Máa Fiyè Sí Ẹ̀kọ́ Rẹ Nígbà Gbogbo
“Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 TÍMÓTÌ 4:16.
1, 2. Èé ṣe táa fi ń fẹ́ àwọn olùkọ́ni onítara ní kánjúkánjú lónìí?
“Ẹ LỌ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Báa bá ronú lórí àṣẹ tí Jésù Kristi pa yìí, a óò rí i pé ó yẹ kí gbogbo Kristẹni sapá láti jẹ́ olùkọ́ni. À ń fẹ́ àwọn olùkọ́ni onítara láti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run kó tó pẹ́ jù. (Róòmù 13:11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (2 Tímótì 4:2) Èyí ń béèrè fún kíkọ́ni nínú àti lóde ìjọ. Ní ti gidi, iṣẹ́ kíkọ́ni tí a gbé lé wa lọ́wọ́ kò mọ sórí wíwulẹ̀ kéde iṣẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀nà ìkọ́ni tó gbéṣẹ́ ṣe pàtàkì bí a óò bá sọ àwọn olùfìfẹ́hàn di ọmọ ẹ̀yìn.
2 À ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Wọ́n ti rọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti àwọn ẹ̀kọ́ èké sáwọn èèyàn lágbárí. Ọ̀pọ̀ ló “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí,” tí wọ́n sì ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:18, 19) Àròdùn ti mú kí ọkàn àwọn kan gbọgbẹ́. Kódà, a ti ‘bó àwọn èèyàn láwọ, a sì ti fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Mátíù 9:36) Síbẹ̀síbẹ̀, nípa lílo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, a lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọndandan.
Àwọn Olùkọ́ni Nínú Ìjọ
3. (a) Kí ni iṣẹ́ kíkọ́ni tí Jésù fi rán wa wé mọ́? (b) Àwọn wo ní pàtàkì ló ni ẹrù iṣẹ́ kíkọ́ni nínú ìjọ?
3 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ń rí ìtọ́ni gbà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí àwọn ẹni tuntun bá ti ṣèrìbọmi, wọ́n ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ sí i láti lè “ta gbòǹgbò, kí [wọ́n] sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.” (Éfésù 3:17) Bí a ti ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù fi rán wa, tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, tí a sì ń darí àwọn ẹni tuntun sínú ètò àjọ Jèhófà, àwọn náà ń jàǹfààní láti inú ohun tí a ń kọ́ wọn nínú ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí Éfésù 4:11-13 ti wí, a ti yan àwọn kan láti máa sìn “gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́, láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró.” Nígbà mìíràn, ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn tún kan ṣíṣe tán láti “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra.” (2 Tímótì 4:2) Iṣẹ́ àwọn olùkọ́ni ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tó fi jẹ́ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì, àwọn olùkọ́ni ló mẹ́nu kàn tẹ̀ lé àwọn àpọ́sítélì àti wòlíì.—1 Kọ́ríńtì 12:28.
4. Báwo ni mímọ báa ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Hébérù 10:24, 25?
4 Òtítọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, tàbí alábòójútó. Ṣùgbọ́n, gbogbo wa ni a fún níṣìírí láti máa ru ara wa sókè “sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24, 25) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìpàdé wé mọ́ àwọn ìdáhùn táa ti múra sílẹ̀ dáadáa, táa fi tọkàntọkàn ṣe, tó lè gbéni ró, tó sì lè fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí. Àwọn akéde Ìjọba náà tí wọ́n jẹ́ ẹni ìrírí tún lè máa ‘ru àwọn èèyàn sí àwọn iṣẹ́ àtàtà’ nípa ṣíṣàjọpín ìmọ̀ àti ìrírí wọn pẹ̀lú àwọn ẹni tuntun nígbà tí wọ́n bá jọ ń ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ àti nígbà tí a kò bá tilẹ̀ sí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pàápàá, a lè gbin ìsọfúnni tó ṣeyebíye sí wọn lọ́kàn. Fún àpẹẹrẹ, a rọ àwọn obìnrin tó dàgbà dénú pé kí wọ́n jẹ́ “olùkọ́ni ní ohun rere.”—Títù 2:3.
A Yí Wọ́n Lérò Padà Láti Gbà Gbọ́
5, 6. (a) Báwo ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ṣe yàtọ̀ sí ìjọsìn èké? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?
5 Ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹ̀sìn èké, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń fẹ́ kí àwọn mẹ́ńbà wọn máa ṣe bíi dọ̀bọ̀sìyẹsà. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣe ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń fẹ́ fi àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́, tí ń nini lára, wé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, láìfẹ́ kí wọ́n rímú mí. (Lúùkù 11:46) Bẹ́ẹ̀ náà làwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ń ṣe.
6 Àmọ́ o, ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” tí a ń fi “agbára ìmọnúúrò” wa ṣe. (Róòmù 12:1) Ṣe ni a “yí” àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà “lérò padà láti gbà gbọ́.” (2 Tímótì 3:14) Nígbà mìíràn, ó lè pọndandan kí àwọn tí ń mú ipò iwájú gbé àwọn ìlànà àti ọ̀nà-ìgbàṣe-nǹkan kalẹ̀ kí gbogbo nǹkan lè máa lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n, dípò kí àwọn alàgbà máa wá ọ̀nà láti ṣe ìpinnu fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣe ni wọ́n ń kọ́ wọn “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Ọ̀nà pàtàkì táwọn alàgbà gbà ń ṣe èyí ni nípa fífi “ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ . . . àti ti ẹ̀kọ́ àtàtà” bọ́ ìjọ.—1 Tímótì 4:6.
Fífiyèsí Ẹ̀kọ́ Rẹ
7, 8. (a) Báwo ni àwọn tí kò ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ṣe lè tóótun láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́? (b) Kí ló fi hàn pé ìsapá ṣe pàtàkì bí a óò bá di olùkọ́ tó gbéṣẹ́?
7 Ṣùgbọ́n o, ẹ jẹ́ ká padà sórí àpapọ̀ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́. Ó ha ń béèrè fún òye iṣẹ́ kan pàtàkì, tàbí ìmọ̀ ìwé, tàbí agbára kan pàtàkì láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí? Kò fi dandan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní apá tó pọ̀ jù lọ, àwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ ló ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí kárí ayé. (1 Kọ́ríńtì 1:26-29) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Àwa ní ìṣúra yìí [iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà] nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe [ara àìpé], kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ìtẹ̀síwájú pípabanbarì tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé ti ní, ń jẹ́rìí sí agbára ẹ̀mí Jèhófà!
8 Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó gba ìsapá aláápọn láti di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Báwo gan-an ni èèyàn ṣe lè máa fiyè sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, yálà nínú tàbí lóde ìjọ? Ǹjẹ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń fi dandan béèrè pé kí a ní àwọn agbára ìṣe-nǹkan lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ tàbí àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan?
9. Kí ló ṣe pàtàkì ju àwọn ẹ̀bùn àbínibí?
9 Ó hàn gbangba pé Jésù lo ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú Ìwàásù olókìkí tó ṣe lórí Òkè. Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) A gbà pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ bíi Jésù. Síbẹ̀síbẹ̀, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà táa bá di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ká tó lè di olùkọ́ni tó gbéṣẹ́. Họ́wù, gẹ́gẹ́ bí Jóòbù 12:7 ti wí, kódà “àwọn ẹran agbéléjẹ̀” àti “àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá” pàápàá lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ bí wọn kò tilẹ̀ lè fọhùn! Ní àfikún sí àwọn ẹ̀bùn àbínibí àti òye tó ṣeé ṣe ká ní, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni “irú ẹni” táa jẹ́—irú ànímọ́ táa ní àti àwọn ìwà tẹ̀mí táa ti mú dàgbà, èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fara wé.—2 Pétérù 3:11; Lúùkù 6:40.
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
10. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
10 Olùkọ́ tí ń kọ́ni ní àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 2:21) Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀ lélẹ̀ nínú èyí. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Jésù tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ kan, tàbí sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ àyọkà láti inú nǹkan bí ìlàjì àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.a Mímọ̀ tó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú fara hàn gbangba nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, nígbà tí a rí i tó “jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, [tó] ń fetí sí wọn, [tó] sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” (Lúùkù 2:46) Nígbà tí Jésù dàgbà, ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa lọ sí sínágọ́gù, níbi tí wọ́n ti ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Lúùkù 4:16.
11. Ètò ẹ̀kọ́ kíkọ́ wo ló yẹ kí olùkọ́ni máa tẹ̀ lé?
