeli” ó sì fi ẹmi rẹ̀ sori wọn ki wọn baa lè bá Mose ṣajọpin iṣẹ abojuto naa lọna yíyẹ. (Numeri 11:16, 17, 24, 25) Pẹlu iru awọn ọkunrin titootun bẹẹ tí a yànsípò, iranlọwọ di eyi ti o wà larọọwọto ni sẹpẹ́ fun awọn ọmọ Israeli ati “ọpọ eniyan ti o dapọ mọ́ wọn.”—Eksodu 12:38.
7, 8. (a) Bawo ni Jehofa ṣe pese “ẹbun ninu awọn ọkunrin” ni Israeli igbaani? (b) Ifisilo ọrundun kìn-ín-ní ti Orin Dafidi 68:18 wo ni Paulu ṣe?
7 Lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti wà ni Ilẹ Ileri fun ọpọlọpọ ọdun, Jehofa lọna iṣapẹẹrẹ gbé Oke Sioni ga ó sì sọ Jerusalemu di olu-ilu ijọba gidi kan pẹlu Dafidi gẹgẹ bi ọba. Si iyin Ọlọrun, “Olodumare,” Dafidi gbé ohùn rẹ̀ soke lati kọrin: “Iwọ ti goke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gba ẹbun fun eniyan.” (Orin Dafidi 68:14, 18) Nitootọ, awọn ọkunrin ti a kó ni igbekun nigba ijagunbori Ilẹ Ileri wà larọọwọto lati ran awọn ọmọ Lefi lọwọ ninu iṣẹ wọn.—Esra 8:20.
8 Ní ọrundun kìn-ín-ní C.E., Kristian aposteli Paulu pe afiyesi si imuṣẹ alasọtẹlẹ awọn ọ̀rọ̀ olórin naa. Paulu kọwe pe: “Olukuluku wa ni a fi inurere ailẹtọọsi fun gẹgẹ bi Kristi ti diwọn ẹbun ọfẹ naa funni. Nipa bẹẹ ni o wi pe: ‘Nigba ti o goke si ibi-giga ó kó awọn onde lọ; o funni ni ẹbun ninu awọn ọkunrin.’ Nisinsinyi ọrọ-isọjade naa ‘ó goke,’ ki ni o tumọsi bikoṣe pe ó tun sọkalẹ lọ si awọn ẹkun-ilẹ isalẹ, eyiini ni, ilẹ̀-ayé? Ẹni naa gan-an ti o sọkalẹ ni ẹni naa ti o tun goke jinna rekọja gbogbo ọrun, ki o lè fi ẹ̀kún fun ohun gbogbo.” (Efesu 4:7-10, NW) Ta ni “ẹni naa gan-an” yii? Kìí ṣe ẹlomiran ju aṣoju Jehofa lọ, Dafidi Titobi Ju ati Messia Ọba naa, Jesu Kristi. Oun ni ẹni naa ti Ọlọrun jí dide ti o sì “gbé e ga gidigidi.”—Filippi 2:5-11.
9. (a) Awọn wo ni ẹbun ninu awọn ọkunrin ti ọrundun kìn-ín-ní? (b) Awọn wo ni ẹbun ninu awọn ọkunrin ti ode-oni?
9 Nigba naa, awọn ta ni “ẹbun ninu awọn ọkunrin” (tabi, “ti o jẹ́ èkìdá awọn ọkunrin”) wọnyi? Paulu ṣalaye pe Olu-olori Aṣoju Ọlọrun “fi awọn kan funni bi aposteli, awọn kan bii wolii, awọn kan bi ajihinrere, awọn kan bi oluṣọ-agutan ati olukọ, pẹlu ero itunṣebọsipo awọn ẹni mimọ, fun iṣẹ-ojiṣẹ, fun ìgbéró ara Kristi.” (Efesu 4:11, 12, NW) Gbogbo awọn ọmọlẹhin Kristi ti wọn ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aposteli, wolii, ajihinrere, oluṣọ-agutan, ati olukọ ṣe bẹẹ labẹ idari iṣakoso Ọlọrun. (Luku 6:12-16; Iṣe 8:12; 11:27, 28; 15:22; 1 Peteru 5:1-3) Ní ọjọ wa, awọn àgbà ọkunrin ti wọn tootun nipa tẹmi ti a fi ẹmi mimọ yàn ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi alaboojuto ninu nǹkan bi 70,000 ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kari-aye. Ẹbun wa ni wọn jẹ́ ninu awọn ọkunrin. (Iṣe 20:28) Pẹlu igbooro kari-aye iṣẹ iwaasu Ijọba tí ń baa lọ láìsọsẹ̀, awọn arakunrin pupọ pupọ sii “ń nàgà” tí wọn sì ń tẹ́rí gba awọn ẹrùiṣẹ ti o sopọ mọ “ipo alaboojuto.” (1 Timoteu 3:1, NW) Nigba ti a bá ti yàn wọn sipo tán, awọn pẹlu di ẹbun ninu awọn ọkunrin.
10. Bawo ni apejuwe Isaiah nipa “awọn ọmọ-alade” ṣe bá ipa iṣẹ́ awọn Kristian alagba lonii mu?
10 Awọn Kristian alagba wọnyi, tabi ẹbun ninu awọn ọkunrin, bá apejuwe ti wolii Isaiah fifunni mu nigba ti ó ń sọ asọtẹlẹ ipa iṣẹ́ “awọn ọmọ-alade” (NW), awọn oluṣabojuto labẹ iṣakoso Ijọba. Ẹnikọọkan gbọdọ jẹ́ “bi ibi ìlùmọ̀ kuro loju ẹfuufu, ati aabo kuro lọwọ ìjì; bi odò omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata ńlá ni ilẹ gbigbẹ.” (Isaiah 32:1, 2) Eyi ṣípayá bi iṣabojuto onifẹẹ ti awọn ọkunrin ti a yàn sipo wọnyi ti nilati jẹ́ eyi tí ń rannilọwọ tó. Bawo ni o ṣe lè janfaani lati inu rẹ̀ dé ẹkunrẹrẹ ìwọ̀n julọ?
Lilo Idanuṣe Naa
11. Nigba ti a kò bá lera tó nipa tẹmi, bawo ni a ṣe lè rí iranlọwọ gbà?
11 Ọkunrin kan ti ń rì sinu omi maa ń ké fun iranlọwọ lọna àdánidá. Kò sí ìlọ́tìkọ̀. Nigba ti iwalaaye bá wà ninu ewu, kò sí ẹni ti ó nilo gbígbún ni kẹ́ṣẹ́ lati ké fun iranlọwọ. Ọba Dafidi kò ha ké fun iranlọwọ lati ọ̀dọ̀ Jehofa leralera bi? (Orin Dafidi 3:4; 4:1; 5:1-3; 17:1, 6; 34:6, 17-19; 39:12) Nigba ti a bá ṣalaini tó nipa tẹmi, boya ti a ń rilẹ̀ sinu ainireti, awa bakan naa ń yiju si Jehofa ninu adura a sì ń bẹ̀ ẹ́ lati tọ́ wa sọna nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀. (Orin Dafidi 55:22; Filippi 4:6, 7) A ń wá itunu lati inu Iwe Mimọ. (Romu 15:4) A ń wo inu awọn itẹjade Kristian ti Watch Tower Society fun amọran ti o gbeṣẹ. Eyi niye ìgbà maa ń mu ki a lè yanju awọn iṣoro tiwa funraawa. Bi o bá dabi ẹni pe awọn iṣoro bò wá mọ́lẹ̀, sibẹ, a tun lè wá imọran awọn alagba ti a yàn sipo ninu ijọ. Niti tootọ, awọn akoko lè wa ninu eyi ti a nilati “késí awọn àgbà ọkunrin” niti gidi. Eeṣe ti a fi nilati késí awọn Kristian alagba? Bawo ni wọn ṣe lè ran awọn wọnni ti wọn nilo itilẹhin tẹmi lọwọ?
12-14. (a) Ki ni ipa-ọna ọgbọ́n lati tẹle nigba ti ẹnikan bá ń ṣaisan? (b) Gẹgẹ bi Jakọbu 5:14 ṣe sọ, ki ni a gba awọn Kristian ti wọn “ń ṣaisan” niyanju lati ṣe? (c) Iru aisan wo ni Jakọbu 5:14 ń tọkasi, eesitiṣe ti o fi dahun bẹẹ?
12 Nigba ti ara wa kò bá le, a ń sinmi ki a baa lè fun agbara ìkọ́fẹpadà ara ni anfaani lati ṣiṣẹ. Ṣugbọn bi aisan wa bá ń baa lọ laidawọ duro, a ń fi ọgbọn wá iranlọwọ iṣegun ti o tootun. Kò ha yẹ ki a ṣe ohun kan-naa bi a bá di alailera nipa tẹmi bi?
13 Ṣakiyesi ohun ti ọmọ-ẹhin naa Jakọbu gbà wá nimọran lori kókó yii. Ó sọ pe: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu yin bi? ki o pe awọn àgbà ijọ, ki wọn sì gbadura sori rẹ̀, ki wọn fi òróró kun un ni orukọ Oluwa.” (Jakọbu 5:14) Iru aisan wo ni Jakọbu ń tọka si nihin-in? Awọn alálàyé Bibeli kan pari-ero si pe okunrun ti ara-ìyára ni, ní rironu pe fifi òróró kunni jẹ́ aṣa iṣegun ti ó wọ́pọ̀ ni ọjọ yẹn. (Luku 10:34) Wọn tun gbagbọ pe Jakọbu ní iwosan oniṣẹ iyanu nipasẹ ẹbun imularada lọ́kàn. Bi o ti wu ki o ri, ki ni ayika-ọrọ naa fihàn?
14 ‘Inu didun’ ni a ṣe iyatọ ifiwera rẹ̀ pẹlu ‘ibanujẹ.’ Eyi dọgbọn tumọsi pe Jakọbu ń jiroro aisan tẹmi. (Jakọbu 5:13) “Awọn àgbà [alagba, King James Version (Gẹẹsi)] ijọ,” kìí ṣe awọn dokita tabi awọn wọnni ti wọn ni ẹbun imularada paapaa, ni a nilati pè. Ki sì ni wọn nilati ṣe? Jakọbu sọ pe: “Ki wọn . . . gbadura sori rẹ̀ . . . Adura igbagbọ yoo sì gba alaisan naa là.” (Jakọbu 5:14, 15, fiwe Orin Dafidi 119:9-16.) Eyi ti o fi ẹ̀rí ti kò ṣeéjáníkoro hàn pe Jakọbu ń tọkasi okunrun tẹmi ni otitọ naa pe ó gbaniniyanju ijẹwọ ẹṣẹ ni isopọ pẹlu ireti fun imularada. Ó kọwe pe: “Ẹ jẹwọ ẹṣẹ yin fun ara yin, ki ẹ sì maa gbadura fun ara yin, ki a lè mú yin larada.” Bi ẹṣẹ wiwuwo bá ti jẹ́ okunfa okunrun tẹmi, alaisan naa ni a lè nireti pe ki ara rẹ̀ yá kìkì bi ó bá dahunpada lọna rere si iṣinileti ti a gbekari Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ronupiwada, ti o bá sì yipada kuro ninu ipaọna ẹṣẹ rẹ̀.—Jakọbu 5:16; Iṣe 3:19.
15. Iru igbesẹ wo ni a damọran ni Jakọbu 5:13, 14?
15 Ohun miiran kan wà ti a nilati ṣakiyesi ninu imọran ti Jakọbu fifunni. Nigba ti ó bá ń banujẹ, Kristian kan nilati “gbadura.” Bi inu rẹ̀ bá dun, “ki o kọrin mimọ.” Ipo kọọkan—yala inu ẹnikan bajẹ tabi inu rẹ̀ ń dun—beere fun igbesẹ. Adura ni a nilo ni ọwọ́ kan, igbe ayọ ni ọwọ́ keji. Wayi o, nigba naa, ki ni a nilati reti nigba ti Jakọbu beere pe: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu yin bi?” Lẹẹkan sii ó damọran igbesẹ pàtó, bẹẹni, lilo idanuṣe. “Ki ó pe awọn àgbà ijọ.”—Orin Dafidi 50:15; Efesu 5:19; Kolosse 3:16.
Bi ‘Awọn Àgbà Ọkunrin’ Ṣe Ń Ṣeranlọwọ
16, 17. Bawo ni awọn àgbà ọkunrin ṣe ń ràn wá lọwọ lati fi awọn ilana Bibeli silo?
16 Nigba miiran ó maa ń ṣoro fun wa lati mọ bi a tii fi awọn ilana Bibeli silo ninu awọn ipo-ayika ti ara-ẹni. Nihin-in awọn Kristian alagba lè jásí orisun iranlọwọ ti kò ṣeediyele. Fun apẹẹrẹ, wọn ń gbadura sori alaisan nipa tẹmi wọn sì ‘ń fi òróró kùn ún ni orukọ Jehofa’ nipa fifi ijafafa lo itọni amáradẹni lati inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Awọn alagba lè tipa bayii ṣe pupọpupọ ni afikun si iwosan wa nipa tẹmi. (Orin Dafidi 141:5) Niye ìgbà, gbogbo ohun ti a nilo ni riri i daju pe a ń ronu ni ọ̀nà titọ. Bíbá Kristian oniriiri alagba kan sọrọ yoo fun ipinnu wa lokun lati ṣe ohun ti o tọ́.—Owe 27:17.
17 Nigba ti a bá késí wọn lati ṣebẹwo, awọn Kristian alagba nilati “maa tu awọn alailọkan ninu.” Wọn yoo tun “ran awọn alailera lọwọ, [ati] mú suuru fun gbogbo eniyan.” (1 Tessalonika 5:14) Iru ipo-ibatan pẹkipẹki, ti liloye bẹẹ laaarin ‘awọn àgbà ọkunrin’ ati “awọn alailera” mú ṣiṣeeṣe naa fun jijere okun tẹmi pada patapata pọ sii.
Ẹrù-Iṣẹ́ Ara-Ẹni ati Adura
18, 19. Ipa wo ni awọn Kristian alagba ń kó ni isopọ pẹlu Galatia 6:2, 5?
18 Awọn Kristian alagba gbọdọ gbé ẹrù-iṣẹ́ wọn siha agbo Ọlọrun. Wọn gbọdọ jẹ́ atinilẹhin. Fun apẹẹrẹ, Paulu sọ pe: “Ẹyin ará, àní bi eniyan kan bá tilẹ ṣi ẹsẹ gbé ki o tó mọ̀, ẹyin ti ẹ ní ẹ̀rí-títóótun ti ẹmi nilati gbiyanju lati tun iru eniyan bẹẹ ṣebọsipo ninu ẹmi iwapẹlẹ, bi olukuluku yin ti ń kiyesi araarẹ̀, ni ibẹru pe a lè dẹ ẹyin naa wò. Ẹ maa baa lọ ni riru ẹrù-ìnira ara yin ẹnikinni keji, ki ẹ sì tipa bayii mú ofin Kristi ṣẹ.” Aposteli naa tun kọwe pe: “Olukuluku ni yoo ru ẹrù ti araarẹ̀.”—Galatia 6:1, 2, 5, NW.
19 Bawo ni a ṣe lè bá araawa ẹnikinni keji ru ẹrù-ìnira ati sibẹ ki a ru ẹrù tiwa funraawa? Iyatọ ninu itumọ awọn ọ̀rọ̀ Griki ti a tumọsi “ẹrù-ìnira” ati “ẹrù” pese idahun naa. Bi Kristian kan bá bọ́ sinu iṣoro tẹmi ti o jẹ́ ẹrù-ìnira gan-an fun un, awọn alagba ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ miiran yoo ràn án lọwọ, ni titipa bayii ràn án lọwọ lati gbé “ẹrù-ìnira” rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, onitọhun funraarẹ ni a reti pe ki o gbé “ẹrù” ti ẹrù-iṣẹ́ tirẹ̀ si Ọlọrun funraarẹ.a Awọn alagba fi tayọtayọ gbé “awọn ẹrù-ìnira” ti awọn arakunrin wọn nipasẹ iṣiri, imọran ti o bá Iwe Mimọ mu, ati adura. Sibẹ, awọn alagba kìí mú “ẹrù” ti ẹrù-iṣẹ́ tẹmi ti o jẹ tiwa kuro.—Romu 15:1.
