Orí 9
“Kristi Agbára Ọlọ́run”
1-3. (a) Ìrírí tó báni lẹ́rù wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ní lójú agbami Òkun Gálílì, kí sì ni Jésù ṣe? (b) Kí nìdí tó fi tọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe Jésù ní “Kristi agbára Ọlọ́run”?
Ẹ̀RÙ tó ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kúrò ní kékeré. Ìjì líle ló ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ ojú omi ń gbé wọn lọ lórí Òkun Gálílì. Òótọ́ ni pé ìyẹn kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ìjì máa bá wọn lórí òkun yìí, nítorí pé ògbólógbòó apẹja làwọn kan lára wọn.a (Mátíù 4:18, 19) Ṣùgbọ́n “ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá” ni tọ̀tẹ̀ yìí, ó le débi pé kíá ni gbogbo ojú òkun dà rú, tó sì ń ru gùdù. Làwọn ọkùnrin wọ̀nyí bá ń sapá kíkankíkan láti darí ọkọ̀ wọn, síbẹ̀ ìjì yìí ń borí wọn. Ìgbì tó ń ru gùdù yìí “ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi” náà, omi sì ti ń kún inú rẹ̀. Nínú gbogbo làásìgbò yìí, fọnfọn ni Jésù sùn lọ lápá ẹ̀yìn ọkọ̀ ní tirẹ̀. Ìdí ni pé àtàárọ̀ ló ti ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gidigidi. Nígbà tí wọ́n rí i pé ẹ̀mí àwọn fẹ́ẹ́ bọ́, wọ́n bá lọ jí Jésù, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé: ‘Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣègbé!’—Máàkù 4:35-38; Mátíù 8:23-25.
2 Ẹ̀rù ò ba Jésù ní tirẹ̀. Ìfọ̀kànbalẹ̀ ló fi bá afẹ́fẹ́ àti òkun wí, ó ní: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, afẹ́fẹ́ àti òkun ṣe bó ṣe wí, ìjì náà dáwọ́ dúró, ìgbì òkun rọlẹ̀, “ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” Ni ìbẹ̀rù àrà ọ̀tọ̀ kan bá dà bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí. Wọ́n wá ń bi ara wọn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Ta nìyí ní ti gidi?” Bẹ́ẹ̀ ni o, àní irú ẹ̀dá wo lẹni tó ń bá afẹ́fẹ́ àti òkun wí bí ẹní ń bá ọmọ tó ń ṣeré ipá wí yìí ná?—Máàkù 4:39-41; Mátíù 8:26, 27.
3 Ó dájú pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán. Agbára Jèhófà ló ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀, òun náà sì ń gbé agbára yẹn yọ lọ́nà ìyanu. Ìyẹn ló fi tọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tipa ìmísí Ọlọ́run pè é ní “Kristi agbára Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 1:24) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù ti gbà gbé agbára Ọlọ́run yọ? Ipa wo sì ni ọ̀nà tí Jésù gbà ń lo agbára náà lè ní lórí ìgbésí ayé wa?
Agbára Ọmọ Bíbí Kan Ṣoṣo Ọlọ́run
4, 5. (a) Irú agbára àti ọlá àṣẹ wo ni Jèhófà gbé wọ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe múra Ọmọ yìí sílẹ̀ kí ó lè ṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ ṣe?
4 Wo agbára tí Jésù ní ṣáájú kó tó wá di ọmọ èèyàn láyé. Nígbà tí Jèhófà dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo tó dẹni tá a wá ń pè ní Jésù Kristi, “agbára ayérayé” rẹ̀ ló lò. (Róòmù 1:20; Kólósè 1:15) Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé agbára àti ọlá àṣẹ ńláǹlà wọ Ọmọ yìí, ó ní òun ni kó máa ṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀dà tóun fẹ́ ṣe. Bíbélì sọ nípa ti Ọmọ yìí pé: “Ohun gbogbo di wíwà nípasẹ̀ rẹ̀, àti pé láìsí i, àní ohun kan kò di wíwà.”—Jòhánù 1:3.
5 Díẹ̀ la kàn lè fòye gbé nínú bí iṣẹ́ yẹn á ṣe pọ̀ tó. Ìwọ wo irú agbára tó máa gbà láti dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì alágbára, láti dá ìsálú ọ̀run tó ṣeé fojú rí tòun ti àìmọye bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ inú rẹ̀, àti láti dá ilẹ̀ ayé tòun ti ọ̀pọ̀ yanturu onírúurú ohun alààyè inú rẹ̀. Kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí lè rí iṣẹ́ yẹn ṣe yanjú, Ọlọ́run fún un ní ipá tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ìdùnnú ńláǹlà ló sì jẹ́ fún Ọmọ yìí láti jẹ́ Ọ̀gá Òṣìṣẹ́, ẹni tí Jèhófà lò láti ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan yòókù.—Òwe 8:22-31.
6. Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, irú agbára àti ọlá àṣẹ wo ló rí gbà?
6 Ǹjẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí tún lè rí agbára àti ọlá àṣẹ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ gbà bí? Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó ní: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù gba ọ̀pá àṣẹ láti máa lo agbára níbikíbi láyé àti lọ́run. Òun gẹ́gẹ́ bí “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa” ti gba àṣẹ láti “sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára,” èyí tó ṣeé fojú rí àti èyí tí kò ṣeé fojú rí, tó bá ti tàpá sí Bàbá rẹ̀ “di asán.” (Ìṣípayá 19:16; 1 Kọ́ríńtì 15:24-26) “Ọlọ́run kò fi nǹkan kan sílẹ̀ tí a kò fi sábẹ́” Jésù àyàfi Jèhófà tìkára rẹ̀.—Hébérù 2:8; 1 Kọ́ríńtì 15:27.
7. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé Jésù kò ní ṣi agbára tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ yìí lò rárá?
7 Ṣé ká máa wá kọminú ni pé Jésù lè ṣi agbára rẹ̀ lò? Rárá o! Jésù fẹ́ràn Bàbá rẹ̀ gan-an, nípa bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bí i nínú. (Jòhánù 8:29; 14:31) Jésù mọ̀ dájú pé Jèhófà ò ṣi agbára tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè lò rí láé. Jésù ti kíyè sí i pé ńṣe ni Jèhófà tiẹ̀ máa ń wá ọ̀nà tí yóò gbà “fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Bí Bàbá rẹ̀ sì ṣe fẹ́ràn aráyé gẹ́lẹ́ náà ni Jésù ṣe fẹ́ràn wọn, nípa bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé nǹkan ire ni Jésù yóò máa fi agbára rẹ̀ ṣe. (Jòhánù 13:1) Ìgbésí ayé tí Jésù ti ń gbé látẹ̀yìnwá sì fi hàn pé kì í ṣi agbára lò rárá. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò agbára tó ní nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé kí á sì wo ohun tó máa ń sún un lo agbára náà.
“Alágbára Nínú . . . Ọ̀rọ̀”
8. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi òróró yan Jésù, kí ló fún un lágbára láti máa ṣe, báwo ló sì ṣe lo agbára rẹ̀ yìí?
8 Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù kò ṣe iṣẹ́ ìyanu rárá nígbà kékeré rẹ̀ ní Násárétì. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi lọ́dún 29 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tó di ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún, èyí yí padà. (Lúùkù 3:21-23) Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára.” (Ìṣe 10:38) Ǹjẹ́ sísọ tí ibí sọ pé “ó ń ṣe rere” yìí kò fi hàn pé Jésù ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́? Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fàmì òróró yàn án, ó “di wòlíì kan tí ó jẹ́ alágbára nínú iṣẹ́ àti nínú ọ̀rọ̀.”—Lúùkù 24:19.
9-11. (a) Lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ ibo ni Jésù ti ń kọ́ni, àwọn ìpèníjà wo ló sì ní láti borí? (b) Kí nìdí tí ẹnu fi ya àwọn èèyàn nípa ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?
9 Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀? Ó sábà máa ń kọ́ni ní ìta gbangba, ì báà jẹ́ létíkun, níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, lójúde ìgboro tàbí ní ọjà. (Máàkù 6:53-56; Lúùkù 5:1-3; 13:26) Dandan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n á kúrò níbẹ̀ wọ́n á sì máa bá tiwọn lọ. Láyé ìgbà yẹn sì rèé, tí kò tíì sí ìwé títẹ̀, ọkàn ni gbogbo àwọn tó gba ohun tí Jésù ń sọ máa ń tọ́jú rẹ̀ sí kí wọ́n má bàa gbàgbé. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di dandan kí ẹ̀kọ́ Jésù wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kí ó yé wọn yékéyéké, kó sì jẹ́ èyí tí wọn ò ní tètè gbàgbé. Bí ẹni ń fàkàrà jẹ̀kọ ni gbogbo ìyẹn sì jẹ́ fún Jésù. Wo Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè bí àpẹẹrẹ.
10 Ó ṣẹlẹ̀ pé láàárọ̀ ọjọ́ kan lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 31 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwùjọ èèyàn kan kóra jọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè létí Òkun Gálílì. Iyànníyàn Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún tàbí àádọ́fà kìlómítà lọ́hùn-ún, làwọn kan tiẹ̀ ti wá síbẹ̀. Àwọn mìíràn wá láti ẹkùn etíkun Tírè àti Sídónì níhà àríwá. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ló sún mọ́ Jésù láti lè fọwọ́ kàn án, ó sì wo gbogbo wọn sàn pátá. Nígbà tó sì di pé kò tún sí ẹnikẹ́ni lára wọn tó fi bẹ́ẹ̀ láìsàn lára mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 6:17-19) Nígbà tó fi máa parí ọ̀rọ̀ rẹ́ nígbà tó yá, ẹnu ya àwọn èèyàn sí ohun tí wọ́n ti gbọ́. Kí ló fà á?
11 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọkàn lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù yẹn kọ̀wé pé: “Háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ.” (Mátíù 7:28, 29) Agbára tí Jésù fi sọ̀rọ̀ ga débi pé àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n lára. Ó gbẹnu sọ fún Ọlọ́run, ó sì fi ọlá àṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn. (Jòhánù 7:16) Ọ̀rọ̀ ẹnu Jésù yéni yékéyéké, ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ wọni lọ́kàn, àwọn àlàyé tó ń ṣe kò sì ṣeé bì ṣubú. Ó máa ń sọ̀rọ̀ sí ibi tí ọ̀rọ̀ wà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń wọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn. Ó kọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe lè máa láyọ̀, bí wọ́n ṣe lè máa gbàdúrà, bí wọ́n ṣe lè máa wá Ìjọba Ọlọ́run, àti ohun tí wọ́n lè ṣe kí ọjọ́ ọ̀la wọn lè dára. (Mátíù 5:3–7:27) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ta àwọn ẹni tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òtítọ́ àti òdodo jí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sì fi tinútinú “sẹ́” ara wọn, wọ́n pa ohun gbogbo tì láti lè máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. (Mátíù 16:24; Lúùkù 5:10, 11) Ẹ̀rí ńlá gbáà lèyí jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Jésù lágbára gan-an!
“Alágbára Nínú Iṣẹ́”
12, 13. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “alágbára nínú iṣẹ́,” oríṣiríṣi ọ̀nà wo sì ni iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ pín sí?
12 Jésù tún jẹ́ “alágbára nínú iṣẹ́” pẹ̀lú. (Lúùkù 24:19) Ó ju ọgbọ̀n iṣẹ́ ìyanu ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ tí àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́nu kàn pé ó ṣe, àti pé “agbára Jèhófà” ló fi ṣe gbogbo wọn.b (Lúùkù 5:17) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló jàǹfààní iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Àní méjì péré lára iṣẹ́ ìyanu ọ̀hún kan àwùjọ èèyàn tí yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ kan [20,000] lápapọ̀! Èyí jẹ́ nígbà tí ó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin àti lẹ́yìn náà ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, “láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.”—Mátíù 14:13-21; 15:32-38.
“Wọ́n rí i tí Jésù ń rìn lórí òkun”
13 Oríṣiríṣi ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Ó láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù, tìrọ̀rùntìrọ̀rùn ló sì fi ń lé wọn jáde. (Lúùkù 9:37-43) Ó lágbára lórí iná, omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, débi pé ó sọ omi di ọtí wáìnì. (Jòhánù 2:1-11) Ìyanu gbáà ló jẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti rí i pé ó ń rìn lójú agbami Òkun Gálílì lásìkò tí ìjì ń jà lọ́wọ́. (Jòhánù 6:18, 19) Ó lágbára lórí àrùn, débi pé ó ń wo ẹ̀yà inú ara pàápàá sàn, àtàwọn àìsàn tí ò gbóògùn àti àìsàn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí ẹni. (Máàkù 3:1-5; Jòhánù 4:46-54) Onírúurú ọ̀nà ló sì gbà ṣe iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn. Ọ̀nà jíjìn réré ni Jésù wà síbi tó ti wo àwọn kan sàn, ó sì fọwọ́ ara rẹ̀ kan àwọn mìíràn ní tààràtà. (Mátíù 8:2, 3, 5-13) Àwọn kan gba ìwòsàn lọ́gán, ó sì wo àwọn mìíràn sàn ní ṣísẹ̀ n tẹ̀ lé.—Máàkù 8:22-25; Lúùkù 8:43, 44.
14. Onírúurú ipò wo ni Jésù ti fi hàn pé òun lágbára láti jí ẹni tó ti kú dìde padà?
14 Pabanbarì rẹ̀ ni pé Jésù lágbára láti jí ẹni tó kú dìde. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà lákọọ́lẹ̀ pé ó jí òkú dìde, ìyẹn ìgbà tó jí òkú ọmọ ọdún méjìlá kan dìde padà fún àwọn òbí rẹ̀, ìgbà tó jí ọmọ kan ṣoṣo tí opó kan bí dìde padà fún un, àti ìgbà tó jí arákùnrin ọ̀wọ́n kan dìde padà fún àwọn arábìnrin rẹ̀. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-56; Jòhánù 11:38-44) Kò sí èyíkéyìí tó mu ún lómi nínú gbogbo rẹ̀. Kò pẹ́ sígbà tí ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá yẹn kú tó fi jí i dìde lórí ibi tó kú sí. Orí àga ìgbókùú ni ọmọkùnrin opó yẹn ṣì wà tó fi jí dìde, ó sì dájú pé ọjọ́ kan náà tó kú ni. Ó sì jí Lásárù dìde nínú ibojì lẹ́yìn ọjọ́ kẹrin tó ti kú.
Ó Fi Àìmọtara-Ẹni-Nìkan, Òye àti Ìgbatẹnirò Lo Agbára
15, 16. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jésù kò lo agbára rẹ̀ lọ́nà ìmọtara-ẹni-nìkan?
15 Ká ní pé alákòóso tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé ni a gbé agbára tí Jésù ní yìí lé lọ́wọ́ ǹjẹ́ kò ní ṣí agbára ọ̀hún lò? Ṣùgbọ́n aláìlẹ́ṣẹ̀ ni Jésù jẹ́ ní tirẹ̀. (1 Pétérù 2:22) Kò gbà kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìlépa ipò àti ìwà ìwọra tó ń ti ẹ̀dá aláìpé láti máa lo agbára wọn láti fi ṣèpalára fáwọn ẹlòmíràn gun òun.
16 Jésù kò lo agbára rẹ̀ lọ́nà ìmọtara-ẹni-nìkan, kò lò ó láti fi gbọ́ tara rẹ̀ rí. Nígbà tí ebi ń pa á, ó kọ̀ láti fi agbára yìí sọ òkúta di ìṣù búrẹ́dì tó lè jẹ. (Mátíù 4:1-4) Níwọ̀n bí ohun ìní rẹ̀ kò ti ju bíi mélòó kan lọ, ìyẹn fi hàn pé kò lo agbára rẹ̀ láti fi kó ọrọ̀ jọ. (Mátíù 8:20) Ẹ̀rí tún wà síwájú sí i pé ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan ló ń sùn ún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Nígbà tó bá ṣe iṣẹ́ ìyanu ó máa ń ná an ní nǹkan kan. Nígbà tó bá mú aláàárẹ̀ lára dá, agbára máa ń jáde lára rẹ̀. Ó ń mọ̀ ọ́n lára pé agbára jáde lára òun, àní bó tiẹ̀ jẹ́ ẹnì kan péré ló wò sàn. (Máàkù 5:25-34) Síbẹ̀ ó gbà kí odindi àwùjọ èèyàn máa fọwọ́ kan òun, tí wọ́n sì ń gba ìmúláradá. (Lúùkù 6:19) Áà, inúure rẹ̀ mà pọ̀ jọjọ o!
17. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun máa ń fi òye lo agbára?
17 Jésù fi òye lo agbára rẹ̀. Kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan nítorí ẹ̀mí ṣekárími, kò sì ṣe èyíkéyìí láti fi ṣe àṣehàn lásán. (Mátíù 4:5-7) Ó kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìyanu láti kàn lè tẹ́ ìtọpinpin òdì Hẹ́rọ́dù lọ́rùn. (Lúùkù 23:8, 9) Dípò tí Jésù ì bá fi sọ agbára rẹ̀ di ìran àpéwò, ó sábà máa ń sọ pé kí àwọn tóun wò sàn má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni. (Máàkù 5:43; 7:36) Kò fẹ́ káwọn èèyàn tipasẹ̀ ìròyìn kàyéfì tí wọ́n bá ń gbọ́ pinnu irú ẹni tóun jẹ́.—Mátíù 12:15-19.
18-20. (a) Kí ló ń sún Jésù lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó gbà ń lò ó? (b) Kí lérò rẹ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà mú adití kan lára dá?
18 Jésù ọkùnrin alágbára yìí yàtọ̀ pátápátá sí àwọn alákòóso tó kàn ń lo agbára bó ṣe wù wọ́n láìka ohun táwọn èèyàn ń fẹ́ àti ìyà tó ń jẹ wọ́n sí. Ire àwọn èèyàn ló máa ń jẹ Jésù lógún. Rírí i lásán pé àwọn kan tiẹ̀ wà nínú ìpọ́njú máa ń dùn ún dọ́kàn débi pé á wá nǹkan kan ṣe láti yọ wọ́n nínú ìyà. (Mátíù 14:14) Ó máa ń gba tiwọn rò, ẹ̀mí ìgbatẹnirò yìí sì ń nípa lórí ọ̀nà tó ń gbà lo agbára rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan tó wúni lórí gan-an wà nínú Máàkù 7:31-37.
19 Ó ṣẹlẹ̀ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá rí Jésù, wọ́n sì gbé ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá, ó sì wo gbogbo wọn sàn. (Mátíù 15:29, 30) Ṣùgbọ́n Jésù dá ẹnì kan yà sọ́tọ̀ lára wọn, ó sì fún un láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Adití lọkùnrin náà, díẹ̀ ló sì fi yàtọ̀ sí odi. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti fi òye mọ̀ pé ẹ̀rù ń ba ọkùnrin yìí tàbí pé ojú ń tì í. Jésù lo òye, ó mú ọkùnrin yìí lọ sí kọ̀rọ̀ kúrò láàárín àwọn èrò. Jésù wá fi àmì sọ ohun tó fẹ́ ṣe fún ọkùnrin náà. Ó “ki àwọn ìka rẹ̀ bọ àwọn etí ọkùnrin náà àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.”c (Máàkù 7:33) Lẹ́yìn náà, Jésù wo ọ̀run, ó sì mí ìmí-ẹ̀dùn. Ọkùnrin náà máa lóye ìgbésẹ̀ méjèèjì yìí pé ó ń sọ fóun pé, ‘Agbára Ọlọ́run ni mo fẹ́ fi ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ẹ yìí o.’ Níkẹyìn Jésù wá sọ pé: “Là.” (Máàkù 7:34) Bẹ́ẹ̀ ló di pé ọkùnrin náà ń gbọ́rọ̀, ó sì lè sọ̀rọ̀ geerege.
20 Ó mà wúni lórí gan-an o, pé bí Jésù ṣe ń lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi wo àwọn èèyàn sàn, ó tún ṣì ń gba tiwọn rò! Ǹjẹ́ bá a ṣe mọ̀ pé irú Alákòóso aláàánú àti agbatẹnirò bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà gbé Ìjọba Mèsáyà lé lọ́wọ́ kò fọkàn wa balẹ̀ bí?
Àpẹẹrẹ Àwọn Nǹkan Tó Ń Bọ̀
21, 22. (a) Àpẹẹrẹ ohun tí à ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú wo làwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù jẹ́? (b) Kí la lè máa retí pé kí Ìjọba Jésù ṣe níwọ̀n bí Jésù tí lágbára lórí àwọn ipá àdáyébá?
21 Àpẹẹrẹ àwọn ìbùkún ńláǹlà tí a máa rí gbà lábẹ́ ìjọba Jésù làwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe nígbà tó wà láyé jẹ́. Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, Jésù á tún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n kárí ayé nìyẹn o! Wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan amóríyá gágá tí à ń wọ̀nà fún lọ́jọ́ iwájú ná.
22 Jésù yóò mú kí àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn tún gún régé padà. Rántí pé ó fi hàn pé òun lágbára lórí àwọn ipá àdáyébá nípa mímú tó mú kí ìjì ńlá rọlẹ̀. Èyí fi hàn dájú pé, lábẹ́ Ìjọba Kristi, kò ní sídìí fún aráyé láti máa bẹ̀rù nítorí ìjì líle, ìsẹ̀lẹ̀, òkè ayọnáyèéfín, tàbí àwọn ìjábá àdáyébá mìíràn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ni Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ tí Jèhófà lò láti dá ayé àti gbogbo ẹ̀dá alààyè inú rẹ̀, ó mọ tinú tòde ilẹ̀ ayé wa dunjú. Ó mọ ọ̀nà tó lè gbà lo àwọn ìpèsè inú rẹ̀ bó ṣe yẹ. Abẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ ni ayé yìí yóò ti yí padà di Párádísè.—Lúùkù 23:43.
23. Gẹ́gẹ́ bí ọba Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni Jésù yóò ṣe yanjú àwọn ohun tí aráyé nílò?
23 Àwọn ohun tí ọmọ aráyé nílò ńkọ́, kí ló máa ṣe nípa wọn? Nígbà tí Jésù ti lè lo ìwọ̀nba oúnjẹ táṣẹ́rẹ́ láti fi bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, tí wọ́n tún jẹ àjẹṣẹ́kù, ìyẹn mú un dá wa lójú pé a óò bọ́ lọ́wọ́ ebi nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Lóòótọ́, bí oúnjẹ bá pọ̀ yanturu, tí a sì ń pín-in kárí àwọn èèyàn bó ṣe tọ́, a kò ní gbúròó ebi mọ́ láéláé. (Sáàmù 72:16) Bó ṣe káwọ́ àìsàn àti àrùn jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn aláìsàn, afọ́jú, adití, aláàbọ̀ ara àti arọ yóò rí ìwòsàn gbà pátápátá àní títí láé. (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Nígbà tó ti lè jí òkú dìde, ìyẹn jẹ́ kó yéni pé ara ohun tó lágbára láti ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run ni pé yóò jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó wà ní ìrántí Bàbá rẹ̀ dìde.—Jòhánù 5:28, 29.
24. Bí a ṣe ń gbé agbára Jésù yẹ̀ wò, kí ni kí á fi sọ́kàn, kí sì nìdí rẹ̀?
24 Bí a ṣe ń gbé agbára Jésù yẹ̀ wò, kí á máa fi í sọ́kàn pé ìṣe Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́ ni Ọmọ yìí ń fara wé o. (Jòhánù 14:9) Ọ̀nà tí Jésù gbà ń lo agbára wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń lo agbára. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo ọ̀nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jésù gbà mú adẹ́tẹ̀ kan lára dá. Àánú adẹ́tẹ̀ yìí ṣe Jésù débi pé ó fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” (Máàkù 1:40-42) Ńṣe ni Jèhófà ń fi yé wa nípasẹ̀ irú àkọsílẹ̀ báyìí pé, ‘Bí mo ṣe ń lo agbára mi lẹ̀ ń rí yẹn o!’ Ǹjẹ́ èyí kò mú ọ yin Ọlọ́run wa Olódùmarè lógo kí o dúpẹ́ pé ó ń lo agbára rẹ̀ ní irú ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ bí?
a Ìjì àìròtẹ́lẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an lójú Òkun Gálílì. Nítorí pé ibi tí òkun yìí wà lọ sílẹ̀ gan-an (ní nǹkan bí igba mítà sí ìsàlẹ̀ ìtẹ́jú òkun), afẹ́fẹ́ ibẹ̀ máa ń gbóná ju ìyókù àgbègbè ibẹ̀ lọ, èyí kì í sì í jẹ́ kí atẹ́gùn ibẹ̀ fẹ́ wọ́ọ́rọ́wọ́. Atẹ́gùn líle máa ń fẹ́ wá láti orí Òkè Hámónì níhà àríwá a sì máa rọ́ lu Àfonífojì Jọ́dánì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ojú òkun tó pa rọ́rọ́ ní ìṣẹ́jú kan kàn lè bẹ̀rẹ̀ ìjì líle ní ìṣẹ́jú kejì.
b Láfikún sí i, àwọn ìwé Ìhìn Rere máa ń fi àlàyé kan ṣoṣo kó àwọn iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ pa pọ̀ nígbà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìhìn Rere kan sọ pé nígbà kan “gbogbo ìlú ńlá” kan wá a wá, ó sì mú “ọ̀pọ̀” aláìsàn lára dá.—Máàkù 1:32-34.
c Títu itọ́ jẹ́ ọ̀nà kan tàbí àmì ìwòsàn kan tí àwọn Júù àti Kèfèrí jọ tẹ́wọ́ gbà, ìwé àwọn rábì sì sọ nípa lílo itọ́ láti fi ṣe ìwòsàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jésù tutọ́ láti fi sọ fún ọkùnrin náà pé ó fẹ́ gba ìwòsàn. Èyí tó wù kí ó jẹ́, kinní kan ṣáà dájú, kì í ṣe pé Jésù ń lo itọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oògùn ìwòsàn.