11 O ha kúndùn kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí? Fífarabalẹ̀ kà á ni ọ̀nà tí “ìwọ yóò [fi] lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, [tí] ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:4, 5) Nítorí náà, kọ́ bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Gbìyànjú láti máa kà lára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. (Sáàmù 1:2) Sọ ọ́ dàṣà láti máa ka gbogbo ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní gbàrà tó bá ti dọ́wọ́ rẹ. Máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nínú àwọn ìpàdé ìjọ. Kọ́ báa ṣe ń ṣe ìwádìí àfẹ̀sọ̀ṣe. Bóo bá kọ́ láti ‘tọpasẹ̀ ohun gbogbo pẹ̀lú ìpéye,’ ìwọ yóò lè yẹra fún àbùmọ́ àti ẹ̀kọ́ tí kò péye nígbà tóo bá ń kọ́ni.—Lúùkù 1:3.
Ìfẹ́ àti Ọ̀wọ̀ fún Àwọn Táa Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
12. Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
12 Ànímọ́ pàtàkì mìíràn ni ìṣarasíhùwà tó bójú mu sí àwọn tí o ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn Farisí fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí ń fetí sí Jésù. Wọ́n sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Ṣùgbọ́n Jésù ní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nítorí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣùgbọ́n mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Jòhánù 15:15) Ohun tí èyí fi hàn ni bó ṣe yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ṣe iṣẹ́ ìkọ́ni wọn.
13. Kí ni ìmọ̀lára Pọ́ọ̀lù nípa àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?
13 Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kò ṣàìtúraká sí àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kò ṣe bí ẹni pé iṣẹ́ ajé lásán ló pa wọ́n pọ̀. Ó sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ lè ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nínú Kristi, dájúdájú, ẹ kò ní baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jésù, èmi ti di baba yín nípasẹ̀ ìhìn rere.” (1 Kọ́ríńtì 4:15) Nígbà mìíràn, Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ da omijé lójú nígbà tó ń fún àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní ìtọ́ni! (Ìṣe 20:31) Ó tún mú sùúrù fún wọn gan-an, ó sì fi inú rere àrà ọ̀tọ̀ hàn. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ fún àwọn ará Tẹsalóníkà pé: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.”—1 Tẹsalóníkà 2:7.
14. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì gan-an láti ní ọkàn ìfẹ́ sí àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ṣàpèjúwe.
14 Ǹjẹ́ o ń fara wé Jésù àti Pọ́ọ̀lù? Ìfẹ́ àtọkànwá táa bá ní sí àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yóò kájú àwọn ẹ̀bùn àbínibí tó ṣeé ṣe kí a máà ní. Ǹjẹ́ àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé a ní ìfẹ́ àtọkànwá sí àwọn alára? Ǹjẹ́ a ń wá àyè láti túbọ̀ mọ̀ wọ́n dunjú? Nígbà tí Kristẹni arábìnrin kan rí i pé ó ṣòro láti ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó fẹ̀sọ̀ bi í pé: “Ṣé kò sí o?” Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo tinú rẹ̀ jáde, ó to gbogbo ohun tó ń dà á láàmú, tó sì ń kó àníyàn bá a. Ìjíròrò onífẹ̀ẹ́ yẹn yọrí sí àkókò ìyípadà ńlá fún obìnrin náà. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àwọn ìrònú àti ọ̀rọ̀ ìtùnú pẹ̀lú ìṣírí tí a gbé ka Ìwé Mímọ́ jẹ́ ohun yiyẹ́. (Róòmù 15:4) Ṣùgbọ́n, ìkìlọ̀ kan rèé: Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè máa tẹ̀ síwájú gan-an ṣùgbọ́n síbẹ̀ kí ó ṣì ní àwọn ìwà kan tí kò bá ẹ̀sìn Kristẹni mu, tó yẹ kí ó jáwọ́ nínú ẹ̀. Nítorí náà, kò ní mọ́gbọ́n dání kí ìfararora tó pọ̀ jù wà pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn ààlà yíyẹ gbọ́dọ̀ wà láàárín Kristẹni àti irú ẹni bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
15. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
15 Ọ̀wọ̀ fún àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tún kan pé kí a má máa gbìyànjú láti máa darí ìgbésí ayé wọn. (1 Tẹsalóníkà 4:11) Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé a ń bá obìnrin kan kẹ́kọ̀ọ́, tó ń bá ọkùnrin kan gbé láìjẹ́ pé onítọ̀hún fẹ́ ẹ ṣaya. Bóyá wọ́n ti bímọ fúnra wọn. Nísinsìnyí tí obìnrin náà ti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, ó fẹ́ mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìlànà Jèhófà mu. (Hébérù 13:4) Ṣé kí ó fẹ́ ọkùnrin náà ni, àbí kí ó kó jáde kúrò nílé rẹ̀? Bóyá inú wa kò dùn sí pé kí ó fẹ́ ẹ, torí pé tó bá fẹ́ ọkùnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìfẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí, ó lè ṣàkóbá fún ìtẹ̀síwájú obìnrin náà lẹ́yìnwá ọ̀la. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, a lè máa ṣàníyàn nípa ire tàwọn ọmọ rẹ̀, ká sì wá ronú pé kò sí nǹkan tó dáa tó pé kí ó fẹ́ ọkùnrin náà. Bó ti wù kó rí, ó jẹ́ ìwà àìlọ́wọ̀ àti àìnífẹ̀ẹ́ láti ṣe àyọnusọ sí ọ̀ràn ìgbésí ayé akẹ́kọ̀ọ́ kan, ká sì gbìyànjú láti gbé èrò tara wa kà á lórí nínú irú ọ̀ràn báyìí. Ṣebí òun fúnra rẹ̀ ló máa forí fá ohunkóhun tó bá tìdí ìpinnu rẹ̀ yọ. Ǹjẹ́ kò ní sàn jù, láti kọ́ irú akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ láti lo “agbára ìwòye” tara rẹ̀, kí ó sì tìkára rẹ̀ pinnu ohun tó yẹ kó ṣe?—Hébérù 5:14.
16. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún agbo Ọlọ́run?
16 Ó ṣe pàtàkì ní ti gidi pé kí àwọn alàgbà ìjọ fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá agbo lò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Fílémónì, ó sọ pé: “Bí mo tilẹ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láti pa àṣẹ fún ọ láti ṣe ohun tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, kàkà bẹ́ẹ̀, mo ń gbà ọ́ níyànjú nítorí ìfẹ́.” (Fílémónì 8, 9) Nígbà mìíràn, àwọn ipò tí ń tánni ní sùúrù lè dìde nínú ìjọ. Ó tilẹ̀ lè di dandan láti má gba gbẹ̀rẹ́. Pọ́ọ̀lù rọ Títù pé kó “máa bá a nìṣó ní fífi ìbáwí tọ́ [àwọn tó ṣisẹ̀ gbé] sọ́nà pẹ̀lú ìmúnájanjan, kí wọ́n lè jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́.” (Títù 1:13) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ìjọ nígbà kankan. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.”—2 Tímótì 2:24; Sáàmù 141:3.
17. Àṣìṣe wo ni Mósè ṣe, kí sì ni àwọn alàgbà lè rí kọ́ láti inú èyí?
17 Àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ máa rán ara wọn létí nígbà gbogbo pé “agbo Ọlọ́run” làwọn ń bá lò. (1 Pétérù 5:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, sáà ráńpẹ́ kan wà tó gbàgbé kókó yìí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “mú ẹ̀mí rẹ̀ korò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.” (Sáàmù 106:33) Inú Ọlọ́run kò dùn rárá sí ohun yìí tí Mósè ṣe sí agbo Rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an lọ̀ràn náà ti wọ́ wá. (Númérì 20:2-12) Nígbà táwọn alàgbà bá dojú kọ irú ìpèníjà bẹ́ẹ̀ lónìí, ṣe ló yẹ kí wọ́n làkàkà láti fi ìjìnlẹ̀ òye àti inú rere kọ́ni, kí wọ́n sì fi tọ́ni sọ́nà. Àwọn arákùnrin wa máa ń hùwà padà lọ́nà tó dára jù lọ báa bá gba tiwọn rò, tí a sì hùwà sí wọn bí ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́, tí a kò kà wọ́n sí ẹni tí kò lè ṣàtúnṣe láé. Àwọn alàgbà ní láti ní ojú ìwòye rere tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ pé: “Àwa ní ìgbọ́kànlé nínú Olúwa nípa yín, pé ẹ ń ṣe àwọn ohun tí a pa láṣẹ, ẹ ó sì máa bá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.”—2 Tẹsalóníkà 3:4.
