Wọ́n Wà Ní Ìṣọ̀kan Nínú Ìdè Ìfẹ́ Pípé
“[Ẹ] so . . . pọ̀ ní ìbáramuṣọ̀kan ninu ìfẹ́.”—KOLOSSE 2:2, NW.
1, 2. Agbára ìdarí tí ń pínniníyà wo ni a ń nímọ̀lára rẹ̀ lónìí?
TẸ́TÍSÍLẸ̀! Ohùn rara kan ń dún ní àdúntúndún jákèjádò ọ̀run tí ń sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” (Ìṣípayá 12:12, NW) Bí ọdún kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá lọ, ìhìn-iṣẹ́ yẹn ń di àmì-ibi síwájú àti síwájú síi fún àwọn olùgbé ayé.
2 Elénìní ńlá fún Jehofa ni a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ gẹ́gẹ́ bí alátakò (Satani) àti abanijẹ́ (Eṣu). Ṣùgbọ́n atannijẹ yìí ń kó ipa olùdámọ̀ràn ibi mìíràn nísinsìnyí—ó ti di ọlọrun tí inú ń bí! Èéṣe? Nítorí pé Mikaeli náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lé e jáde kúrò ní ọ̀run nínú ogun náà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run ní 1914. (Ìṣípayá 12:7-9) Eṣu mọ̀ pé kìkì sáà àkókò kúkúrú ni òun ní láti jẹ́rìí gbe ìpèníjà òun pé òun lè yí gbogbo ènìyàn padà kúrò nínú jíjọ́sìn Ọlọrun. (Jobu 1:11; 2:4, 5) Láìní ibòmíràn tí ó lè yíjú sí fún àsálà, òun àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ àwọn oyin tí inú ń bí tí wọ́n ń fi ìkanra ìbínú wọn mọ́ àwọn gbáàtúù aráyé tí ara wọn kò balẹ̀.—Isaiah 57:20.
3. Kí ni ó ti jẹ́ ìyọrísí ìrẹ̀nípòwálẹ̀ Satani ní àkókò wa?
3 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, tí ẹ̀dá ènìyàn kò fojú rí, ṣàlàyé ìdí ti ìwólulẹ̀ ìwàrere ní gbogbogbòò fi wà báyìí láàárín aráyé. Wọ́n tún ṣàlàyé àwọn ìsapá oníkìtàkìtà tí àwọn ènìyàn ń ṣe láti ṣe ìsopọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ èyí tí ó dájú pé wọn kò lè gbé papọ̀ ní ìṣọ̀kan. Àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀yà-èdè àti ẹ̀yà-ìran ń kọlu araawọn lẹ́nìkínní kejì lọ́nà rírorò, ó sì ń yọrísí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọn kò nílé àti àwọn tí a fipá lé kúrò nílé. Abájọ ti ìwà àìlófin fi ń pọ̀ síi ní ìwọ̀n kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí! Gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe sọtẹ́lẹ̀, ‘ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jùlọ nínú aráyé ń di tútù.’ Níbi gbogbo tí o bá yíjú sí, àìsí ìṣọ̀kan àti àìsí ìfẹ́ ni a ń rí nínú ìran ènìyàn tí ara wọn kò balẹ̀ ti òde-ìwòyí.—Mattteu 24:12, NW.
4. Èéṣe tí àwọn ènìyàn Ọlọrun fi wà nínú ewu àrà-ọ̀tọ̀?
4 Lójú bí ipò ọ̀ràn ayé ti rí lónìí, àdúrà Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìjẹ́pàtàkì jíjinlẹ̀ síi pé: “Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ, kì í ṣe lati mú wọn kúrò ní ayé, bíkòṣe lati máa ṣọ́ wọn nitori ẹni burúkú naa. Wọn kì í ṣe apákan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí emi kì í ti í ṣe apákan ayé.” (Johannu 17:15, 16, NW) Lónìí, “ẹni burúkú naa” ní pàtàkì ń tú ìkanra ìbínú rẹ̀ sórí àwọn wọnnì “tí ń pa awọn àṣẹ Ọlọrun mọ́ tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jesu.” (Ìṣípayá 12:17, NW) Bí kì í bá ṣe ìṣọ́ àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jehofa ni, àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ olùṣòtítọ́ ìbá ti parẹ́. Ìgbésí-ayé wa sinmi lé lílo gbogbo àwọn ìpèsè tí Ọlọrun ń ṣe fún àìléwu àti ire tẹ̀mí wa lọ́nà tí ó ṣàǹfààní. Èyí wémọ́ lílo araawa ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ agbára Rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi, gẹ́gẹ́ bí aposteli náà ṣe rọni ní Kolosse 1:29.
5, 6. Ìmọ̀lára wo ni aposteli Paulu ní nípa àwọn Kristian ní Kolosse, èésìtiṣe tí ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa fún 1995 fi ṣe rẹ́gí?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí Paulu má rí wọn rí lójú-koro-jú, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará rẹ̀ ní Kolosse. Ó sọ fùn wọn pé: “Mo lérò pé ẹ̀yin lè lòye bí àníyàn mi fún yin ṣe jinlẹ̀ tó.” (Kolosse 2:1, The New Testament in Modern English, láti ọwọ́ J. B. Phillips) Níwọ̀n bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu kì í ti í ṣe apákan ayé, “ẹni burúkú naa” yóò máa báa nìṣó ní gbígbìyànjú láti ba ìṣọ̀kan àwọn ará jẹ́ nípa gbígbin ẹ̀mí ayé sáàárín wọn. Ìròyìn tí Epafra mú wá sí Kolosse fihàn pé èyí ti ń ṣẹlẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan.
6 Ọ̀kan lára àwọn olórí àníyàn Paulu fún àwọn Kristian arákùnrin rẹ̀ ni a lè kópọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: ‘Ẹ so pọ̀ ní ìbáramuṣọ̀kan ninu ìfẹ́.’ Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àkànṣe ìtumọ̀ lónìí, nínú ayé kan tí ó kún fún àìsí ìṣọ̀kan àti àìsí ìfẹ́. Bí a bá fi àwọn ìmọ̀ràn Paulu sọ́kàn, àwa yóò gbádùn àbójútó Jehofa. Àwa yóò sì tún ní ìrírí agbára ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé wa, ní ríràn wá lọ́wọ́ láti dènà àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹ wo bì ìmọ̀ràn yìí ti mọ́gbọ́ndání tó! Nípa bẹ́ẹ̀, Kolosse 2:2 yóò jẹ́ ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa fún ọdún 1995.
7. Ìṣọ̀kan wo ni a níláti rí láàárín àwọn Kristian tòótọ́?
7 Nínú lẹ́tà rẹ̀ kan tí ó kọ́kọ́ kọ sí àwọn ará Korinti, aposteli náà lo ara ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àkàwé. Ó kọ̀wé pé “kí ó má baà sí ìpínyà kankan” nínú ìjọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ṣùgbọ́n kí ‘awọn ẹ̀yà-ara rẹ̀ ní aájò kan naa fún ara wọn lẹ́nìkínní kejì.’ (1 Korinti 12:12, 24, 25, NW) Ẹ wo irú àgbàyanu àkàwé tí ìyẹn jẹ́! Àwọn ẹ̀yà-ara wa sinmiléra, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì sopọ̀ mọ́ ìyókù ara wa. Ohun kan náà ni a lè sọ nípa ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí-ayé, tí wọ́n parapọ̀ jẹ́ àwọn ẹni-àmì-òróró àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí paradise ilẹ̀-ayé. A kò gbọdọ̀ ya araawa sọ́tọ̀ láti máa gbé ní òmìnira kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa! Ní ṣíṣiṣẹ́ nípasẹ̀ Kristi Jesu, ẹ̀mí Ọlọrun ń ṣàn wá sọ́dọ̀ wa ní ìwọ̀n ńláǹlà nípasẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ará wa.
Ìbáramuṣọ̀kan ní Ìsopọ̀ Pẹ̀lú Ìmọ̀
8, 9. (a) Kí ni ó ṣe pàtàkì bí a bá níláti fikún ìṣọ̀kan nínú ìjọ? (b) Báwo ni o ṣe jèrè ìmọ̀ nípa Kristi?
8 Ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì Paulu ni pé ìbáramuṣọ̀kan Kristian ní ó sopọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀, ní pàtàkì èyí tí ó níí ṣe pẹ̀lú Kristi. Paulu kọ̀wé pé àwọn Kristian níláti “so . . . pọ̀ ní ìbáramuṣọ̀kan ninu ìfẹ́ ati pẹlu níní gbogbo ọrọ̀ tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú òye wọn lọ́kàn, pẹlu níní lọ́kàn ìmọ̀ pípéye nipa àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ Ọlọrun, èyíinì ni, Kristi.” (Kolosse 2:2, NW) A ti gba ìmọ̀—àwọn òkodoro òtítọ́—láti ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí apákan jíjèrè òye nípa iye àwọn òkodoro òtítọ́ wọ̀nyí tí wọ́n bá ète Ọlọrun mu, a rí ipa pàtàkì tí Jesu kó. “Ní inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ti ìmọ̀ pamọ́ sí.”—Kolosse 2:3, NW.
9 Ṣé bí ìmọ̀lára rẹ nípa Jesu àti ipa rẹ̀ nínú ète Ọlọrun ṣe rí nìyẹn? Pípe orúkọ Jesu yá sí ọ̀pọ̀ ti ń bẹ ní Kristẹndọm lẹ́nu, ní jíjẹ́wọ́ pé àwọn ti gbà á sínú ayé wọn tí a sì ti gbà wọ́n là. Ṣùgbọ́n wọ́n ha mọ̀ ọ́n níti tòótọ́ bí? Agbára káká ni, nítorí pé ọ̀pọ̀ jùlọ gbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò bá ìwé mímọ́ mu. Kìí ṣe kìkì pé ìwọ mọ òtítọ́ nípa èyí nìkan ni ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí o ní ìmọ̀ gbígbòòrò nípa ohun tí Jesu sọ tí ó sì ṣe. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni a ti ràn lọ́wọ́ níhà yìí nípa ẹ̀kọ́ tí ó kún fún ìsọfúnni ní lílo ìwé náà Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Síbẹ̀ a nílò láti túbọ̀ mú kí ìmọ̀ wa nípa Jesu àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ síi.
10. Ní ọ̀nà wo ni ìmọ̀ tí ó farasin fi wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa?
10 Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà pé “a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ti ìmọ̀ pamọ́ sí” inú Jesu kò túmọ̀ sí pé irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ rékọjá ohun tí a lè lóye. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dàbí kòtò ìwakùsà kan tí a ti dá lójú. A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ níláti máa wò yányànyán káàkiri agbègbè gbígbòòrò náà ní ṣíṣe kàyéfì nípa ibi tí a óò ti bẹ̀rẹ̀ sí walẹ̀. A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀—ìmọ̀ tòótọ́ ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí Bibeli ṣípayá nípa Jesu Kristi. Bí a ṣe túbọ̀ ń mọrírì ipa Jesu ní kíkún síi nínú ìṣiṣẹ́yọrí àwọn ète Jehofa, a ń gba àwọn ìṣúra ọgbọ́n tòótọ́ àti ìmọ̀ pípéye. Nítorí náà ohun tí a nílò ni láti máa walẹ̀jìn síwájú àti síwájú síi, ní wíwú púpọ̀ síi lára àwọn ohun ìṣúra tàbí ohun tí ó ṣeyebíye náà tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó jáde láti orísun yìí níbi tí a ti walẹ̀ tẹ́lẹ̀.—Owe 2:1-5.
11. Báwo ni a ṣe lè sọ ìmọ̀ àti ọgbọ́n wa di púpọ̀ nípa ṣíṣàṣàrò nípa Jesu? (Fi bí Jesu ṣe wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ṣe àkàwé, tàbí kí o lo àwọn àpẹẹrẹ mìíràn.)
11 Fún àpẹẹrẹ, a lè mọ̀ pé Jesu wẹ ẹsẹ̀ àwọn aposteli rẹ̀. (Johannu 13:1-20) Ṣùgbọ́n, a ha ti ṣàṣàrò lórí ẹ̀kọ́ tí ó fi ń kọ́ni àti ìṣarasíhùwà tí ó fihàn bí? Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè fa ìṣúra ọgbọ́n jáde tí yóò lè ràn wá lọ́wọ́—bẹ́ẹ̀ni, tí yóò lè sún wa—láti ṣe ìyípadà bí a ṣe ń bá arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí ìwà rẹ̀ ti ń bí wa nínú tipẹ́tipẹ́ lò. Tàbí nígbà tí a bá fún wa ní iṣẹ́ àyànfúnni kan tí a kò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn, a lè hùwàpadà lọ́nà tí ó yàtọ̀ gbàrà tí a bá ti lóye ìjẹ́pàtàkì ohun tí ó wà nínú Johannu 13:14, 15. Bí ìmọ̀ àti ọgbọ́n náà ṣe ń nípa lórí wa nìyẹn. Ipa ìdarí wo ni ó lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn bí a ti ń ṣàfarawé àpẹẹrẹ Kristi lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ síi ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ tí ń pọ̀ síi nípa Kristi? Ó ṣeé ṣe kí agbo náà ‘di èyí tí a sopọ̀ ní ìbáramuṣọ̀kan nínú ìfẹ́.’a
Àìpọkànpọ̀ Lè Ba Ìṣọ̀kan Jẹ́
12. Ìmọ̀ wo ni a níláti kíyèsára fún?
12 Bí ìmọ̀ pípéye bá mú kí ‘wíwà ní ìṣọ̀kan wa nínú ìfẹ́’ rọrùn síi, kí ni ó lè jẹyọ láti inú ohun náà tí wọ́n ń “fi èké pè ní ‘ìmọ̀’”? Òdìkejì gan-an ni—awuyewuye, àìsí ìrẹ́pọ̀, àti yíyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́. Nítorí náà a gbọ́dọ̀ dènà irú ìmọ̀ èké bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kìlọ̀ fún Timoteu. (1 Timoteu 6:20, 21) Paulu tún kọ̀wé pé: “Èyí ni mo ń wí kí ènìyàn kankan má baà fi awọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà mọ̀ọ́mọ̀ ṣì yín lọ́nà. Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹni kan lè wà tí yoo gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò-orí ati ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹlu òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹlu awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé tí kò sì sí ní ìbámu pẹlu Kristi.”—Kolosse 2:4, 8, NW.
13, 14. (a) Èéṣe tí àwọn ará ni Kolosse fi wà nínú ewu níti ìmọ̀? (b) Èéṣe tí àwọn kan lónìí fi lè nímọ̀lára pé àwọn kò sí nínú irú ewu kan náà?
13 Ó dájú pé àwọn agbára ìdarí ayọ́kẹ́lẹ́-ṣọṣẹ́ ti àwọn ohun tí a fi èké pè ní ìmọ̀ ni ó yí àwọn Kristian ní Kolosse ká. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ìlú Kolosse àti agbègbè rẹ̀ ni wọ́n gbé ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn Griki gẹ̀gẹ̀. Àwọn onísìn Juda tí wọ́n fẹ́ kí àwọn Kristian máa pa Òfin Mose mọ́, irúfẹ́ bí àwọn ọjọ́ aláyẹyẹ rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó béèrè fún níti ọ̀ràn oúnjẹ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Kolosse 2:11, 16, 17) Paulu kò lòdì síi pé kí àwọn arákùnrin rẹ̀ jèrè ìmọ̀ tòótọ́, ṣùgbọ́n wọ́n níláti ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni mà baà fi wọ́n ṣe ẹran-ìjẹ, ní lílo àwọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà láti yí èrò wọn padà láti máa fi ojú ìwòye ti ẹ̀dá ènìyàn lásán wo ìgbésí-ayé àti ìhùwàsí. Ẹ lè lóye rẹ̀ pé bí àwọn kan nínú ìjọ bá ń jẹ́ kí àwọn ìpìlẹ̀-èrò àti ìṣarasíhùwà tí kò bá ìwé mímọ́ mu máa darí ìrònú àti àwọn ìpinnu wọn, yóò ṣisẹ́ lòdìsí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ tí ń bẹ láàárín àwọn mẹ́ḿbà ìjọ.
14 O lè ronú pé: ‘Bẹ́ẹ̀ni, mo rí ewu tí àwọn ará Kolosse dojúkọ, ṣùgbọ́n èmi kò sí nínú ewu dídi ẹni tí àwọn ìpìlẹ̀-èrò Griki ní agbára ìdarí lé lórí, irú bíi àìlèkú ọkàn tàbí ọlọrun mẹ́talọ́kan; bẹ́ẹ̀ ni ń kò sì rí ewu kankan ní ti dídi ẹni tí àwọn họlidé abọ̀rìṣà ti ìsìn èké tí mo ti ja àjàbọ́ nínú rẹ̀ lè fà mọ́ra.’ Ìyẹn dára. Ó dára kí a gbèròpinnu lórí ìṣepàtàkì òtítọ́ ìpìlẹ̀ tí a tipasẹ̀ Jesu ṣípayá tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó nínú Ìwé Mímọ́. Ṣùgbọ́n, ó ha lè ṣeé ṣe pé kí a wà nínú irú ewu àwọn ọgbọ́n èrò-orí tàbí ojú-ìwòye ẹ̀dá ènìyàn mìíràn tí ó gbilẹ̀ lónìí bí?
15, 16. Ojú-ìwòye wo nípa ìgbésí-ayé ni ó lè nípa lórí ìrònú Kristian kan?
15 Ọ̀kan lára àwọn irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ ti wà tipẹ́ pé: “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà báyìí? Àwọn bàbá wa ti sùn nínú ikú, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ohun gbogbo ń bá a nìṣó gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ń fìgbà gbogbo wà rí.” (2 Peteru 3:4, The New English Bible) A lè sọ èrò-ìmọ̀lára yẹn jáde lọ́nà mìíràn, ṣùgbọ́n bákan náà ní ojú-ìwòye náà rí. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè ronú pé, ‘Nígbà tí mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní àwọn ẹ̀wádún sẹ́yìn, òpin náà ti “fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.” Ṣùgbọ́n kò tí ì dé síbẹ̀, ta ni ó sì mọ ìgbà tí yóò dé?’ Òtítọ́ ni pé, kò sí ẹnì kan tí ó mọ ìgbà tí òpin náà yóò dé. Síbẹ̀, kíyèsí ojú-ìwòye tí Jesu rọni láti ní: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ máa wà lójúfò, nitori ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yànkalẹ̀ jẹ́.”—Marku 13:32, 33, NW.
16 Ẹ wo bí yóò ti léwu tó láti mú ojú-ìwòye náà dàgbà pé, níwọ̀n bí a kò ti mọ ìgbà tí òpin náà yóò dé, a níláti wéwèé fún ìgbésí-ayé oníyọ̀tọ̀mì àti èyí tí ó “sẹ́lẹ́ńkẹ́jọ̀”! A lè fi irú ojú-ìwòye yẹn hàn nínú ìrònú náà pé, ‘Yóò dára fún mi láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí yóò yọ̀ọ̀da fún èmi (tàbí àwọn ọmọ mi) láti ní iṣẹ́-ìgbésí ayé kan tí ó bójúmu tí ń mówó wọlé gidigidi tí yóò sì lè mú kí ó ṣeé ṣe fún èmi àti àwọn ọmọ mi láti gbádùn ìgbésí-ayé tí ó dẹrùn. Àmọ́ ṣáá o, èmi yóò máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristian n óò sì máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù, ṣùgbọ́n kò sí ìdí kankan fún mi láti lo araami tokunra-tokunra tàbí ṣe àwọn ìrúbọ ńláǹlà.’—Matteu 24:38-42.
17, 18. Ojú-ìwòye wo ni Jesu àti àwọn aposteli rọ̀ wá láti ní?
17 Bí ó ti wù kí ó rí, a kò lè sẹ́ pé Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ dámọ̀ràn pé kí a máa gbé ìgbésí-ayé pẹ̀lú èrò ìjẹ́kánjúkánjú nípa wíwàásù ìhìnrere náà, ní lílo araawa tokunra-tokunra kí a sì múratán láti ṣe àwọn ìrúbọ. Paulu kọ̀wé pé: “Èyí ni mo wí, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ ti dínkù. Lati ìsinsìnyí lọ kí awọn wọnnì tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní, . . . ati awọn wọnnì tí ń rà bí awọn wọnnì tí kò ní, ati awọn wọnnì tí ń lo ayé bí awọn wọnnì tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nitori ìrísí ìran ayé yii ń yípadà.”—1 Korinti 7:29-31, NW; Luku 13:23, 24; Filippi 3:13-15; Kolosse 1:29; 1 Timoteu 4:10; 2 Timoteu 2:4; Ìṣípayá 22:20.
18 Dípò dídá a lábàá pé kí a fi ìgbésí-ayé gbẹ̀fẹ́ ṣe góńgó wa, Paulu kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Nitori a kò mú nǹkankan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nitori naa, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró ati ìbora, awa yoo ní ìtẹ́lọ́rùn-ọkàn pẹlu nǹkan wọnyi. . . . Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ tí iwọ sì ṣe ìpolongo àtàtà ní gbangba níwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ẹlẹ́rìí.”—1 Timoteu 6:7-12, NW.
19. Ipa wo ni ó máa ń ní lórí ìjọ kan nígbà tí àwọn wọnnì tí wọ́n wà níbẹ̀ bá tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye tí Jesu fúnni ní ìṣírí láti ní nípa ìgbésí-ayé?
19 Nígbà tí ìjọ kan bá kún fún àwọn Kristian onítara tí wọ́n ń làkàkà gidigidi láti “ṣe ìpolongo àtàtà ní gbangba,” ìṣọ̀kan máa ń wà lọ́nà ti ẹ̀dá. Wọn kì í juwọ́sílẹ̀ fún àwọn ìṣarasíhùwà bíi, ‘O ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun rere tí o ti tòjọ pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún; farabalẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, kí o sì máa gbádùn araarẹ̀.’ (Luku 12:19, NW) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú ìsapá kan náà, ní mímúratán láti ṣe àwọn ìrúbọ láti lè nípìn-ín kíkún bí ó ba ti lè ṣeé ṣe tó nínú iṣẹ́ tí a kì yóò tún padà ṣe mọ́ yìí.—Fiwé Filippi 1:27, 28.
Ṣọ́ra fún Àwọn Ìjiyàn Tí Ń Yíniléròpadà
20. Ní agbègbè mìíràn wo ni a ti lè ṣi àwọn Kristian lọ́nà?
20 Àmọ́ ṣáá o, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí a lè gbà ‘fọgbọ́n tan’ àwọn Kristian ‘jẹ pẹ̀lú àwọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà’ tàbí àwọn ẹ̀tàn òfìfo tí ó lè ké ‘wíwà ní ìṣọ̀kan ninu ìfẹ́’ nígbèrí. Ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Germany kọ̀wé pé: “Ọ̀ràn kan yọrí sí awuyewuye, àwọn akéde àti àwọn alàgbà pàápàá ń pọ̀n sí onírúurú ìhà lórí irú ọ̀nà ìgbàtọ́jú kan tí arákùnrin kan lò.” Wọ́n fikún un pé: “Nítorí onírúurú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nà ìṣètọ́jú tí a lò àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aláìsàn agbàtọ́jú, agbègbè kan tí ó yọ̀ọ̀da fún awuyewuye ni èyí jẹ́, bí ó bá sì lọ jẹ́ pé àwọn ọ̀nà ìgbàtọ́jú bá lọ́wọ́ ìbẹ́mìílò nínú lábẹ́lẹ̀, ó lè léwu pẹ̀lú.”—Efesu 6:12.
21. Báwo ni Kristian kan ṣe lè kùnà láti darí àfiyèsí sí ibi tí ó tọ̀nà lónìí?
21 Àwọn Kristian fẹ́ láti máa wàláàyè kí wọ́n sì máa ní ìlera ara nìṣó kí wọ́n baà lè máa jọ́sìn Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nínú ètò-ìgbékalẹ̀ yìí ọjọ́ ogbó àti àìsàn tí ó jẹ́ àbárèbábọ̀ àìpé lè nípa lórí wa. Kàkà tí a ó fi máa tẹnumọ́ ọ̀ràn ìlera, ó yẹ kí a pọkànpọ̀ sórí ojútùú tòótọ́, fún àwa àti fún àwọn ẹlòmíràn. (1 Timoteu 4:16) Kristi ni kókó àfiyèsí fún ojútùú yẹn, àní bí òun ti jẹ́ kókó àfiyèsí nínú ìmọ̀ràn Paulu sí àwọn ará Kolosse. Ṣùgbọ́n rántí, Paulu fihàn pé àwọn kan lè mú “awọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà” wá ní yíyí àfiyèsí wa kúrò lọ́dọ̀ Kristi, bóyá síhà ọ̀nà ìgbàṣàyẹ̀wò, ìtọ́jú, tàbí ìdíwọ̀n-oúnjẹ.—Kolosse 2:2-4, NW.
22. Ìṣarasíhùwà wíwàdéédéé wo ni a níláti ní nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun tí a ń sọ nípa ọ̀nà ìgbàṣàyẹ̀wò àti ìgbàtọ́jú?
22 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpolówó-ọjà àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó dá lórí àǹfààní tí àwọn kan ti jẹ láti inú onírúurú àwọn ọ̀nà-ìtọ́jú àti ọ̀nà ìgbàṣàyẹ̀wò ń yalu àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé. A ń lo àwọn kan lára wọn a sì mọ̀ wọ́n níbi púpọ̀; a ń ṣòfíntótó àwọn kan níbi púpọ̀ tàbí kí a máa fura sí wọn.b Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ò ni ẹrù-iṣẹ́ láti pinnu ohun tí yóò ṣe nípa ìlera rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn Paulu tí a rí ní Kolosse 2:4, 8 (NW) ni a óò dáàbòbò kúrò lọ́wọ́ dídi ẹni tí a gbé lọ bí ẹran-ọdẹ nípasẹ̀ “awọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà” tàbí “ẹ̀tàn òfìfo” tí ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣáko lọ, láìní ìrètí Ìjọba náà, tí wọ́n sì ń gbékútà fún ìtura. Kódà bí Kristian kan bá ní ìdánilójú pé ọ̀nà-ìgbàtọ́jú kan dàbí èyí tí ó dára fún òun, òun kò níláti máa gbé èyí lárugẹ nínú ẹgbẹ́ àwọn ara ti Kristian, nítorí èyí lè di kókó-ọ̀rọ̀ ìjíròrò àti awuyewuye tí ń tànkálẹ̀. Òun yóò lè tipa bẹ́ẹ̀ fihàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ìjẹ́pàtàkì ìṣọ̀kan nínú ìjọ lọ́nà gíga.
23. Èéṣe tí a fi ní ìdí fún ìdùnnú ní pàtàkì?
23 Paulu tẹnumọ́ ọn pè ìṣọ̀kan Kristian jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ayọ̀ tòótọ́. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ iye wọn ìjọ kéré jọjọ sí ti òde-òní. Síbẹ̀ òun lè kọ̀wé sí àwọn ará Kolosse pé: “Nitori bí emi kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín ninu ẹran-ara, síbẹ̀síbẹ̀ mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí, tí mo ń yọ̀ tí mo sì ń wo wíwà létòlétò yín ati ìfìdímúlẹ̀ gbọn-in ìgbàgbọ́ yín ninu Kristi.” (Kolosse 2:5, NW; tún wo Kolosse 3:14.) Ẹ wo bí àwa ti ní ìdí púpọ̀ tó láti kún fún ayọ̀! A lè rí ẹ̀rì tòótọ́ ti ìṣọ̀kan, ìwàlétòlétò, àti ìdúróṣinṣin ti ìgbàgbọ́ nínú ìjọ tiwa fúnraawa, èyí tí ń fihàn bí ipò ọ̀ràn àwọn ènìyàn Ọlọrun káàkiri ilẹ̀-ayé ti rí ní gbogbogbòò. Nítorí náà ní àkókò kúkúrú tí ó ṣẹ́kù nínú ètò-ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí, ẹ jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa pinnu láti “so . . . pọ̀ ní ìbáramuṣọ̀kan ninu ìfẹ́.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ wà tí a lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn, láti inú àwọn àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀lé e yìí, kíyèsí ohun tí ìwọ fúnraàrẹ lè kọ́ nípa Jesu tí ó lè fikún ìṣọ̀kan nínú ìjọ rẹ: Matteu 12:1-8; Luku 2:51, 52; 9:51-55; 10:20; Heberu 10:5-9.
b Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti June 15, 1982, ojú-ìwé 22 sí 29.
Ìwọ Ha Fiyèsíi Bí?
◻ Kí ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ọdún 1995 fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
◻ Èéṣe tí àwọn Kristian ní Kolosse fi níláti báramuṣọ̀kan nínú ìfẹ́, èésìtiṣe tí àwa fi níláti ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?
◻ Ojú-ìwòye ayọ́kẹ́lẹ́-ṣọṣẹ́ wo nípa ìgbésí-ayé ni àwọn Kristian ní pàtàkì níláti kíyèsára fún?
◻ Èéṣe tí àwọn Kristian fi níláti wà lójúfò kí a má baà fi àwọn ìjiyàn tí ń yíniléròpadà nípa ìlera àti ọ̀nà ìgbàṣàyẹ̀wò ṣì wọ́n lọ́nà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
O ha gbé àwọn ìwéwèé rẹ̀ fún ọjọ́-ọ̀la karí wíwà níhìn-ín Jesu bí?