Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mò Ń sin Jèhófà Tayọ̀tayọ̀ Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Aláìlera
GẸ́GẸ́ BÍ VARNAVAS SPETSIOTIS ṢE SỌ Ọ́
Lọ́dún 1990, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínláàádọ́rin, mo yarọ látòkèdélẹ̀. Àmọ́ láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn báyìí ni mo ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún tí mo sì ń sìn tayọ̀tayọ̀ ní erékùṣù Kípírọ́sì. Kí ló fún mi lágbára láti lè máa bá iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà lọ láìka àìlera mi sí?
ỌJỌ́ kọkànlá oṣù October ọdún 1922 ni wọ́n bí mi. Àwa mẹ́sàn-án làwọn òbí wa bí, ọkùnrin mẹ́rin àti obìnrin márùn-ún. Abúlé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Xylophagou lérékùṣù Kípírọ́sì la sì ń gbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ṣẹnuure fáwọn òbí mi díẹ̀, wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ kára nínú oko kí wọ́n lè bójú tó ìdílé ńlá bí èyí.
Bàbá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antonis jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ gan-an ó sì máa ń fẹ́ láti mọ̀dí àwọn nǹkan. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí mi ló rí ìwé àṣàrò kúkúrú kan nígbà tó lọ sọ́dọ̀ ẹni tó jẹ́ olùkọ́ ní iléèwé tó wà ní abúlé wa. Àkòrí ìwé àṣàrò kúkúrú náà ni “Peoples Pulpit,” àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli (ìyẹn orúkọ tá a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn) ló tẹ̀ ẹ́ jáde. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, kò sì pẹ́ rárá tí gbogbo ohun tó wà nínú ìwé náà fi gbà á lọ́kàn. Èyí ló mú kí bàbá mi àti ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ́ Andreas Christou wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní erékùṣù yẹn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Pọ̀ Sí I Bí Wọ́n Tilẹ̀ Ń Ṣàtakò Sí Wọn
Bí àkókò ti ń lọ, àwọn méjèèjì tún rí àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì gbà sí i látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò sì pẹ́ tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí bàbá mi àti Andreas ń kọ́ nínú Bíbélì fi sún wọn láti lọ máa wàásù fáwọn ará abúlé wọn. Iṣẹ́ ìwàásù yìí fa inúnibíni líle látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Gíríìsì àtàwọn mìíràn tí wọ́n rò pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ lè ṣàkóbá fún ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ará abúlé yìí máa ń buyì fáwọn méjèèjì tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí. Gbogbo èèyàn ló mọ bàbá mi sí onínúure èèyàn àti ẹni tó lawọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn ìdílé tó jẹ́ aláìní. Nígbà míì á rọra yọ́ kẹ́lẹ́ jáde nílé lóru ọ̀gànjọ́ á sì lọ gbé àlìkámà tàbí búrẹ́dì sẹ́nu ọ̀nà àwọn ìdílé tó jẹ́ aláìní. Ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan tó jẹ́ ìwà Kristẹni yìí mú káwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù àwọn òjíṣẹ́ méjèèjì yìí.—Mátíù 5:16.
Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, nǹkan bí èèyàn méjìlá fìfẹ́ hàn sóhun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ látinú Bíbélì. Bí wọ́n sì ṣe túbọ̀ ń lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n ń kọ́, wọ́n rí i pé ó yẹ káwọn máa pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní nǹkan bí ọdún 1934, arákùnrin Nikos Matheakis tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún láti ilẹ̀ Gíríìsì wá sí erékùṣù Kípírọ́sì, ó sì bá àwùjọ tó wà lábúlé Xylophagou yìí ṣèpàdé. Arákùnrin Matheakis fi sùúrù àti ẹ̀mí ìmúratán hàn, ó ṣètò àwùjọ náà, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ sí i. Àwùjọ yìí ló wá di ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àkọ́kọ́ ní Kípírọ́sì.
