Ìwé Kìíní Pétérù
3 Bákan náà, kí ẹ̀yin aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín,+ kó lè jẹ́ pé, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tí kò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, a máa lè jèrè wọn nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn+ láìsọ ohunkóhun, 2 torí pé wọ́n fojú rí ìwà mímọ́ yín+ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀. 3 Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara, bí irun dídì, wíwọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà+ tàbí wíwọ àwọn aṣọ olówó ńlá, 4 àmọ́ kó jẹ́ ti ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn, kí ẹ fi ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù ṣe ọ̀ṣọ́ tí kò lè bà jẹ́,+ èyí tó níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run. 5 Torí pé báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ṣe máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn, 6 bí Sérà ṣe ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, tó ń pè é ní olúwa.+ Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀, tí ẹ bá ń ṣe ohun tó dáa, tí ẹ ò sì bẹ̀rù.+
7 Bákan náà, kí ẹ̀yin ọkọ máa fi òye bá wọn gbé.* Ẹ máa bọlá fún wọn+ bí ohun èlò ẹlẹgẹ́, tó jẹ́ abo, torí ẹ jọ jẹ́ ajogún+ ojúure ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.
8 Lákòótán, kí èrò gbogbo yín ṣọ̀kan,*+ kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú,+ kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.+ 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú,+ ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre,+ torí ọ̀nà yìí la pè yín sí, kí ẹ lè jogún ìbùkún.
10 Torí “ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ìgbésí ayé rẹ̀, tó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn gbọ́dọ̀ ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ kó má bàa sọ ohun búburú,+ kó má sì fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀tàn. 11 Kí ó jáwọ́ nínú ohun búburú,+ kó sì máa ṣe rere;+ kó máa wá àlàáfíà, kó sì máa lépa rẹ̀.+ 12 Nítorí ojú Jèhófà* wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ àmọ́ Jèhófà* kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”+
13 Lóòótọ́, ta ló máa ṣe yín léṣe tí ẹ bá ń fi ìtara ṣe ohun rere?+ 14 Síbẹ̀, tí ẹ bá tiẹ̀ jìyà nítorí òdodo, inú yín máa dùn.+ Àmọ́ ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń bẹ̀rù,* ẹ má sì jáyà.+ 15 Ṣùgbọ́n ẹ gbà nínú ọkàn yín pé Kristi jẹ́ mímọ́, òun ni Olúwa, kí ẹ ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà ara yín níwájú gbogbo ẹni tó bá béèrè ìdí tí ẹ fi ní ìrètí yìí, àmọ́ kí ẹ máa fi ìwà tútù+ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.+
16 Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere,+ kó lè jẹ́ pé nínú ohunkóhun tí wọ́n bá ti sọ̀rọ̀ yín láìdáa, ìwà rere tí ẹ̀ ń hù torí ẹ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi+ máa jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń sọ̀rọ̀ yín láìdáa.+ 17 Tó bá wu Ọlọ́run pé kó fàyè gbà á, ó sàn kí ẹ jìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere,+ ju kó jẹ́ torí pé ẹ̀ ń ṣe ohun tó burú.+ 18 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé,+ ó jẹ́ olódodo tó kú nítorí àwọn aláìṣòdodo,+ kó lè mú yín wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Wọ́n pa á nínú ẹran ara,+ àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.+ 19 Bẹ́ẹ̀ ló ṣe lọ wàásù fún àwọn ẹ̀mí tó wà lẹ́wọ̀n,+ 20 àwọn tó ṣàìgbọràn nígbà tí Ọlọ́run ń fi sùúrù dúró* ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ lákòókò tí wọ́n ń kan ọkọ̀ áàkì,+ tí a fi gba àwọn èèyàn díẹ̀ là nígbà ìkún omi, ìyẹn ọkàn* mẹ́jọ.+
21 Ìrìbọmi tó tún ń gbà yín là báyìí fara jọ èyí, (kì í ṣe pé ó ń wẹ èérí ara kúrò, àmọ́ ó ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run),+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi. 22 Ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ torí ó lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì, àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sí ìkáwọ́ rẹ̀.+