Orí Kọkànlélógún
Ète Jèhófà Ń Ṣàṣeyọrí Ológo
1, 2. (a) Kí ni ète Jèhófà fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè? (b) Àwọn wo ló wà nínú ìdílé àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan?
ÈTE onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní fún gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè ni pé kí wọ́n jùmọ̀ ṣọ̀kan nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, kí gbogbo wọn sì gbádùn òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ohun tí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo sì fọkàn fẹ́ nìyẹn.
2 Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí mú ète kíkọyọyọ yìí ṣẹ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ọmọ kan, tó jẹ́ pé látìgbà àjíǹde rẹ̀ ló ti di “àgbéyọ ògo [Ọlọ́run] àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà rẹ̀ gan-an” ni ó kọ́kọ́ dá. (Hébérù 1:1-3) Àkàndá ni Ọmọ yìí, nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá a. Nígbà tó bá yá, ipasẹ̀ Ọmọ yìí ni gbogbo ohun mìíràn yóò ti wá: àwọn áńgẹ́lì ọ̀run lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà àwọn ẹ̀dá ènìyàn orí ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:7; Lúùkù 3:38) Gbogbo ìwọ̀nyí ló para pọ̀ jẹ́ ìdílé àgbáyé kan. Jèhófà ni Ọlọ́run gbogbo wọn, òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run fún wọn, òun sì ni Baba wọn onífẹ̀ẹ́.
3. (a) Kí ni gbogbo wa jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́? (b) Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wo ni Jèhófà ṣe fún àtọmọdọ́mọ Ádámù?
3 Nígbà tí Ọlọ́run dájọ́ ikú fáwọn òbí wa àkọ́kọ́ tí wọ́n jẹ́ amọ̀ọ́mọ̀dẹ́ṣẹ̀, ó lé wọn jáde kúrò ní Édẹ́nì, ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Wọn kì í ṣe ara ìdílé àgbáyé rẹ̀ mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:22-24; Diutarónómì 32:4, 5) Àtọmọdọ́mọ wọn ni gbogbo wa jẹ́, nítorí náà a bí ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀ mọ́ wa. Àmọ́ Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà máa nífẹ̀ẹ́ òdodo. Nítorí náà, Ó fìfẹ́ pèsè ọ̀nà tí ọwọ́ àwọn wọ̀nyí yóò fi tẹ “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:20, 21.
Ísírẹ́lì Pàdánù Ipò Ojú Rere
4. Àǹfààní wo ni Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì?
4 Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀dá Ádámù, Jèhófà tún nawọ́ àǹfààní níní àjọṣe ara ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Òun sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan. Ó yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀, ó sì fún wọn ní Òfin rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 2) Ó fi wọ́n ṣe orílẹ̀-èdè kan, ó sì lò wọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ète rẹ̀. (Diutarónómì 14:1, 2; Aísáyà 43:1) Àmọ́, wọ́n ṣì wà nínú ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, nítorí náà, wọn ò gbádùn òmìnira ológo tí Ádámù àti Éfà gbádùn níbẹ̀rẹ̀.
5. Báwo ni Ísírẹ́lì ṣe pàdánù ipò àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
5 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní ipò ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ojúṣe wọn sì ni láti bọ̀wọ̀ fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba wọn kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ète rẹ̀. Jésù tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó fún wọn láti ṣe ojúṣe yẹn. (Mátíù 5:43-48) Àmọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kùnà láti ṣe èyí. Nígbà táwọn Júù yẹn sọ pé “Baba kan ni àwa ní, Ọlọ́run,” Jésù là á mọ́lẹ̀ pé ìṣe wọn àti irú ẹ̀mí tí wọ́n ní kò bá ohun tí wọ́n sọ yẹn mu rárá. (Jòhánù 8:41, 44, 47) Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run mú Òfin náà kúrò, àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín òun àti Ísírẹ́lì sì dópin. Àmọ́, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn ò lè ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ ni?
Kíkó “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run” Jọ
6. Kí ni ète “iṣẹ́ àbójútó” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nínú Éfésù 1:9, 10?
6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn kan lára ìran ènìyàn lè ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa ètò tí Jèhófà ṣe kí àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ lè di ara agboolé Rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí ó pète nínú ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:9, 10) Jésù Kristi ni “iṣẹ́ àbójútó” yìí já lé léjìká. Nípasẹ̀ rẹ̀ la fi mú ẹ̀dá ènìyàn wá sínú ipò ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run. Ìwọ̀nba kéréje lára àwọn èèyàn ló nírètí wíwà ní ọ̀run. Iye tó pọ̀ gan-an jùyẹn lọ ló máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.
7. Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run”?
7 Lákọ̀ọ́kọ́, bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a pe àfiyèsí sórí “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” ìyẹn ni àwọn tó máa jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run. Ọlọ́run sì polongo wọn ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ìjẹ́pàtàkì ẹbọ Jésù. (Róòmù 5:1, 2) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí wá wà lára wọn, “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” yóò sì wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Gálátíà 3:26-29; Ìṣípayá 14:1) Ìwọ̀nba díẹ̀ péré lára wọn ló kù sórí ilẹ̀ ayé báyìí.
Kíkó “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Lórí Ilẹ̀ Ayé” Jọ
8. Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” kí sì ni àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà?
8 Iṣẹ́ àbójútó kan náà ló tún fi ń kó “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” jọ. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn là ń kó jọ nísinsìnyí pẹ̀lú ète gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ajogún Ìjọba, wọ́n ń gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ, wọ́n sì ń gbé ìjọsìn rẹ̀ ga. (Aísáyà 2:2, 3; Sefanáyà 3:9) Wọ́n tún ń pe Jèhófà ní “Baba,” nítorí pé wọ́n gbà pé òun ni orísun ìyè. Wọ́n sì ń gbádùn ipò ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀. (Ìṣípayá 7:9, 14) Àmọ́ nítorí pé wọ́n ṣì jẹ́ aláìpé, kíkà wọ́n sí ọmọ Ọlọ́run ní kíkún ṣì di ọjọ́ iwájú.
9. Ìlérí wo ni Róòmù 8:21 ṣe fún aráyé?
9 Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé ń fi ìháragàgà dúró dé àkókò tí a óò “dá” ìṣẹ̀dá “sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” (Róòmù 8:21) Ìdásílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú yẹn yóò bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Kristi àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní ọ̀run bá mú ìpọ́njú ńlá wá sópin nípa fífi Amágẹ́dọ́nì kásẹ̀ rẹ̀ nílẹ̀. Èyí yóò túmọ̀ sí pípa gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì run, ìbùkún Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi nínú agbára Ìjọba yóò sì tẹ̀ lé e.—Ìṣípayá 19:17-21; 20:6.
10. Irú orin ìyìn wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò kọ?
10 Ẹ wo bí yóò ṣe múnú ẹni dùn tó nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórí ilẹ̀ ayé bá jùmọ̀ sọ irú ọ̀rọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti ọ̀run sọ, àwọn tó fayọ̀ polongo pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ, nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.” (Ìṣípayá 15:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni yóò fìmọ̀ ṣọ̀kan nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Kódà àwọn òkú yóò jíǹde, wọn ó sì láǹfààní láti dara pọ̀ nínú gbígbé ohùn wọn sókè láti yin Jèhófà.—Ìṣe 24:15.
Àgbàyanu Òmìnira Ń Bẹ Níwájú
11. Àgbàyanu òmìnira wo làwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá já yóò gbádùn?
11 Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá pẹ̀lú Amágẹ́dọ́nì tó máa fòpin sí i bá ti gbá ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, Sátánì Èṣù kò tún ní jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” mọ́. Kò ní sí pé àwọn olùjọsìn Jèhófà yóò tún máa fara da ipa búburú ti Sátánì mọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 20:1, 2) Ìsìn èké kò tún ní parọ́ mọ́ Jèhófà mọ́, kò sì ní í jẹ́ ipa tó ń pín àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn níyà mọ́. Kò ní sí pé à ń rẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ jẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláṣẹ ayé kò sì ní kó wọn nífà mọ́. Ẹ ò rí i pé àgbàyanu òmìnira la óò gbádùn!
12. Báwo ni gbogbo èèyàn yóò ṣe bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ipa tó ń ní?
12 Gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ,” Jésù yóò lo ìtóye ẹbọ rẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ aráyé kúrò. (Jòhánù 1:29) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan jì í, ó mú ẹni yẹn lára dá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdáríjì náà. (Mátíù 9:1-7; 15:30, 31) Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, Kristi Jésù yóò wo àwọn afọ́jú, àwọn odi, àwọn adití, àwọn arọ, àwọn wèrè àtàwọn tó ní àwọn àìsàn èyíkéyìí mìíràn sàn lọ́nà ìyanu. (Ìṣípayá 21:3, 4) Gbogbo àwọn onígbọràn ni yóò bọ́ lọ́wọ́ “òfin ẹ̀ṣẹ̀” kí èrò inú àti ìṣe wọn lè máa múnú tiwọn àti ti Ọlọ́run dùn. (Róòmù 7:21-23) Ní òpin Ẹgbẹ̀rúndún náà, a ó ti mú wọn wá sí ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn, ní ‘àwòrán àti ìrí’ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26.
13. Ní òpin Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso náà, kí ni Kristi yóò ṣe, kí ni yóò sì yọrí sí?
13 Nígbà tí Kristi bá ti gbé ìran ènìyàn dé ìjẹ́pípé, yóò wá dá ọlá àṣẹ tí a fún un láti fi ṣe iṣẹ́ yìí padà fún Baba: “[Yóò] . . . fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí ó ní láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:24, 25) Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Ìjọba náà yóò ti mú ète tó wà fún ṣẹ ní kíkún; nítorí náà a ò tún ní í nílò àkóso amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kankan láti wà láàárín Jèhófà àti ìran ènìyàn mọ́. Níwọ̀n bí a ó ti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò pátápátá nígbà yẹn, tí a ó sì ti ra ènìyàn padà, jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ Olùtúnniràpadà dópin nìyẹn. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́ríńtì 15:28.
14. Kí la ó ṣe fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pípé, èé sì ti ṣe?
14 Lẹ́yìn èyí, a óò fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé láǹfààní láti fi hàn pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà làwọn yàn láti sìn títí láé. Nítorí náà, kí Jèhófà tóó tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀, yóò ṣe ìdánwò ìkẹyìn fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pípé. A óò tú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Èyí kò ní fa ìpalára tó máa wà pẹ́ títí fáwọn tó dìídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá fi àìṣòótọ́ gbà kí a mú àwọn ṣàìgbọràn sí Jèhófà yóò pa run títí láé, pa pọ̀ pẹ̀lú ọlọ̀tẹ̀ láéláé nì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—Ìṣípayá 20:7-10.
15. Ipò wo ni yóò tún padà wà láàárín gbogbo àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tí Jèhófà dá?
15 Gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pípé tó bá rọ̀ mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ní àkókò ìdánwò ìkẹyìn yẹn ni Jèhófà yóò wá tẹ́wọ́ gba pé wọ́n jẹ́ ọmọ òun. Láti àkókò yẹn lọ, wọ́n á gbádùn òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ìdílé àgbáyé ti Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé yóò tún wà ní ìṣọ̀kan nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ète Jèhófà yóò ti ṣàṣeyọrí ológo nígbà yẹn! Ṣé o fẹ́ wà lára ìdílé àgbáyé tó jẹ́ aláyọ̀, tó sì máa wà títí láé yẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ láti kọbi ara sí ohun tí Bíbélì sọ nínú 1 Jòhánù 2:17 pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Ṣáájú kí ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì, àjọṣe wo ni gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà ní pẹ̀lú rẹ̀?
• Ẹrù iṣẹ́ wo ló já lé àwọn tó jẹ ìránṣẹ́ Ọlọ́run léjìká?
• Àwọn wo ló ṣì máa di ọmọ Ọlọ́run, báwo ni èyí sì ṣe kan ète Jèhófà nípa ìjọsìn tó wà ní ìṣọ̀kan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 190]
Àwọn ènìyàn onígbọràn yóò gbádùn ìwàláàyè nínú Párádísè kárí ayé