Bí iṣẹ́ àwọn Kristẹni yìí ṣe ń tẹ̀ síwájú tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì túbọ̀ ń tẹ́wọ́ gba ohun tí Bíbélì sọ, àwọn arákùnrin náà rí i pé ó yẹ káwọn ní ibì kan táwọn á ti máa pàdé láti máa ṣe àwọn ìpàdé wọn. Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó dàgbà jù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ George àti Eleni, ìyàwó rẹ̀, fún wọn ní ibì kan tí wọ́n máa ń kó àwọn nǹkan oko sí. Àwọn ará ṣàtúnṣe ilé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀gbọ́n mi yìí, wọ́n sì sọ ọ́ di ibi tó bójú mu láti máa ṣe ìpàdé wọn. Báwọn arákùnrin wọ̀nyí ṣe dẹni tó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn àkọ́kọ́ lérékùṣù náà nìyẹn. Inú wọn dùn gan-an ni! Ó sì tún mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa dara pọ̀ mọ́ wọn!
Mo Pinnu Láti Sin Jèhófà
Lọ́dún 1938, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, mo sọ pé iṣẹ́ káfíńtà ni mo fẹ́ ṣe. Bí bàbá mi ṣe mú mi lọ sílùú Nicosia tó jẹ́ olú ìlú Kípírọ́sì nìyẹn. Ó ronú gan-an nípa ibi tí màá máa gbé, èyí sì mú kó ṣètò pé kí n máa gbé lọ́dọ̀ arákùnrin Nikos Matheakis. Ọ̀pọ̀ ṣì ń rántí arákùnrin olóòótọ́ yìí nítorí ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìwàásù àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àlejò. Bó ṣe jẹ́ ọlọ́yàyà èèyàn tó sì tún nígboyà gan-an ran àwọn ará lọ́wọ́ gidi nílẹ̀ Kípírọ́sì lákòókò yẹn.
Arákùnrin Matheakis ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti dẹni tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú ìmọ̀ Bíbélì àti láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ní gbogbo ìgbà tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀, mi ò lè ṣe kí n má wà ní gbogbo ìpàdé tí wọ́n ń ṣe nílé rẹ̀. Fún ìgbà àkọ́kọ́, mo rí i pé ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ń pọ̀ sí i. Mo sì wá pinnu lọ́kàn mi pé èmi náà fẹ́ láti ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú Ọlọ́run. Láàárín oṣù díẹ̀ péré, mo sọ fún Arákùnrin Matheakis pé mo fẹ́ máa bá a lọ sí òde ìwàásù. Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1939.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo padà lọ sílé láti lọ wo àwọn èèyàn mi. Wíwà tí mo wà pẹ̀lú bàbá mi fúngbà díẹ̀ yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́ àtohun tó ń jẹ́ káyé èèyàn nítumọ̀. Oṣù September ọdún 1939 ni Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tá a jọ jẹ́ ojúgbà ló yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sójú ogun, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ ni mo tẹ̀ lé. Mo pinnu pé mi ò ní lọ́wọ́ sógun rárá. (Aísáyà 2:4; Jòhánù 15:19) Ọdún yẹn gan-an ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1940. Fún ìgbà àkọ́kọ́, mo rí i pé mo bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù èèyàn!
Lọ́dún 1948, mo gbé Efprepia níyàwó a sì bí ọmọ mẹ́rin. Kò pẹ́ rárá tá a fi rí i pé láti lè tọ́ àwọn ọmọ náà dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” a ní láti sapá gan-an. (Éfésù 6:4) Ohun tí gbogbo àdúrà wa àti ìsapá wa sì dá lé lórí ni pé káwọn ọmọ wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn òfin àtàwọn ìlànà rẹ̀.
Àìlera Ara Dá Ìṣòro Sílẹ̀
Lọ́dún 1964, nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìlélógójì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkíyèsí pé ọwọ́ ọ̀tún àti ẹsẹ̀ ọ̀tún mi ń kú tipiri. Díẹ̀díẹ̀, àìsàn yìí tàn dé ẹ̀gbẹ́ òsì mi. Àyẹ̀wò àwọn dókítà fi hàn pé àìsàn tó ń mú kí gbogbo iṣan ara daṣẹ́ sílẹ̀ ni àìsàn yìí àti pé kò lóògùn, tó bá sì yá, èèyàn á yarọ látòkèdélẹ̀. Ohun tí mo gbọ́ yìí bà mí lẹ́rù gan-an, òjijì ló sì dé bá mi! Bí inú ṣe ń bí mi bẹ́ẹ̀ lara ń kan mí, mo sì ń rò ó lọ́kàn mi pé ‘Kí ló dé tí irú nǹkan báyìí fi ṣẹlẹ̀ sí mi? Kí ni mo ṣe?’ Àmọ́ nígbà tó yá, mo borí ẹ̀rù tó bà mí nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa àìsàn yẹn. Lẹ́yìn náà ni ìdààmú ọkàn àti èrò àìmọ bí ọjọ́ iwájú mi ṣe máa rí wá mú kí gbogbo nǹkan tójú sú mi pátápátá. Àìmọye ìbéèrè sì ń wá sí mi lọ́kàn. Ṣé pé màá yarọ pátápátá táwọn èèyàn á sì máa bá mi ṣe gbogbo nǹkan ni? Ọgbọ́n wo ni màá ta sí i? Ṣé màá lè pèsè fún ìdílé mi, ìyẹn ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin? Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí mú kí ọkàn mi bà jẹ́ gan-an.
Lákòókò tí gbogbo nǹkan dojú rú fún mi yìí, mó rí i pé ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó yẹ kí n tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà kí n sì sọ gbogbo ìdààmú ọkàn mi fún un pátápátá àtàwọn nǹkan tó ń bà mí lẹ́rù. Tọ̀sántòru ni mò ń gbàdúrà pẹ̀lú omijé lójú. Kò sì pẹ́ tí mo fi rí i pé Jèhófà tù mí nínú. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó wà nínú ìwé Fílípì 4:6, 7 mú kára tù mí gan-an, ó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”
Bí Mo Ṣe Ń Kojú Àìsàn Yìí
Àìsàn náà túbọ̀ ń le sí i. Mo sì rí i pé mo ní láti tètè wá nǹkan ṣe sọ̀rọ̀ ara mi. Níwọ̀n ìgbà tí mi ò lè ṣiṣẹ́ káfíńtà mọ́, mo pinnu láti wá iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gba agbára tí mo lè ṣe nírú ipò tí mo wà yìí, táá sì jẹ́ kí n lè pèsè fún ìdílé mi. Áásìkiriìmù ni mo kọ́kọ́ ń tà, inú ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan ni mo sì ti ń tà á. Mo ṣèyẹn fún bí ọdún mẹ́fà kó tó di pé àìsàn yìí sọ mí dẹni tó ń jókòó pa sínú kẹ́kẹ́ àwọn arọ. Lẹ́yìn náà ni mo tún yí sáwọn iṣẹ́ míì tí kò nira tóyẹn tí mo lè rọra máa ṣe.
Láti ọdún 1990, mi ò tiẹ̀ wá lè ṣiṣẹ́ kankan mọ́. Báyìí, àwọn èèyàn ló ń bá mi ṣe gbogbo nǹkan, títí kan àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa fúnra rẹ̀ ṣe pàápàá. Tí mo bá fẹ́ sùn, ńṣe ni wọ́n máa gbé mi sórí bẹ́ẹ̀dì, ńṣe ni wọ́n ń wẹ̀ fún mi, tí wọ́n sì ń wọṣọ fún mi. Tí mo bá ń lọ sípàdé ìjọ, wọ́n ní láti fi kẹ̀kẹ́ àwọn arọ tì mí lọ sídìí ọkọ̀ kí wọ́n sì gbé mi látinú rẹ̀ sínú ọkọ̀. Bí mo bá sì dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n ní láti gbé mi látinú ọkọ̀ padà sínú kẹ̀kẹ́ kí wọ́n sì tì mí wọlé. Típàdé bá ń lọ lọ́wọ́, mo máa ń lo ohun èlò kan tó ń lo iná mànàmáná láti mú kí ẹsẹ̀ mi máa lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́.
Àmọ́ o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo yarọ látòkèdélẹ̀, mi ò kì í pa ìpàdé kankan jẹ. Mo mọ̀ pé ibi tí Jèhófà ti ń kọ́ wa nìyẹn, ààbò gidi sì ni wíwà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nípa tẹ̀mí jẹ́, bákan náà ló tún ń fún wa ní ìṣírí àti òkun. (Hébérù 10:24, 25) Wíwá táwọn olùjọ́sìn ẹlẹ́gbẹ́ mi tó dàgbà nípa tẹ̀mí máa ń wá sọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo tún ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Dáfídì gẹ́lẹ́ ló rí lára mi, ó ní: “Ife mi kún dáadáa.”—Sáàmù 23:5.
Látìgbà tí ìṣòro yìí ti bẹ̀rẹ̀ ni aya mi ọ̀wọ́n ti ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Àwọn ọmọ mi pàápàá kò gbẹ́yìn nínú ríràn mí lọ́wọ́. Láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn báyìí, àwọn ló ń bá mi ṣe àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa fúnra rẹ̀ ṣe lójoojúmọ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí kò rọrùn rárá, bọ́dún sì ti ń gorí ọdún ló túbọ̀ ń ṣòro fún wọn láti bójú tó mi. Ká sòótọ́, tá a bá ń sọ nípa níní sùúrù àti lílo ara ẹni, àpẹẹrẹ gidi ni wọ́n jẹ́, àdúrà mi sì ni pé kí Jèhófà túbọ̀ máa bù kún wọn.
Nǹkan àgbàyanu mìíràn tí Jèhófà tún ń pèsè láti máa fi ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ni àdúrà. (Sáàmù 65:2) Jèhófà ń dáhùn àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nítorí pé látìgbà tí àìsàn yìí ti kọ lù mí ló ti ń fún mi lókun kí n lè máa nígbàgbọ́ nìṣó. Àdúrà máa ń jẹ́ kí ara tù mí ó sì ń jẹ́ kí n lè máa láyọ̀, pàápàá nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá dé bá mi. Bíbá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé ń tù mí lára ó sì ń jẹ́ kí n lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu mi pé mi ò ní juwọ́ sílẹ̀. Mi ò ṣiyè méjì rárá pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ó sì máa ń fún wọn ní ìbàlẹ̀ ọkàn.—Sáàmù 51:17; 1 Pétérù 5:7.
Olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, mo máa ń ni okun gan-an nígbàkigbà tí mo bá rántí pé bópẹ́bóyá, Ọlọ́run á wo gbogbo ẹni tó bá gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé nínú Párádísè sàn, ìyẹn lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni omijé ayọ̀ ti bọ́ lójú mi bí mo ṣe ń ronú nípa ìrètí àgbàyanu yẹn.—Sáàmù 37:11, 29; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4.
Mò Ń Sìn Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Alákòókò-Kíkún
Ní nǹkan bí ọdún 1991, lẹ́yìn tí mo gbé ipò mi yẹ̀ wò dáadáa, mo rí i pé ọ̀nà tó dára jù láti yẹra fún kíkáàánú ara mi ni pé kí n jẹ́ kọ́wọ́ mi dí lẹ́nu iṣẹ́ sísọ ìhìn rere tó ṣeyebíye nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ọdún yẹn gan-an ni mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún.
Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ aláàbọ̀ ara, lẹ́tà kíkọ ni ọ̀nà tí mo ń lò jù láti wàásù. Àmọ́ ìwé kíkọ ọ̀hún pàápàá kò rọrùn fún mi, iṣẹ́ ńlá ni. Ọwọ́ mi kò ṣeé di gègé mú dáadáa torí pé àìsàn tó ń mú kí iṣan ara daṣẹ́ sílẹ̀ yìí ti sọ ọ́ di aláìlágbára. Àmọ́ pẹ̀lú ìsapá àti àdúrà, ó ti lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún báyìí tí mo ti ń fi lẹ́tà kíkọ wàásù. Mo tún máa ń lo tẹlifóònù láti wàásù fáwọn èèyàn. Mi ò kì í jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí tí mo bá ní láti wàásù lọ mọ́ mi lọ́wọ́. Mo máa ń sọ ìrètí mi nípa ayé tuntun àti Párádísè tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé fáwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò tó máa ń wá kí mi nínú ilé mi.
Èyí ti jẹ́ kí n ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń fún mi níṣìírí. Inú mi máa ń dùn gan-an bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ mi tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nǹkan bí ọdún méjìlá sẹ́yìn ti ń tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ dáadáa ti mú kó dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀ lórí ọ̀ràn kíkọ̀ láti lọ́wọ́ sí ogun.
Inú mi tún máa ń dùn gan-an nígbà táwọn èèyàn tí mo ti kọ lẹ́tà sí bá kàn sí mi pé àwọn fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì. Nígbà míì, àwọn kan máa ń sọ pé kí n fi àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sáwọn láfikún sí èyí ti mo ti fi ránṣẹ́ sí wọn tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan pè mí lórí fóònù ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ mi nítorí lẹ́tà tí mo kọ sí ọkọ̀ rẹ̀ láti fún un níṣìírí. Àwọn kókó tó wà nínú lẹ́tà náà dùn mọ́ ọn nínú gan-an. Èyí ti mú kí n bá òun àti ọkọ rẹ̀ jíròrò Bíbélì lọ́pọ̀ ìgbà nínú ilé mi.
Ìrètí Tí Mo Ní Ń Fún Mi Láyọ̀
Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti pọ̀ sí i lójú mi lágbègbè yìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé George ẹ̀gbọ́n mi ṣe tí wọ́n sì ti mú kó fẹ̀ sí i. Ibi ìjọsìn tó lẹ́wà ni, ìjọ méjì tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì ń lò ó.
Ọdún 1943 ni bàbá mi kú lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́ta. Àmọ́ ogún tẹ̀mí ńlá ló fi sílẹ̀ fún wa! Mẹ́jọ lára àwa ọmọ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ a sì ń sin Jèhófà títí dòní. Lábúlé Xylophagou tí wọ́n ti bí bàbá mi àtàwọn abúlé tó yí i ká, ìjọ mẹ́ta ló wà níbẹ̀ báyìí, igba ó lé ọgbọ̀n sì ni àpapọ̀ àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà láwọn ìjọ náà!
Àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń fún mi láyọ̀ gan-an. Báyìí tí mo ti dẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin, ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kọ máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ní díẹ̀ lọ́wọ́, ebi sì ń pa wọ́n; ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ń wá Jèhófà, wọn kì yóò ṣaláìní ohun rere èyíkéyìí.” (Sáàmù 34:10) Tọkàntara ni mo fi ń dúró de ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 35:6 máa nímùúṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.” Títí dìgbà tí àkókò yẹn á fi dé, mo pinnu láti máa sin Jèhófà nìṣó tayọ̀tayọ̀ bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìlera.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 17]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
TURKEY
SÍRÍÀ
LẸ́BÁNÓNÌ
KÍPÍRỌ́SÌ
Nicosia
Xylophagou
Òkun Mẹditaréníà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ ní Xylophagou, wọ́n ṣì ń lò ó títí dòní
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi àti Efprepia lọ́dún 1946 àti lónìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Fífi tẹlifóònù wàásù àti wíwàásù nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ máa ń fún mi láyọ̀