Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JUNE 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | GÁLÁTÍÀ 4-6
“ ‘Àkàwé’ Kan àti Ìtumọ̀ Rẹ̀”
it-1 1018 ¶2
Hágárì
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú àkàwé kan pé, Hágárì ṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó wà lábẹ́ Òfin májẹ̀mú tí Jèhófà gbé kalẹ̀ lórí Òkè Sínáì, májẹ̀mú yìí ló bí àwọn “ọmọ fún ìsìnrú.” Kò ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn náà láti dójú ìlà àwọn nǹkan tí májẹ̀mú náà ń béèrè fún torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Májẹ̀mú yìí kò sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di òmìnira, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú; ìdí nìyẹn tí wọ́n fi jẹ́ ẹrú. (Jo 8:34; Ro 8:1-3) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé, Jerúsálẹ́mù ni Hágárì ń ṣàpẹẹrẹ, torí pé Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú. Àmọ́ ní ti àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí bí, wọ́n jẹ́ ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” tó jẹ́ obìnrin ìṣàpẹẹrẹ ti Ọlọ́run. Bíi ti Sárà tó jẹ́ obìnrin òmìnira, Jerúsálẹ́mù yìí kò fi ìgbà kan rí jẹ́ ẹrú. Àmọ́ bí Íṣímáẹ́lì ṣe ta ko Ísákì, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ ẹrú ṣe ta ko àwọn ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” tí Ọmọ náà ti dá sílẹ̀ lómìnira. Àmọ́ ṣá o, a lé Hágárì àti ọmọ rẹ̀ síta, ìyẹn sì ń ṣàpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe lé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dànù.—Ga 4:21-31; tún wo Jo 8:31-40.
Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Nínú Ìjọba Ọlọ́run
11 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣẹ sára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n jogún Ilẹ̀ Ìlérí. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ májẹ̀mú náà tún jẹ́ kó ní ìmúṣẹ nípa tẹ̀mí. (Gál. 4:22-25) Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàlàyé ohun tí ìmúṣẹ májẹ̀mú náà nípa tẹ̀mí jẹ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Kristi ni apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù, nígbà tí àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ náà. (Gál. 3:16, 29; Ìṣí. 5:9, 10; 14:1, 4) Láìsí àní-àní, obìnrin tí ó bí irú-ọmọ náà ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ìyẹn apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, tó ní nínú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí adúróṣinṣin. (Gál. 4:26, 31) Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fi hàn pé Ọlọ́run ṣèlérí pé irú-ọmọ obìnrin náà yóò bù kún aráyé.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “Ábà, Baba” nígbà tó ń gbàdúrà sí Jèhófà?
Tá a bá tú ʼab·baʼʹ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì sí èdè Yorùbá, ó lè túmọ̀ sí “bàbá ò.” Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Ìwé Mímọ́, inú àdúrà sí Jèhófà tó jẹ́ Bàbá wa ọ̀run ni wọ́n sì ti lò ó. Kí nìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ọmọ sábà máa ń sọ pé ʼabbāʼ nígbà tí wọ́n bá ń bá bàbá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn fi hàn pé àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwọn àti bàbá wọn, ó sì tún fi hàn pé àwọn ọmọ wọ̀nyẹn bọ̀wọ̀ fún bàbá wọn.” Ọ̀rọ̀ yìí ń fi hàn pé ọmọ àti bàbá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, ó sì wà lára àwọn ọ̀rọ̀ táwọn ọmọdé kọ́kọ́ máa ń kọ́. Ìgbà tí Jésù ń gbàdúrà àtọkànwá sí Bàbá rẹ̀ ló lo ọ̀rọ̀ yìí. Jésù lo “Ábà, Baba” nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà nínú ọgbà Gẹtisémánì, nígbà tó ku nǹkan bíi wákàtí mélòó kan kí wọ́n pa á.—Máàkù 14:36.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yẹn tún sọ pé: “Bóyá la máa rí ọ̀rọ̀ náà ʼabbāʼ nínú àwọn ìwé táwọn Júù kọ nígbà tí ọ̀làjú orílẹ̀-èdè Gíríìsì àti Róòmù gbayé kan, ìdí sì ni pé ṣe ló máa dà bí àfojúdi láti lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà téèyàn bá ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.” Àmọ́, “bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń gbàdúrà tún jẹ́rìí sí i pé àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àti Ọlọ́run ṣàrà ọ̀tọ̀.” Inú àwọn ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ la ti rí ibi méjì yòókù tí “Ábà” ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, èyí sì fi hàn pé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni pàápàá máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà.—Róòmù 8:15; Gálátíà 4:6.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun ń gbé “àwọn àpá àmì ti ẹrú Jésù” kiri lára òun?—Gálátíà 6:17.
▪ Oríṣiríṣi ìtumọ̀ lọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí lè gbé wá sọ́kàn àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, ní ayé ìgbàanì, irin gbígbóná ni wọ́n máa fi ń sàmì sára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó bọ̀ lójú ogun, àwọn tó ń a tẹ́ńpìlì lólè àtàwọn ẹrú tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn kí wọ́n lè dá wọn mọ̀. Ohun àbùkù ló jẹ́ tí wọ́n bá fi irú àmì yìí sí èèyàn lára.
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àmì máa ń jẹ́ ohun àbùkù. Láyé ìgbàanì, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo àmì káwọn èèyàn lè mọ ẹ̀yà tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìwé tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì, ìyẹn Theological Dictionary of the New Testament, sọ pé, “àwọn ará Síríà máa ń sàmì sí ọrùn ọwọ́ wọn tàbí ọrùn wọn láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún ọlọ́run Hadad àti Atargatis . . . Àmì ewéko ivy ni wọ́n máa ń ṣe sára àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run Dionysus.”
Ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé lóde òní ló parí èrò sí pé àwọn àpá tí wọ́n dá sí Pọ́ọ̀lù lára láwọn ìgbà tí wọ́n lù ú lákòókò tó ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló ní lọ́kàn. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé ọ̀nà tí òun gbà gbé ìgbésí ayé òun ló fi òun hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kì í ṣe àmì tó wà lára òun.
Bíbélì Kíkà
JUNE 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÉFÉSÙ 1-3
“Iṣẹ́ Àbójútó Jèhófà àti Ohun Tó Wà Fún”
it-2 837 ¶4
Àṣírí Mímọ́
Ìjọba Mèsáyà. Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa ìṣípayá àṣírí mímọ́ ti Kristi. Nínú Éfésù 1:9-11 ó sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ká mọ “àṣírí mímọ́” nípa ìfẹ́ rẹ̀, ó ní: “Èyí bá ohun tó ń wù ú mu, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò iṣẹ́ àbójútó kan láti kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi nígbà tí àwọn àkókò tí a yàn bá tó, àwọn ohun tó wà ní ọ̀run àti àwọn ohun tó wà ní ayé. Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ẹni tí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí a sì yàn wá láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú rẹ̀, ní ti pé a ti yàn wá ṣáájú nítorí ohun tí ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo fẹ́, bí ó ṣe ń pinnu ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.” “Àṣírí mímọ́” yìí ní nínú Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà máa jẹ́ alákòóso rẹ̀. “Àwọn ohun tó wà ní ọ̀run,” tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ni àwọn tó fẹ́ jọba pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run. “Àwọn ohun tó wà ní ayé” ni àwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba yẹn lórí ilẹ̀ ayé. Jésù jẹ́ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ̀ pé àṣírí mímọ́ yẹn ní ohun kan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ìjọba náà nígbà tó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la jẹ́ kó mọ àṣírí mímọ́ Ìjọba Ọlọ́run.”—Mk 4:11.
“Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
3 Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.” (Diu. 6:4) Jèhófà máa ń ṣe nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, “ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀,” Ọlọ́run mú kí “iṣẹ́ àbójútó” kan bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ìṣètò kan táá mú kí gbogbo ẹ̀dá rẹ̀ olóye wà ní ìṣọ̀kan. (Ka Éfésù 1:8-10.) Apá méjì ni iṣẹ́ àbójútó yìí pín sí. Ní apá àkọ́kọ́, Ọlọ́run múra ìjọ àwọn ẹni àmì òróró sílẹ̀ láti lọ gbé lọ́run. Níbẹ̀ Jésù Kristi tí Ọlọ́run yàn ṣe Orí wọn ni yóò máa darí wọn. Apá yìí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run jọ. (Ìṣe 2:1-4) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti polongo àwọn ẹni àmì òróró ní olódodo fún ìyè lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, èyí mú kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ti gba ìsọdọmọ gẹ́gẹ́ bí “ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23, 24; 5:1; 8:15-17.
4 Ní apá kejì iṣẹ́ àbójútó náà, Ọlọ́run ṣe àkójọ àwọn tó máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa wọn ni apá àkọ́kọ́ lára àwùjọ àwọn èèyàn yìí. (Ìṣí. 7:9, 13-17; 21:1-5) Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó jíǹde máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. (Ìṣí. 20:12, 13) Fojú inú yàwòrán bí àjíǹde ṣe máa mú ká túbọ̀ fi hàn pé a wà ní ìṣọ̀kan! Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Kristi, “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ogunlọ́gọ̀ ńlá àtàwọn tó jíǹde ni a máa dán wò fún ìgbà ìkẹyìn. Àwọn tó bá yege ìdánwò náà máa gba ìsọdọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn “ọmọ Ọlọ́run” lórí ilẹ̀ ayé.—Róòmù 8:21; Ìṣí. 20:7, 8.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Sá Fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá ẹ Lọ́lá
15 Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí Jèhófà lè dá wọn lọ́lá? Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ní ìfaradà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Éfésù pé: “Èmi béèrè pé kí ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní tìtorí ìpọ́njú mi wọ̀nyí nítorí yín, nítorí ìwọ̀nyí túmọ̀ sí ògo fún yín.” (Éfé. 3:13) Ọ̀nà wo ni ìpọ́njú Pọ́ọ̀lù gbà “túmọ̀ sí ògo” fún àwọn ará Éfésù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní ìṣòro tó pọ̀, ó fara da àdánwò, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni Kristẹni kan gbọ́dọ̀ kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ká ní Pọ́ọ̀lù ti juwọ́ sílẹ̀ nígbà àdánwò ni, àwọn arákùnrin rẹ̀ ì bá ti lérò pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn àti ìrètí tí wọ́n ní kò ṣe pàtàkì. Àmọ́, nítorí pé Pọ́ọ̀lù ní ìfaradà, ó fi han àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé àdánwò yòówù ká fara dà nítorí pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
“Láti Mọ Ìfẹ́ Kristi”
21 Ọrọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “láti mọ̀” túmọ̀ sí mímọ̀ “tó hàn nínú ìṣe, mímọ̀ nípasẹ̀ ìrírí.” Bá a bá ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù, ìyẹn nípa fíforí-fọrùn ṣe fáwọn ẹlòmíràn, fífi tìyọ́nú-tìyọ́nú ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà àìní, dídáríjì wọ́n látọkànwá, nígbà náà la ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀ lóòótọ́. Lọ́nà yìí, nípasẹ̀ ìrírí a ó “mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.” Ká má sì gbàgbé pé bá a ṣe túbọ̀ ń fìwà jọ Kristi, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, ẹni tí Jésù fara wé lọ́nà pípé.
Bíbélì Kíkà
JUNE 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÉFÉSÙ 4-6
“Ẹ Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wọ̀”
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Dúró Gbọn-In Lòdì sí Èṣù
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé ọmọ ogun kan tó wà lójú ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tẹ̀mí là ń jà, síbẹ̀ ẹni gidi làwọn ọ̀tá wa. Ọ̀jáfáfá ọmọ ogun ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n sì ti ń jagun. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé a ò lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yìí, pàápàá tá a bá jẹ́ ọ̀dọ́. Torí náà, báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè kojú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí kí wọ́n sì borí? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀dọ́ lè ṣẹ́gun, kódà wọ́n tiẹ̀ ti ń ṣẹ́gun! Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń “bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa.” Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, ṣe ni wọ́n tún máa ń dira ogun. Bíi tàwọn akínkanjú ọmọ ogun, wọ́n ti “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.”—Ka Éfésù 6:10-12.
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Dúró Gbọn-In Lòdì sí Èṣù
4 Lọ́nà kan náà, àwọn òtítọ́ Bíbélì tá a ti kọ́ máa ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tó kúnnú ayé. (Jòh. 8:31, 32; 1 Jòh. 4:1) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti gbé “àwo ìgbàyà” wọ̀, ìyẹn ni pé á rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. (Sm. 111:7, 8; 1 Jòh. 5:3) Bákan náà, tá a bá lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àá fìgboyà gbèjà òtítọ́ lọ́dọ̀ àwọn alátakò.—1 Pét. 3:15.
7 Àfiwé yìí bá a mu gan-an torí pé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. (Òwe 4:23) Ó dájú pé ọmọ ogun kan ò ní pààrọ̀ àwo ìgbàyà tí wọ́n fi ojúlówó irin ṣe fún èyí tó jẹ́ gbàrọgùdù. Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká fi ohun tá a rò pé ó tọ́ rọ́pò àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Ìdí ni pé òye wa ò tó nǹkan, a ò sì lè fi ọgbọ́n orí wa dáàbò bo ara wa. (Òwe 3:5, 6) Torí náà, ó yẹ ká máa yẹ ‘àwo ìgbàyà’ tí Jèhófà fún wa wò déédéé, ká lè rí i dájú pé ó ṣì ń dáàbò bo ọkàn wa.
10 Bó ṣe jẹ́ pé bàtà táwọn ọmọ ogun Róòmù wọ̀ ló máa ń gbé wọn lọ sójú ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni bàtà ìṣàpẹẹrẹ táwa Kristẹni wọ̀ máa ń jẹ́ ká lè mú ìhìn rere àlàáfíà lọ fáwọn èèyàn. (Aísá. 52:7; Róòmù 10:15) Síbẹ̀, ó gba ìgboyà ká tó lè sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Ọmọ ogún [20] ọdún ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Bo, ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà mí láti wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì mi torí pé ojú máa ń tì mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó ń jẹ́ kójú tì mí. Àmọ́ ní báyìí, inú mi máa ń dùn láti wàásù fún wọn.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 1128 ¶3
Ìjẹ́mímọ́
Ẹ̀mí mímọ́. Jèhófà máa ń darí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́ kó di ṣíṣe. Ohun mímọ́ ní, kò lábàwọ́n, ó tún jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ láti máa fi ṣiṣẹ́. Torí náà, a pè é ní “ẹ̀mí mímọ́” tàbí ẹ̀mí ìjẹ́mímọ́. (Sm 51:11; Lk 11:13; Ro 1:4; Ef 1:13) Kí ẹ̀mí mímọ́ tó lè ṣiṣẹ́ lára ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Tí ẹni náà kò bá jẹ́ mímọ́ tàbí tó ń hùwà àìtọ́, ó máa dènà tàbí “kó ẹ̀dùn ọkàn” bá ẹ̀mí mímọ́. (Ef 4:30) Lóòótọ́ ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìmọ̀lára, àmọ́ ó ń gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, torí náà a lè “kó ẹ̀dùn ọkàn” bá ẹ̀mí mímọ́. Ẹni tó bá ń hùwà tí kò bójú mu máa “pa iná ẹ̀mí” tó wà lára rẹ̀. (1Tẹ 5:19) Tí ẹni náà kò bá jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́, ó máa fa “ẹ̀dùn ọkàn” fún ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn sì máa mú kí Ọlọ́run di ọ̀tá ẹni tó ń hùwà àìtọ́ náà. (Ais 63:10) Ẹni tó bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ tún lè ṣeé débi tó fi máa sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, Jésù sì ti sọ pé ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kò ní rí ìdáríjì nínú ètò nǹkan yìí tàbí nínú èyí tó ń bọ̀.—Mt 12:31, 32; Mk 3:28-30; wo Ẹ̀MÍ.
it-1 1006 ¶2
Ojúkòkòrò
Ó Máa Ń Hàn Nínú Ìwà. Téèyàn kan bá ní ojúkòkòrò, ó máa ń hàn nínú ohun tí onítọ̀hún bá ń ṣe, débi táwọn míì á fi mọ̀ pé olójúkòkòrò ni ẹni náà. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jémíìsì sọ pé tí ìfẹ́ ọkàn ẹnì kan bá ti gbilẹ̀, ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀. (Jem 1:14, 15) Ohun tí ẹnì kan bá ń ṣe ló máa fi hàn bóyá ó ní ojúkòkòrò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹni tó bá ní ojúkòkòrò tún jẹ́ abọ̀rìṣà. (Ef 5:5) Ẹni tó bá ní ojúkòkòrò fún nǹkan kan, máa sọ ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fà sí yẹn di ọlọ́run rẹ̀, á sì tún fi í sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀, kódà ṣáájú ìjọsìn rẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá.—Ro 1:24, 25.
Bíbélì Kíkà
JUNE 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | FÍLÍPÌ 1-4
“Ẹ Má Ṣe Máa Ṣàníyàn Nípa Ohunkóhun”
‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
10 Kí ni kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, táá sì mú ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run”? Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Fílípì pé àdúrà lòògùn àníyàn. Nígbà tá a bá ń ṣàníyàn, ṣe ló yẹ ká tú gbogbo ọkàn wa jáde nínú àdúrà. (Ka 1 Pétérù 5:6, 7.) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó yẹ kó dá wa lójú pé á gbọ́ wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa dúpẹ́ àwọn oore tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa. Tá a bá ń rántí pé Jèhófà “lè ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò,” ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ máa túbọ̀ lágbára.—Éfé. 3:20.
‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
7 Kò sí àní-àní pé táwọn ará ní Fílípì bá ń ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn, wọ́n á rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i àti bí Jèhófà ṣe dá òun àti Sílà nídè lọ́nà tí ẹnikẹ́ni ò lérò. Ẹ̀kọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n kọ́? Ẹ̀kọ́ náà ni pé kí wọ́n má ṣàníyàn. Ó ní kí wọ́n gbàdúrà, wọ́n á sì rí àlàáfíà Ọlọ́run. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé “àlàáfíà Ọlọ́run . . . ta gbogbo ìrònú yọ.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun táwọn atúmọ̀ èdè kan tú gbólóhùn yìí sí ni pé àlàáfíà Ọlọ́run “ju ìmọ̀ gbogbo lọ” tàbí pé “ó tayọ òye eniyan.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé “àlàáfíà Ọlọ́run” kọjá gbogbo ohun tá a lè rò lọ. Nígbà míì, àwa fúnra wa lè má rí ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro wa, àmọ́ Jèhófà mọ ọ̀nà àbáyọ, ó sì lè gba ọ̀nà àrà kó wa yọ nínú ìṣòro náà.—Ka 2 Pétérù 2:9.
‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
16 Kí ni “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” máa ń ṣe fún wa? Ìwé Mímọ́ sọ pé ‘yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílí. 4:7) Àwọn ẹ̀ṣọ́ ni wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ṣọ́” nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn fún. Ọ̀rọ̀ náà sì ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n máa ń ṣọ́ àwọn ìlú olódi láyé àtijọ́. Fílípì wà lára irú àwọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ọkàn àwọn aráàlú Fílípì máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ń sùn lálẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ wà tó ń ṣọ́ ibodè ìlú. Lọ́nà kan náà, tá a bá ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ọkàn wa máa balẹ̀, ara sì máa tù wá. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ káyé wa dùn kó sì lóyin. (1 Pét. 5:10) Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, kì í sì í jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 528 ¶5
Ọrẹ
Ọrẹ ohun mímu. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń mú u wá pẹ̀lú àwọn ọrẹ míì, pàápàá jù lọ lẹ́yìn tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Nu 15:2, 5, 8-10) Wáìnì wà nínú rẹ̀ (“ọtí tí ń pani”), wọ́n sì máa ń dà á sórí pẹpẹ. (Nọ 28:7, 14; fi wé Ẹk 30:9; Nọ 15:10.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì pé: “Bí a tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu sórí ẹbọ àti iṣẹ́ mímọ́ tí ìgbàgbọ́ yín ń mú kí ẹ ṣe, inú mi ń dùn.” Níbí, Pọ́ọ̀lù lo ọrẹ ohun mímu lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti jẹ́ ká mọ bí òun ṣe ti múra tán láti lo ara òun fún àwọn Kristẹni bí tiẹ̀. (Flp 2:17) Kó tó kú, ó kọ̀wé sí Tímótì pé: “A ti ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu, a sì máa tó tú mi sílẹ̀.”—2Ti 4:6.
“Àjíǹde Èkíní” Ti Ń lọ Lọ́wọ́!
5 Lẹ́yìn èyí, àwọn tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ Olúwa Jésù Kristi nínú ògo ti ọ̀run, níbi tí wọn yóò ti “máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.” (Gálátíà 6:16; 1 Tẹsalóníkà 4:17) Èyí ni Bíbélì pè ní “àjíǹde àkọ́kọ́” tàbí “àjíǹde èkíní.” (Fílípì 3:10, 11; Ìṣípayá 20:6) Nígbà tí àjíǹde yìí bá parí ni àkókò á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá tó láti jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn dìde sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè. Nítorí náà, yálà ọ̀run ni ìrètí wa tàbí orí ilẹ̀ ayé, ó wù wá láti mọ̀ nípa “àjíǹde èkíní.” Irú àjíǹde wo ni? Ìgbà wo ló sì máa ṣẹlẹ̀?
Bíbélì Kíkà