Sáàmù
Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin atunilára. Orin.
68 Kí Ọlọ́run dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tú ká,
Kí àwọn tó kórìíra rẹ̀ sì sá kúrò níwájú rẹ̀.+
2 Bí afẹ́fẹ́ ṣe ń gbá èéfín lọ, bẹ́ẹ̀ ni kí o gbá wọn lọ;
Bí ìda ṣe ń yọ́ níwájú iná,
Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ẹni burúkú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.+
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run; ẹ fi orin yin* orúkọ rẹ̀.+
Ẹ kọrin sí Ẹni tó ń la àwọn aṣálẹ̀ tó tẹ́jú* kọjá.
Jáà* ni orúkọ rẹ̀!+ Ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀!
Àmọ́ ilẹ̀ gbígbẹ ni àwọn alágídí* yóò máa gbé.+
7 Ọlọ́run, nígbà tí o darí* àwọn èèyàn rẹ,+
Nígbà tí o gba aṣálẹ̀ kọjá, (Sélà)
8 Ayé mì tìtì;+
Ọ̀run rọ òjò* nítorí Ọlọ́run;
Sínáì yìí mì tìtì nítorí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
9 O mú kí òjò rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ìwọ Ọlọ́run;
O sọ agbára àwọn èèyàn* rẹ tí àárẹ̀ mú dọ̀tun.
10 Wọ́n gbé inú àwọn àgọ́ tó wà ní ibùdó rẹ;+
Ọlọ́run, nínú oore rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.
12 Àwọn ọba ẹgbẹ́ ọmọ ogun sá lọ,+ wọ́n fẹsẹ̀ fẹ!
Obìnrin tí kò kúrò nílé pín nínú ẹrù tí wọ́n kó bọ̀.+
13 Bí ẹ̀yin ọkùnrin tilẹ̀ dùbúlẹ̀ sáàárín iná ibùdó,*
Ẹ máa ní àdàbà tí a fi fàdákà bo ìyẹ́ apá rẹ̀,
Tí a sì fi wúrà tó dáa* bo ìyẹ́ tó fi ń fò.
Dájúdájú, Jèhófà yóò máa gbé ibẹ̀ títí láé.+
17 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.+
Jèhófà wá láti Sínáì sínú ibi mímọ́.+
O kó àwọn èèyàn lẹ́rú;
O kó àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn,+
Kódà, àwọn alágídí,+ láti máa gbé láàárín wọn, Jáà Ọlọ́run.
19 Ìyìn ni fún Jèhófà, tó ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́,+
Ọlọ́run tòótọ́, olùgbàlà wa. (Sélà)
22 Jèhófà sọ pé: “Màá mú wọn pa dà láti Báṣánì;+
Màá mú wọn pa dà látinú ibú òkun,
23 Kí o lè wẹ ẹsẹ̀ rẹ nínú ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọ̀tá,
Kí ahọ́n àwọn ajá rẹ sì lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn.”
24 Wọ́n rí ìkọ́wọ̀ọ́rìn rẹ, Ọlọ́run,
Ìkọ́wọ̀ọ́rìn Ọlọ́run mi, Ọba mi, sínú ibi mímọ́.+
25 Àwọn akọrin ń lọ níwájú, àwọn tó ń ta ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín ń tẹ̀ lé wọn,+
Àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń lu ìlù tanboríìnì sì wà ní àárín.+
27 Ibẹ̀ ni Bẹ́ńjámínì,+ tó kéré jù lọ, ti ń ṣẹ́gun wọn,
Bákan náà ni àwọn olórí Júdà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn wọn tó ń pariwo
Àti àwọn olórí Sébúlúnì pẹ̀lú àwọn olórí Náfútálì.
28 Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ pé kí o lágbára.
Ìwọ Ọlọ́run, fi agbára rẹ hàn, o ti gbé ìgbésẹ̀ nítorí wa.+
30 Bá ẹranko tó wà nínú àwọn esùsú* wí,
Àpéjọ àwọn akọ màlúù+ àti àwọn ọmọ màlúù,
Títí àwọn èèyàn á fi tẹrí ba tí wọ́n á sì mú fàdákà wá.*
Àmọ́, tú àwọn èèyàn tó fẹ́ràn ogun ká.
32 Ẹ̀yin ìjọba ayé, ẹ kọrin sí Ọlọ́run,+
Ẹ fi orin yin* Jèhófà, (Sélà)
33 Ẹni tó ń gun ọ̀run àwọn ọ̀run tó ti wà láti ayébáyé.+
Wò ó! Ó fi ohùn rẹ̀ sán ààrá, ohùn rẹ̀ alágbára ńlá.
34 Ti Ọlọ́run ni agbára.+
Ọlá ńlá rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lì
Àti okun rẹ̀ lójú ọ̀run.*
35 Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù ní ibi mímọ́ rẹ̀* títóbi lọ́lá.+
Òun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì,
Ẹni tó ń fún àwọn èèyàn ní okun àti agbára.+
Ẹ yin Ọlọ́run.