Máa Wá Àlàáfíà Tòótọ́, Kí O Sì Máa Lépa Rẹ̀!
“Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, . . . kí ó yí pa dà kúrò nínú ohun búburú kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—PÉTÉRÙ KÍNÍ 3:10, 11.
1. Àwọn ọ̀rọ̀ olókìkí inú Aísáyà wo ni ó dájú pé yóò ní ìmúṣẹ?
“WỌN óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ píláù, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.” (Aísáyà 2:4) Bí wọ́n tilẹ̀ kọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lílókìkí yìí sára ohun kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní New York City, àjọ àgbáyé yẹn kò mú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹ páàpáà. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí apá kan ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tí kì í kùnà, ìsọjáde yẹn kì yóò lọ láìṣẹ.—Aísáyà 55:10, 11.
2. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ ìkẹyìn,” gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 2:2, 3 ti sọ?
2 Àwọn ọ̀rọ̀ tí a rí nínú Aísáyà 2:4 jẹ́ apá kan àsọtẹ́lẹ̀ yíyani lẹ́nu kan ní tòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa àlàáfíà tòótọ́—ó sì ń ní ìmúṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ní sànmánì wa. Kí ó tó sọ nípa ìfojúsọ́nà amúniláyọ̀ náà, nípa àìsí ogun àti ohun ìjà ogun mọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà wí pé: “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, a óò fi òkè ilé Olúwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a óò sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò sì wọ́ sí inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò sì lọ, wọn óò sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Olúwa, sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù; Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀; Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerúsálẹ́mù.”—Aísáyà 2:2, 3.
Àwọn Ènìyàn Lè Di Olùfẹ́ Àlàáfíà
3. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè yí pa dà láti inú jíjẹ́ aríjàgbá sí olùfẹ́ àlàáfíà?
3 Ṣàkíyèsí pé kí àwọn ènìyàn tó lè lépa ipa ọ̀nà àlàáfíà, a gbọ́dọ̀ kọ́ wọn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà. Ìdáhùnpadà onígbọràn sí ẹ̀kọ́ Jèhófà lè yí ọ̀nà ìrònú àti ìhùwà ènìyàn pa dà, kí ẹni tí ó ti jẹ́ aríjàgbá tẹ́lẹ̀ baà lè di olùfẹ́ àlàáfíà. Báwo ni a ṣe lè ṣàṣeparí ìyípadà yí? Róòmù 12:2 sọ pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.” A ń yí èrò inú wa pa dà, tàbí sún un ṣiṣẹ́ ní ipa ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀, nípa fífi àwọn ìlànà àti òfin inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún inú rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà yí, ó sì ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi ohun tí ìfẹ́ Jèhófà fún wa jẹ́ han ara wa, kí a baà lè rí ọ̀nà tí ó yẹ kí a gbà kedere.—Orin Dáfídì 119:105.
4. Báwo ni ẹnì kan ṣe ń gbé àkópọ̀ ìwà tuntun alálàáfíà wọ̀?
4 Kì í ṣe ọ̀nà tí a ń gbà ronú nìkan ni òtítọ́ Bíbélì ń yí pa dà, ṣùgbọ́n, ó tún ń yí ìhùwà wa àti àkópọ̀ ìwà wa pa dà pẹ̀lú. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọni láti ṣe pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ èyí tí ó bá ìlà ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé èyí tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ atannijẹ; ṣùgbọ́n kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Ipá tí ń mú èrò inú ṣiṣẹ́ jẹ́ ti inú lọ́hùn-ún. Ó ń para dà, ó sì ń di alágbára bí ìfẹ́ wa fún Jèhófà àti fún àwọn òfin rẹ̀ ti ń pọ̀ sí i, ó sì ń sọ wá di ẹni tẹ̀mí àti onífẹ̀ẹ́ àlàáfíà.
5. Báwo ni “òfin tuntun” tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ń fi kún àlàáfíà aárín wọn?
5 A rí ìjẹ́pàtàkì ìparadà yí nínú ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ní àwọn wákàtí tí ó kẹ́yìn tí ó lò pẹ̀lú wọn, pé: “Èmí ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan, bíi ti Kristi yìí, so àwọn ọmọ ẹ̀yìn pọ̀ nínú ìṣọ̀kan pípé pérépéré. (Kólósè 3:14) Kìkì àwọn tí wọ́n múra tán láti tẹ́wọ́ gba “òfin tuntun” yìí, kí wọ́n sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, ni yóò gbádùn àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Àwọn ènìyàn kankan ha wà tí ń ṣe èyí lónìí bí?
6. Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń gbádùn àlàáfíà, ní ìyàtọ̀ sí àwọn ènìyàn inú ayé?
6 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sakun láti fi ìfẹ́ hàn nínú ẹgbẹ́ ará wọn kárí ayé. Bí wọ́n tilẹ̀ wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, wọn kì í lọ́wọ́ nínú àríyànjiyàn ayé, àní nígbà tí a bá fúngun líle koko mọ́ wọn ní ti ìṣèlú àti ìsìn pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn onírẹ̀ẹ́pọ̀, Jèhófà ń kọ́ wọn, wọ́n sì ń gbádùn àlàáfíà. (Aísáyà 54:13) Wọ́n wà láìdásí tọ̀tún tòsì nínú rògbòdìyàn ìṣèlú, wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ogun. Àwọn kan tí wọ́n ti jẹ́ oníwà ipá tẹ́lẹ̀ ti pa ìwà yẹn tì. Wọ́n ti di Kristẹni olùfẹ́ àlàáfíà, tí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi Jésù. Wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù tọkàntọkàn pé: “Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, kí ó kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu kúrò nínú ohun búburú àti ètè rẹ̀ kúrò nínú sísọ ẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kí ó yí pa dà kúrò nínú ohun búburú kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—Pétérù Kíní 3:10, 11; Éfésù 4:3.
Àwọn Tí Ń Lépa Àlàáfíà
7, 8. Fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣíwọ́ ogun, tí wọ́n sì di olùwá àlàáfíà tòótọ́ kiri. (Sọ àwọn mìíràn ti ó mọ̀.)
7 Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan ń bẹ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rami Oved, ọ̀gá kan tẹ́lẹ̀ rí nínú ẹ̀ka ẹgbẹ́ ògbóǹtagí agbógunti àwọn apániláyà. Ó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bí ó ṣe lè pa àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó gbà gbọ́ tìtaratìtara nínú ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀, Ísírẹ́lì, títí di ọjọ́ tí ó wá mọ̀ pé àwọn rábì kò fẹ́ kí òun fẹ́ obìnrin tí ó jẹ́ ààyò ọkàn òun, kìkì nítorí pé obìnrin náà jẹ́ ará Éṣíà, Kèfèrí kan. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá òtítọ́ inú Bíbélì kiri. Lẹ́yìn náà, ó ṣalábàápàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí mú un gbà gbọ́ dájú pé, òun kò lè jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ẹlẹ́mìí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni mọ́. Ìfẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí kíkọ ogun àti ohun ìjà ogun sílẹ̀ àti kíkọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ẹ̀yà ìran gbogbo. Ẹ wo bí ó ṣe yà á lẹ́nu tó láti gba lẹ́tà onínúure kan pẹ̀lú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, “Arákùnrin mi Rami”! Kí ni ó ṣàjèjì nípa ìyẹn? Ẹlẹ́rìí ọmọ ilẹ̀ Palẹ́sìnì ni ó kọ ọ́. Rami sọ pé: “Ìyẹn ṣòro láti gbà gbọ́, bí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Palẹ́sìnì jẹ́ ọ̀tá mi, níhìn-ín kẹ̀ ni ọ̀kan lára wọ́n ti ń pè mí ni ‘Arákùnrin Mi.’” Rami àti ìyàwó rẹ̀ ń lépa àlàáfíà tòótọ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run nísinsìnyí.
8 Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Georg Reuter, tí ó ṣiṣẹ́ sìn nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany tí ó gbógun ti Rọ́ṣíà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìwéwèé pípabanbarì Hitler fún jíjẹgàba lórí ayé bà á lọ́kàn jẹ́. Nígbà tí ó togun dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó kọ̀wé pé: “Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere sí mi. Mo wá mọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́run ni a ní láti dálẹ́bi fún gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ . . . Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé, ète rẹ̀ ni láti fìdí párádísè kan múlẹ̀ yíká ayé pẹ̀lú ìbùkún àìnípẹ̀kun fún aráyé onígbọràn. . . . Hitler ti fọ́nnu nípa ‘Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún’ rẹ̀, ṣùgbọ́n [ọdún] 12 péré ni ó fi ṣàkóso—ẹ sì wò bí àbájáde rẹ̀ ti burú tó! Kì í ṣe Hitler . . . ṣùgbọ́n Kristi ni ó lè gbé ìṣàkóso ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún kalẹ̀ lórí ayé, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.” Georg ti ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣojú fún àlàáfíà tòótọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún nǹkan bí 50 ọdún nísinsìnyí.
9. Báwo ni ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nazi Germany ṣe fẹ̀rí hàn pé, wọ́n jẹ́ onígboyà, síbẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ olùfẹ́ àlàáfíà?
9 Ìwà títọ́ àti àìdásí-tọ̀tún-tòsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany nígbà ìṣàkóso Nazi ń bá a nìṣó láti jẹ́rìí sí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti fún àlàáfíà, àní títí di ìsinsìnyí pàápàá, ní èyí tí ó lé ní 50 ọdún lẹ́yìn náà. Ìwé pélébé kan tí a tẹ̀ jáde láìpẹ́ yìí ní Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé ti Ìpakúpa Rẹpẹtẹ ní Washington, D.C., sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara da inúnibíni gbígbóná janjan lábẹ́ ìṣàkóso Nazi. . . . Ìgboyà tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọ́n fi hàn ní kíkọ̀ [láti kọ ìsìn wọn sílẹ̀], lójú ìdálóró, híhùwà ìkà síni ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àti ṣíṣekú pa wọ́n nígbà míràn, mú kí wọ́n jèrè ọ̀wọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn.” Ìwé pélébé náà fi kún un pé: “Nígbà tí a dá àwọn tí ó wà ní àgọ́ náà sílẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá iṣẹ́ wọn lọ, wọ́n ń lọ wọ́n ń bọ̀ láàárín àwọn olùlàájá, ní yíyí wọn lọ́kàn pa dà.”
Ìyípadà Ńláǹlà Kan
10. (a) Ìyípadà ńlá wo ni ó ń béèrè, kí àlàáfíà tòótọ́ tó lè wá? (b) Báwo ni ìwé Dáníẹ́lì ṣe ṣàgbéyọ èyí?
10 Èyí ha túmọ̀ sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé àwọn lè mú àlàáfíà wá sí ayé nípasẹ̀ ìyílọ́kànpadà ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ sí ìgbàgbọ́ nínú àìdásí-tọ̀tún-tòsì Kristẹni bí? Rárá o! Láti lè mú àlàáfíà pa dà wá sí ilẹ̀ ayé, a nílò ìyípadà ńláǹlà kan. Kí nìyẹn? Àkóso ẹ̀dá ènìyàn oníyapa, oníkòórìíra, àti oníwà ipá gbọ́dọ̀ fàyè sílẹ̀ fún àkóso Ìjọba Ọlọ́run, tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún. (Mátíù 6:9, 10) Ṣùgbọ́n, báwo ni ìyẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Nínú àlá kan tí a mí sí látọ̀runwá, wòlíì Dáníẹ́lì rí i pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Ìjọba Ọlọ́run, tí ó dà bí òkúta ńlá ‘tí kì í ṣe ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ni ó jù ú,’ yóò fọ́ ère gàgàrà kan, tí ó dúró fún ìṣàkóso ìṣèlú aráyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé lórí ilẹ̀ ayé, túútúú. Lẹ́yìn náà, ó polongo pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyí ni Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè pa run títí láé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè míràn lọ́wọ́, yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.”—Dáníẹ́lì 2:31-44.
11. Kí ni Jèhófà yóò lò láti mú ìyípadà sí àlàáfíà tí a nílò wá?
11 Èé ṣe tí ìyípadà tegbòtigaga yìí nínú ipò ayé yóò fi wáyé? Nítorí Jèhófà ti ṣèlérí pé, òun yóò run gbogbo àwọn tí ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́, tí wọ́n sì ń pa á run. (Ìṣípayá 11:18) Ìyípadà yí yóò wáyé nígbà ogun òdodo Jèhófà lòdì sí Sátánì àti ayé búburú rẹ̀. A kà ní Ìṣípayá 16:14, 16 pé: “Wọn [ìyẹn ni, àwọn àgbéjáde onímìísí àìmọ́] jẹ́ àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì, wọ́n sì jáde lọ bá àwọn ọba [ìyẹn ni, àwọn olùṣàkóso ìṣèlú] gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá, láti kó wọn jọ pa pọ̀ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè. Wọ́n sì kó wọn jọ pa pọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”
