Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ẹ Dúró Gbọn-In Lòdì sí Èṣù
“Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—ÉFÉ. 6:11.
1, 2. (a) Kí ni àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ń ṣe tó ń mú kí wọ́n ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí la máa jíròrò?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé ọmọ ogun kan tó wà lójú ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tẹ̀mí là ń jà, síbẹ̀ ẹni gidi làwọn ọ̀tá wa. Ọ̀jáfáfá ọmọ ogun ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n sì ti ń jagun. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé a ò lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yìí, pàápàá tá a bá jẹ́ ọ̀dọ́. Torí náà, báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè kojú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí kí wọ́n sì borí? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀dọ́ lè ṣẹ́gun, kódà wọ́n tiẹ̀ ti ń ṣẹ́gun! Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń “bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa.” Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, ṣe ni wọ́n tún máa ń dira ogun. Bíi tàwọn akínkanjú ọmọ ogun, wọ́n ti “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.”—Ka Éfésù 6:10-12.
2 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìhámọ́ra táwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń wọ̀ ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nínú àpèjúwe yìí. (Ìṣe 28:16) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìhámọ́ra náà, ká sì wo bá a ṣe lè lò wọ́n. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ máa kíyè sí ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú. Àá sì tún rí àwọn àǹfààní tí wọ́n rí nínú bí wọ́n ṣe lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìhámọ́ra tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn.
‘ABẸ́NÚ TÍ A FI ÒTÍTỌ́ DÌ LÁMÙRÈ’
3, 4. Báwo ni òtítọ́ Bíbélì ṣe dà bíi bẹ́líìtì àwọn ọmọ ogun Róòmù?
3 Ka Éfésù 6:14. Àwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń wọ bẹ́líìtì tàbí àmùrè tí wọ́n to irin sí kó lè dáàbò bo abẹ́nú wọn. Bẹ́líìtì yìí ni kì í jẹ́ káwọn ìhámọ́ra míì tí wọ́n wọ̀ wúwo jù fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn bẹ́líìtì kan tún ní apó tí wọ́n lè fi idà àti ọ̀bẹ aṣóró sí. Tí ọmọ ogun kan bá de bẹ́líìtì rẹ̀ dáadáa, á dúró wámúwámú lójú ogun.
4 Lọ́nà kan náà, àwọn òtítọ́ Bíbélì tá a ti kọ́ máa ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tó kúnnú ayé. (Jòh. 8:31, 32; 1 Jòh. 4:1) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti gbé “àwo ìgbàyà” wọ̀, ìyẹn ni pé á rọrùn fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. (Sm. 111:7, 8; 1 Jòh. 5:3) Bákan náà, tá a bá lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àá fìgboyà gbèjà òtítọ́ lọ́dọ̀ àwọn alátakò.—1 Pét. 3:15.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sọ òtítọ́?
5 Tá a bá ń jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì darí ìgbésí ayé wa, á rọrùn fún wa láti máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa parọ́? Ìdí ni pé ọ̀kan gbòógì nínú àwọn nǹkan tí Sátánì fi ń gbéjà kò wá ni irọ́ pípa. Irọ́ máa ń tàbùkù sẹ́ni tó pa á, ó sì máa ń ṣàkóbá fẹ́ni tó bá gba irọ́ náà gbọ́. (Jòh. 8:44) Torí náà, láìka pé a jẹ́ aláìpé, ó yẹ ká sapá láti máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. (Éfé. 4:25) Àmọ́ ká sòótọ́, kì í rọrùn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Abigail sọ pé: “Nígbà míì, ó lè dà bíi pé òótọ́ ò lérè, pàápàá tó bá jẹ́ pé irọ́ máa kó wa yọ nínú wàhálà kan.” Kí wá nìdí tó fi máa ń sapá láti sòótọ́ nígbà gbogbo? Ó ní: “Sísọ òtítọ́ máa ń jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn rere. Àwọn òbí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sì fọkàn tán mi.” Victoria tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] sọ pé: “Tó o bá ń sòótọ́, tó o sì ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, àwọn kan lè halẹ̀ mọ́ ẹ. Síbẹ̀, àǹfààní tó o máa rí kì í ṣe kékeré, lára ẹ̀ ni pé: Wàá nígboyà, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.” Ẹ ò rí i báyìí pé ó ṣe pàtàkì ká fi ‘òtítọ́ di abẹ́nú wa lámùrè’ nígbà gbogbo.
“ÀWO ÌGBÀYÀ TI ÒDODO”
6, 7. Kí nìdí tá a fi fi òdodo wé àwo ìgbàyà?
