Ohun Tí Ọjọ́ Jèhófà Máa Ṣí Payá
“Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, . . . ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.”—2 PÉT. 3:10.
1, 2. (a) Báwo ni ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ṣe máa dópin? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
ORÍ irọ́ ni ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí dúró lé. Irọ́ náà sì ni pé èèyàn lè ṣàkóso ayé kó sì ṣàṣeyọrí láìsí ọwọ́ Jèhófà níbẹ̀. (Sm. 2:2, 3) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ohunkóhun tó dúró lórí irọ́ láti wà títí láé? Kò lè ṣeé ṣe! Síbẹ̀, a kò ní dúró dìgbà tí ayé Sátánì á fi pa run fúnra rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ló máa pa á run ní àkókò tó yàn àti lọ́nà tó fẹ́. Ìgbésẹ̀ tí Ọlọ́run máa gbé lòdì sí ayé búburú yìí á fi hàn pé onídàájọ́-òdodo ni, ó sì tún jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́.—Sm. 92:7; Òwe 2:21, 22.
2 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” (2 Pét. 3:10) Kí ni “àwọn ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” tá a mẹ́nu kàn níbí? Kí ni “àwọn ohun ìpìlẹ̀” tó máa di yíyọ́? Kí sì ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí”? Tá a bá mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnikún-fún-ẹ̀rù tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́.
Àwọn Ọ̀run àti Ilẹ̀ Ayé Tó Máa Kọjá Lọ
3. Kí ni “àwọn ọ̀run” tá a mẹ́nu kàn nínú 2 Pétérù 3:10, báwo ni wọ́n sì ṣe máa kọjá lọ?
3 Nínú Bíbélì, tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọ̀run” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó sábà máa ń tọ́ka sí àwọn alákòóso, tí wọ́n wà ní ipò tó ga ju ti àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí lọ. (Aísá. 14:13, 14; Ìṣí. 21:1, 2) “Àwọn ọ̀run [tí] yóò kọjá lọ” dúró fún àwọn ìjọba èèyàn tó ń ṣàkóso àwùjọ ẹ̀dá èèyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Bí wọ́n ṣe máa kọjá lọ pẹ̀lú “ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì,” èyí tí ìtumọ̀ Bíbélì míì pè ní “ariwo ńlá,” lè dúró fún bí wọ́n ṣe máa pa run lọ́gán.
4. Kí ni “ilẹ̀ ayé,” báwo ló sì ṣe máa pa run?
4 “Ilẹ̀ ayé” dúró fún àwọn èèyàn tó sọ ara wọn di àjèjì sí Ọlọ́run. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wà ní ọjọ́ Nóà, Ọlọ́run sì fi Ìkún-Omi pa wọ́n run. “Nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pét. 3:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kan náà ni Ìkún-Omi pa gbogbo àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run run, ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni ìparun tó ń bọ̀ máa wáyé nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣí. 7:14) Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà, Ọlọ́run máa lo àwọn olóṣèlú láti pa “Bábílónì Ńlá” run, á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun kórìíra aṣẹ́wó ìsìn yẹn. (Ìṣí. 17:5, 16; 18:8) Lẹ́yìn náà, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tó jẹ́ apá tó kẹ́yìn nínú ìpọ́njú ńlá náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ máa pa ìyókù ayé Sátánì run.—Ìṣí. 16:14, 16; 19:19-21.
“Àwọn Ohun Ìpìlẹ̀ . . . Yóò Di Yíyọ́”
5. Kí ló wà lára àwọn ohun ìpìlẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ náà?
5 Kí ni “àwọn ohun ìpìlẹ̀” tó máa “di yíyọ́”? Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan túmọ̀ “àwọn ohun ìpìlẹ̀” sí “àwọn ìlànà àkọ́kọ́,” tàbí “ibi tí nǹkan ti pilẹ̀ ṣẹ̀.” Ó sọ pé, “wọ́n máa ń lò ó fún àwọn lẹ́tà a, b, d, tó jẹ́ apá tó kéré jù lọ nínú ọ̀rọ̀ sísọ.” Nípa bẹ́ẹ̀, “àwọn ohun ìpìlẹ̀” tí Pétérù mẹ́nu kàn ń tọ́ka sí àwọn nǹkan ìpìlẹ̀ tó mú kí ìṣe, ìwà, àwọn ọ̀nà àti àfojúsùn ayé yìí jẹ́ ti aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Lára “àwọn ohun ìpìlẹ̀” náà ni “ẹ̀mí ayé,” èyí ‘tí ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.’ (1 Kọ́r. 2:12; ka Éfésù 2:1-3.) Ẹ̀mí tàbí “afẹ́fẹ́” yẹn kún inú ayé Sátánì. Ó máa ń fipá mú àwọn èèyàn láti ronú, wéwèé, sọ̀rọ̀, tàbí hùwà ní àwọn ọ̀nà tó ń ṣàgbéyọ ìwà Sátánì, agbéraga àti ọlọ̀tẹ̀, tó jẹ́ “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́.”
6. Báwo ni ẹ̀mí ayé ṣe máa ń fara hàn?
6 Nítorí náà, yálà àwọn tó ń jẹ́ kí ẹ̀mí ayé darí àwọn mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí wọn kò mọ̀, ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ kí Sátánì darí ìrònú wọn, débi tí wọ́n fi ń ronú bó ṣe fẹ́ tí wọ́n sì ń hùwà bíi tiẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe ohun tó wù wọ́n, láìbìkítà nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí ọ̀ràn kan bá yọjú, wọ́n máa ń gbéra ga, wọ́n máa ń fi ìmọtara-ẹni nìkan hàn, wọ́n máa ń hùwà ọ̀tẹ̀ sí àwọn aláṣẹ, wọ́n sì máa ń gba “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” láyè.—Ka 1 Jòhánù 2:15-17.a
7. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa “ṣọ́ ọkàn-àyà [wa]”?
7 Ẹ ò wá rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa “ṣọ́ ọkàn-àyà [wa]” nípa lílo ọgbọ́n Ọlọ́run bá a bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, ohun tá a ó máa kà, eré ìnàjú àti ìkànnì tá a ó máa lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì! (Òwe 4:23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kól. 2:8) Àṣẹ yìí wá túbọ̀ ṣe pàtàkì bí ọjọ́ Jèhófà ti ń sún mọ́lé, torí pé ‘ooru’ rẹ̀, irú èyí tí kò sí rí, máa yọ́ gbogbo “àwọn ohun ìpìlẹ̀” inú ètò Sátánì dà nù, ó sì máa fi wọ́n hàn bí èyí tí kò ní àwọn ànímọ́ tó lè dúró níwájú ooru ìbínú Ọlọ́run. Èyí mú wa rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú Málákì 4:1, tó sọ pé: “Ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ń jó bí ìléru, gbogbo àwọn oníkùgbù àti gbogbo àwọn tí ń hùwà burúkú yóò sì dà bí àgékù pòròpórò. Ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jẹ wọ́n run dájúdájú.”
“Ayé àti Àwọn Iṣẹ́ Tí Ń Bẹ Nínú Rẹ̀ Ni A Ó sì Wá Rí”
8. Báwo la ṣe “wá” ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ “rí”?
8 Kí ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé “ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí”? Ọ̀rọ̀ náà “wá rí” la tún lè túmọ̀ sí “ṣe àwárí” tàbí “tú fó.” Ohun tí Pétérù ní lọ́kàn ni pé nígbà ìpọ́njú ńlá, Jèhófà máa tú ayé Sátánì fó, á jẹ́ kó hàn gbangba pé ó ta ko Òun àti Ìjọba Òun, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìparun. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 26:21 nípa àkókò yẹn kà pé: “Jèhófà ń jáde bọ̀ láti ipò rẹ̀, láti béèrè ìjíhìn fún ìṣìnà àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lòdì sí òun, dájúdájú, ilẹ̀ náà yóò sì fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ hàn síta, kì yóò sì tún bo àwọn tirẹ̀ tí a pa mọ́.”
9. (a) Kí la gbọ́dọ̀ kọ̀ sílẹ̀, kí sì nìdí? (b) Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe, kí sì nìdí?
9 Ní ọjọ́ Jèhófà, àwọn tí ayé yìí àti ẹ̀mí búburú rẹ̀ ti sọ dìdàkudà máa fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an hàn, kódà wọ́n á máa pa ara wọn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni onírúurú eré ìnàjú oníwà ipá tó gbajúmọ̀ lóde òní ń múra ọkàn àwọn èèyàn sílẹ̀ de àkókò náà tí ọwọ́ olúkúlùkù “yóò sì wá láti gbéjà ko ọwọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” (Sek. 14:13) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká kọ ohunkóhun, ì báà jẹ́ fíìmù, ìwé, géèmù orí fídíò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tó lè mú ká máa hu ìwà tí Ọlọ́run kórìíra, bí ìgbéraga àti ìfẹ́ fún ìwà ipá! (2 Sám. 22:28; Sm. 11:5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ká máa fi èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù, torí pé irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ èyí tí kò ní yọ́ nígbà ooru ìṣàpẹẹrẹ ọjọ́ Jèhófà.—Gál. 5:22, 23.
“Ọ̀run Tuntun àti Ilẹ̀ Ayé Tuntun”
10, 11. Kí ni “ọ̀run tuntun” àti “ilẹ̀ ayé tuntun”?
10 Ka 2 Pétérù 3:13. “Ọ̀run tuntun” ni Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run, èyí tá a gbé kalẹ̀ lọ́dún 1914 nígbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin. (Lúùkù 21:24) Kristi Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti gba èrè ti òkè ọ̀run, ni wọ́n wà nínú Ìjọba aládé yìí. Nínú ìwé Ìṣípayá, àwọn àyànfẹ́ yìí la pè ní ‘ìlú ńlá mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.’ (Ìṣí. 21:1, 2, 22-24) Bó ṣe jẹ́ pé Jerúsálẹ́mù ilẹ̀ ayé ni ibùjókòó ìjọba ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, bẹ́ẹ̀ náà ni Jerúsálẹ́mù Tuntun àti Ọkọ rẹ̀ ṣe para pọ̀ jẹ́ Ìjọba ètò àwọn nǹkan tuntun. Ìlú òkè ọ̀run yìí máa “ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀” nípa dídarí àfiyèsí rẹ̀ sí ilẹ̀ ayé.
11 “Ilẹ̀ ayé tuntun” tọ́ka sí àwùjọ tuntun ti àwọn ẹ̀dá èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, tí ẹ̀rí fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fínnú fíndọ̀ tẹrí ba fún. Ìgbà yẹn gan-an ni Párádísè tẹ̀mí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn nísinsìnyí yóò wà níbi tó yẹ kó wà nínú “ilẹ̀ ayé gbígbé” ẹlẹ́wà “tí ń bọ̀.” (Héb. 2:5) Báwo la ṣe lè jẹ́ apá kan ètò àwọn nǹkan tuntun yẹn?
Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Ńlá Jèhófà
12. Kí nìdí tí ọjọ́ Jèhófà fi máa dé bá aráyé lójijì?
12 Pọ́ọ̀lù àti Pétérù sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ Jèhófà máa dé “gẹ́gẹ́ bí olè,” ìyẹn ni pé ó máa yọ́ wọlé, láìròtẹ́lẹ̀. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1, 2.) Kódà, ọ̀nà tó máa gbà wọlé dé lójijì máa ya àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ yẹn lẹ́nu. (Mát. 24:44) Àmọ́, ó máa ju ohun ìyàlẹ́nu lọ fún aráyé. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n [ìyẹn, àwọn tó sọ ara wọn di àjèjì sí Jèhófà] bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tẹs. 5:3.
13. Báwo ni a ò ṣe ní jẹ́ kí igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” tàn wá jẹ?
13 Irọ́ mìíràn tí ẹ̀mí búburú mí sí ni igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” yẹn máa jẹ́, síbẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò ní jẹ́ kí ìyẹn tan àwọn jẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè, nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán.” (1 Tẹs. 5:4, 5) Torí náà, ẹ jẹ́ ká dúró nínú ìmọ́lẹ̀, ká jìnnà réré sí òkùnkùn inú ayé Sátánì. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn [ìyẹn, àwọn olùkọ́ èké tó wà nínú ìjọ Kristẹni] nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.”—2 Pét. 3:17.
14, 15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń buyì kún wa? (b) Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn?
14 Ṣàkíyèsí pé Jèhófà kò wulẹ̀ sọ fún wa pé ká ‘ṣọ́ ara wa,’ kó sì parí ọ̀rọ̀ náà síbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó buyì kún wa nípa fífún wa ní “ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀,” ìyẹn bó ṣe ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa.
15 Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti ń ṣiyè méjì nípa àwọn ìránnilétí tó ń jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa wà lójúfò tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ ka àwọn ìránnilétí náà sí rárá. Wọ́n lè máa sọ pé, ‘Ó ti pẹ́ tá a ti ń gbọ́ àwọn ìránnilétí yẹn.’ Àmọ́, ó yẹ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi sọ́kàn pé nípa sísọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe pé wọ́n ń ṣiyè méjì nípa ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń ṣiyè méjì nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà.” (Háb. 2:3) Bákan náà, Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Ní àfikún, Pétérù kọ̀wé pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pét. 3:11, 12) Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀ kò jẹ́ gbójú fo àwọn ọ̀rọ̀ tí Pétérù fìtara sọ yẹn láé!
16. Ìwà wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún, kí sì nìdí?
16 Ó dájú pé “ẹrú búburú” náà ló sọ pé Ọ̀gá òun ń pẹ́. (Mát. 24:48) Ẹrú búburú yẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ tí ìwé 2 Pétérù 3:3, 4 ṣàpèjúwe. Pétérù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá” àti pé “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn,” wọ́n á máa fi àwọn tó ń ṣègbọràn, tí wọ́n sì ń fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn, ṣe ẹlẹ́yà. Dípò tí àwọn olùyọṣùtì yẹn ì bá fi pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀ràn ti ara wọn nìkan ló máa ń jẹ wọ́n lógún. Ẹ má ṣe jẹ́ ká dẹni tó ń hu irú ìwà àìgbọràn àti ìwà tó léwu bẹ́ẹ̀ láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa “ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà” nípa mímú kí ọwọ́ wá dí lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ká má sì ṣe máa ṣàníyàn jù nípa àkókò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ èyí tó wà níkàáwọ́ Jèhófà Ọlọ́run.—2 Pét. 3:15; ka Ìṣe 1:6, 7.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Ìgbàlà
17. Kí ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ ṣe nípa ìkìlọ̀ Jésù pé kí wọ́n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, kí ló sì mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù wọ Jùdíà lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni olóòótọ́ lo àǹfààní tí wọ́n kọ́kọ́ ní láti sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe kìlọ̀ pé kí wọ́n ṣe. (Lúùkù 21:20-23) Kí ló mú kí wọ́n sá kúrò níbẹ̀ lọ́gán, láìfi àkókò falẹ̀? Fífi tí wọ́n fi ìkìlọ̀ Jésù sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n mọ̀ dájú pé ìpinnu táwọn máa ṣe á mú ìnira dání, gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n mọ̀ pé Jèhófà kò ní fi àwọn adúróṣinṣin sílẹ̀.—Sm. 55:22.
18. Ojú wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 21:25-28 ń mú kó o máa fi wo ìpọ́njú ńlá?
18 Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, torí pé òun nìkan ló lè gbà wá là nígbà tí ìpọ́njú ńlá tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí bá dé bá ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, àmọ́ kó tó di pé Jèhófà mú ìdájọ́ ṣẹ sórí gbogbo aráyé, àwọn èèyàn yóò “máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí ìbẹ̀rù, ẹ̀rù kankan kò ní ba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa yọ̀ torí pé wọ́n mọ̀ pé ìgbàlà àwọn ti sún mọ́lé.—Ka Lúùkù 21:25-28.
19. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
19 Ó dájú pé ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ló ń dúró de àwọn tó bá ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé àti “àwọn ohun ìpìlẹ̀” rẹ̀! Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí ṣe fi hàn, bá a bá fẹ́ jèrè ìyè, a gbọ́dọ̀ ṣe ju pé ká kórìíra ibi. A tún gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ tó wu Jèhófà ká sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.—2 Pét. 3:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ìwà tí ẹ̀mí ayé ń gbé lárugẹ, wo ìwé Reasoning From the Scriptures, ojú ìwé 389 sí 393 àti ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ojú ìwé 54 sí 59.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún . . .
“àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” tó wà nísinsìnyí?
“àwọn ohun ìpìlẹ̀”?
“ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”?
• Kí nìdí tá a fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Báwo lo ṣe lè máa “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ” kó o sì ya ara rẹ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Báwo la ṣe ń fi hàn pé a “ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà”?