Jèhófà Ń sọ ‘Òpin Láti Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀’
“Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—AÍSÁYA 46:10.
1, 2. Kí ló jọni lójú nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣubú Bábílónì, kí sì lèyí fi hàn nípa Jèhófà?
NÍ Ọ̀GÀNJỌ́ òru, àwọn ọmọ ogun ọ̀tá rọra rìn gba inú Odò Yúfírétì lọ sí ibi tí wọ́n ń gbógun lọ, ìyẹn Bábílónì ìlú ńlá nì. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ìlú náà ni wọ́n rí ohun àrà kan tó jọ wọ́n lójú. Ilẹ̀kùn gìrìwò aláwẹ́ méjì tó wà lẹ́nu ọ̀nà ìlú Bábílónì ti ṣí sílẹ̀ gbayawu! Bí wọ́n ṣe jáde kúrò nínú odò yẹn ni wọ́n gòkè tí wọ́n sì wọnú ìlú náà. Ní wàràǹṣeṣà, wọ́n gba ìlú náà. Kírúsì tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ tí wọ́n gbà yẹn. Lẹ́yìn náà, ó pa àṣẹ kan tó fi dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wà nígbèkùn sì padà sílé láti mú ìjọsìn Jèhófà padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù.—2 Kíróníkà 36:22, 23; Ẹ́sírà 1:1-4.
2 Ní báyìí, àwọn òpìtàn gbà pé òótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 539 sí 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni yẹn wáyé. Ohun tó jọni lójú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ti mọ̀ nípa rẹ̀ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀. Ó ti pẹ́ gan-an tí Jèhófà ti mí sí wòlíì rẹ̀ Aísáyà láti sọ nípa bí Bábílónì yóò ṣe ṣubú. (Aísáyà 44:24–45:7) Kì í ṣe kìkì ohun tó yí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ká nìkan ni Ọlọ́run sọ, àmọ́ ó tún sọ orúkọ aṣáájú tó máa ṣẹ́gun Bábílónì.a Nígbà tí Jèhófà ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, pé èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.” (Aísáyà 46:9, 10a) Lóòótọ́, Ọlọ́run tó lè mọ nǹkan ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀ ni Jèhófà.
3. Àwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nísinsìnyí?
3 Báwo ni ohun tí Ọlọ́run mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ṣe tó? Ǹjẹ́ Jèhófà ti mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe? Àní, ṣé ó ti kádàrá ọjọ́ ọ̀la wa ni? Nínú àpilẹ̀kọ́ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a óò gbé àwọn ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò àtàwọn ìbéèrè mìíràn tó jẹ mọ́ ọn.
Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Àsọtẹ́lẹ̀
4. Ọ̀dọ̀ ta ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ti wá?
4 Nítorí pé Jèhófà mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ó mí sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti kọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, èyí sì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe kó tó di pé ó ṣe wọ́n. Jèhófà polongo pé: “Àwọn nǹkan àkọ́kọ́—àwọn ni ó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tuntun ni mo ń sọ jáde. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rú yọ, mo mú kí ẹ gbọ́ wọn.” (Aísáyà 42:9) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn Ọlọ́run mà ní o!
5. Iṣẹ́ wo ni mímọ̀ tá a mọ àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀ gbé lé wa lọ́wọ́?
5 Wòlíì Ámósì mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” Mímọ̀ tá a mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú yìí gbé iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́. Wo àpèjúwe tó fakíki tí Ámósì lò tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tó sọ yìí, ó ní: “Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù! Ta ni kì yóò fòyà?” Bí èèyàn àti ẹranko ṣe máa ń wá rìrì nígbà tí kìnnìún bá bú ramúramù nítòsí wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn wòlíì bí Ámósì ṣe polongo ọ̀rọ̀ Jèhófà. “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kì yóò sọ tẹ́lẹ̀?”—Ámósì 3:7, 8.
“Ọ̀rọ̀” Jèhófà Ń Ní “Àṣeyọrí sí Rere Tí Ó Dájú”
6. Ọ̀nà wo ni “ìpinnu” Jèhófà nípa ìṣubú Bábílónì gbà nímùúṣẹ?
6 Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.” (Aísáyà 46:10b) “Ìpinnu” Ọlọ́run, ìyẹn ìfẹ́ rẹ̀, tàbí ohun tó ní lọ́kàn fún Bábílónì, ní í ṣe pẹ̀lú pípè tó pe Kírúsì wá láti Páṣíà kó wá ṣẹ́gun Bábílónì kó sì bì í ṣubú. Jèhófà ti sọ ohun tó fẹ́ ṣe yẹn tipẹ́tipẹ́. Gẹ́gẹ́ bá a ti mọ̀, àsọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ láìkùnà lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lojú pé “ọrọ̀” Jèhófà máa ń ṣẹ?
7 Ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin ṣáájú kí Kírúsì tó ṣẹ́gun Bábílónì, Jèhóṣáfátì ọba Júdà dojú kọ àpapọ̀ àwọn ọmọ ogun Ámọ́nì àti ti Móábù. Ó gbàdúrà láìmikàn pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ìwọ ha kọ́ ni Ọlọ́run ní ọ̀run, ìwọ kò ha sì ń jọba lé gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè, agbára àti agbára ńlá kò ha sì sí ní ọwọ́ rẹ, tí kò fi sí ẹnì kankan tí ó lè kò ọ́ lójú?” (2 Kíróníkà 20:6) Wòlíì Aísáyà fi irú ìgbọ́kànlé kan náà hàn nígbà tó sọ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti pinnu, ta sì ni ó lè sọ ọ́ di asán? Ọwọ́ rẹ̀ sì ni èyí tí a nà, ta sì ni ó lè dá a padà?” (Aísáyà 14:27) Lẹ́yìn tí orí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì tó dàrú pé padà, ó sọ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dá a lọ́wọ́ dúró tàbí tí ó lè sọ fún un pé, ‘Kí ni o ti ń ṣe?’” (Dáníẹ́lì 4:35) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé: “Ọ̀rọ̀ mi . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:11) Ó yẹ ká ní ìgbọ́kànlé pé “ọ̀rọ̀” Jèhófà máa ń ṣẹ nígbà gbogbo. Kò sóhun tó lè dí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́wọ́.
“Ète Ayérayé” ti Ọlọ́run
8. Kí ni “ète ayérayé” Ọlọ́run?
8 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ní Éfésù, ó sọ pé Ọlọ́run ní “ète ayérayé” kan lọ́kàn. (Éfésù 3:11) Èyí kì í ṣe pé Ọlọ́run ń wéwèé nǹkan o, bí ẹni pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti máa la ọ̀nà tó máa gbà ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí Jèhófà ti pinnu látìbẹ̀rẹ̀ pé òun máa ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ẹ jẹ́ ká gbé àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì yẹ̀ wò ká lè mọ̀ pé ète Ọlọ́run kò lè kùnà.
9. Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe ní í ṣe pẹ̀lú ète Ọlọ́run?
9 Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 fi hàn pé kété lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà pinnu pé obìnrin rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ yóò pèsè irú ọmọ kan tàbí ọmọkùnrin kan. Jèhófà tún mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìṣọ̀tá tó wà láàárín obìnrin òun àti Sátánì, àtèyí tó wà láàárín àwọn irú ọmọ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fún ejò náà láyè láti pa Irú Ọmọ obìnrin Ọlọ́run ní gìgísẹ̀, tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, Irú Ọmọ náà yóò pa ejò tàbí Sátánì ní orí. Kí ìgbà yẹn tó dé, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nímùúṣẹ ní gbogbo ìran tó wá jálẹ̀ sọ́dọ̀ Jésù, ẹni tó jẹ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Lúùkù 3:15, 23-38; Gálátíà 4:4.
Ohun Tí Jèhófà Ti Pinnu Tẹ́lẹ̀ Pé Yóò Ṣẹlẹ̀
10. Ǹjẹ́ Jèhófà ti kádàrá rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ pé Ádámù àti Éfà yóò ṣẹ̀? Ṣàlàyé.
10 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ipa tí Jésù máa kó nínú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láti ṣe, ó kọ̀wé pé: “A mọ [Jésù] tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n a fi í hàn kedere ní òpin àwọn àkókò nítorí ẹ̀yin.” (1 Pétérù 1:20) Ǹjẹ́ Jèhófà ti kádàrá rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ pé Ádámù àti Éfà yóò ṣẹ̀ àti pé a óò nílò ẹbọ ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Kristi? Rárá o. Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “pípilẹ̀” túmọ̀ sí lólówuuru ni “dída irúgbìn sílẹ̀.” Ǹjẹ́ “dída irúgbìn sílẹ̀” tàbí lílóyún ọmọ èèyàn ti ṣẹlẹ̀ kí Ádámù àti Éfà tó ṣẹ̀? Rárá o. Ẹ̀yìn tí Ádámù àti Éfà ṣẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Nítorí náà, lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ ṣùgbọ́n ṣáájú kí wọ́n tó bímọ ni Jèhófà pinnu pé “irú ọmọ” náà máa fara hàn. Ikú àti àjíǹde Jésù ló mú kí ìràpadà tó jẹ́ ìpèsè onífẹ̀ẹ́ ṣeé ṣe, òun ló sọ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún àti gbogbo ìsapá Sátánì di asán.—Mátíù 20:28; Hébérù 2:14; 1 Jòhánù 3:8.
11. Kí ni Jèhófà tún ti pinnu tẹ́lẹ̀ nípa bó ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?
11 Ọlọ́run tún pinnu ohun mìíràn nípa bó ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará Éfésù pé, Ọlọ́run yóò “kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” ìyẹn àwọn tá a yàn láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú Jésù Kristi. Ó ṣàlàyé pé: “A yàn wá ṣáájú gẹ́gẹ́ bí ète ẹni tí ń mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ pinnu.” (Éfésù 1:10, 11) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ti pinnu ṣáájú pé àwọn èèyàn díẹ̀ yóò jẹ́ apá kejì irú ọmọ obìnrin Ọlọ́run, wọ́n á sì ṣàjọpín pẹ̀lú Kristi nínú mímú káwọn èèyàn jàǹfààní ìràpadà náà. (Róòmù 8:28-30) Àpọ́sítélì Pétérù pè wọ́n ní “orílẹ̀-èdè mímọ́.” (1 Pétérù 2:9) Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, ó láǹfààní láti mọ iye àwọn tó máa di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. Iye wọn ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn. (Ìṣípayá 7:4-8; 14:1, 3) Wọ́n ń ti Kristi lẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí Ọba, wọ́n sì ń sìn “fún ìyìn ògo [Ọlọ́run].”—Éfésù 1:12-14.
12. Báwo lá ṣe mọ̀ pé a kò kádàrá ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ara ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì?
12 Yíyàn tí Ọlọ́run yan àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tẹ́lẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ó ti kádàrá àwọn kan ní pàtó láti sin Ọlọ́run tọkàntọkàn lọ́nà yìí. Ká sòótọ́, ìdí tí wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì ni láti tọ́ àwọn ẹni àmì òróró sọ́nà àti láti fún wọn lókun kí wọ́n lè máa jólóòótọ́ nìṣó kí wọ́n sì lè máa jẹ́ ẹni yíyẹ fún ìpè wọn ti ọ̀run. (Fílípì 2:12; 2 Tẹsalóníkà 1:5, 11; 2 Pétérù 1:10, 11) Jèhófà ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn yóò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ òun. Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa jẹ́ níkẹyìn wà lọ́wọ́ bí wọ́n bá ṣe lo ìgbésí ayé wọn, èyí sì jẹ́ ìpinnu tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbọ́dọ̀ dá ṣe.—Mátíù 24:13.
Àwọn Ohun Tí Jèhófà Mọ̀ Tẹ́lẹ̀
13, 14. Ohun wo ni agbára tí Jèhófà ní láti mọ ọjọ́ iwájú gbọ́dọ̀ bá mu, kí sì nìdí?
13 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ àti Ọlọ́run ète, báwo ló ṣe ń lo agbára tó ní láti mọ ọjọ́ iwájú? Lákọ̀ọ́kọ́, Bíbélì mú un dá wa lójú pé gbogbo ọ̀nà Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́, òdodo, àti ìfẹ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé “ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́” ni ìbúra rẹ̀ àtàwọn ìlérí rẹ̀. (Hébérù 6:17, 18) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Títù, ó tún sọ èrò rẹ̀ nígbà tó sọ pé Ọlọ́run “kò lè purọ́.”—Títù 1:2.
14 Síwájú sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára Jèhófà kò ní ààlà, síbẹ̀ kì í ṣe ohun tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu. Mósè pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Gbogbo ohun tí Jèhófà bá ń ṣe ló máa ń bá àkópọ̀ ìwà rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu mu. Gbogbo rẹ̀ ló máa ń ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ pàtàkì, ìyẹn ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, àti agbára, lọ́nà pípé pérépéré.
15, 16. Àwọn ohun wo ni Jèhófà fi síwájú Ádámù láti yàn ní ọgbà Édẹ́nì?
15 Ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn ànímọ́ pàtàkì yìí ṣe kan ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́, ó pèsè gbogbo ohun táwa ẹ̀dá ènìyàn nílò. Ó dá Ádámù lọ́nà tó fi lè ronú, lọ́nà tó fi lè gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò dáadáa, kí ó sì ṣe ìpinnu. Ádámù kò dà bí àwọn ẹranko tó jẹ́ pé wọn ò lè dá ronú ṣe nǹkan kan, àfohun tí Ọlọ́run ti dá mọ́ wọn pé kí wọ́n máa ṣe. Ádámù lè ṣèpinnu. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó wo ayé láti ọ̀run ó sì rí “ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-31; 2 Pétérù 2:12.
16 Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Ádámù pé kó má ṣe jẹ lára “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” ó fún Ádámù ní ìtọ́ni tó pọ̀ tó kí Ádámù bàa lè pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Ó yọ̀ǹda fún un láti jẹ nínú “gbogbo igi ọgbà náà” àyàfi ọ̀kan ṣoṣo, ó sì kìlọ̀ fún un nípa àbájáde burúkú tí jíjẹ èso tó kà léèwọ̀ yóò mú wá. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ọlọ́run ṣàlàyé fún Ádámù nípa ohun tó máa jẹ́ ìyọrísí ohun tó bá ṣe. Kí ni Ádámù yóò ṣe?
17. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè mọ nǹkan ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀, kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó máa ń yan nǹkan tó bá fẹ́ láti mọ̀ ni?
17 Ó hàn kedere pé Jèhófà kò yàn láti mọ ohun tí Ádámù àti Éfà yóò ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè mọ ohun gbogbo ṣáájú kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ bóyá Jèhófà lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí kò lè mọ̀ ọ́n, àmọ́ ó jẹ́ ọ̀rọ̀ bóyá ó yàn láti mọ̀ ọ́n. Síwájú sí i, ó yẹ ká mọ̀ pé níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, kò ní mọ̀ọ́mọ̀ pinnu pé kí ìṣọ̀tẹ̀ wáyé pẹ̀lú gbogbo àbájáde burúkú rẹ̀. (Mátíù 7:11; 1 Jòhánù 4:8) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè mọ nǹkan ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀, ó máa ń yan èyí tó bá fẹ́ láti mọ̀ ni.
18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìkì ohun tí Jèhófà bá fẹ́ mọ̀ ló máa ń yàn láti mọ̀, kí nìdí tí èyí kò fi túmọ̀ sí pé kò lágbára tó?
18 Ṣé yíyàn tí Jèhófà máa ń yan nǹkan tó bá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ túmọ̀ sí pé kò lágbára tó ni? Rárá o. Mósè pe Jèhófà ní “Àpáta náà,” ó sì fi kún un pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” A kò lè dá a lẹ́bi nítorí ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ aráyé fà. Àìgbọ́ràn Ádámù ló fa àjálù tí gbogbo wa ń fàyà rán lónìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní kedere pé “ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Diutarónómì 32:4, 5; Róòmù 5:12; Jeremáyà 10:23.
19. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Látinú ohun tá a ti ń jíròrò bọ̀, a ti rí i pé Jèhófà kì í ṣe àìṣòdodo. (Sáàmù 33:5) Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára Jèhófà, àwọn ànímọ́ rere rẹ̀, àtàwọn ìlànà rẹ̀ máa ń bá ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ mu. (Róòmù 8:28) Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀, ó máa ‘ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.’ (Aísáyà 46:9, 10) A tún ti rí i pé ohun tí Ọlọ́run bá fẹ́ mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ló máa ń yàn láti mọ̀. Báwo ni ọ̀ràn náà ṣe wá kàn wá? Báwo la ṣe lè rí i dájú pé àwọn ìpinnu wa bá ète Ọlọ́run tó dá lórí ìfẹ́ mu? Àwọn ìbùkún wo lèyí sì máa mú bá wa? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 28. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Àwọn àpẹẹrẹ ìgbàanì wo ló jẹ́rìí sí i pé “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run máa ń ní “àṣeyọrí sí rere tí ó dájú”?
• Kí ni Jèhófà ti pinnu tẹ́lẹ̀ nípa “ète ayérayé” rẹ̀?
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń lo agbára tó ní láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Jèhóṣáfátì gbọ́kàn lé Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọlọ́run sàsọtẹ́lẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ Jèhófà ti kádàrá ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe?