Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Àti Ọ̀wọ̀ Hàn Fún Ara Yín Nípa Kíkó Ahọ́n Yín Níjàánu
“Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—ÉFÉSÙ 5:33.
1, 2. Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ kí gbogbo àwọn tó bá ti ṣègbéyàwó bi ara wọn, kí sì nìdí rẹ̀?
KÁ NÍ wọ́n fi ẹ̀bùn kan tí wọ́n dì sínú ohun kan ránṣẹ́ sí ọ, tí wọ́n sì kọ ọ́ sára rẹ̀ pé: “Ohun Ẹlẹgẹ́ Ni O.” Báwo lo ṣe máa ṣe ẹ̀bùn ọ̀hún? Ó dájú pé ńṣe lo máa rọra gbé e nítorí o ò ní fẹ́ kí nǹkan kan ṣe é. Ǹjẹ́ irú ọwọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ ló yẹ kó o fi mú ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn?
2 Opó ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Náómì sọ fáwọn obìnrin méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Ópà àti Rúùtù pé: “Kí Jèhófà fún yín ní ẹ̀bùn, kí ẹ sì rí ibi ìsinmi, olúkúlùkù ní ilé ọkọ rẹ̀.” (Rúùtù 1:3-9) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa aya rere, ó sọ pé: “Ogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ni ilé àti ọlà, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá.” (Òwe 19:14) Tó o bá ti ṣègbéyàwó, ó yẹ kó o wo ọkọ tàbí aya rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Irú ọwọ́ wo lo fi ń mú ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ọ yìí?
3. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wo ló yẹ káwọn ọkọ àtàwọn aya máa tẹ̀ lé?
3 Nínú ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ó ní: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ọkọ àtàwọn aya ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò tó bá dọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa lo ahọ́n wọn.
Ṣọ́ra fún “Ohun Ewèlè Tí Ń Ṣeni Léṣe”
4. Báwo ni ahọ́n ṣe jẹ́ ohun tó lè ṣe rere tó sì lè ṣe ibi?
4 Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé ahọ́n jẹ́ “ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe” tó “kún fún panipani májèlé.” (Jákọ́bù 3:8) Jákọ́bù mọ̀ dájú pé téèyàn ò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó lè ba nǹkan jẹ́. Láìsí àní-àní, Jákọ́bù mọ òwe Bíbélì náà tó fi ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú wé “ìgúnni idà.” Ṣùgbọ́n, òwe yẹn kan náà sọ pé “ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Èyí fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ lágbára. Ó lè gúnni bí idà, ó sì lè gbéni ró. Ibo ni ọ̀rọ̀ rẹ máa ń bọ́ sí lára ọkọ tàbí aya rẹ? Tí ìwọ ọkọ bá bi aya rẹ ní ìbéèrè yẹn, tí ìwọ aya sì bi ọkọ rẹ, kí ló máa sọ?
5, 6. Kí làwọn nǹkan tó mú kó nira fáwọn kan láti kó ahọ́n wọn níjàánu?
5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ti mọ́ ọ lára láti máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ọkọ tàbí aya rẹ, o ṣì lè ṣàtúnṣe. Àmọ́, o ní láti sapá gidigidi kí èyí tó lè ṣeé ṣe. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, àìpé ara yóò fẹ́ máa lò ẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ló fà á téèyàn fi ń ro èròkérò nípa ẹlòmíì, téèyàn sì fi ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí ẹlòmíì. Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.”—Jákọ́bù 3:2.
6 Yàtọ̀ sí jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, ìdílé téèyàn ti dàgbà tún lè jẹ́ kó nira fúnni láti kó ahọ́n ẹni níjàánu. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn jẹ́ ‘aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu àti òǹrorò.’ (2 Tímótì 3:1-3) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé irú ìwà báwọ̀nyí làwọn ọmọ tí wọ́n bí sírú ìdílé bẹ́ẹ̀ sábà máa ń hù nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ tìtorí pé a jẹ́ aláìpé tàbí torí pé a ò rẹ́ni tọ́ wa dáadáa ká wá máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ọkọ tàbí aya wa. Ṣùgbọ́n, mímọ̀ tá a bá mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí á jẹ́ ká lè mọ ìdí tó fi nira gan-an fáwọn kan láti kó ahọ́n wọn níjàánu kí wọ́n má máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀.
‘Ẹ Mú Ìsọ̀rọ̀ Ẹni Lẹ́yìn Kúrò’
7. Kí ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n ‘mú gbogbo onírúurú ìsọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn kúrò’?
7 Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, tẹ́nì kan bá ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀, èyí lè fi hàn pé onítọ̀hún ò nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ̀ kò sì bọ̀wọ̀ fún un. Ìdí rèé tí Pétérù fi gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n ‘mú gbogbo onírúurú ìsọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn kúrò.’ (1 Pétérù 2:1) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìsọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn” túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀ èébú.” Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ mọ́ ‘sísọ òkò ọ̀rọ̀ luni.’ Àbẹ́ ò rí nǹkan, ohun tí ahọ́n téèyàn ò bá kó níjàánu máa ń ṣe nìyẹn!
8, 9. Kí ló lè jẹ́ àbájáde ọ̀rọ̀ èébú, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kí ọkọ àti aya máa sọ̀rọ̀ èébú síra wọn?
8 Ọ̀rọ̀ èébú lè dà bí nǹkan kékeré lójú ẹni, àmọ́ ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kan bá ń bú ọkọ tàbí aya rẹ̀. Téèyàn bá ń pe ọkọ tàbí aya ẹ̀ ní ọ̀dẹ̀, ọ̀lẹ tàbí onímọtara-ẹni-nìkan, ohun téèyàn ń fìyẹn sọ ni pé irú ẹni tí ọkọ tàbí aya òun jẹ́ gan-an nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ìwọ̀sí gbáà ni irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́! Kò dáa rárá kéèyàn máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ọkọ tàbí aya ẹni. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fẹ kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kejì lójú ńkọ́? Ǹjẹ́ kì í ṣe àbùmọ́ téèyàn bá ń lo àwọn gbólóhùn bíi “O ò kì í ṣe nǹkan lákòókò láyé yìí” tàbí “O ò tíì tẹ́tí gbọ́rọ̀ mi rí”? Kò sẹ́ni tí wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí tí ò ní fẹ́ gbèjà ara rẹ̀ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí. Tó bá sì wá fèsì, ọ̀rọ̀ ọ̀hún lè di ariwo.—Jákọ́bù 3:5.
9 Tí ọkọ àti aya bá ń fi èébú sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ síra wọn, àjọṣe wọn ò ní dán mọ́rán, èyí sì lè ṣàkóbá tó pọ̀. Ìwé Òwe 25:24 sọ pé: “Ó sàn láti máa gbé lórí igun òrùlé ju láti máa gbé pẹ̀lú aya alásọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ nínú ilé kan náà.” Bọ́rọ̀ ṣe máa rí náà nìyẹn tí ọkọ bá jẹ́ alásọ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, kòbákùngbé ọ̀rọ̀ tí ọkọ ń sọ sí aya tàbí tí aya ń sọ sí ọkọ kò ní jẹ́ kí àárín wọn gún mọ́, ó tiẹ̀ lè mú kí ọ̀kan lára wọn máa ronú pé ọkọ tàbí aya òun kò fẹ́ràn òun àti pé òun ò tiẹ̀ yẹ lẹ́ni táwọn èèyàn ń fẹ́ràn. Ẹ lè wá rí i báyìí pé ó ṣe pàtàkì kí ọkọ àti aya máa kó ahọ́n wọn níjàánu. Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe èyí?
Ẹ ‘Kó Ahọ́n Yín Níjàánu’
10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kó ahọ́n wa níjàánu?
10 Jákọ́bù 3:8 sọ pé: “Ahọ́n, kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú.” Síbẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń gẹṣin ṣe máa ń fi ìjánu sẹ́nu ẹṣin láti fi darí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti kó ahọ́n wa níjàánu. Bíbélì sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” (Jákọ́bù 1:26; 3:2, 3) Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí fi hàn pé o ò gbọ́dọ̀ fojú kékeré wo ọ̀nà tó o gbà ń lo ahọ́n rẹ. Kì í ṣe àjọṣe ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ nìkan ló máa ṣàkóbá fún, ó tún lè ṣàkóbá fún àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run.—1 Pétérù 3:7.
11. Kí ni ọkọ àti aya lè ṣe tí èdèkòyédè tó bá wáyé kò fi ní di ńlá?
11 Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o kíyè sí bó o ṣe máa ń bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín yín, ẹ fi sùúrù yanjú ẹ̀. Wo ohun kan tó ṣẹlẹ̀ láàárín Ísákì àti Rèbékà aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 27:46 sí 28:4 ṣe sọ. “Rèbékà ń wí ṣáá fún Ísákì pé: ‘Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì bí ìwọ̀nyí nínú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?’” Kò sóhun tó fi hàn pé Ísákì gbaná jẹ nítorí ọ̀rọ̀ tí aya rẹ̀ sọ yìí. Dípò ìyẹn, ńṣe ló rán Jákọ́bù ọmọ wọn lọ sọ́nà jíjìn kó lè lọ wá ìyàwó tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí kò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá Rèbékà. Ká sọ pé èdèkòyédè wáyé láàárín ọkọ àti aya ńkọ́? Ohun kan tí ò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di ńlá ni pé dípò tí wọ́n á fi máa dá ara wọn lẹ́bi, ńṣe ló yẹ kí wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ohun tó fa ìṣòro ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ pé, “Mi ò kì í rójú yín nílẹ̀!” ohun tó máa dára kó o sọ ni pé, “Ì bá mà dára o tá a bá lè jọ máa jókòó sọ̀rọ̀ ká sì jọ máa ṣeré.” Ohun tó fa èdèkòyédè náà ni kẹ́ ẹ jọ wá ojútùú sí, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ máa wá sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ síra yin. Ẹ gbàgbé ọ̀rọ̀ èmi-ni-mo-jàre ìwọ-lo-jẹ̀bi. Róòmù 14:19 sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”
‘Ẹ Mú Ìwà Kíkorò Onínú Burúkú, Ìbínú àti Ìrunú Kúrò’
12. Tá a bá fẹ́ kó ahọ́n wa níjàánu, kí ló yẹ ká gbàdúrà fún, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
12 Yàtọ̀ sí pé kéèyàn ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀, ohun mìíràn tún wà tá a ní láti ṣe tá a bá fẹ́ kó ahọ́n wa níjàánu. Ó ṣe tán, ohun tí ń bẹ lọ́kàn èèyàn lèèyàn ń sọ jáde lẹ́nu. Jésù sọ pé: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Nítorí náà, tó o bá fẹ́ kó ahọ́n rẹ níjàánu, o lè gba irú àdúrà tí Dáfídì gbà pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.”—Sáàmù 51:10.
13. Báwo ni ìwà kíkorò onínú burúkú, ìbínú àti ìrunú ṣe lè yọrí sí ọ̀rọ̀ èébú?
13 Yàtọ̀ sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Éfésù pé kí wọ́n má máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ síra wọn, ó tún ní kí wọ́n mú èrò tó lè mú kí wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn wọn. Ó ní: “Ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) Kíyè sí i pé “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú” ni Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ mẹ́nu kàn kó tó mẹ́nu kan “ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” Ohun tó ń jà gùdù nínú èèyàn ló máa ń múni sọ̀rọ̀ burúkú jáde lẹ́nu. Nítorí náà, bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń fi ẹnì kejì mi sínú, ǹjẹ́ inú ẹ̀ sì máa ń bí mi? Ǹjẹ́ mo máa ń “fi ara [mi] fún ìhónú”?’ (Òwe 29:22) Tó bá jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ọ́, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè fi irú ìwà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ kó o sì lè máa kó ara rẹ níjàánu kó má bàa di pé ò ń fa ìbínú yọ. Sáàmù 4:4 sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” Tó o bá rí i pé inú rẹ fẹ́ máa ru tó o sì mọ̀ pé o ò ní lè kó ara rẹ níjàánu, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe 17:14, tó sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Á dára kó o fibẹ̀ sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ títí dìgbà tí inú rẹ á fi rọlẹ̀.
14. Tí ọkọ àti aya bá ń ní ara wọn sínú, àkóbá wo nìyẹn lè ṣe fún wọn?
14 Kò rọrùn láti yẹra fún ìrunú àti ìbínú, àgàgà tó bá lọ jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “ìwà kíkorò onínú burúkú” ló fà á. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí túmọ̀ sí “kéèyàn bínú sí ẹlòmíràn kó má sì fẹ́ dárí ji onítọ̀hún,” àti ‘kéèyàn ní ẹnì kan sínú kó sì máa ka ẹ̀sùn sí i lọ́rùn.’ Nígbà míì, ọkọ àti aya lè máa bínú síra wọn, kí èyí sì máa bá a lọ fún ìgbà pípẹ́. Tí wọn ò bá yanjú ẹ̀, ó lè yọrí sí pé kí wọ́n máa kanra mọ́ra wọn. Àmọ́, kò sí èrè kankan nínú kí ọkọ àtìyàwó máa ní ara wọn sínú. Ohun tí ì báà ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ná. Torí náà, tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá ṣẹ̀ ọ́ tó o sì ti dárí jì í, ńṣe ni kó o gbàgbé ọ̀rọ̀ náà. Ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
15. Kí ló máa ran àwọn tó ti mọ́ lára láti máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ luni lọ́wọ́ láti yí padà?
15 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹ máa ń sọ òkò ọ̀rọ̀ lura yín nínú ìdílé tó o ti dàgbà, tí ìyẹn sì ti mọ́ ọ lára ńkọ́? O ṣì lè yí padà. Ó dájú pé àwọn ohun kan wà tí wàá ti pinnu pé o ò ní jẹ́ dán wò láyé rẹ. Tó bá wá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kó o lo ahọ́n rẹ ńkọ́? Ṣé wàá lè kó ahọ́n rẹ níjàánu kó o má bàa sọ̀rọ̀ èébú? Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Éfésù 4:29, tó sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.” Láti lè ṣe ohun tí ẹsẹ yẹn sọ, o ní láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, [kí o] sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara [rẹ] láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.”—Kólósè 3:9, 10.
“Ọ̀rọ̀ Ìfinúkonú” Ṣe Pàtàkì, Ó Ṣe Kókó
16. Kí nìdí tí kò fi dára kí ẹnì kan máa bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ yodì?
16 Kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn máa bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ yodì, àní irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè ba nǹkan jẹ́. Nígbà míì, tí ẹnì kan ò bá bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó lè máà jẹ́ pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ pé ìjákulẹ̀ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ló fà á. Àmọ́, tẹ́ ẹ bá ń bá ara yín yodì, ńṣe nìyẹn máa jẹ́ kí ìṣòro ọ̀hún le sí i tí kò sì ní yanjú. Ìyàwó ilé kan sọ pé, “tí èmi àti ọkọ mi bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wa sọ̀rọ̀ padà, a kì í sọ̀rọ̀ lọ síbi ìṣòro ọ̀hún mọ́.”
17. Kí ló yẹ kí àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni ṣe tí èdèkòyédè bá wà láàárín wọn?
17 Tí èdèkòyédè tó wà láàárín yín ò bá yanjú, ọ̀nà kan ṣoṣo tẹ́ ẹ lè gbà yanjú ẹ̀ ni pé kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jọ jókòó sọ ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tẹ́ ẹ bá sì ń sọ̀rọ̀ ọ̀hún, ẹ fetí sílẹ̀ sí ara yín láìsí pé ẹnì kan ń ta ko ẹnì kejì. Ìwé Òwe 15:22 sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Tó bá sì wá dà bíi pé kò ṣeé ṣe fún yín láti jọ sọ̀rọ̀ ọ̀hún, ǹjẹ́ ẹ lè fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn alàgbà ìjọ? Àwọn alàgbà wọ̀nyí ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, wọ́n mọ béèyàn ṣe ń fi ìlànà Bíbélì yanjú ìṣòro. Ńṣe ni wọ́n “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.”—Aísáyà 32:2.
O Lè Kó Ahọ́n Rẹ Níjàánu
18. Ìjàkadì wo ni Róòmù 7:18-23 sọ̀rọ̀ ẹ̀?
18 Kò rọrùn láti kó ahọ́n ẹni níjàánu o. Bákan náà, kò rọrùn láti kó ara wa níjàánu. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ ohun tójú ẹ̀ rí lórí ọ̀rọ̀ kíkó ara ẹni níjàánu, ó ní: “Mo mọ̀ pé nínú mi, èyíinì ni, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀; nítorí agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù. Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé ohun tí èmi kò fẹ́ ni èmi ń ṣe, ẹni tí ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.” Nítorí “òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara [wa]” la ṣe ń ṣi ahọ́n wa àtàwọn ẹ̀yà ara wa mìíràn lò. (Róòmù 7:18-23) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó borí wa. A sì lè borí rẹ̀ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.
19, 20. Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti kó ahọ́n wọn níjàánu?
19 Níbi tí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá wà, kò yẹ kó sí kòbákùngbé ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ tó ń gúnni bí idà níbẹ̀. Ronú nípa àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Jésù ò sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí. Kódà lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù máa kú táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń bára wọn jiyàn lórí ẹni tí yóò jẹ́ olórí, Ọmọ Ọlọ́run ò nà wọ́n ní pàṣán ọ̀rọ̀. (Lúùkù 22:24-27) Bíbélì gba àwọn ọkọ nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.”—Éfésù 5:25.
20 Àmọ́, aya ńkọ́? Aya ní láti “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Ǹjẹ́ aya tó bá bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ yóò máa jágbe mọ́ ọn tàbí kó máa bú u? Rárá o. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Àwọn aya ní láti tẹrí ba fún ẹni tó jẹ́ orí wọn gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe tẹrí ba fún ẹni tó jẹ́ orí rẹ̀. (Kólósè 3:18) Òótọ́ ni pé kò sí ẹ̀dá aláìpé tó lè ṣe bíi Jésù gẹ́lẹ́, àmọ́ táwọn ọkọ àtàwọn aya bá gbìyànjú láti máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ [Jésù] pẹ́kípẹ́kí,” wọ́n á lè kó ahọ́n wọn níjàánu.—1 Pétérù 2:21.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Bí ọkọ àti aya ò bá kó ahọ́n wọn níjàánu, báwo nìyẹn ṣe lè da àárín wọn rú?
• Kí ló mú kó ṣòro láti kó ahọ́n ẹni níjàánu?
• Kí ló máa jẹ́ ká lè kó ahọ́n wa níjàánu?
• Kí ló yẹ kó o ṣe tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn alàgbà máa ń lo Bíbélì láti fi ranni lọ́wọ́