Ṣíṣe Gírí Láti Mọ Ìṣòro Wọn
18, 19. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe gírí láti mọ ìṣòro àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n, tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lóye? (b) Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn kókó ọ̀ràn kan kò yé?
18 Olùkọ́ tó gbéṣẹ́ ń múra tán láti yíwọ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí òye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ. (Fi wé Jòhánù 16:12.) Nínú àkàwé Jésù nípa àwọn tálẹ́ńtì, ọ̀gá náà fi àǹfààní “fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀.” (Mátíù 25:15) A lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ kan náà nígbà táa bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, ó máa ń wù wá ká tètè parí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín àkókò tó gùn mọ níwọ̀n. Ṣùgbọ́n, ó yẹ ká mọ̀ pé gbogbo èèyàn kọ́ ló lè kàwé dáadáa, kì í sì í ṣe gbogbo èèyàn ló tètè máa ń lóye ẹ̀kọ́ tuntun. Nítorí náà, ó gba ọgbọ́n láti mọ ìgbà tó yẹ ká ti orí kókó kan bọ́ sórí kókó mìíràn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ bí ó bá ṣòro fún ẹni táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti tètè lóye ohun tó ń kọ́. Ríran awọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe pàtàkì ju kíkárí ẹ̀kọ́ kan láàárín àkókò kan táa fojú bù.—Mátíù 13:51.
19 Bákan náà lọ̀ràn rí ní ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn kókó kan kò yé, àwọn kókó bíi Mẹ́talọ́kan tàbí àwọn àjọ̀dún ẹ̀sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ àwọn tí a ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, kì í sábà pọndandan láti lo àfikún àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ táa kó jọ láti inú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n a lè lò ó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bó bá hàn gbangba pé lílò ó yóò ṣàǹfààní. A ní láti lo òye kí a lè yẹra fún fífawọ́ aago akẹ́kọ̀ọ́ náà sẹ́yìn láìyẹ.
Jẹ́ Onítara!
20. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti fífi ìtara àti ìdánilójú hàn nínú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
20 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.” (Róòmù 12:11) Bẹ́ẹ̀ ni, yálà a ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé, tàbí à ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ìjọ, ọ̀yàyà àti ìtara ló yẹ ká máa fi ṣe é. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Tẹsalóníkà pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.” (1 Tẹsalóníkà 1:5) Nípa báyìí, ‘kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan ni Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n tún fún wọn ní ọkàn àwọn fúnra wọn pẹ̀lú.’—1 Tẹsalóníkà 2:8.
21. Báwo la ṣe lè máa fi ẹ̀mí ìtara ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa?
21 Ìtara àtọkànwá máa ń wá láti inú dídá tó dá wa lójú ṣáká pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa yóò fẹ́ gbọ́ ohun táa ní í sọ. Ká má ṣe fojú yẹpẹrẹ wo iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí láé. Ó dájú pé Ẹ́sírà akọ̀wé fiyè sí apá ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó jẹ mọ́ èyí. Ó “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ni . . . ní Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Ó yẹ kí àwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa àti ríronú síwá sẹ́yìn lórí ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fi ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú kún ọkàn wa. (Lúùkù 17:5) Ìtara wa lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mú ojúlówó ìfẹ́ dàgbà fún òtítọ́. Àmọ́ ṣá o, fífiyèsí ẹ̀kọ́ wa tún lè kan lílo àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ pàtó. Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e yóò sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára irú àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé náà, Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 1071, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Èé ṣe táa fi ń fẹ́ àwọn Kristẹni olùkọ́ni tó jáfáfá lónìí?
◻ Ètò ẹ̀kọ́ kíkọ́ wo la lè máa tẹ̀ lé?
◻ Èé ṣe tí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ fún àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fi ṣe pàtàkì?
◻ Báwo la ṣe lè dáhùn padà sí àìní àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
◻ Èé ṣe tí ìtara àti ìdánilójú fi ṣe pàtàkì gan-an nígbà táa bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn olùkọ́ rere alára pẹ̀lú jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ní ọkàn ìfẹ́ sí àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì