Ẹ̀KỌ́ 50
Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?—Apá Kejì
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọmọ jẹ́. Jèhófà sì retí pé káwọn òbí tọ́jú ẹ̀bùn náà dáadáa. Jèhófà ti fún àwọn òbí ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìmọ̀ràn yìí tún lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ báwọn náà ṣe lè mú kí ayọ̀ tó wà nínú ìdílé pọ̀ sí i.
1. Ìmọ̀ràn wo ni Jèhófà fún àwọn òbí?
Jèhófà fẹ́ káwọn òbí máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa wá àyè láti wà pẹ̀lú wọn. Ó fẹ́ kí àwọn òbí máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì jẹ́ kí ìlànà Bíbélì máa darí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn. (Òwe 1:8) Jèhófà sọ fáwọn bàbá pé: “Ẹ máa tọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú . . . ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Ka Éfésù 6:4.) Inú Jèhófà máa ń dùn táwọn òbí bá ń tẹ̀ lé ìlànà tó fún wọn nípa bí wọ́n ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ wọn, tí wọn ò sì gbéṣẹ́ náà fún ẹlòmíì.
2. Ìmọ̀ràn wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ?
Jèhófà sọ fáwọn ọmọ pé: “Ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu.” (Ka Kólósè 3:20.) Táwọn ọmọ bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, wọ́n á múnú Jèhófà dùn, inú àwọn òbí wọn náà á sì dùn. (Òwe 23:22-25) Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn nígbà tó wà ní kékeré. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni, ó máa ń gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ̀ lẹ́nu, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn.—Lúùkù 2:51, 52.
3. Báwo ni ìdílé rẹ ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
Tó o bá jẹ́ òbí, ó dájú pé wàá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi tìẹ. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ pé: ‘Kí o máa fi ọ̀rọ̀ Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ rẹ léraléra, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà.’ (Diutarónómì 6:7) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé o ní láti máa sọ ohun kan náà fáwọn ọmọ rẹ léraléra kí wọ́n tó lè rántí. Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé ó yẹ kó o máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Torí náà, á dáa kí ìdílé yín wá àkókò kan pàtó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kódà tẹ́ ò bá lọ́mọ, ọ̀pọ̀ àǹfààní lẹ ṣì máa rí tẹ́ ẹ bá ń wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe kí ìdílé rẹ lè láyọ̀, kí ọkàn yín sì balẹ̀.
4. Máa fìfẹ́ bá àwọn ọmọ rẹ wí
Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni láti tọ́ ọmọ. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́? Ka Jémíìsì 1:19, 20, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo làwọn òbí ṣe lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀?
Kí nìdí tí kò fi yẹ kí òbí kan bá ọmọ rẹ̀ wí nígbà tínú ṣì ń bí òbí náà?a
5. Dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ
Kó o lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ, ó ṣe pàtàkì kó o bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àmọ́ èyí lè má rọrùn. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ló máa ń jẹ́ kó nira fáwọn òbí kan láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?
Báwo làwọn òbí kan ṣe máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí, ṣe ni ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí ń burú sí i. Ka 2 Tímótì 3:1, 13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ẹsẹ kẹtàlá (13) sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn burúkú, ọ̀kan lára ohun tí wọ́n sì máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Torí náà, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn tó lè fẹ́ bá wọn ṣèṣekúṣe?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé àti fídíò tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ àti bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Díẹ̀ lára wọn rèé:
Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ (fídíò)
“Kọ́ Ọmọ Rẹ Nípa Ìbálòpọ̀” (Jí! No. 5 2016)
6. Máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ
Bí àwọn ọmọ ṣe ń bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ lè fi hàn bóyá wọ́n bọ̀wọ̀ fún wọn. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ máa bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀?
Báwo ni ọmọ kan ṣe lè bá àwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún wọn?
Ka Òwe 1:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló yẹ kí ọmọ kan ṣe táwọn òbí ẹ̀ bá tọ́ ọ sọ́nà?
7. Ẹ máa sin Jèhófà pa pọ̀ nínú ìdílé yín
Àwọn ìdílé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àkókò kan pàtó tí wọ́n máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí ni wọ́n máa ń ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé náà? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí làwọn ìdílé lè ṣe kí wọ́n lè máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé?
Kí làwọn òbí lè ṣe kí ìjọsìn ìdílé wọn lè gbádùn mọ́ni, kó sì ṣe ìdílé wọn láǹfààní?—Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí.
Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún ìdílé yín láti kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀?
Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà fẹ́ káwọn ìdílé máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé. Ka Diutarónómì 6:6, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo lo ṣe lè máa tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?
Àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé:
Ẹ lè jọ múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀.
Ẹ lè jọ ka ìtàn kan nínú Bíbélì, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ lọ́nà táá fi gbádùn mọ́ni.
Tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọdé, ẹ máa rí eré ọwọ́ fún àwọn ọmọdé lórí ìkànnì jw.org, ẹ lè wàá jáde tàbí kẹ́ ẹ tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé.
Tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọ tó jẹ́ ọ̀dọ́, ẹ lè jọ ka ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fáwọn ọ̀dọ́ lórí ìkànnì jw.org.
Ẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín lè jọ fi ìtàn kan nínú Bíbélì ṣe eré tó gbádùn mọ́ni.
Ẹ lè jọ wo fídíò kan tó wà lórí ìkànnì jw.org, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àwọn ọmọdé ò lè lóye Bíbélì, torí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ti le jù.”
Kí lèrò ẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ káwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n máa fìfẹ́ bá wọn wí, kí wọ́n sì máa dáàbò bò wọ́n; ó fẹ́ káwọn ọmọ máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí, kí wọ́n sì máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu; ó tún fẹ́ kí ìdílé máa jọ́sìn òun pa pọ̀.
Kí lo rí kọ́?
Báwo làwọn òbí ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn wí, kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n?
Báwo làwọn ọmọ ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn?
Àwọn àǹfààní wo ni ìdílé máa rí tí wọ́n bá ń wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo lo lè kọ́ ọmọ rẹ kó lè níwà ọmọlúwàbí tó bá dàgbà?
Ka ìwé yìí kó o lè rí àwọn ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn tó ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà.
“Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí A Ṣe Lè Tọ́jú Àwọn Òbí Wa Tó Ti Dàgbà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan tí kò mọ̀ nípa ọmọ títọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ yanjú.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí àwọn bàbá ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn.
“Kí Làwọn Bàbá Lè Ṣe Tí Àjọṣe Wọn Pẹ̀lú Ọmọkùnrin Wọn Kò Fi Ní Bà Jẹ́?” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2011)