6 Àwọn irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ tí wọ́n dè mọ́ ara wọn ni wọ́n fi ṣe àwo ìgbàyà táwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń lò. Wọ́n sì fi awọ tó nípọn de àwọn irin náà kó lè bo àyà àwọn ọmọ ogun. Àwọn irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ tí wọ́n ṣẹ́ sórí ara wọn, tí wọ́n sì fi awọ tó nípọn dè ni wọ́n fi bo èjìká àwọn ọmọ ogun náà. Ìhámọ́ra yìí lè mú kó ṣòro díẹ̀ fún ọmọ ogun kan láti rìn bó ṣe fẹ́, ó sì lè gba pé kó máa yẹ ìhámọ́ra náà wò lóòrèkóòrè kó lè rí i dájú pé ó dúró bó ṣe yẹ. Àmọ́ táwọn ọ̀tá bá fẹ́ gún un ní idà tàbí tí wọ́n ta á lọ́fà, àwo ìgbàyà yìí ló máa dáàbò bo ọkàn rẹ̀, kò sì ní jẹ́ káwọn nǹkan yẹn pa á lára.
7 Àfiwé yìí bá a mu gan-an torí pé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. (Òwe 4:23) Ó dájú pé ọmọ ogun kan ò ní pààrọ̀ àwo ìgbàyà tí wọ́n fi ojúlówó irin ṣe fún èyí tó jẹ́ gbàrọgùdù. Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká fi ohun tá a rò pé ó tọ́ rọ́pò àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Ìdí ni pé òye wa ò tó nǹkan, a ò sì lè fi ọgbọ́n orí wa dáàbò bo ara wa. (Òwe 3:5, 6) Torí náà, ó yẹ ká máa yẹ ‘àwo ìgbàyà’ tí Jèhófà fún wa wò déédéé, ká lè rí i dájú pé ó ṣì ń dáàbò bo ọkàn wa.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà?
8 Nígbà míì, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà kò jẹ́ kó o lè ṣe bó o ṣe fẹ́? Daniel tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé: “Àwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọléèwé mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Èyí mú kí n rẹ̀wẹ̀sì nígbà kan, mi ò sì mọ ohun tí màá ṣe.” Báwo lọ̀rọ̀ ṣe wá rí lára ẹ̀ báyìí? Ó sọ pé: “Ní báyìí, mo ti rí i pé àwọn ìlànà Jèhófà máa ń ṣe wá láǹfààní. Àwọn ọmọléèwé mi kan bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, àwọn míì sì fi iléèwé sílẹ̀. Tí mo bá rí bí ìgbésí ayé wọn ṣe dìdàkudà, mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń dáàbò bò wá.” Madison tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọ̀tọ̀ ni ohun táwọn ẹgbẹ́ mi fẹ́ kí n ṣe.” Kí ni Madison wá ṣe? Ó ní: “Mo máa ń rán ara mi létí pé mò ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà àti pé Sátánì ló ń lo àwọn ìdẹwò yẹn kó lè dẹkùn mú mi. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ti borí ìdẹwò kan.”
‘ẸSẸ̀ TÍ A FI OHUN ÌṢIṢẸ́ ÌHÌN RERE ÀLÀÁFÍÀ WỌ̀ NÍ BÀTÀ’
9-11. (a) Bàtà ìṣàpẹẹrẹ wo làwa Kristẹni wọ̀? (b) Kí ló máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti wàásù?
9 Ka Éfésù 6:15. Ọmọ ogun Róòmù kan ò lè lọ sójú ogun láìwọ bàtà rẹ̀. Awọ mẹ́ta tó nípọn tí wọ́n rán pa pọ̀ ni wọ́n fi ṣe bàtà náà. Wọ́n ṣe bàtà náà lọ́nà táá mú kí ọmọ ogun kan lè rìn dáadáa, kó má sì ta á lẹ́sẹ̀.
10 Bó ṣe jẹ́ pé bàtà táwọn ọmọ ogun Róòmù wọ̀ ló máa ń gbé wọn lọ sójú ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni bàtà ìṣàpẹẹrẹ táwa Kristẹni wọ̀ máa ń jẹ́ ká lè mú ìhìn rere àlàáfíà lọ fáwọn èèyàn. (Aísá. 52:7; Róòmù 10:15) Síbẹ̀, ó gba ìgboyà ká tó lè sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Ọmọ ogún [20] ọdún ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Bo, ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà mí láti wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì mi torí pé ojú máa ń tì mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó ń jẹ́ kójú tì mí. Àmọ́ ní báyìí, inú mi máa ń dùn láti wàásù fún wọn.”
