Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni èdìdì tí Ìṣípayá 7:3 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Ìṣípayá 7:1-3 sọ pé: “Mo rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin, kí ẹ̀fúùfù kankan má bàa fẹ́ sórí ilẹ̀ ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí. Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè láti ibi yíyọ oòrùn, ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké pẹ̀lú ohùn rara sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a yọ̀ǹda fún láti pa ilẹ̀ ayé àti òkun lára, pé: ‘Ẹ má ṣe pa ilẹ̀ ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.’”
Nígbà táwọn áńgẹ́lì yẹn bá ju “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” ilẹ̀ ayé sílẹ̀, ohun tí yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé “ìpọ́njú ńlá” á dé, ìsìn èké àti gbogbo apá yòókù nínú ayé búburú yìí á sì pa run. (Ìṣípayá 7:14) Àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Kristi lórí ilẹ̀ ayé làwọn “ẹrú Ọlọ́run” wọ̀nyẹn. (1 Pétérù 2:9, 16) Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé fífi èdìdì di àwọn arákùnrin Kristi ti ní láti parí nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá dé. Àmọ́ o, àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn fi hàn pé Ọlọ́run ti kọ́kọ́ fi èdìdì kan di àwọn ẹni àmì òróró ṣáájú èyí. Fún ìdí yìí, nígbà mìíràn, a máa ń sọ nípa èdìdì ti ìṣáájú tàbí ti ìkẹyìn. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín méjèèjì?
Ẹ jẹ́ ká gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “fi èdìdì di” yẹ̀ wò. Láyé ọjọ́un, èdìdì jẹ́ ohun kan tí wọ́n máa ń fi ṣàmì sára àkọsílẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí tún lè tọ́ka sí àmì náà fúnra rẹ̀. Láyé ìgbà yẹn, wọ́n sábà máa ń lẹ èdìdì mọ́ àwọn àkájọ ìwé tàbí àwọn nǹkan mìíràn láti fi hàn pé ó jẹ́ ojúlówó tàbí láti mọ ọ̀dọ̀ ẹni tó ti wá.—1 Àwọn Ọba 21:8; Jóòbù 14:17.
Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀mí mímọ́ wé èdìdì nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ń fọwọ́ sọ̀yà pé ẹ̀yin àti àwa jẹ́ ti Kristi àti ẹni tí ó fòróró yàn wá ni Ọlọ́run. Ó tún ti fi èdìdì rẹ̀ sórí wa, ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí náà, tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22) Nípa báyìí, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ sàmì òróró fáwọn Kristẹni wọ̀nyí láti fi hàn pé tóun ni wọ́n jẹ́.
Àmọ́, ìpele méjì ni fífi èdìdì di àwọn ẹni àmì òróró pín sí. Ti ìṣáájú sì yàtọ̀ sí ti ìkẹyìn tá a bá ń sọ nípa: (1) ìdí tí wọ́n fi fi èdìdì dì wọ́n, àti (2) àkókò tó wáyé. Èdìdì ti ìṣáájú wà fún yíyan ẹni kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ti ìkẹyìn sì fi hàn pé ẹni tí Ọlọ́run yàn tó sì fi èdìdì dì yìí ti fi hàn láìkù síbì kankan pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Àyàfi nígbà yìí nìkan, ìyẹn nígbà èdìdì ìkẹyìn, ni Ọlọ́run á tó fi èdìdì náà ‘síwájú orí’ ẹni àmì òróró náà, èyí ló sì máa wá fi hàn délẹ̀délẹ̀ pé ‘ẹrú Ọlọ́run’ tá a ti dán wò tó sì jẹ́ olóòótọ́ ni onítọ̀hún. Èdìdì ti ìkẹyìn yìí ni ìwé Ìṣípayá orí 7 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Ìṣípayá 7:3.
Ní ti àkókò èdìdì ìṣáájú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ẹ̀yin pẹ̀lú nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà, ìhìn rere nípa ìgbàlà yín. Nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ẹ gbà gbọ́, a fi èdìdì dì yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí.” (Éfésù 1:13, 14) Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé, lọ́pọ̀ ìgbà, kété lẹ́yìn táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbọ́ ìhìn rere tí wọ́n sì di onígbàgbọ́ nínú Kristi ni Ọlọ́run fi èdìdì dì wọ́n. (Ìṣe 8:15-17; 10:44) Irú fífi èdìdì dì wọ́n bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Àmọ́ o, ìyẹn kò fi hàn pé Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n délẹ̀délẹ̀. Kí nìdí?
Pọ́ọ̀lù sọ pé a fi “èdìdì di [àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró] fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” (Éfésù 4:30) Èyí fi hàn pé sáà àkókò kan ní láti kọjá, èyí sì sábà máa ń jẹ́ ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn èdìdì ti ìṣáájú. Àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ látọjọ́ tí Ọlọ́run bá ti fi èdìdì dì wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ títí di ‘ọjọ́ tí a bá tú wọn sílẹ̀’ kúrò nínú ẹran ara wọn, ìyẹn títí di ìgbà tí wọ́n bá kú. (Róòmù 8:23; Fílípì 1:23; 2 Pétérù 1:10) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù sún mọ́ bèbè ikú ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lè sọ pé: “Mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí.” (2 Tímótì 4:6-8) Bákan náà, Jésù sọ fún ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan pé: “Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.”—Ìṣípayá 2:10; 17:14.
Ọ̀rọ̀ náà, “adé,” túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà tí wọ́n fi èdìdì ti ìṣáájú dì wọ́n jìnnà sí ìgbà tí wọ́n fi ti ìkẹyìn dì wọ́n. Kí nìdí? Láyé ọjọ́un, wọ́n máa ń fún àwọn tó bá yege nínú eré sísá ní adé. Kí sárésáré kan tó lè gba adé, kì í ṣe pé á kàn bẹ̀rẹ̀ eré náà nìkan ni. Ó gbọ́dọ̀ sá a dé ìparí. Lọ́nà kan náà, àfi táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn láti àkókò èdìdì ti ìṣáájú títí dé ti ìkẹyìn, nìkan ni wọ́n fi lè gba adé ìyè àìleèkú ní ọ̀run.—Mátíù 10:22; Jákọ́bù 1:12.
Ìgbà wo làwọn àṣẹ́kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run ti fi èdìdì ìṣáájú dì yóò gba èdìdì wọn ti ìkẹyìn? Èyíkéyìí lára wọn tó bá ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé yóò gba èdìdì “ní iwájú orí wọn” kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá fi máa ju ẹ̀fúùfù mẹ́rin ìpọ́njú ńlá sílẹ̀, gbogbo àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí pátá ni yóò ti gba èdìdì ìkẹyìn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára wọn á ṣì wà láàyè nínú ẹran, tí wọ́n á ṣì ní láti parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé.