ORÍ 10
“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
1. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn bá wà nípò àṣẹ?
ÒWE kan sọ pé: “Kò sẹ́ni tí wọ́n máa gbé gẹṣin tí kò ní ju ìpàkọ́.” Òwe yìí jẹ́ ká rí i pé táwọn èèyàn bá wà nípò àṣẹ, wọ́n sábà máa ń ṣi agbára lò. Ó dunni pé ọ̀pọ̀ èèyàn nirú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Kódà, àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn jẹ́rìí sí i pé “èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ká sòótọ́, àwọn tó wà nípò àṣẹ kì í fìfẹ́ hàn bí wọ́n ṣe ń lo agbára wọn, ìyẹn sì ti mú kí nǹkan nira gan-an fáwọn èèyàn.
2, 3. (a) Kí ló wúni lórí nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo agbára? (b) Àwọn nǹkan wo la lè lágbára láti ṣe, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa lo agbára náà?
2 Jèhófà Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sáwa èèyàn. Òun ló lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, síbẹ̀ kò ṣi agbára rẹ̀ lò rí. Bá a ṣe rí i nínú àwọn orí tó ṣáájú, Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, láti pani run, láti dáàbò boni tàbí láti mú nǹkan bọ̀ sípò. Gbogbo ìgbà tó bá sì lo agbára náà ló fi ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀, ó máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Èyí sì lè mú ká ‘máa fara wé e’ nínú bá a ṣe ń lo agbára. (Éfésù 5:1) Àmọ́ o, agbára wo làwa èèyàn lásánlàsàn ní?
3 Rántí pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn “ní àwòrán rẹ̀” ká lè fìwà jọ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Torí náà àwa èèyàn ní agbára díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè ní agbára tàbí okun tá a lè fi ṣe iṣẹ́ àṣekára, a lè ní àṣẹ lórí àwọn èèyàn, a lè ní nǹkan ìní tó pọ̀ ju tàwọn èèyàn kan lọ, a tún lè gbọ́n ju àwọn míì tàbí ká ní ìmọ̀ jù wọ́n lọ, kíyẹn sì mú ká máa fún wọn nímọ̀ràn lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ní pàtàkì àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́, agbára wa kéré gan-an tá a bá fi wé ti Ọlọ́run. Onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Torí náà, Ọlọ́run ni orísun gbogbo agbára tá a ní. Ó sì yẹ ká máa lo agbára náà lọ́nà táá múnú ẹ̀ dùn. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì
4, 5. (a) Kí ló máa jẹ́ ká lo agbára wa lọ́nà tó dáa, báwo ni àpẹẹrẹ Ọlọ́run sì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? (b) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa lọ́nà tó dáa?
4 Kẹ́nì kan tó lè lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó dáa, ẹni náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Rántí pé ní Orí Kìíní, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà àti ìṣe pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ní, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ìwà àti ìṣe mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà? Ìfẹ́ ni. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ ni Jèhófà, ìfẹ́ yìí ló sì máa ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Torí náà, ìfẹ́ ló máa ń mú kí Ọlọ́run lo agbára rẹ̀, ó sì máa ń lò ó láti ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́.
5 Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àá máa lo agbára wa lọ́nà tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ máa ń ní “inú rere” àti pé “kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Torí náà tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a ò ní máa kanra mọ́ wọn tàbí hùwà ìkà sí wọn, ní pàtàkì àwọn tá a bá láṣẹ lé lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa ṣenúure sáwọn èèyàn, àá máa bọ̀wọ̀ fún wọn, àá sì máa gba tiwọn rò dípò ká máa ro tara wa nìkan.—Fílípì 2:3, 4.
6, 7. (a) Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe lè mú ká yẹra fún àṣìlò agbára? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká tó lè bẹ̀rù rẹ̀.
6 Jẹ́ ká wo ọ̀nà míì tí ìfẹ́ lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa lọ́nà tó dáa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ ká bẹ̀rù ẹ̀. Òwe 16:6 sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà . . . máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.” Ọ̀kan lára ohun búburú tó sì yẹ ká máa yẹra fún ni pé ká má ṣe máa ṣi agbára wa lò. Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, a ò ní máa hùwà ìkà sáwọn tá a láṣẹ lé lórí. Kí nìdí? Ìdí ni pé, a mọ̀ pé a máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa bá a ṣe ń hùwà sí wọn. (Nehemáyà 5:1-7, 15) Àmọ́ o, ìdí míì tún wà tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ìbẹ̀rù” sábà máa ń tọ́ka sí pé kéèyàn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká tó lè bẹ̀rù rẹ̀. (Diutarónómì 10:12, 13) Àmọ́, kò yẹ kó jẹ́ pé torí kí Ọlọ́run má bàa fìyà jẹ wá nìkan ló ṣe yẹ ká máa sá fún ìwà burúkú o! Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a ò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí i, àá sì máa bọ̀wọ̀ fún un.
7 Bí àpẹẹrẹ: Ronú nípa bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré gan-an. Ọmọ náà mọ̀ pé bàbá òun ò fọ̀rọ̀ òun ṣeré, síbẹ̀ ó máa gbà pé bàbá òun ń retí pé kóun máa ṣe àwọn nǹkan kan, ó sì mọ̀ pé tóun bá ṣe ohun tí kò dáa, bàbá òun máa bá òun wí. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ náà á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì torí bàbá ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa fẹ́ràn bàbá ẹ̀ gan-an. Ó sì máa wù ú pé kó máa ṣe ohun tó máa múnú bàbá ẹ̀ dùn. Bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn. Torí pé a fẹ́ràn Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 6:6) Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa ṣe ohun tó máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Torí náà, a ò ní máa lo agbára wa lọ́nà tí kò dáa. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa lo agbára wa lọ́nà tó dáa.
Nínú Ìdílé
8. (a) Àṣẹ wo ni ọkọ ní nínú ìdílé, báwo ló sì ṣe yẹ kó lò ó? (b) Báwo ni ọkọ kan ṣe lè máa fi hàn pé òun ń bọlá fún ìyàwó òun?
8 Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè lo agbára lọ́nà tó dáa nínú ìdílé. Éfésù 5:23 sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀.” Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún un yìí? Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n máa “fi òye” bá àwọn aya wọn gbé, kí wọ́n sì máa “bọlá fún wọn bí ohun èlò ẹlẹgẹ́.” (1 Pétérù 3:7) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “bọlá fún” nínú ẹsẹ yìí tún máa ń túmọ̀ sí ‘kà sí pàtàkì, kà sí ohun tó ṣeyebíye tàbí bọ̀wọ̀ fún.’ A sì tún máa ń túmọ̀ ẹ̀ sí “ẹ̀bùn” àti “iyebíye.” (Ìṣe 28:10; 1 Pétérù 2:7) Tí ọkọ kan bá ń bọlá fún ìyàwó rẹ̀, kò ní máa nà án; bẹ́ẹ̀ ni kò ní máa bú u tàbí kó máa sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i tí obìnrin náà á fi máa wo ara ẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà máa mọyì ìyàwó rẹ̀, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ó máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà ẹ̀ pé ìyàwó ẹ̀ ṣeyebíye sí i, ì báà jẹ́ nígbà tí wọ́n dá nìkan wà tàbí nígbà tí wọ́n wà láàárín àwọn èèyàn. (Òwe 31:28) Tí ọkọ kan bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó máa rọrùn fún ìyàwó ẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ní pàtàkì jù lọ, inú Jèhófà máa dùn sí i.
9. (a) Kí làwọn aya ní agbára láti ṣe nínú ìdílé? (b) Kí ló máa ran aya kan lọ́wọ́ láti máa lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti fi ṣètìlẹyìn fún ọkọ rẹ̀, àǹfààní wo ló sì máa rí tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀?
9 Àwọn aya náà ní agbára láti ṣe àwọn nǹkan kan nínú ìdílé. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin olóòótọ́ tó gbìyànjú láti ran àwọn ọkọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó tọ́, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn tó jẹ́ olórí ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12; 27:46–28:2) Aya kan lè ní ìmọ̀ ju ọkọ rẹ̀ lọ tàbí kó láwọn ìwà àti ìṣe míì tí ọkọ rẹ̀ kò ní. Síbẹ̀, ó yẹ kó ní “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀ kó sì “máa tẹrí ba” fún un “bíi fún Olúwa.” (Éfésù 5:22, 33) Tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣe pàtàkì sí obìnrin kan ni báá ṣe máa múnú Ọlọ́run dùn, á máa lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tó ní láti máa ṣètìlẹyìn fún ọkọ rẹ̀ dípò táá fi máa fojú kéré ọkọ rẹ̀ tàbí kó máa ṣe bí ọ̀gá lórí rẹ̀. Irú aya bẹ́ẹ̀ máa fi hàn pé “ọlọ́gbọ́n obìnrin” lòun, á máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti gbé ìdílé wọn ró, èyí á sì jẹ́ kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Òwe 14:1.
10. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún àwọn òbí? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí,” báwo ló sì ṣe yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 Ọlọ́run tún fún àwọn òbí ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” lè túmọ̀ sí kí wọ́n tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó lè ṣe ohun tó tọ́. Ká sòótọ́, àwọn ọmọ nílò ìbáwí; wọ́n sábà máa ń ṣe dáadáa táwọn òbí bá fún wọn ní ìtọ́ni tó dáa, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwọn òbí máa bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. (Òwe 13:24) Torí náà táwọn òbí bá ń lo “ọ̀pá ìbáwí,” kò yẹ kí wọ́n máa lò ó lọ́nà tí wọ́n á fi ṣe àwọn ọmọ wọn léṣe tàbí lọ́nà tí wọ́n á fi kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn.a (Òwe 22:15; 29:15) Tí òbí kan bá ń kanra mọ́ ọmọ ẹ̀ tàbí tó le koko jù mọ́ ọn, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọmọ náà. Ìyẹn ò sì ní fi hàn pé irú òbí bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa fi hàn pé òbí náà ń ṣi agbára rẹ̀ lò. (Kólósè 3:21) Àmọ́, táwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó tọ́, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ̀ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n á sì gbà pé ohun tó dáa làwọn òbí wọ́n fẹ́ fún wọn.
11. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà tó dáa?
11 Àwọn ọmọ ńkọ́? Báwo ni wọ́n ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà tó dáa? Òwe 20:29 sọ pé: “Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” Ó dájú pé ọ̀nà tó dáa jù lọ táwọn ọ̀dọ́ lè gbà lo okun àti agbára wọn ni pé kí wọ́n fi sin ‘Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá.’ (Oníwàásù 12:1) Bákan náà, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa rántí pé ohun tí wọ́n bá ṣe lè mú inú àwọn òbí wọn dùn, ó sì lè bà wọ́n nínú jẹ́. (Òwe 23:24, 25) Táwọn ọmọ bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó tọ́, wọ́n máa múnú àwọn òbí wọn dùn. (Éfésù 6:1) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń “dára gidigidi lójú Olúwa.”—Kólósè 3:20.
Nínú Ìjọ
12, 13. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwọn alàgbà máa lo àṣẹ wọn nínú ìjọ? (b) Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà máa fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú àwọn àgùntàn Jèhófà.
12 Jèhófà pèsè àwọn alábòójútó kí wọ́n lè máa múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. (Hébérù 13:17) Ó yẹ káwọn ọkùnrin yìí máa lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn láti bójú tó àwọn ará àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ṣó wá yẹ káwọn alàgbà máa ṣe bí ọ̀gá lórí àwọn ará? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ káwọn alàgbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nínú ìjọ. (1 Pétérù 5:2, 3) Bíbélì sọ fáwọn alábòójútó pé kí wọ́n máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ káwọn alábòójútó máa fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú gbogbo àwọn ará nínú ìjọ.
13 Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ lọ́nà yìí. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ní kó o bá òun tọ́jú ohun ìní kan tó fẹ́ràn gan-an, tó o sì mọ̀ pé ohun kékeré kọ́ ni ọ̀rẹ́ rẹ san kó tó lè ra ohun ìní náà. Ó dájú pé o máa tọ́jú ẹ̀ dáadáa kó má bàa bà jẹ́! Bákan náà, Ọlọ́run yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa bójú tó ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye, ìyẹn àwọn ará tó wà nínú ìjọ, Bíbélì sì sábà máa ń fi àwọn ará yìí wé àgùntàn. (Jòhánù 21:16, 17) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ gan-an débi pé ó fi ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wọ́n. Ohun tó ṣeyebíye jù lọ ni Jèhófà san láti fi ra àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn alàgbà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa ń fi èyí sọ́kàn ní gbogbo ìgbà, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.
“Ahọ́n Ní Agbára”
14. Kí ni ahọ́n lágbára láti ṣe?
14 Bíbélì sọ pé: “Ahọ́n ní agbára láti fa ikú tàbí ìyè.” (Òwe 18:21) Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè kó àwa tàbí àwọn ẹlòmíì sí wàhálà. Ó ṣe tán, gbogbo wa ló máa ń mọ̀ ọ́n lára tẹ́nì kan bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wa. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ ẹnu wa tún lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Òwe 12:18 sọ pé: “Ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.” Ká sòótọ́, tá a bá sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún ẹnì kan, ṣe ló máa dà bíi pé a fún ẹni náà ní oògùn táá mára tù ú. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
15, 16. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo ahọ́n wa láti fún àwọn èèyàn níṣìírí?
15 Ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:14 sọ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́.” Ká sòótọ́, nígbà míì àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn náà máa ń sorí kọ́. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? A lè sọ àwọn nǹkan dáadáa tí wọ́n ti ṣe, ká sì gbóríyìn fún wọn látọkàn wá kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fún wọn táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ní “ọgbẹ́ ọkàn” àtàwọn tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn.” (Sáàmù 34:18) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ láti tu àwọn èèyàn nínú, ńṣe là ń fara wé Ọlọ́run wa, tó máa ń tu àwọn tó sorí kọ́ nínú.—2 Kọ́ríńtì 7:6.
16 A tún lè sọ ọ̀rọ̀ tó máa fún àwọn èèyàn níṣìírí àtèyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá rí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kú, a lè bá a kẹ́dùn, ká sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ara máa tù ú. Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan tó ti darúgbó nínú ìjọ ló ń ronú pé òun ò wúlò mọ́, a lè sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó gbà pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà. Bákan náà, tá a bá mọ ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an, a lè sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un látorí fóònù tàbí ká kọ lẹ́tà sí i, a sì lè lọ kí i láti ṣaájò rẹ̀. Ìyẹn á múnú ẹni náà dùn, á sì mára tù ú. Tá a bá ń sọ “ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró,” ó dájú pé inú Ẹlẹ́dàá wa máa dùn gan-an!—Éfésù 4:29.
17. Ọ̀nà tó dáa jù lọ wo la lè gbà lo ahọ́n wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà lo ahọ́n wa ni pé ká fi sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Òwe 3:27 sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún tó bá wà níkàáwọ́ rẹ láti ṣe é.” Jèhófà ti fún wa ní iṣẹ́ pàtàkì kan, ó fẹ́ ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, ó sì fẹ́ kí wọ́n tètè gbọ́ ìhìn rere yìí kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Torí náà, kò yẹ ká fà sẹ́yìn láti sọ fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 9:16, 22) Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe nínú iṣẹ́ yìí pọ̀ tó?
Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà lo agbára wa ni pé ká máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn
Máa Fi “Gbogbo Okun” Rẹ Sin Jèhófà
18. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ tó?
18 Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń wù wá láti wàásù ìhìn rere. Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ohun tá a máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí pọ̀ tó? Ohun tó fẹ́ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé láìka ipò wa sí. Bíbélì sọ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn bíi pé Jèhófà lẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.” (Kólósè 3:23) Nígbà tí Jésù ń sọ àṣẹ tó ṣe pàtàkì jù, ó ní: “Kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:30) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ òun ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa sin òun.
19, 20. (a) Bó ṣe jẹ́ pé ara, èrò, àti okun ló para pọ̀ di ọkàn, kí nìdí tí Jésù fi dìídì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú Máàkù 12:30? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà?
19 Kí ló túmọ̀ sí láti máa fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run? Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkàn, ohun tó máa ń túmọ̀ sí ni àwa èèyàn lódindi, ìyẹn sì kan ara wa, okun wa àti èrò wa. Kí wá nìdí tí Jésù fi dìídì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú Máàkù 12:30? Wo àpèjúwe yìí ná. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹnì kan lè ta ara rẹ̀ sóko ẹrú. Síbẹ̀, ẹni náà lè má fi tọkàntọkàn sin ọ̀gá ẹ̀; ó lè má lo gbogbo okun ẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ ọ̀gá ẹ̀, ó sì lè má fọkàn siṣẹ́ náà. (Kólósè 3:22) Torí náà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkàn, ara, èrò àti okun wa, ńṣe ló fẹ́ ká rí i pé gbogbo wọn ló yẹ ká máa lò nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run.
20 Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé iye àkókò àti okun kan náà ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ìyẹn ò lè ṣeé ṣe, torí ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yàtọ̀ síra, a ò sì lókun bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tára ẹ̀ le koko lè máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ju ẹnì kan tó ti ń dàgbà tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ẹni tí kò tíì lọ́kọ tàbí ẹni tí kò tíì láya ní ọ̀pọ̀ àkókò láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ju ẹni tó ti ní ìdílé lọ. Tá a bá lókun dáadáa, tí ipò wa sì gbà wá láyé láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́! Àmọ́ o, kò yẹ ká máa fi ohun tá a lè ṣe wé tàwọn ẹlòmíì, kò sì yẹ ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn. (Róòmù 14:10-12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa gbìyànjú láti fún àwọn èèyàn níṣìírí.
21. Ọ̀nà wo ló dáa jù lọ tá a lè gbà lo agbára wa?
21 Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó dáa, àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn sì jẹ́ fún wa. Torí náà, ó yẹ ká gbìyànjú láti fara wé e débi tágbára àwa èèyàn aláìpé bá lè gbé e dé. A máa fi hàn pé à ń lo agbára wa lọ́nà tó dáa tá a bá ń buyì kún àwọn tá a láṣẹ lé lórí, tá a sì ń ṣenúure sí wọn. Bákan náà, ó yẹ ká máa fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà gbé fún wa, torí ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn èèyàn rí ìgbàlà. (Róòmù 10:13, 14) Rántí pé inú Jèhófà máa dùn tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ìyẹn ni pé tó o bá ń fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín. Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa sin Ọlọ́run yìí, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń ṣenúure sí wa. Ká sòótọ́, kò sí ọ̀nà míì tó dáa jùyẹn lọ tá a lè gbà lo agbára wa.
a Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ọ̀pá” ni wọ́n máa ń lò fún igi táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi ń da àgùntàn. (Sáàmù 23:4) Torí náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé káwọn òbí fi “ọ̀pá” bá àwọn ọmọ wọn wí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, kì í ṣe pé kí wọ́n kanra mọ́ wọn tàbí kí wọ́n hùwà ìkà sí wọn.