11 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí ti rí i pé táwọn bá múra sílẹ̀ dáadáa, ó túbọ̀ máa ń rọrùn fún wọn láti wàásù. Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀? Julia tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Mo máa ń kó àwọn ìtẹ̀jáde sínú báàgì mi, mo sì máa ń tẹ́tí sí àwọn ọmọ kíláàsì mi tí wọ́n bá ń sọ èrò wọn tàbí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sọ àwọn nǹkan táá ṣe wọ́n láǹfààní torí pé mo ti múra sílẹ̀.” Makenzie tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] sọ pé: “Tó o bá ń tẹ́tí sí wọn dáadáa, tó o sì ń jẹ́ kára tù wọ́n, wàá lè mọ ohun táwọn ẹgbẹ́ rẹ ń kojú. Mo rí i dájú pé mo ti ka gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n ṣe fáwa ọ̀dọ́. Èyí máa ń jẹ́ kí n lè lo Bíbélì tàbí àwọn àpilẹ̀kọ orí ìkànnì jw.org láti ran àwọn ẹgbẹ́ mi lọ́wọ́.” Báwọn ọ̀dọ́ yìí ṣe sọ, tá a bá ń múra sílẹ̀ dáadáa láti wàásù, ṣe la túbọ̀ ń jẹ́ kí “bàtà” ìṣàpẹẹrẹ náà dúró digbí lẹ́sẹ̀ wa.
“APATA ŃLÁ TI ÌGBÀGBỌ́”
12, 13. Kí ni díẹ̀ lára àwọn “ohun ọṣẹ́ oníná” tí Sátánì máa ń lò?
12 Ka Éfésù 6:16. “Apata ńlá” táwọn ọmọ ogun Róòmù ń lò máa ń ní igun mẹ́rin, ó sì máa ń bò wọ́n láti èjìká dé orúnkún. Apata yìí máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ohun ọṣẹ́ táwọn ọ̀tá ń lò bí idà, ọ̀kọ̀ tàbí ọfà.
13 Onírúurú “ohun ọṣẹ́ oníná” ni Sátánì máa ń lò fún wa. Lára ẹ̀ ni irọ́ tó máa ń pa nípa Jèhófà. Ó máa ń jẹ́ ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kò sẹ́ni tó rí tiwa rò. Ida tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] máa ń ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Ó sọ pé, “Ó máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà jìnnà sí mi àti pé kò fẹ́ jẹ́ Ọ̀rẹ́ mi.” Kí wá ni Ida ṣe? Ó sọ pé: “Àwọn ìpàdé máa ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun. Tẹ́lẹ̀, mi ò kì í dáhùn nípàdé, màá kàn jókòó síbẹ̀ lásán torí mo máa ń ronú pé kò sẹ́ni tó kúkú fẹ́ gbọ́ ohun tí màá sọ. Àmọ́ ní báyìí, mo máa ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, mo sì máa ń sapá láti dáhùn lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹta. Kì í rọrùn fún mi, àmọ́ ara máa ń tù mí tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará ò fi mí sílẹ̀. Kí n sòótọ́, gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sípàdé ni mo máa ń rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”
14. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ida?
14 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ida kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan: Apata táwọn ọmọ ogun Róòmù ń lò ti ní bó ṣe fẹ̀ tó, kò ṣeé sọ di kékeré tàbí ńlá. Àmọ́ apata ńlá ti ìgbàgbọ́ táwa ní lè kéré tàbí kó túbọ̀ tóbi. Bóyá ìgbàgbọ́ wa máa kéré tàbí ó máa tóbi, ọwọ́ wa nìyẹn kù sí. (Mát. 14:31; 2 Tẹs. 1:3) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára sí i!
“ÀṢÍBORÍ ÌGBÀLÀ”
15, 16. Báwo ni ìrètí ṣe dà bí àṣíborí?
15 Ka Éfésù 6:17. Wọ́n dìídì ṣe àṣíborí táwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń dé kó lè dáàbò bo orí wọn, ọrùn wọn àti ojú wọn lọ́wọ́ ohun ọṣẹ́ èyíkéyìí. Àwọn àṣíborí kan sì wà tó ní ìfàlọ́wọ́ táwọn ọmọ ogun lè dì mú.
16 Bí àṣíborí ṣe máa ń dáàbò bo ọpọlọ ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìrètí ìgbàlà” tá a ní máa ń dáàbò bo èrò orí wa, ìyẹn bá a ṣe ń ronú. (1 Tẹs. 5:8; Òwe 3:21) Ìrètí tá a ní máa ń jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí Ọlọ́run, kì í sì í jẹ́ ká gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. (Sm. 27:1, 14; Ìṣe 24:15) Àmọ́ tá a bá fẹ́ kí “àṣíborí” yìí dáàbò bò wá, orí la gbọ́dọ̀ dé e sí, kì í ṣe pé ká fà á lọ́wọ́.
17, 18. (a) Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì lè lò láti mú ká ṣí àṣíborí wa? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí Sátánì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí tàn wá jẹ?
17 Tá ò bá ṣọ́ra, Sátánì lè mú ká ṣí àṣíborí wa. Lọ́nà wo? Ẹ wo ohun tó ṣe fún Jésù. Sátánì mọ̀ dájú pé Jésù ló máa di ọba gbogbo ayé lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ Jésù gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù títí di àsìkò tí Jèhófà yàn kalẹ̀. Kí Jésù tó di ọba, ó máa jìyà, á sì kú. Sátánì wá sọ fún un pé ó lè di ọba láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ jẹ gbogbo ìyà yẹn. Sátánì ní tí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó máa di ọba lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Lúùkù 4:5-7) Sátánì ṣì ń lo irú ọgbọ́n yẹn lónìí. Ó mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún wa nínú ayé tuntun. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù kí ìlérí yẹn tó ṣẹ, kódà a tiẹ̀ lè jìyà pàápàá. Torí náà, Sátánì lè mú ká máa ronú pé kò dìgbà tá a bá dúró kí ayé tuntun dé ká tó lè gbádùn ayé wa. Ó fẹ́ ká gbájú mọ́ bá a ṣe máa kó àwọn nǹkan tara jọ, ká sì fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kejì.—Mát. 6:31-33.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lónìí ò jẹ́ kí Sátánì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí tàn wọ́n jẹ. Bí àpẹẹrẹ, Kiana tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Mo mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro wa.” Kí wá ni ìrètí tó dájú yìí mú kó ṣe? Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń ronú nípa Párádísè kì í jẹ́ kí n máa lé àwọn nǹkan tara. Dípò tí màá fi máa lé bí màá ṣe rọ́wọ́ mú nínú ayé yìí, iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni mò ń lo àkókò mi àti okun mi fún.”
“IDÀ Ẹ̀MÍ” TÍ Í ṢE Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
19, 20. Báwo la ṣe lè túbọ̀ jáfáfá nínú bá a ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
19 Lásìkò tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀, idà àwọn ọmọ ogun Róòmù máa ń gùn tó àádọ́ta [50] sẹ̀ǹtímítà. Akínkanjú làwọn ọmọ ogun Róòmù tó bá di pé kí wọ́n lo idà, ìdí sì ni pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń lo idà yìí tí wọ́n bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ jáfáfá sí i lójú ogun.
20 Pọ́ọ̀lù fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé idà tí Jèhófà fún wa. Àmọ́ ó yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè lo idà yìí dáadáa tá a bá fẹ́ gbèjà ìgbàgbọ́ wa tàbí tá a bá fẹ́ tún èrò wa ṣe. (2 Kọ́r. 10:4, 5; 2 Tím. 2:15) Báwo la ṣe lè túbọ̀ jáfáfá nínú bá a ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Sebastian tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé: “Tí mo bá ka orí kan nínú Bíbélì, màá fi ẹsẹ kan sọ́kàn màá sì kọ ọ́ sílẹ̀, torí pé mò ń ṣàkójọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo nífẹ̀ẹ́ sí. Bí mo ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan.” Daniel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tí mo bá ń ka Bíbélì, mo máa ń wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo lè kà fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí. Mo ti rí i pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tí wọ́n bá rí i pé a lóye Bíbélì dáadáa, a sì fẹ́ ran àwọn lọ́wọ́.”
21. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀?
21 Ohun táwọn ọ̀dọ́ tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ ti jẹ́ ká rí i pé kò sídìí kankan fún wa láti máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Wọ́n lágbára lóòótọ́, àmọ́ a lè ṣẹ́gun wọn, kódà wọn ò ní pẹ́ pa run. Tó bá dìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Níbẹ̀, wọn ò ní lè pa ẹnikẹ́ni lára, lẹ́yìn náà wọ́n máa pa run pátápátá. (Ìṣí. 20:1-3, 7-10) Inú wa dùn pé a ti mọ ọ̀tá wa, a mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń lò, a sì mọ ohun tó fẹ́ ṣe. Ó dájú pé lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a máa dúró gbọin-in, Èṣù ò sì ní rí wa gbé ṣe.