12. Báwo ni Amágẹ́dọ́nì yóò ṣe rí?
12 Báwo ni Amágẹ́dọ́nì yóò ṣe rí? Kì yóò dà bí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti átọ́míìkì tàbí ìjàǹbá tí aráyé ṣokùnfà. Rárá o, èyí jẹ́ ogun Ọlọ́run tí yóò fòpin sí gbogbo ogun tí ẹ̀dá ènìyàn ń jà, tí yóò sì fòpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ogun lárugẹ. Èyí jẹ́ ogun Ọlọ́run tí yóò mú àlàáfíà tòótọ́ wá fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. Bẹ́ẹ̀ ni, Amágẹ́dọ́nì ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣèlérí. Kì yóò pẹ́. A mí sí wòlíì rẹ̀ Hábákúkù láti kọ̀wé pé: “Ìran náà jẹ́ ti ìgbà kan tí a yàn, yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn, kì yóò sì ṣèké, bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Nítorí ìmọ̀lára wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ó lè jọ bíi pé ó ti pẹ́ jù, ṣùgbọ́n Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìṣètò àkókò tí ó ti ṣe. Amágẹ́dọ́nì yóò dé ní wákàtí náà gan-an tí Jèhófà ti pinnu tẹ́lẹ̀.
13. Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe rí sí ọ̀daràn náà gan-an, Sátánì Èṣù?
13 Ìgbésẹ̀ gúnmọ́ yìí yóò pa ọ̀nà mọ́ fún àlàáfíà tòótọ́! Ṣùgbọ́n kí àlàáfíà tòótọ́ tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ohun kan tún wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe—mímú ẹni tí ń fa ìyapa, ìkórìíra, àti gbọ́nmi-si-omi-ò-to kúrò. Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ gan-an nìyẹn pé yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e—gbígbé Sátánì, ẹni tí ń dá ogun sílẹ̀ àti bàbá irọ́, jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìṣẹ̀lẹ̀ yí nínú ìran alásọtẹ́lẹ̀ kan, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Ìṣípayá 20:1-3 pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà ó sì tì í ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má baà ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin.”
14. Báwo ni a ṣe lè ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ oníjagunmólú Jèhófà sí Sátánì?
14 Èyí kì í ṣe àlá lásán; ìlérí Ọlọ́run ni—Bíbélì sì sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi lè sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀, Jeremáyà, pé: “Èmi ni Olúwa, tí ń ṣe àánú àti ìdájọ́ àti òdodo ní ayé: nítorí inú mí dùn nínú ohun wọ̀nyí, ni Olúwa wí.” (Jeremáyà 9:24) Jèhófà ń gbégbèésẹ̀ ní ìdájọ́ àti ní òdodo, inú rẹ̀ sì ń dùn sí àlàáfíà tí òun yóò mú wá sí ilẹ̀ ayé.
Ìṣàkóso Láti Ọwọ́ Ọmọ Aládé Àlàáfíà
15, 16. (a) Ta ni Jèhófà yàn láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba? (b) Báwo ni a ṣe ṣàpèjúwe àkóso yẹn, àwọn wo ni yóò sì ṣàjọpín nínú rẹ̀?
15 Láti rí i dájú pé àlàáfíà tòótọ́ yóò wà fún gbogbo àwọn tí ń gbé lábẹ́ ìṣètò Ìjọba rẹ̀, Jèhófà ti fi àkóso náà lé ọwọ́ Ọmọ Aládé Àlàáfíà tòótọ́ náà, Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ní Aísáyà 9:6, 7, pé: “A bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa: ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Bàbá Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ìjọba yóò bí sí i, àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun . . . Ìtara Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Onísáàmù náà pẹ̀lú kọ̀wé alásọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso alálàáfíà ti Mèsáyà náà, pé: “Ní ọjọ́ rẹ̀ ni àwọn olódodo yóò gbilẹ̀: àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà níwọ̀n bí òṣùpá yóò ti pẹ́ tó.”—Orin Dáfídì 72:7.
16 Ní àfikún sí i, àwọn 144,000 ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi yóò máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyí ni ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, àwọn tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé: “Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà yóò tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́ láìjìnnà. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù wà pẹ̀lú yín.” (Róòmù 16:20) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn wọ̀nyí yóò nípìn-ín látọ̀run pẹ̀lú Kristi nínú ìṣẹ́gun lórí Sátánì Èṣù, arógunyọ̀!
17. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún àlàáfíà tòótọ́?
17 Wàyí o, ìbéèrè náà ni pé, Kí ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún àlàáfíà tòótọ́? Kìkì lọ́nà ti Ọlọ́run nìkan ni àlàáfíà tòótọ́ lè gbà wá, láti jèrè rẹ̀, ìwọ gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tí ó tọ́. O gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba Ọmọ Aládé Àlàáfíà náà, kí o sì yíjú sí i. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, o gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba Kristi nínú ipa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùdáǹdè àti Olùràpadà ìran ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. Jésù fúnra rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ olókìkí náà pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà pa run ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ìwọ ha ti ṣe tán láti lo ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Ọlọ́run fún mímú àlàáfíà tòótọ́ àti ìgbàlà wá bí? Kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí ó lè fìdí àlàáfíà múlẹ̀, kí ó sì mú un dáni lójú. (Fílípì 2:8-11) Èé ṣe? Nítorí Jésù ni Àyànfẹ́ Ọlọ́run. Òun ni ońṣẹ́ àlàáfíà títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé orí ilẹ̀ ayé rí. Ìwọ yóò ha fetí sílẹ̀ sí Jésù, kí o sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bí?
18. Kí ni a ní láti ṣe ní ìdáhùnpadà sí ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Jòhánù 17:3?
18 Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ìsinsìnyí ni àkókò láti gba ìmọ̀ pípéye sínú nípa lílọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ìpàdé tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí yóò sún ọ láti ṣàjọpín ìmọ̀ rẹ àti ìrètí rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìwọ pẹ̀lú lè di aṣojú fún àlàáfíà Ọlọ́run. O lè gbádùn àlàáfíà nísinsìnyí nípa gbígbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní Aísáyà 26:3, ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ New International Version, pé: “Ìwọ yóò pa ẹni tí èrò inú rẹ̀ dúró ṣinṣin mọ́ ní àlàáfíà pípé, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” Ta ni ó yẹ kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé? “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin wà.”—Aísáyà 26:4, NW.
19, 20. Kí ní ń dúró de àwọn tí ń wá àlàáfíà, tí wọ́n sì ń lépa rẹ̀ lónìí?
19 Mú ìdúró rẹ fún ìyè ayérayé nínú ayé tuntun alálàáfíà ti Ọlọ́run. Ní Ìṣípayá 21:3, 4, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, òun yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Kì í ha ṣe ọjọ́ ọ̀la alálàáfíà tí o ń yán hànhàn fún nìyẹn bí?
20 Nígbà náà, rántí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. Máa kíyè sí ẹni pípé, kí o sì máa wo ẹni dídúró ṣinṣin: nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.” (Orin Dáfídì 37:11, 37) Nígbà tí ọjọ́ aláyọ̀ yẹn bá dé, ǹjẹ́ kí a lè sọ pẹ̀lú ọpẹ́ pé, “Àlàáfíà tòótọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín! Ọpẹ́ ni fún Jèhófà Ọlọ́run, orísun àlàáfíà tòótọ́!”
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ní lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣèyípadà nínú èrò àti ìwà rẹ̀?
◻ Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀, ṣe fi ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àlàáfíà tòótọ́ hàn?
◻ Báwo ni Jèhófà yóò ṣe rí sí gbogbo àwọn tí ń gbé ìkórìíra àti ogun lárugẹ?
◻ Kí ni àkóso Ọmọ Aládé Àlàáfíà yóò ṣe fún aráyé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Kì í ṣe àjọ UN ni ó ń mú ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ, bí kò ṣe àwọn tí ó dáhùn pa dà sí ẹ̀kọ́ Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí ṣe ìyípadà láti lépa àlàáfíà
Rami Oved
Georg Reuter
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àlàáfíà tòótọ́ yóò gbilẹ̀ lábẹ́ àkóso Ọmọ Aládé Àlàáfíà