20. Eeṣe ti a kò fi nilati ṣainaani adura?
20 Adura ṣekoko a kò sì nilati ṣainaani rẹ̀. Ṣugbọn o ṣòro fun ọpọ awọn Kristian ti ń ṣaisan nipa tẹmi lati gbadura. Nigba ti awọn alagba bá gba adura igbagbọ nititori ẹnikan ti ara rẹ̀ kò le nipa tẹmi, ki ni ohun ti wọn ní lọ́kàn? “Oluwa yoo sì gbé e dide,” bi ẹni pe lati inu isọretinu, yoo sì fun un lokun lati lepa ipa-ọna otitọ ati òdodo. Kristian kan ti ń ṣaisan nipa tẹmi lè ní iṣarasihuwa òdì ṣugbọn ó lè má tíì fi dandan dá ẹṣẹ gbígbópọn, nitori ti Jakọbu sọ pe: “Bi o bá sì ṣe pe o ti dẹṣẹ, a o dari jì í.” Imọran ti ó ba Iwe Mimọ mu ti awọn alagba pẹlu adura àfitọkàntọkàn gbà nigba miiran maa ń gbún ọkàn alailera nipa tẹmi naa ni kẹ́ṣẹ́ lati jẹwọ awọn ẹṣẹ wiwuwo ti ó lè ti dá ati lati fi ẹmi ironupiwada hàn. Eyi, ni odikeji ẹ̀wẹ̀, ń mú idariji ni apá ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.—Jakọbu 5:15, 16.
21. (a) Eeṣe ti awọn Kristian kan fi ń lọ́ra lati késí awọn àgbà ọkunrin? (b) Ki ni a o gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e?
21 Bi wọn ti dojukọ ipenija ti bibojuto ogidigbo awọn ẹni titun ti wọn ń wá sinu ijọ Kristian, awọn àgbà ọkunrin tí ń fẹ̀rí-ọkàn-ṣiṣẹ́ ní pupọ lati ṣe ni pipese abojuto ti ó tó. Loootọ, awọn ẹbun ninu awọn ọkunrin wọnyi jẹ́ ipese rere lati ọ̀dọ̀ Jehofa lati ràn wá lọwọ lati farada ni awọn akoko lilekoko wọnyi. Sibẹ, awọn Kristian kan ń fà sẹ́hìn ninu bibeere fun iranlọwọ wọn, ni rironu pe ọwọ́ awọn arakunrin wọnyi ti dí jù tabi pe iṣoro ti wọ̀ wọn lọ́rùn. Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo ràn wá lọwọ lati mọriri pe awọn ọkunrin wọnyi layọ lati ṣetilẹhin, nitori pe wọn ń fi imuratan ṣiṣẹsin gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ ninu ijọ Kristian.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A Linguistic Key to the Greek New Testament, lati ọwọ́ Fritz Rienecker, tumọ phor·tiʹon gẹgẹ bi “ẹrù ti a reti pe ki ẹnikan rù” ó sì fikun un pe: “A lò ó gẹgẹ bi èdè-ìsọ̀rọ̀ ológun fun àdìpọ̀-ẹrù ọkunrin kan tabi àpò ìkó-nǹkan-sí ti ọmọ-ogun kan.”
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Nigba ti a bá nilo iranlọwọ, aranṣe oniṣẹẹpo mẹta wo ni Jehofa pese?
◻ Awọn wo ni ẹbun ninu awọn ọkunrin ti ode-oni?
◻ Nigba wo ni a nilati késí awọn àgbà ọkunrin?
◻ Iranlọwọ wo ni a lè reti lati ọ̀dọ̀ awọn Kristian alagba?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Iwọ ha ń gbadun awọn anfaani tẹmi ti adura, ikẹkọọ Bibeli, ati iranlọwọ lati ọ̀dọ̀ awọn Kristian alagba bi?