Máa Lo Ìjìnlẹ̀ Òye Àti Ìyíniléròpadà Nígbà Tóo Bá Ń Kọ́ni
“Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”—ÒWE 16:23.
1. Èé ṣe tí fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni kò fi mọ sórí wíwulẹ̀ gbé ìsọfúnni kalẹ̀?
GÓŃGÓ wa gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò mọ sí kìkì títànmọ́lẹ̀ sí èrò inú àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́dọ̀ mọ́lẹ̀ dé ọkàn-àyà wọn. (Éfésù 1:18) Fún ìdí yìí, kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe ọ̀ràn wíwulẹ̀ gbé ìsọfúnni kalẹ̀. Ìwé Òwe 16:23 sọ pé: “Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”
2. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti yíni lérò padà? (b) Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún gbogbo Kristẹni láti jẹ́ olùkọ́ni tó mọ báa ti ń yíni lérò padà?
2 Ó dájú pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìlànà yìí sílò nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Nígbà tó wà ní Kọ́ríńtì, “òun a máa sọ àsọyé nínú sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì, a sì máa yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò padà.” (Ìṣe 18:4) Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtọ́kasí kan ti wí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa tú sí “yí lérò padà” níhìn-ín túmọ̀ sí “mímú kí ìyípadà nínú èrò inú ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ agbára ìfèròwérò tàbí nípasẹ̀ gbígbé àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwà rere yẹ̀ wò.” Nípasẹ̀ àlàyé ọ̀rọ̀ tí ń yíni lọ́kàn padà, ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti mú kí àwọn èèyàn yí ọ̀nà ìrònú wọn gan-an padà. Ọgbọ́n tó ní láti yíni lérò padà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi ń bẹ̀rù rẹ̀. (Ìṣe 19:24-27) Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù kì í ṣe ìfihàn ọgbọ́n ènìyàn. Ó sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ọ̀rọ̀ mi àti ohun tí mo ń wàásù kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ń yíni lérò padà bí kò ṣe pẹ̀lú ìfihàn ẹ̀mí àti agbára, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa wà nínú ọgbọ́n ènìyàn, bí kò ṣe nínú agbára Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:4, 5) Níwọ̀n bí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà Ọlọ́run ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo Kristẹni, gbogbo wọn ló lè jẹ́ olùkọ́ni tó mọ báa ti ń yíni lérò padà. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo ni? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ mélòó kan.
Fetí Sílẹ̀ Dáadáa
3. Èé ṣe táa fi nílò ìjìnlẹ̀ òye nígbà táa bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́, báwo sì ni a ṣe lè dé inú ọkàn-àyà ẹni táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ jẹ mọ́ fífetísílẹ̀, kì í ṣe mímọ̀rọ̀ọ́sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Òwe 16:23 ti wí, láti lè yíni lérò padà, a gbọ́dọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye. Dájúdájú, Jésù ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn èèyàn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Jòhánù 2:25 sọ pé: “Òun tìkára rẹ̀ mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.” Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè mọ ohun tó wà nínú ọkàn-àyà àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? Ọ̀nà kan táa lè gbà mọ̀ ọ́n ni láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Jákọ́bù 1:19 sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” Lóòótọ́ ni, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló tètè máa ń sọ èrò wọn jáde. Bó bá dá àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ní tòótọ́, ó lè túbọ̀ rọrùn fún wọn láti sọ èrò wọn gan-an jáde. Àwọn ìbéèrè onínúure tó tún ń fòye hàn sábà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti dé inú ọkàn-àyà kí a sì “fa” irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ “jáde.”—Òwe 20:5.
4. Èé ṣe tó fi yẹ káwọn Kristẹni alàgbà máa tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn èèyàn?
4 Ó ṣe pàtàkì gidi gan-an pé kí àwọn Kristẹni alàgbà máa tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn èèyàn ná. Ní tòótọ́, àfi tí wọ́n bá ń kọ́kọ́ tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn èèyàn ni wọ́n tó lè “mọ bí ó ti yẹ kí [wọ́n máa] fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Ìwé Òwe 18:13 kìlọ̀ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n lọ́kàn rere, fún arábìnrin kan ní ìmọ̀ràn nípa ẹ̀mí ayé nítorí pé ó pa àwọn ìpàdé kan jẹ. Ó dun arábìnrin náà gan-an pé wọn kò bi òun léèrè ohun tó fà á tí òun kò fi wá sí ìpàdé ní àwọn àkókò yẹn. Àṣé kò pẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún un, ara rẹ̀ sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́fẹ ni. Àbí ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti kọ́kọ́ tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn èèyàn ká tó bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn nímọ̀ràn!
5. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè yanjú àwọn awuyewuye tó bá dìde láàárín àwọn ará?
5 Fún àwọn alàgbà, kíkọ́ni sábà máa ń wé mọ́ fífún àwọn ẹlòmíràn nímọ̀ràn. Ní apá ibí yìí, pẹ̀lú, ó ṣe pàtàkì láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Fífetísílẹ̀ pọndandan pàápàá jù lọ nígbà tí awuyewuye bá dìde láàárín àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni. Àfi bí àwọn alàgbà bá fetí sílẹ̀ nìkan ni wọ́n fi lè ṣàfarawé “Baba tí ń ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú.” (1 Pétérù 1:17) Àwọn èèyàn sábà máa ń gbaná jẹ nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ó sì yẹ kí alàgbà máa rántí ìmọ̀ràn inú ìwé Òwe 18:17 tó sọ pé: “Ẹnì kìíní nínú ẹjọ́ rẹ̀ jẹ́ olódodo; ọmọnìkejì rẹ̀ wọlé wá, dájúdájú, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.” Olùkọ́ tó gbéṣẹ́ yóò fetí sí tọ̀tún tòsì. Nípa gbígbàdúrà nígbà tí àwọn méjèèjì tí ọ̀ràn kàn wà níkàlẹ̀, alàgbà náà yóò fìdí ipò àlàáfíà múlẹ̀. (Jákọ́bù 3:18) Bó bá di pé ìbínú ru, ó lè dámọ̀ràn pé kí arákùnrin kọ̀ọ̀kan sọ ohun tó ń dùn ún fóun, dípò tí àwọn méjèèjì yóò fi máa sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn. Nípasẹ̀ àwọn ìbéèrè yíyẹ, alàgbà náà lè mú kí ọ̀ràn tí wọ́n ń fà mọ́ ara wọn lọ́wọ́ ṣe kedere. Lọ́pọ̀ ìgbà tí irú èyí máa ń wáyé, àìgbọ́ra-ẹni-yé ló sábà máa ń fa awuyewuye, kì í ṣe pé ẹnì kan ní inú burúkú sí ẹnì kejì. Ṣùgbọ́n bó bá ṣe pé wọ́n ti rú ìlànà Bíbélì, olùkọ́ onífẹ̀ẹ́ yóò wá fi ìjìnlẹ̀ òye fún wọn ní ìtọ́ni, lẹ́yìn tó ti gbọ́ ẹjọ́ tọ̀tún tòsì.
Ìjẹ́pàtàkì Mímú Nǹkan Rọrùn
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú kíkọ́ni lọ́nà tó rọrùn?
6 Mímú nǹkan rọrùn tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì mìíràn nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Lóòótọ́ la fẹ́ kí àwọn táa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì “lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn [òtítọ́] jẹ́.” (Éfésù 3:18) Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan wà tó gba ìpọkànpọ̀, tó sì sábà máa ń muni lómi. (Róòmù 11:33) Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún àwọn Gíríìkì, ó darí àfiyèsí sí ìhìn rírọrùn nípa ‘Kristi tí a kàn mọ́gi.’ (1 Kọ́ríńtì 2:1, 2) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù wàásù lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì fani mọ́ra. Ó lo èdè rírọrùn nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè. Síbẹ̀, ohun tó sọ kún fún àwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀ jù lọ, tí a kò gbọ́ lẹ́nu ẹnikẹ́ni mìíràn rí.—Mátíù, orí 5 sí 7.
7. Báwo la ṣe lè mú nǹkan rọrùn nígbà táa bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
7 Àwa pẹ̀lú lè mú nǹkan rọrùn nígbà táa bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́nà wo? Nípa dídarí àfiyèsí sí “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Nígbà táa bá ń ṣàlàyé àwọn kókó tó jinlẹ̀, ó yẹ ká máa gbìyànjú láti lo èdè tó ṣe kedere. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe kókó ló yẹ ká darí àfiyèsí sí, dípò gbígbìyànjú láti ka gbogbo ẹsẹ Bíbélì táa tọ́ka sí nínú ìtẹ̀jáde náà, ká sì jíròrò rẹ̀. Láti lè ṣe èyí, a ní láti múra sílẹ̀ dáadáa. A ní láti yẹra fún dídi gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni ru akẹ́kọ̀ọ́, kò sì yẹ ká jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì mú wa yà bàrá kúrò lórí kókó ọ̀rọ̀ gan-an. Bí akẹ́kọ̀ọ́ bá béèrè ìbéèrè tí kò tan mọ́ ẹ̀kọ́ táa ń kọ́ ní tààràtà, a lè fọgbọ́n dábàá pé ká jíròrò ìbéèrè náà táa bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tán.
Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
8. Báwo ni Jésù ṣe lo ìbéèrè lọ́nà gbígbéṣẹ́?
8 Ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wúlò ni bíbéèrè ìbéèrè tó gbéṣẹ́. Jésù Kristi lo ìbéèrè gan-an nínú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: “‘Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?’ Nígbà tí ó sọ pé: ‘Lọ́wọ́ àwọn àjèjì,’ Jésù wí fún un pé: ‘Ní ti gidi, nígbà náà, àwọn ọmọ bọ́ lọ́wọ́ owó orí.’” (Mátíù 17:24-26) Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ẹni táa ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì, kò pọndandan fún Jésù láti san owó orí tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n Jésù gbé òtítọ́ yìí kalẹ̀ nípasẹ̀ lílo ìbéèrè lọ́nà gbígbéṣẹ́. Jésù tipa báyìí ran Pétérù lọ́wọ́ láti dórí ìpinnu yíyẹ, tí ó gbé ka ìsọfúnni tó ní lọ́wọ́.
9. Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè nígbà táa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
9 A lè lo ìbéèrè lọ́nà rere nígbà táa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí akẹ́kọ̀ọ́ bá ṣi ìbéèrè kan dáhùn, a lè fẹ́ sọ ìdáhùn tó tọ́, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ yóò lè rántí ìsọfúnni náà ní ti gidi? Ó sábà máa ń sàn ká gbìyànjú láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ ìdáhùn tó tọ́ jáde nípa bíbéèrè ìbéèrè. Fún àpẹẹrẹ, bó bá ṣòro fún un láti lóye ìdí tó fi yẹ kó máa lo orúkọ Ọlọ́run, a lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ orúkọ rẹ ṣe pàtàkì sí ẹ? . . . Èé ṣe? . . . Báwo ni yóò ṣe rí lára rẹ tí ẹnì kan bá kọ̀ láti lo orúkọ rẹ? . . . Fífẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun kò ha bọ́gbọ́n mu bí?’
10. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè lo ìbéèrè nígbà tí wọ́n bá ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìbànújẹ́ bá?
10 Àwọn alàgbà tún lè lo ìbéèrè lọ́nà rere nígbà tí wọ́n bá ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo. Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ni ayé Sátánì ti mú ìbànújẹ́ bá, ayé ọ̀hún sì ti ṣe àwọn kan ṣúkaṣùka, débi pé wọ́n lè wá nímọ̀lára pé àwọn ti di ẹlẹ́gbin, kò sì sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ́. Alàgbà kan lè bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ fèrò wérò nípa sísọ pé: ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ka ara rẹ sí aláìmọ́, ojú wo ni Jèhófà fi ń wò ẹ́? Bí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ bá yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ kú, kí ó sì pèsè ìràpadà fún ẹ, ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ?’—Jòhánù 3:16.
11. Ète wo ni àwọn ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú ń ṣiṣẹ́ fún, báwo sì ni a ṣe lè lò wọ́n nígbà táa bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀?
11 Ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú tún jẹ́ ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wúlò. A kò retí kí àwọn olùgbọ́ dáhùn rẹ̀ síta ketekete, ṣùgbọ́n yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú lórí kókó náà. Àwọn wòlíì ìgbàanì sábà máa ń lo irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ láti mú kí àwọn olùgbọ́ wọn ronú jinlẹ̀. (Jeremáyà 18:14, 15) Jésù lo ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú lọ́nà gbígbéṣẹ́. (Mátíù 11:7-11) Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ gbéṣẹ́ gan-an nígbà táa bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀. Dípò wíwulẹ̀ sọ fún àwùjọ pé kí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn kí wọ́n lè mú inú Jèhófà dùn, ó lè túbọ̀ gbéṣẹ́ láti béèrè pé, ‘Bí a kò bá jẹ́ olùfọkànsìn, ǹjẹ́ inú Jèhófà yóò dùn?’
12. Kí ni ìjẹ́pàtàkì bíbéèrè ìbéèrè tí ń fi ojú ìwòye ẹni hàn?
12 Ìbéèrè tí ń fi ojú ìwòye ẹni hàn wúlò nígbà táa bá fẹ́ mọ̀ bóyá òótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan gba ohun tó ń kọ́ gbọ́. (Mátíù 16:13-16) Akẹ́kọ̀ọ́ kan lè dáhùn lọ́nà tó tọ́ pé àgbèrè lòdì. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí o kò tún bi í ní irú ìbéèrè bí, Ojú wo ni ìwọ alára fi ń wo ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run nípa ìwà rere? Ǹjẹ́ o nímọ̀lára pé ó ti le koko jù? Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì ní ti gidi yálà o tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run tàbí o kò tẹ̀ lé e?
Àpèjúwe Tó Dé Inú Ọkàn-Àyà
13, 14. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti ṣàpèjúwe nǹkan kan? (b) Èé ṣe tí àpèjúwe tó gbámúṣé fi máa ń gbéṣẹ́?
13 Ọ̀nà mìíràn táa lè gbà dé inú ọkàn-àyà àwọn olùgbọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni nípa lílo àpèjúwe tó gbéṣẹ́. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “àpèjúwe,” báa bá tú u ní olówuuru, ó túmọ̀ sí, “fífi sẹ́gbẹ̀ẹ́ tàbí mímú pa pọ̀.” Nígbà tí o bá lo àpèjúwe, ṣe ni o ń ṣàlàyé nǹkan kan nípa ‘fífi í sẹ́gbẹ̀ẹ́’ ohun kan tó jọ ọ́. Fún àpẹẹrẹ, Jésù béèrè pé: “Kí ni ohun tí a ó fi ìjọba Ọlọ́run wé, tàbí àpèjúwe wo ni a ó fi gbé e kalẹ̀?” Nínú ìdáhùn Jésù, ó mẹ́nu kan hóró músítádì tí wọ́n mọ̀ dunjú.—Máàkù 4:30-32.
14 Àwọn wòlíì Ọlọ́run lo ọ̀pọ̀ àpèjúwe tó múná dóko. Nígbà tí àwọn ará Ásíríà, tí Ọlọ́run lò láti fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wá bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà òǹrorò tó burú jáì, Aísáyà tú ìwà ìkùgbù wọn fó nípa lílo àpèjúwe yìí: “Àáké yóò ha gbé ara rẹ̀ lékè ẹni tí ń fi í gé nǹkan, tàbí kẹ̀, ayùn yóò ha gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tí ń mú kí ó lọ síwá-sẹ́yìn?” (Aísáyà 10:15) Nígbà tí Jésù pẹ̀lú ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, ó lo àpèjúwe rẹpẹtẹ. A tilẹ̀ ròyìn pé “kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe.” (Máàkù 4:34) Àpèjúwe tó gbámúṣé máa ń gbéṣẹ́ nítorí pé ó máa ń wọni lọ́kàn ṣinṣin. Ó máa ń jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ tètè tẹ́wọ́ gba ìsọfúnni tuntun láìjanpata, nípa fífiwé ohun tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀.
15, 16. Kí ni yóò mú kí àpèjúwe gbéṣẹ́ jù lọ? Mú àpẹẹrẹ wá.
15 Báwo la ṣe lè lo àwọn àpèjúwe tó dé inú ọkàn-àyà ní tòótọ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àpèjúwe gbọ́dọ̀ bá ohun táa ń ṣàlàyé mu. Bí ìfiwéra náà kò bá bára mu rárá, ṣe ni àpèjúwe náà yóò pín ọkàn àwọn olùgbọ́ níyà, dípò tí ì bá fi là wọ́n lóye. Nígbà kan rí, olùbánisọ̀rọ̀ kan tó ní èrò rere, gbìyànjú láti ṣàlàyé ìtẹríba àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró fún Jésù Kristi nípa fífi wọ́n wé ajá tí ń gbọ́rọ̀ síni lẹ́nu. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ irú ìfiwéra tí ń rẹni wálẹ̀ bẹ́ẹ̀ bójú mu rárá? Bíbélì gbé èrò kan náà yọ lọ́nà tó fani mọ́ra gan-an, tó sì gbéni níyì. Ó fi ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù wé “ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.”—Ìṣípayá 21:2.
16 Àpèjúwe máa ń gbéṣẹ́ jù lọ nígbà tó bá ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn. Àpèjúwe Nátánì nípa ọ̀dọ́ àgùntàn tí a pa, wọ Ọba Dáfídì lọ́kàn nítorí pé ó fẹ́ràn àgùntàn, olùṣọ́ àgùntàn kúkú ni nígbà èwe rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 16:11-13; 2 Sámúẹ́lì 12:1-7) Ká sọ pé àpèjúwe akọ màlúù ni, ó lè máà gbéṣẹ́ tó báyẹn rárá. Lọ́nà kan náà, àwọn àpèjúwe táa gbé ka kókó kan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, tàbí ìtàn kan tó ṣàjèjì sáwọn olùgbọ́, lè máà nítumọ̀ kankan létí wọn. Àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń rí lójoojúmọ́ ni Jésù máa ń lò gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà níbi gbogbo, àwọn nǹkan bí fìtílà, ẹyẹ ojú ọ̀run, àti òdòdó lílì tí ń bẹ ní pápá. (Mátíù 5:15, 16; 6:26, 28) Àwọn olùgbọ́ Jésù mọ nǹkan wọ̀nyẹn bí ẹní mowó.
17. (a) Kí ni a lè gbé àpèjúwe wa kà? (b) Báwo la ṣe mú àpèjúwe tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa bá ipò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa mu?
17 Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti lo àwọn àpèjúwe rírọrùn, ṣùgbọ́n tó gbéṣẹ́. Jẹ́ ẹni tí ń kíyè sí nǹkan. (Ìṣe 17:22, 23) Bóyá a lè gbé àpèjúwe wa ka àwọn ọmọ, tàbí ilé, tàbí iṣẹ́, tàbí ìgbòkègbodò àfipawọ́ ti olùgbọ́ wa. Tàbí kẹ̀, a lè lo ohun táa mọ̀ nípa akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan láti fi mú kí àwọn àpèjúwe tó wà nínú ìwé táa ń kẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àpèjúwe gbígbéṣẹ́ tí a lò nínú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ní orí kẹjọ, ìpínrọ̀ kẹrìnlá. Ìyẹn ni àpèjúwe òbí onífẹ̀ẹ́ tí àwọn aládùúgbò kan tan irọ́ kálẹ̀ nípa rẹ̀. Ó dára ká ronú nípa báa ṣe lè mú àpèjúwe yẹn bá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí òun alára jẹ́ òbí mu.
Kíka Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Jáfáfá
18. Èé ṣe tó fi yẹ ká làkàkà láti jẹ́ ẹni tí ń kàwé lọ́nà tó já geere?
18 Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni.” (1 Tímótì 4:13) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Bíbélì ni a gbé ẹ̀kọ́ wa kà, yóò ṣàǹfààní báa bá lè kà á lọ́nà tó já geere. Àwọn ọmọ Léfì láǹfààní kíka Òfin Mósè sí etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí wọ́n ti ń kà á, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ń kọ́ wọn lẹ́nu, àbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kà á tilẹ̀ ń mú oorun kunni? Rárá o, Bíbélì sọ nínú Nehemáyà 8:8 pé: “Wọ́n sì ń bá a lọ láti ka ìwé náà sókè, láti inú òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.”
19. Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀nà táa gbà ń ka Ìwé Mímọ́ sunwọ̀n sí i?
19 Àwọn ọkùnrin Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ máa ń ní ìṣòro tó bá dọ̀ràn ìwé kíkà. Báwo ni wọ́n ṣe lè túbọ̀ kàwé lọ́nà tó sunwọ̀n sí i? Nípa ṣíṣe ìfidánrawò. Bẹ́ẹ̀ ni, nípa kíkàwé sókè léraléra títí wọn yóò fi lè kà á lọ́nà tó já geere. Bí àwọn kásẹ́ẹ̀tì táa ka Bíbélì sínú rẹ̀ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó lédè rẹ, ó dára láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí òǹkàwé náà tẹnu mọ́ àti bó ṣe ń yí ohùn padà, ó sì dára láti ṣàkíyèsí bó ṣe ń pe àwọn orúkọ àti ọ̀rọ̀ tó ṣàjèjì. Àwọn tó ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè wọn pẹ̀lú lè jàǹfààní láti inú ètò táa ṣe láti mú kí ọ̀rọ̀ rọrùn-ún pè.a Báa bá ń ṣe ìfidánrawò, kódà àwọn orúkọ bí Maheri-ṣalali-háṣí-básì yóò ṣeé pè.—Aísáyà 8:1.
20. Báwo la ṣe lè ‘máa fiyè sí ẹ̀kọ́ wa’?
20 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Jèhófà, ẹ wo àǹfààní ńlá táa ní, pé a ń lò wá gẹ́gẹ́ bí olùkọ́! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù wa fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ wa. Ǹjẹ́ kí a ‘máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wa.’ (1 Tímótì 4:16) A lè jẹ́ olùkọ́ àtàtà nípa fífetísílẹ̀ dáadáa, nípa mímú kí nǹkan rọrùn, nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè tó fi ìjìnlẹ̀ òye hàn, nípa lílo àwọn àpèjúwe gbígbéṣẹ́, àti nípa kíka ìwé mímọ́ lọ́nà jíjáfáfá. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa jàǹfààní láti inú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, torí pé èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́” lẹ́kọ̀ọ́. (Aísáyà 50:4) Nípa lílo gbogbo irinṣẹ́ táa pèsè fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, títí kan àwọn ìwé pẹlẹbẹ, kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́, àti fídíò, a lè mọ báa ti ń lo ìjìnlẹ̀ òye àti ìyíniléròpadà nígbà tí a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A fàmì sórí àwọn fáwẹ̀lì inú ọ̀rọ̀ àti orúkọ lọ́nà tó tọ́. Àwọn àmì wọ̀nyí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ìgbà tó yẹ ká fohùn òkè tàbí ohùn ìsàlẹ̀ pe ọ̀rọ̀. Àmọ́ ṣá o, a kò fàmì kankan sórí ohùn àárín. Fún ìdí yìí, bí a kò bá fàmì sórí fáwẹ̀lì kan, á jẹ́ pé ohùn àárín la ó fi pè é.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Báwo ní fífetísílẹ̀ dáadáa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa?
◻ Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù àti Jésù nínú kíkọ́ni lọ́nà tó rọrùn?
◻ Irú àwọn ìbéèrè wo la lè lò táa bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
◻ Irú àwọn àpèjúwe wo ló gbéṣẹ́ jù lọ?
◻ Báwo la ṣe lè túbọ̀ jáfáfá sí i nínú ìwé kíkà ní gbangba?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Olùkọ́ rere máa ń fetí sílẹ̀ kí ó lè ní ìjìnlẹ̀ òye
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ohun táwọn èèyàn ń rí lójoojúmọ́ ayé ni Jésù máa ń lò gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe