TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | TÍMÓTÌ
“Ọmọ Mi Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n àti Olùṣòtítọ́ Nínú Olúwa”
TÍMÓTÌ ti fi ilé sílẹ̀ báyìí, bó ṣe ń lọ lọ́nà, ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa ohun tó máa bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí. Ẹni tí wọ́n jọ ń lọ ló ṣáájú. Wọ́n gba àwọn pápá tí Tímótì mọ̀ dáadáa kọjá. Wọ́n ti jìnnà díẹ̀ sí ìlú Lísírà báyìí. Tímótì rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń ronú nípa ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ tí inú wọ́n dùn bó ṣe ń lọ, tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ nu omijé wọn. Ṣé Tímótì máa bojú wẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kan sí i, kó tún juwọ́ sí wọ́n pé ó dìgbóṣe?
Ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń wo Tímótì tí á sì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé onítìjú èèyàn ni Tímótì, àmọ́ inú rẹ̀ dùn bó ṣe rí i tí ara rẹ̀ yá gágá. Tímótì kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà, bóyá ló tíì pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún. Ó bọ̀wọ̀ fún Pọ́ọ̀lù, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní báyìí, Tímótì àti akínkanjú ọkùnrin tó jẹ́ olóòótọ́ yìí ni wọ́n jọ ń rìnrìn àjò tó máa mú kó jìnnà gan-an sílé. Bí wọ́n ṣe ń fi ẹsẹ̀ rìn, ni wọ́n á máa wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì máa dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu lójú ọ̀nà. Tímótì ò mọ̀ bóyá òun tiẹ̀ tún máa pa dà sílé.
Kí ló mú kí ọ̀dọ́kùnrin yìí dáwọ́ lé irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀? Èrè wo ló máa rí gbà tó máa tó ohun tó yááfì? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ tí Tímótì ní?
“LÁTI ÌGBÀ ỌMỌDÉ JÒJÒLÓ”
Ẹ jẹ́ ká ronú pa dà sí nǹkan bí ọdún méjì tàbí mẹ́ta ṣáájú àkókò yìí. Ká gbà pé ó ṣeé ṣe kí Tímótì jẹ́ ọmọ ìlú Lísírà. Ìlú àdádó kékeré ni, ó sì jẹ́ ilẹ̀ olómi. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbọ́ èdè Gíríìkì, àmọ́ wọ́n tún máa ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn èdè Likaóníà. Lọ́jọ́ kan, ariwo ta ní ìlú tó pa rọ́rọ́ yìí. Ohun tó fà á ni pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì dé sí ìlú Lísírà láti ìlú Íkóníónì. Bí wọ́n ṣe ń wàásù lọ, Pọ́ọ̀lù tajú kán rí ọkùnrin arọ kan tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Pọ́ọ̀lù sì wo ọkùnrin arọ náà sàn!—Ìṣe 14:5-10.
Ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú Lísírà nígbàgbọ́ nínú àwọn ìtàn àròsọ kan pé nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, àwọn òrìṣà máa ń gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n á sì wá sí àgbègbè yẹn. Fún ìdí yìí, àwọn aráàlú Lísírà fi Pọ́ọ̀lù pe òrìṣà Hẹ́mísì, wọ́n sì pe Bánábà ní òrìṣà Súúsì! Agbára káká ni àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yìí fi ṣèdíwọ́ fún wọn kí wọ́n má báa rúbọ sí wọn.—Ìṣe 14:11-18.
Àwọn èèyàn díẹ̀ nílùú Lísírà gbà pé èèyàn ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, pé wọn kì í ṣe òrìṣà rárá. Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Yùníìsì, obìnrin Júù kan tó fẹ́ ọkùnrin Gíríìkì kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́,a àti màmá rẹ̀, Lọ́ìsì. Ó hàn gbangba pé wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, inú wọn sì dùn sí i. Ọ̀rọ̀ tí gbogbo àwọn Júù olóòótọ́ ti ń fojú sọ́nà fún ni. Ìyẹn ni pé Mèsáyà ti wá, ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ ló sì ṣẹ sí i lára!
Ó ṣe kedere pé ìbẹ̀wò Pọ́ọ̀lù ṣe Tímótì láǹfààní. Àtìgbà tí Tímótì ti wà ní “ọmọdé jòjòló” làwọn òbí rẹ̀ ti kọ́ ọ láti nífẹ̀ẹ́ Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:15) Bíi ti ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀, Tímótì náà gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa Mèsáyà. Ohun míì tó tún mú kí Tímótì gbà gbọ́ ni ọkùnrin arọ tí Pọ́ọ̀lù mú lára dá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìmọye ìgbà ni Tímótì ti rí ọkùnrin yìí ní ìgboro ìlú Lísírà. Ní báyìí, Tímótì rí ọkùnrin arọ yìí tó fẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé rẹ̀. Abájọ tí Yùníìsì, Lọ́ìsì àti Tímótì fi di Kristẹni. Lóde òní, àwọn òbí àtàwọn òbí àgbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Lọ́ìsì àti Yùníìsì. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti kékeré?
“INÚ Ọ̀PỌ̀ ÌPỌ́NJÚ”
Inú àwọn tó di Kristẹni ní ìlú Lísírà dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìrètí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní. Àmọ́, wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ pé jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi máa ná àwọn ní nǹkan kan. Àwọn Júù tí wọ́n ń ta ko ẹ̀sìn Kristẹni wá láti ìlú Íkóníónì àti Áńtíókù, wọ́n sì mú kí àwọn aráàlú Lísírà kọjú ìjà sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn èrò tinú ń bí yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta. Bí òkúta náà ṣe ń ba Pọ́ọ̀lù lemọ́lemọ́, ó ṣubú lulẹ̀. Àwọn jàǹdùkú náà sì wọ́ ọ lọ sí ẹ̀yín ìlú, kó lè kú síbẹ̀.—Ìṣe 14:19.
Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọlẹ́yìn tó wà ní ìlú Lísírà lọ wo Pọ́ọ̀lù níbi tí wọ́n wọ̀ ọ́ jù sí, wọ́n sì dúró yí i ká. Ó dájú pé ara máa tù wọ́n gan-an nígbà tí Pọ́ọ̀lù yíra pa dà, tó dìde, tó sì pa dà sí ìlú Lísírà láìfọ̀tá pè. Lọ́jọ́ kejì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbéra lọ sí ìlú Déébè kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn, wọ́n mọ́kàn le, wọ́n sì pa dà sí ìlú Lísírà. Kí nìdí? Bíbélì sọ fún wa pé: “Wọ́n ń fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun, wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́.” Fojú inú wo bí Tímótì á ṣe tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe ń kọ́ àwọn Kristẹni yẹn pé ohun yòówù kí wọ́n jìyà rẹ̀ báyìí kò tó ohun tí wọn máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 14:20-22.
Tímótì ti fojú ara rẹ̀ rí i pé Pọ́ọ̀lù ń fi gbogbo ohun tó ń kọ́ wọn sílò, ó fara da ìpọ́njú kó báa lè wàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì. Torí náà, Tímótì mọ̀ pé tí òun bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, àwọn aráàlú Lísírà máa ṣe inúnibíni sí òun, bàbá òun náà sì máa ta ko òun. Ṣùgbọ́n, Tímótì kò gbà kí àwọn nǹkan yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a débi tí kò fi ní lè sin Ọlọ́run tó bó ṣe fẹ́. Lóde òní, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló fìwà jọ Tímótì. Àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára ni wọ́n máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn àwọn tó lè fún wọn ní ìṣírí kí ìgbàgbọ́ tiwọn náà lè lágbára. Wọn ò sì jẹ́ kí àtakò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn débi tí wọn ò fi ní lè sin Ọlọ́run tó bí wọ́n ṣe fẹ́!
‘ÀWỌN ARÁ RÒYÌN RẸ̀ DÁADÁA’
Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, nǹkan bí ọdún méjì sí mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù pa dà sí ìlú Lísírà. Wo bí ìdùnnú ṣe máa ṣubú lu ayọ̀ nílé àwọn Tímótì nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà dé sílé wọn. Àkókò ayọ̀ ló jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù alára. Ó fojú ara rẹ̀ rí bí èso òtítọ́ tó gbìn sílùú Lísírà ṣe ti dàgbà. Yùníìsì àti ìyá rẹ̀ Lọ́ìsì ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ láìsí ẹ̀tàn. Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ràn àwọn tó bá ní irú ìgbàgbọ́ yìí. (2 Tímótì 1:5) Tímótì wá ń kọ́ ní tiẹ̀?
Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé ìgbàgbọ́ Tímótì ti lágbára sí i ju ti ìgbà tó kọ́kọ́ wá sí ìlú Lísírà. Bíbélì sọ nípa Tímótì pé ‘àwọn ará ròyìn rẹ̀ dáadáa.’ Àmọ́ kì í ṣe àwọn ará Lísírà nìkan ló ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tó wà ní ìlú Íkóníónì tó jẹ́ nǹkan bí kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] sí ìlú Lísírà náà ròyìn Tímótì dáadáa. (Ìṣe 16:2) Kí ló mú káwọn ará ròyìn rẹ̀ dáadáa?
“Láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni ìyá Tímótì àti ìyá ìyá rẹ̀ ti ń kọ́ ọ ní “Ìwé Mímọ́.” Ara ohun tí wọ́n kọ́ ọ ni àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò fún àwọn ọ̀dọ́. (2 Tímótì 3:15) Ọ̀kan lára irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ni: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníwàásù 12:1) Ìgbà tí Tímótì di Kristẹni ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé e dáadáa. Ó rí i pé ọ̀nà kan tí òun lè gbà rántí Ẹlẹ́dàá òun ni pé kí òun wàásù ìhìn rere nípa Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Tímótì kọ́ bó ṣe máa borí ìtìjú, kó lè máa fìgboyà wàásù ìhìn rere nípa Jésù Kristi.
Àwọn ọkùnrin tó ń bójú tó ìjọ kíyè sí ìtẹ̀síwájú Tímótì. Kò sí àní-àní pé bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe lágbára àti bó ṣe ń fún àwọn ará ní ìṣírí wú wọn lórí gan-an. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé Jèhófà náà ń kíyè sí Tímótì. Ọlọ́run mú kí wọ́n sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa rẹ̀, ìyẹn àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kan bó ṣe máa ran ọ̀pọ̀ ìjọ lọ́wọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sí ìlú Lísírà, ó rí i pé Tímótì máa wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì táwọn ń ṣe. Àwọn ará ní Lísírà sì yọ̀ǹda pé kí Tímótì máa báwọn lọ. Wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé ọ̀dọ́kùnrin yìí, tó jẹ́ àmì pé wọ́n ti yàn án láti ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn fún Jèhófà Ọlọ́run.—1 Tímótì 1:18; 4:14.
Ó ṣeé ṣe kí ẹnu ya Tímótì sí àkànṣe iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fún un yìí àti bí àwọn ará ṣe fọkàn tán an. Ó sì múra tán láti bá Pọ́ọ̀lù lọ.b Kí ni bàbá Tímótì tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ṣe nígbà tó gbọ́ pé ọmọ rẹ̀ máa di míṣọ́nnárì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lóhùn tó fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ fayé rẹ̀ ṣe. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ìyá Tímótì àti ìyá ìyá rẹ̀? Ṣé inú wọn dùn sí àkànṣe iṣẹ́ ìsìn yìí, lẹ́sẹ̀ kan náà, ṣé wọ́n jáyà nípa ohun tó ṣeé ṣe kí ojú ọmọ wọn rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn náà? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ọrọ̀ ọmọ ni wọ́n ń ṣe.
Ohun tó dájú ni pé Tímótì bá Pọ́ọ̀lù lọ. Àárọ̀ ọjọ́ tá a ṣàpèjúwe níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni Tímótì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì pẹ̀lú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Tímótì ti fi ìlú Lísírà sílẹ̀ báyìí, bó ṣe ń gbé ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń jìnnà sí ilé láìmọ̀ ohun tójú rẹ̀ máa rí lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ kan gbáko, àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dé ìlú Íkóníónì. Níbẹ̀, Tímótì kíyè sí bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe ń fún àwọn ará ní àwọn ìtọ́ni tí ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù fi lélẹ̀. Bákan náà, ó rí bí wọ́n ń ṣe ń fún ìgbàgbọ́ àwọn ará tó wà ní ìlú Íkóníónì lókùn. (Ìṣe 16:4, 5) Bí Tímótì ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nìyẹn.
Lẹ́yìn táwọn míṣọ́nnárì yìí ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún máìlì gba àwọn ọ̀nà olókè ti Fíríjíà. Wọ́n kọ́kọ́ lọ sọ́nà àríwá àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yà bàrà sápá ìwọ̀ oòrùn. Ibikíbi tí ẹ̀mí mímọ̀ Ọlọ́run bá darí wọn sí ni wọ́n máa ń lọ, wọ́n dé Tíróásì, wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Makedóníà. (Ìṣe 16:6-12) Lákòókò yẹn, Pọ́ọ̀lù ti rí bí Tímótì ṣe wúlò tó. Ìdí nìyẹn tọ́kàn rẹ̀ fi bálẹ̀ láti fi Sílà àti Tímótì sílẹ̀ sí Bèróà. (Ìṣe 17:14) Kódà, ó tún rán Tímótì nìkan lọ sí Tẹsalóníkà. Níbẹ̀, Tímótì fi ohun tó kọ́ lára Sílà àti Pọ́ọ̀lù sílò, ó sì gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró.—1 Tẹsalóníkà 3:1-3.
Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.” (Fílípì 2:20) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni Pọ́ọ̀lù sọ. Tímótì ṣiṣẹ́ kára gan-an, ó tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn, kódà ó fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro tó dojú kọ, ó sì jẹ́ olóòótọ́. Àpẹẹrẹ àtàtà ni èyí jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ lóde òní! Ẹ má ṣe gbàgbé pé ọwọ́ yín ló wà tẹ́ ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn sọ dáadáa nípa yín. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ìwọ náà láǹfààní láti ṣe orúkọ rere fún ara rẹ tó o bá fi ti Jèhófà Ọlọ́run ṣáájú láyé rẹ tó o jẹ́ onínúrere, tó o sì tún ń bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn.
“SA GBOGBO IPÁ RẸ LÁTI WÁ SỌ́DỌ̀ MI”
Ó lé lọ́dún mẹ́rìnlá [14] gbáko tí Tímótì fi bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́. Òun àti Pọ́ọ̀lù jọ la ọ̀pọ̀ ewu kọjá lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n sì jọ gbádùn ayọ̀ tí iṣẹ́ náà ń mú wá. (2 Kọ́ríńtì 11:24-27) Ó tiẹ̀ nígbà kan tí wọ́n sọ Tímótì sẹ́wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìwàásù. (Hébérù 13:23) Òun náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tọkàntọkàn bíi ti Pọ́ọ̀lù. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé sí i pé: ‘Mo ń rántí omijé rẹ.’ (2 Tímótì 1:4) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, Tímótì kọ́ béèyàn ṣe ń “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún,” ìyẹn ni pé ó lẹ́mìí ìgbatẹnirò, ó máa ń fún àwọn míì ní ìṣírí, ó sì máa ń tù wọ́n nínú. (Róòmù 12:15) Ó yẹ kí àwa náà sapá láti ní ìwà àtàtà yìí.
Kò yà wá lẹ́nu pé Tímótì di alábòójútó tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Láfikún sí bíbẹ àwọn ìjọ wò kó lè gbé wọn ró, Pọ́ọ̀lù tún gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta míì fún un. Ó ní kó máa yan àwọn ọkùnrin tó bá tóótun láti jẹ́ alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.—1 Tímótì 5:22.
Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Tímótì gan-an, ó sì máa ń fún un ní ìmọ̀ràn bàbá sí ọmọ. Ó rọ Tímótì pé kó má ṣe fojú kékeré wo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní, èyí tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kó sì tún máa tẹ̀síwájú. (1 Tímótì 4:15, 16) Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé kó má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ tórí ó jẹ́ ọ̀dọ́. Ó tún sọ fún un pé kó má ṣe jẹ́ kí ìtìjú mú kó bẹ̀rù àtiṣe ohun tó tọ́. (1 Tímótì 1:3; 4:6, 7, 11, 12) Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ tún sọ ohun tó lè ṣe sí àìsàn rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ló ń yọ ọ́ lẹ́nu lóòrèkóòrè.—1 Tímótì 5:23.
Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ọjọ́ ikú òun ti ń sún mọ́lé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n dájọ́ ikú fún un. Ó wá kọ lẹ́tà àkọkẹ́yìn kan tí Ọlọ́run mí sí sí Tímótì. Nínú lẹ́tà náà, ó sọ ọ̀rọ̀ kan tó wọni lọ́kàn pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́.” (2 Tímótì 4:9) Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Tímótì gan-an débi tó fi pè é ní “ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 4:17) Ìdí nìyẹn tó fi fẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí wà lọ́dọ̀ rẹ̀ bí ọjọ́ ikú rẹ̀ ṣe ń sún mọ́lé! Ó máa dáa ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn rí mi bí ẹni tó lè tù wọ́n nínú nígbà ìṣòro?’
Ǹjẹ́ Tímótì dé ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù lásìkò? A ò lè sọ. Ohun tá a mọ̀ ni pé Tímótì sa gbogbo ipa rẹ̀ kó lè tu Pọ́ọ̀lù àti ọ̀pọ̀ àwọn míì nínú kò sì fún wọn ní ìṣírí. Ó ṣe ohun tó bá ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ mu, ìyẹn “Ẹni Tó Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” Ó sì fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lélẹ̀ fún tèwe tàgbà láti tẹ̀ lé.
a Wo àpilẹ̀kọ yìí “Ǹjẹ́ O Mọ̀?” nínú ìwé ìròyìn yìí.