Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run”
INÚ RERE. Àánú. Ìdáríjì. Ìfẹ́. Ó ṣeni láàánú pé ìwọ̀nba làwọn tó ń fàwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣèwà hù lónìí. Ìwọ ńkọ́? Ṣó ti ṣe ẹ́ rí pé pẹ̀lú bó o ṣe ń gbìyànjú tó láti máa fàwọn ànímọ́ yìí ṣèwà hù, pàbó ló ń já sí? Tó o bá ti rora ẹ pin, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn ìwàkiwà tó ti di bárakú tàbí ohun ìbànújẹ́ kan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ sẹ́yìn ò ní jẹ́ kó o lè fàwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ ẹ wọ̀nyẹn ṣèwà hù. Síbẹ̀, òótọ́ kan tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì kọ́ wa ni pé, Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pé fífi àwọn ànímọ́ dáadáa wọ̀nyí ṣèwà hù ò kọjá agbára wa.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gba àwọn Kristẹni tòótọ́ níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé Ọlọ́run ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn tó ń sìn ín. Lọ́nà wo? Jèhófà Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ dá àwọn ànímọ́ bíi tirẹ̀ mọ́ àwa èèyàn.a Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “di aláfarawé Ọlọ́run,” ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ń sọ fún wọn pé: ‘Mo gba ẹ̀rí yín jẹ́. Mo mọ̀ lóòótọ́ pé aláìpé ni yín, àmọ́ ẹ ṣì lè fìwà jọ mí dé àyè kan.’
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá a lè máa fi ṣèwà hù? Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú Éfésù 5:1 àtèyí tó tẹ̀ lé e dáhùn ìbéèrè yìí. Kíyè sí i pé “nítorí náà” ni Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó ti sọ pé ká fara wé Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ti ń bọ́rọ̀ bọ̀ láti ẹsẹ tó ṣáájú níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa inú rere, ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìdáríjì. (Éfésù 4:32; 5:1) Lẹ́yìn náà, nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n fara wé Ọlọ́run, ó sọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá. (Éfésù 5:2) Ká sòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ká finú rere hàn sáwọn èèyàn, ká ṣàánú wọn, ká dárí jì wọ́n fàlàlà, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn, Jèhófà Ọlọ́run ni àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ tá a lè fara wé.
Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti dà bí Ọlọ́run? Kíyè sí ohun pàtàkì tó máa jẹ́ ká fẹ́ dà bí Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó ní: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Ọ̀rọ̀ yìí mà wọni lọ́kàn o. Jèhófà ń fojú ọmọ tó fẹ́ràn gan-an wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí ọmọkùnrin kékeré kan ṣe máa ń fẹ́ láti dà bíi bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́, làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti dà bíi Bàbá wọn ọ̀run.
Jèhófà ò fipá mú àwọn èèyàn láti fara wé òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wa lómìnira láti máa ṣe ohun tó bá wù wá. Nítorí náà, ọwọ́ rẹ ló kù sí bóyá wàá máa fara wé Ọlọ́run tàbí o ò ní fara wé e. (Diutarónómì 30:19, 20) Àmọ́, má gbàgbé pé fífi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù ò kọjá agbára rẹ. Kó o tó lè fara wé Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ irú ẹni tó jẹ́. Bíbélì máa jẹ́ kó o mọ gbogbo ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ tí ò láfiwé. Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò láfiwé sì ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa fara wé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Kólósè 3:9, 10 jẹ́ ká mọ̀ pé dídá tá a dá wa ní àwòrán Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìwà àbínibí. Bíbélì rọ àwọn tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn pé kí wọ́n máa fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” ṣèwà hù, èyí tó máa sọ wọ́n “di tuntun . . . ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán [Ọlọ́run] tí ó dá” wọn.