Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Kan Ṣoṣo—Ló Wà
ÌSÌN tàbí ìjọ kan ṣoṣo ni Jésù Kristi dá sílẹ̀. Ìjọ yẹn jẹ́ ìdílé tẹ̀mí. Ohun tá a ń sọ ni pé ó jẹ́ àgbájọ àwọn èèyàn tá a fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yàn—gbogbo wọn ni Ọlọ́run sì kà sí “ọmọ” rẹ̀.—Róòmù 8:16, 17; Gálátíà 3:26.
Jésù kọ́ni pé ọ̀nà kan ṣoṣo ni Ọlọ́run ń lò láti darí àwọn èèyàn sínú òtítọ́ àti ìyè. Láti ṣàpèjúwe òtítọ́ pàtàkì yẹn, Jésù fi ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun wé ojú ọ̀nà kan. Ó sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14; Jòhánù 14:6; Ìṣe 4:11, 12.
Ìjọ Tó Wà Níṣọ̀kan
Ìwé The New Dictionary of Theology, sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ka ẹ̀sìn ọ̀rúndún kìíní yìí sí irú “ẹgbẹ́ tó wà kárí ayé, tó délé dóko, tá a sì ṣètò gẹ́gẹ́ bíi ti ẹ̀sìn Kátólíìkì òde òní.” Kí nìdí? Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà ti sọ, “ìdí náà kò ju pé kò sí irú ẹgbẹ́ tó wà kárí ayé, tó délé dóko, tá a sì ṣètò lọ́nà yìí lákòókò yẹn.”
Kò sẹ́ni tí ò mọ̀ pé ẹ̀sìn Kristẹni ìgbà ìjímìjí yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò ẹ̀sìn lóde òní. Àmọ́, a ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó dáa. Ìjọ kọ̀ọ̀kan kì í dá ti ara rẹ̀ ṣe. Gbogbo wọn pátá ló ń gba àṣẹ látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣàkóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbààgbà ọkùnrin nínú ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ yẹn—wọ́n sì ń mú kí ìjọ wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “ara kan” tó jẹ́ ti Kristi.—Éfésù 4:4, 11-16; Ìṣe 15:22-31; 16:4, 5.
Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo yẹn? Ṣé òun ló wá di ẹ̀sìn Kátólíìkì tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ báyìí? Àbí òun ló wá gbèrú, tó di àwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lóde òní? Àbí, ó ní nǹkan mìíràn tó ṣẹlẹ̀ sí i?
“Àlìkámà” àti “Èpò”
Láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ohun tí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ yẹ̀ wò. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ pé Jésù mọ̀ pé ìjọ òun yóò di èyí táwọn èèyàn kò ní dá mọ̀ nígbà tó bá yá àti pé òun á ṣì jẹ́ kó máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Nígbà tó ń fi ìjọ rẹ̀ wé “ìjọba ọ̀run,” ó sọ pé: “Ìjọba ọ̀run wá dà bí ọkùnrin kan tí ó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì tún fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà, ó sì lọ. Nígbà tí ewé ọ̀gbìn náà rú jáde, tí ó sì mú èso jáde, nígbà náà ni àwọn èpò fara hàn pẹ̀lú. Nítorí náà, àwọn ẹrú baálé ilé náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Ọ̀gá, kì í ha ṣe irúgbìn àtàtà ni ìwọ fún sínú pápá rẹ? Nígbà náà, báwo ni ó ṣe wá ní àwọn èpò?’ Ó wí fún wọn pé, ‘Ọ̀tá kan, ọkùnrin kan, ni ó ṣe èyí.’ Wọ́n wí fún un pé, ‘Ìwọ ha fẹ́ kí àwa, nígbà náà, jáde lọ kí a sì kó wọn jọ?’ Ó wí pé, ‘Ó tì o; kí ó má bàa jẹ́ pé nípa èèṣì, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn èpò jọ, ẹ óò hú àlìkámà pẹ̀lú wọn. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè; ní àsìkò ìkórè, ṣe ni èmi yóò sì sọ fún àwọn akárúgbìn pé, Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n, lẹ́yìn náà ẹ lọ kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi.’”—Mátíù 13:24-30.
Jésù ṣàlàyé pé òun ni “afúnrúgbìn.” “Irúgbìn àtàtà” sì dúró fún àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. “Ọ̀tá” rẹ̀ sì ni Sátánì Èṣù. “Àwọn èpò” ni àwọn ayédèrú Kristẹni tó yọ́ wọ inú ìjọ Kristẹni ìjímìjí. Ó sọ pé òun á jẹ́ kí “àlìkámà” àti “èpò” máa dàgbà pa pọ̀ títí di ìgbà “ìkórè,” tí yóò dé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 13:37-43) Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí?
Wọ́n Sọ Ìjọ Kristẹni Dìdàkudà
Kété lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì kú tán ni àwọn olùkọ́ tó ti di apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí darí ìjọ. Wọ́n ń sọ “àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ‘yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́.’ Tí wọ́n sì di ẹni tá a mú “yà sínú ìtàn èké.”—1 Tímótì 4:1-3; 2 Tímótì 4:3, 4.
Ìwé The New Dictionary of Theology, sọ pé, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, “Ẹ̀sìn Kátólíìkì di ẹ̀sìn kan ṣoṣo tá a fàṣẹ sí . . ní gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù.” Ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé “ẹ̀sìn àti òṣèlú wá wọnú ara wọn”—èyí sì lòdì pátápátá sí ohun táwọn Kristẹni ìjímìjí gbà gbọ́. (Jòhánù 17:16; Jákọ́bù 4:4) Ìwé náà tún sọ pé nígbà tó ṣe, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ẹ̀sìn, àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ yí padà pátápátá. Ohun tó sì fà á ni “pípa tí wọ́n pa Májẹ̀mú Láéláé pọ̀ mọ́ àkọ̀tun ẹ̀kọ́ Plato, èyí tí kò bára mu rárá tí kò sì ṣeni láǹfààní kankan.” Gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí fara sin bí àwọn ayédèrú Kristẹni ṣe ń pọ̀ sí i.
Àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ Jésù mọ̀ pé ó ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ojúlówó àlìkámà àti èpò, wọ́n dà bí oríṣi èpò onírun lára kan báyìí tó ní májèlé nínú, èyí tó máa ń fara jọ àlìkámà gan-an nígbà tó bá ń dàgbà. Nítorí náà, Jésù ń sọ pé fún ìgbà díẹ̀, yóò ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àti àwọn tó jẹ́ ayédèrú. Èyí kò túmọ̀ sí pé kò ní sí ìjọ Kristẹni mọ́ rárá o, nítorí pé Jésù ṣèlérí pé òun yóò máa bá a lọ láti dáàbò bo àwọn arákùnrin òun nípa tẹ̀mí “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Jésù sọ pé àlìkámà yóò máa dàgbà. Pẹ̀lú ìyẹn náà, fún ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni—yálà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí ní àwùjọ àwùjọ—fi sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé àwọn ohun tí Kristi fi kọ́ni. Àmọ́ wọn kì í ṣe ẹgbẹ́ tàbí àjọ kan tó ṣeé dá mọ̀ mọ́. Ó dájú pé wọn kò dà bíi àwọn ètò ìsìn apẹ̀yìndà tó ṣeé fojú rí, èyí tó ti mú ẹ̀tẹ́ àti àbùkù bá orúkọ Jésù Kristi jálẹ̀ ìtàn.—2 Pétérù 2:1, 2.
‘A Ṣí Ọkùnrin Oníwà Àìlófin Payá’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun mìíràn tó máa fi ayédèrú ètò ìsìn yìí hàn. Ó kọ ọ́ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan sún yín dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí, nítorí [ọjọ́ Jèhófà] kì yóò dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà kọ́kọ́ dé, tí a sì ṣí ọkùnrin oníwà àìlófin payá.” (2 Tẹsalóníkà 2:2-4) “Ọkùnrin oníwà àìlófin” yìí kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe ẹgbẹ́ àlùfáà tó sọ ara rẹ̀ di alákòóso lórí ìjọ “Kristẹni.”a
Ìpẹ̀yìndà náà bẹ̀rẹ̀ nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó túbọ̀ gbilẹ̀ sí i lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì nígbà tí kò sí àwọn tó máa dènà ìpẹ̀yìndà náà mọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé, ohun tí a máa fi dá a mọ̀ gan-an ni “ìṣiṣẹ́ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo.” (2 Tẹsalóníkà 2:6-12) Ẹ ò rí i pé bí iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀pọ̀ aṣáájú ìsìn ṣe rí gan-an nìyẹn látọjọ́ pípẹ́!
Láti gbárùkù ti ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ pé ẹ̀sìn Kátólíìkì ni ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà, àwọn aṣáájú ìjọ Kátólíìkì sọ pé “àtọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì ìpilẹ̀ṣẹ̀” làwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn ti “gba ipò oyè wọn, pé ńṣe ló ń ti orí ẹnì kan bọ́ sórí ẹlòmíràn títí tó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn.” Ní ti gidi, ohun tí wọ́n sọ yìí pé àtọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì ìjímìjí ni ipò oyè yìí ti bẹ̀rẹ̀ títí tó fi dé ọ̀dọ̀ wọn, kò sí nínú ìtàn bẹ́ẹ̀ ni kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Kò sí ẹ̀rí tó ṣe é gbọ́kàn lé tó fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń darí ètò ẹ̀sìn tó gbòde lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Jésù.—Róòmù 8:9; Gálátíà 5:19-21.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó dìde lẹ́yìn tí wọ́n dá èyí tí wọ́n ń pè ní Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe sílẹ̀ ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn ìjọ wọ̀nyí tẹ̀ lé ìlànà ìjọ Kristẹni ìjímìjí? Ǹjẹ́ wọ́n wà ní mímọ́ bíi ti ìjọ Kristẹni ìjímìjí? Òótọ́ ni pé Bíbélì wá di èyí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn gbáàtúù èèyàn, kódà ó wà ní èdè ìbílẹ̀ wọn pàápàá lẹ́yìn tí wọ́n dá Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe sílẹ̀. Síbẹ̀, ìtàn fi hàn pé ẹ̀kọ́ èké làwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí fi ń kọ́ni.b—Mátíù 15:7-9.
Àmọ́ ṣàkíyèsí èyí. Jésù Kristi sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó dájú pé ìjọ òun tòótọ́ kan ṣoṣo náà yóò di èyí tí a mú padà bọ̀ sípò ní àkókò tó pè ní òpin ètò àwọn nǹkan. (Mátíù 13:30, 39) Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì fi hàn pé àkókò náà la wà yìí. (Mátíù 24:3-35) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ibo ni ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo náà wà?’ Ó yẹ kí ìsìn náà túbọ̀ di èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa.
Ó ṣeé ṣe kó o rò pé o tí rí ìsìn tàbí ìjọ tòótọ́ náà. Ó ṣe pàtàkì láti mọ èyí dájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà bíi ti ọ̀rúndún kìíní. Ǹjẹ́ o ti fara balẹ̀ wádìí láti mọ̀ bóyá ìsìn rẹ ń tẹ̀ lé ìlànà tí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi lélẹ̀, kó o sì mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni bá ti Jésù Kristi mu látòkèdélẹ̀? O ò ṣe ṣàyẹ̀wò ìyẹn nísinsìnyí? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 17:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lè rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí a ṣe ń dá “ọkùnrin oníwà àìlófin” náà mọ̀ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1990, ojú ìwé 10 sí 14.
b Wò àpilẹ̀kọ náà, “Ìsìn Protestant—Àtúnṣebọ́sípò Ha Ni Bí?” nínú ìwé ìròyìn Jí! ti September 8, 1989, ojú ìwé 20 sí 24.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe Jésù nípa àlìkámà àti èpò fi kọ́ wa nípa ìsìn tòótọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ ìsìn rẹ ń tẹ̀ lé ìlànà tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn wíwàásù àti kíkẹ́kọ̀ọ́?