Ojú Ìwòye Bíbélì
Ọ̀nà Wo Ni Ọkọ Gbà Jẹ́ Orí Aya?
NÍGBÀ tí wọ́n bá ń ṣayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́nà ti ìbílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìyàwó sábà máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ fọ́kọ pé òun á máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ obìnrin ni kì í fẹ́ gbọ́ pé ọkọ lorí aya, ńṣe ló máa ń ta létí wọn. Torí náà, jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yìí. Wàá rí i pé Ọlọ́run ò pọ̀n síbì kan lórí ọ̀ràn náà, kò sì séyìí tó ṣeé kó dà nù nínú ohun tó sọ.
Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Fẹ́ Kí Ọkọ Gbà Jẹ́ Orí Aya
Ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ kí ọkọ gbà jẹ́ orí aya wà nínú Éfésù 5:22-24, èyí tó kà pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ . . . Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya pẹ̀lú wà fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo.” Gẹ́gẹ́ bí “orí aya rẹ̀,” ọkọ ló yẹ kó máa wakọ̀ ìdílé, kí aya rẹ̀ máa tì í lẹ́yìn, kó sì máa bọ̀wọ̀ fún un.—Éfésù 5:33.
Àmọ́, ó níbi tí àṣẹ ọkọ mọ o, nítorí pé ó tún yẹ kóhun náà máa tẹrí ba fún Ọlọ́run àti Kristi. Kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé kó rú òfin Ọlọ́run tàbí pé kó ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́. Síbẹ̀, pẹ̀lú ìwọ̀nba agbára tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ yìí, ojúṣe rẹ̀ ni pé kó máa ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì fún ìdílé rẹ̀.—Róòmù 7:2; 1 Kọ́ríńtì 11:3.
Bíbélì pàṣẹ pé kí ọkọ má ṣe jẹ́ onímọ-tara-ẹni-nìkan nínú ọ̀nà tó ń gbà ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orí aya, kó sì kọ́kọ́ máa mú taya ẹ̀ gbọ́. Ó sọ nínú Éfésù 5:25 pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” Ọkọ tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ dídára jù lọ tí Kristi fi lélẹ̀ ò ní máa kó ìyàwó rẹ̀ nífà nítorí pé ó jẹ́ orí rẹ̀.
Síwájú sí i, Bíbélì tún gba ọkọ níyànjú pé kó máa bá aya rẹ̀ gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀.” (1 Pétérù 3:7) Káwọn ọkọ wulẹ̀ mọ̀ pé àwọn obìnrin jẹ́ ẹlẹgẹ́ àti pé nǹkan tètè máa ń dùn wọ́n lọ́kàn ju àwọn ọkùnrin lọ nìkan kọ́ lèyí túmọ̀ sí o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ máa fòye mọ àwọn nǹkan tí aya rẹ̀ ń fẹ́.
“Òun Ni Ẹnì Kejì Rẹ”
Ǹjẹ́ ìtẹríba aya fún ọkọ túmọ̀ sí pé kó ṣáà máa wò duu láìsọ̀rọ̀? Jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nípa èyí nínú àpẹẹrẹ ti Sárà tí Bíbélì sọ fún wa pó ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀, Ábúráhámù. (1 Pétérù 3:5, 6) Ó tẹrí ba fún un nínú àwọn ọ̀ràn ńlá àti nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké. Nígbà tọ́kọ ẹ̀ fi tilé-tọ̀nà sílẹ̀ tó ń lọ gbé káàkiri nínú àgọ́, tòun tiẹ̀ ni. Níjọ́ tọ́kọ ẹ̀ sì sọ fún un ní pàpà jájá pé kó gbọ́únjẹ fáwọn àlejò, kíá ló gba ìdí ààrò lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 12:5-9; 18:6) Àmọ́, nígbà tí ọ̀rọ̀ kan ṣe bí ọ̀rọ̀, kò yé sọ tẹnu ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ ni ibi tọ́kọ ẹ̀ ro ọ̀rọ̀ náà gbà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Sárà fẹ́ kí Ábúráhámù lé ìránṣẹ́bìnrin òun Hágárì àti àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìyẹn Íṣímáẹ́lì jáde. Dípò kí Ọlọ́run bá Sárà wí, ó sọ fún Ábúráhámù pé kó “fetí sí ohùn rẹ̀.” Ìyẹn ò sì ní kí Sárà dọ́wọ́ wú, kó wá lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì jáde fúnra ẹ̀. Ńṣe ló ń bá a nìṣó láti máa tẹrí ba fún Ábúráhámù títí tó fi lé obìnrin náà àtọmọ rẹ̀ jáde.—Jẹ́nẹ́sísì 21:8-14.
Àpẹẹrẹ ti Sárà yìí jẹ́ ká rí i pé dípò kí obìnrin wulẹ̀ máa gbé bí olúńdù lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ẹ̀, “ẹnì kejì” ọkọ ẹ̀ ló jẹ́, nítorí náà ipò iyì ni Ọlọ́run tò ó sí lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ. (Málákì 2:14) Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kejì ọkọ, òun náà á máa dá sí ọ̀rọ̀ tí ìdílé bá fẹ́ ṣèpinnu lé lórí, àwọn nǹkan kan sì wà tóun náà lè máa bójú tó, bíi títọ́jú ilé àti ríra àwọn nǹkan tí ìdílé bá nílò. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí orí aya, ọkọ lá máa fàṣẹ sí gbogbo ìpinnu tí ìdílé bá ṣe.—Òwe 31:10-31; 1 Tímótì 5:14.
Ọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá
Jèhófà Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ṣètò pé kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan nínú ìdè ìgbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24) Lẹ́yìn náà ló wá la ojúṣe tó máa mú kí tọkọtaya ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ayọ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún wọn.—Diutarónómì 24:5; Òwe 5:18.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé ìlànà tí tọkọtaya á máa tẹ̀ lé kalẹ̀, ó sì tún lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí tọkọtaya bá ń ṣe ojúṣe wọn, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run pé ọkọ ni orí aya, tí wọn ò sì ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì nítorí pé ìlànà náà dára, àmọ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Ọlọ́run, wọ́n á rí ojú rere rẹ̀, kò sì ní padà lẹ́yìn wọn.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Ta ló fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ nípa ọ̀nà tó yẹ kí ọkọ gbà jẹ́ orí aya?—Éfésù 5:25.
◼ Ǹjẹ́ ó níbi tí àṣẹ ọkọ mọ?—1 Kọ́ríńtì 11:3.
◼ Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ tó sì fi ọkọ ṣe orí aya?—Òwe 5:18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bí ọkọ bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nínú ọ̀nà tó ń gbà ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orí aya, àwọn méjèèjì á máa láyọ̀, ọkàn wọn á sì balẹ̀