Orí Kọkànlá
‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’
1. (a) Èé ṣe tí Jésù fi rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọn máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
NÍ OHUN tó lé ní ẹgbàá dín lọ́gọ́rùn-ún [1,900] ọdún sẹ́yìn báyìí, nínú ìjíròrò kan ní Gálílì, Jésù rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” Àmọ́ kí ló fà á tí ọ̀rọ̀ fi di kánjúkánjú bẹ́ẹ̀? Ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ò ní í kọjá ni lẹ́yìn ìgbà yẹn kí Kristi tóó gba agbára Ìjọba? Òótọ́ ni, àmọ́ Ìjọba Mèsáyà yìí ni Jèhófà máa lò láti dá ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣàkóso láre àti láti mú ète kíkọyọyọ tó ní fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Ipò àkọ́kọ́ ni ẹnikẹ́ni tó bá mọrírì àwọn nǹkan yìí máa fi Ìjọba náà sí nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, mélòómélòó wáá ni lọ́jọ́ òní, ìyẹn ní báyìí tí Kristi ti di Ọba. Nítorí náà, ìbéèrè tó yọjú ni pé, Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mò ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́?—Mátíù 6:33.
2. Kí làwọn èèyàn lápapọ̀ ń fi taratara lé?
2 Ní tòótọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn káàkiri ayé ló ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ lóde òní. Wọ́n ń fi hàn pé àwọn gbárùkù ti ìṣàkóso Ìjọba náà nípa gbígbé gbogbo ìgbésí ayé wọn karí ṣíṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, níwọ̀n bó ti jẹ́ òun ni wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún. Ní ìdàkejì, wíwá ohun ìní tí ara kiri ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú aráyé gbájú mọ́. Owó àtàwọn nǹkan towó lè rà, títí kan owó tí wọ́n máa fi gbádùn làwọn èèyàn ń lé kiri. Wọ́n sì tún lè máa sá sókè sódò pé kí iṣẹ́ wọn lè lọ síwájú. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé nǹkan tara wọn, àti ìgbádùn ló jẹ wọ́n lógún. Ipò kejì ni wọ́n sì fi Ọlọ́run sí, tí wọ́n bá tiẹ̀ nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ rárá.—Mátíù 6:31, 32.
3. (a) Irú ìṣúra wo ni Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wá, fún ìdí wo sì ni? (b) Èé ṣe tí kò fi sí ìdí láti máa ṣàníyàn àṣejù nípa àwọn ohun ìní tara?
3 Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé,” níwọ̀n bí kò ti sí ọ̀kankan nínú àwọn nǹkan ìní yẹn tó máa wà títí ayé. “Kàkà bẹ́ẹ̀” ó sọ pé, “ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run” nípa sísin Jèhófà. Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn jẹ́ kí ‘ojú wọn mú ọ̀nà kan’ nípa dídarí àfiyèsí wọn àti okun wọn sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa rí àwọn ohun tí ara nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé? Jésù gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn.” Ó darí àfiyèsí wọn sí àwọn ẹyẹ pé Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó nítorí pé Ọlọ́run ń fi aṣọ wọ̀ wọ́n. Ǹjẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá kò wá ní láárí ju èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ? Jésù wá sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:19-34) Ǹjẹ́ ìṣe rẹ fi hàn pé o gba ọ̀rọ̀ yìí gbọ́?
Má Ṣe Fún Òtítọ́ Ìjọba Náà Pa
4. Tí ẹnì kan bá ka àwọn nǹkan ìní tara sí pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ, kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀?
4 Ó bọ́gbọ́n mu láti ṣàníyàn nípa bí èèyàn ṣe máa rí ohun tí ó tó láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àti ti ìdílé rẹ̀. Àmọ́ tẹ́nì kan bá ń ṣàníyàn kọjá bó ṣe yẹ nípa ohun ìní tara, àbájáde rẹ̀ á burú jáì. Kódà bó tiẹ̀ ń sọ ọ́ lẹ́nu pé òún nígbàgbọ́ nínú Ìjọba náà, tó bá jẹ́ pé nǹkan mìíràn ló gbà á lọ́kàn, òtítọ́ Ìjọba á di èyí tá a fún pa. (Mátíù 13:18-22) Bí àpẹẹrẹ, ní àkókò kan, ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ alákòóso tó sì tún jẹ́ ọlọ́rọ̀ béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ó ń gbé ìgbé ayé rere ó sì ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn, àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan ìní rẹ̀ kọjá ààlà. Kò lè yááfì wọn láti wáá di ọmọlẹ́yìn Kristi. Bó ṣe pàdánù àǹfààní tí ì bá ní láti wà pẹ̀lú Kristi ní Ìjọba ọ̀run nìyẹn. Àkókò náà ni Jésù sọ gbólóhùn náà pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”—Máàkù 10:17-23.
5. (a) Àwọn ohun wo ni Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó jẹ́ kí ó tẹ́ òun lọ́rùn, èé sì ti ṣe? (b) Báwo ni Sátánì ṣe ń lo “ìfẹ́ owó” bí ìdẹkùn tí ń pani run?
5 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì, tó ń gbé ní ìlú Éfésù tó jẹ́ ìlú aláásìkí àti ibùdó ìṣòwò nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù rán an létí pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” Kò sóhun tó burú nínú ṣíṣiṣẹ́ láti pèsè “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ” fún ara ẹni àti ìdílé ẹni. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” Ọlọ́gbọ́n àyínìke ni Sátánì. Níbẹ̀rẹ̀, ó lè máa lo àwọn ọ̀nà kéékèèké láti tan ẹnì kan jẹ. Tó bá yá, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ohun tó tóbi wá, bóyá kí àǹfààní láti ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ yọjú tàbí kí iṣẹ́ kan tó máa mú owó rẹpẹtẹ wá yọjú, kó sì wá lọ jẹ́ èyí táá máa gba àwọn àkókò tí ẹni náà ti ń lò tẹ́lẹ̀ fún àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ́wọ́ rẹ̀. Láìjẹ́ pé a bá wà lójúfò, “ìfẹ́ owó” lè fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, tí wọ́n ní í ṣe pẹ̀lú ire Ìjọba náà pa nínú wa. Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:7-10.
6. (a) Láti yẹra fún dídi ẹni tá a fi ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì mú, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Ìgbọ́kànlé wo la lè ní, kódà pẹ̀lú bí ipò ìṣúnná owó ayé ṣe rí lónìí?
6 Nítorí ojúlówó ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní fún Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni arákùnrin rẹ̀, ó rọ̀ ọ́ pé: “Sá fún nǹkan wọ̀nyí” kí o sì “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:11, 12) Akitiyan ńlá ló ń béèrè bí a kò bà ní í di ẹni tí ìgbésí ayé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì táwọn èèyàn tó yí wa ká ń gbé, kó sí lórí. Àmọ́ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe níbàámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa, Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Láìka bí owó ọjà ṣe lè lọ sókè tó tàbí kí iṣẹ́ wọ́n bí ojú tó, yóò ri i dájú pé àwọn nǹkan tá a nílò kò wọ́n wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’ Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’” (Hébérù 13:5, 6) Ọba Dáfídì náà sì tún kọ̀wé pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”—Sáàmù 37:25.
Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ìjímìjí Pèsè Àwòkọ́ṣe
7. Ìtọ́ni wo nípa ìwàásù ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìdí wo ni èyí sì fi yẹ bẹ́ẹ̀?
7 Lẹ́yìn tí Jésù ti fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n nílò, ó rán wọn jáde ní Ísírẹ́lì láti lọ wàásù ìhìn rere náà, ó sì sọ pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” Ìhìn tí ń múni láyọ̀ gbáà nìyẹn mà jẹ́ o! Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba náà, wà láàárín wọn níbẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn àpọ́sítélì ti fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run pátápátá, Jésù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀, pé Ọlọ́run á bójú tó wọn. Nítorí náà ó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà, yálà ọ̀pá tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ, tàbí búrẹ́dì tàbí owó fàdákà; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì. Ṣùgbọ́n ibi yòówù tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ dúró síbẹ̀, kí ẹ sì lọ láti ibẹ̀.” (Mátíù 10:5-10; Lúùkù 9:1-6) Jèhófà á rí sí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹgbẹ́ wọn, tí títọ́jú àlejò jẹ́ àṣà wọn á pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn.
8. (a) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, kí nìdí tó fi fún àwọn àpọ́sítélì ní ìtọ́ni tuntun nípa iṣẹ́ ìwàásù? (b) Kí ló ṣì gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun àkọ́kọ́ síbẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?
8 Lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì òun mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, abẹ́ ipò tó yàtọ̀ ni wọ́n á ti máa wàásù. Nítorí àtakò táwọn aláṣẹ máa gbé dìde sí iṣẹ́ ìwàásù wọn, wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ rí ẹni ṣe wọ́n lálejò mọ́ ní Ísírẹ́lì. Yàtọ̀ síyẹn, láìpẹ́, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà lọ sí ilẹ̀ àwọn Kèfèrí. Nísinsìnyí, wọ́n ní láti mú “àpò” àti “àsùnwọ̀n oúnjẹ” dání. Síbẹ̀, wíwá Ìjọba Jèhófà lákọ̀ọ́kọ́ àti òdodo rẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbájú mọ́, kí wọ́n sì fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run yóò bù kún àwọn ìsapá wọn láti rí oúnjẹ àti aṣọ tí wọ́n nílò.—Lúùkù 22:35-37.
9. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ bó ti ń bójú tó àwọn ohun tó nílò nípa tara, ìmọ̀ràn wo ló sì fúnni lórí ọ̀ràn yìí?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára gan-an ní fífi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni Pọ́ọ̀lù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. (Ìṣe 20:24, 25) Nígbà tó lọ sí àgbègbè kan láti lọ wàásù, fúnra rẹ̀ ló gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ó tiẹ̀ ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa pàápàá. Kò retí pé kí àwọn mìíràn máa bá òun gbọ́ bùkátà ara òun. (Ìṣe 18:1-4; 1 Tẹsalóníkà 2:9) Síbẹ̀, ó máa ń fi ìmọrírì hàn nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá gbà á lálejò tí wọ́n sì fún un ní ẹ̀bùn láti fí ìfẹ́ wọn hàn lọ́nà yìí. (Ìṣe 16:15, 34; Fílípì 4:15-17) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti má ṣe pa ojúṣe wọn nínú ìdílé tì nítorí pé wọ́n ń wàásù, kàkà bẹ́ẹ̀ kí wọ́n rí i pé wọ́n ń gbé onírúurú ẹrù iṣẹ́ wọn bó ṣe yẹ. Ó fún wọn nímọ̀ràn láti ṣiṣẹ́, láti nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn, kí wọ́n sì máa ṣàjọpín ohun ìní wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Éfésù 4:28; 2 Tẹsalóníkà 3:7-12) Ó rọ̀ wọ́n pé Ọlọ́run ni kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kí wọ́n má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ohun ìní tara, kí wọ́n sì máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó fi hàn pé lóòótọ́ ni wọ́n lóye àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, èyí túmọ̀ sí wíwá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.—Fílípì 1:9-11.
Fi Ìjọba Náà Sí Ipò Àkọ́kọ́ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ
10. Kí ló túmọ̀ sí láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?
10 Báwo ni àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe ń nípìn-ín nínú sísọ ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn tó? Lọ́nà kan, ìyẹn sinmi lórí ipò wa àti bí ìmọrírì tá a ní fún un bá ṣe pọ̀ tó. Rántí pé Jésù kò sọ pé, ‘Ẹ máa wá Ìjọba náà nígbà tí ọwọ́ yín bá dilẹ̀.’ Nítorí pé ó mọ ìjẹ́pàtàkì Ìjọba náà, ó sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ pé: “Ẹ máa wá ìjọba rẹ̀ nígbà gbogbo.” (Lúùkù 12:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló di dandan fún láti gbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa, bí a bá nígbàgbọ́, iṣẹ́ Ìjọba náà tí Ọlọ́run ti gbé lé wa lọ́wọ́ ló máa ṣe kókó jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Lẹ́sẹ̀ kan náà, àá tún ṣe ojúṣe wa nínú ìdílé.—1 Tímótì 5:8.
11. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé kì í ṣe gbogbo wa la máa lè ṣe iye kan náà nínú títan ìhìn Ìjọba náà kálẹ̀? (b) Àwọn kókó wo ló ń pinnu bí ẹnì kan ṣe lè ṣe tó?
11 Ó ṣeé ṣe fún àwọn kan nínú wa láti lo àkókò ju àwọn mìíràn lọ nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Àmọ́ nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa oríṣiríṣi irú erùpẹ̀ tó wà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ọkàn wọn bá dà bí ilẹ̀ rere yóò so èso. Báwo ni èso tí wọ́n máa so á ṣe pọ̀ tó? Ipò kálukú yàtọ̀. Ọjọ́ ogbó, ìlera àti ẹrù iṣẹ́ ìdílé wà lára àwọn kókó tá a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò. Síbẹ̀, bí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ní ojúlówó ìmọrírì fún Ìjọba náà, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe.—Mátíù 13:23.
12. Àwọn góńgó tẹ̀mí gbígbámúṣé wo ni a rọ àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì láti gbé yẹ̀ wò?
12 Ó dára ká ní góńgó kan tá à ń lépa lọ́kàn, èyí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ipa tí à ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ìjọba náà pọ̀ sí i. Ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ ronú dáadáa lórí àpẹẹrẹ títayọ ti Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni ọ̀dọ́ onítara. (Fílípì 2:19-22) Kí ló tún lè dára ju pé kí wọ́n wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún bí wọ́n bá ti ń parí ilé ẹ̀kọ́ wọn. Àwọn tó ti dàgbà náà á jàǹfààní nípa gbígbé àwọn góńgó tẹ̀mí tó gbámúṣé kalẹ̀.
13. (a) Ta ló ń pinnu ohun tí àwa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà? (b) Tá a bá ń fi tòótọ́tòótọ́ wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀rí kí là ń fi hàn?
13 Dípò tá a ó fi máa ṣàríwísí àwọn tá a rò pé ó yẹ kí wọ́n ṣì lè ṣe sí i, ńṣe ló yẹ kí ìgbàgbọ́ sún wa láti ṣíṣẹ lórí bí àwa fúnra wa ṣe lè sunwọ̀n sí i, kó lè ṣeé ṣe fún wa láti sin Ọlọ́run ní kíkún dé àyè ti ipò tiwa fúnra wa bá yọ̀ǹda. (Róòmù 14:10-12; Gálátíà 6:4, 5) Gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ti fi hàn, Sátánì jiyàn pé ohun tó ṣe pàtàkì sí wa jù lọ ni àwọn ohun ìní wa, ìtura wa àti bá a ṣe máa wà lálàáfíà àti pé torí ohun tá a máa rí gbà la ṣe ń sin Ọlọ́run. Àmọ́ bá a bá ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, ńṣe là ń kópa nínú fífi hàn pé òpùrọ́ pátápátá ni Èṣù. À ń fi ẹ̀rí hàn pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni ohun tó ṣáájú nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà náà, nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, pé a dúró ti ipò rẹ̀ gbágbáágbá gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, a sì tún ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa.—Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5; Òwe 27:11.
14. (a) Kí nìdí tí níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fi ṣàǹfààní? (b) Báwo ni ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá tó?
14 Níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ nǹkan. Jèhófà fúnra rẹ̀ ní “àkókò àyànkalẹ̀” láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. (Ẹ́kísódù 9:5; Máàkù 1:15) Tó bá ṣeé ṣe, ó dára láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lẹ́ẹ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láwọn àkókò tá a ti yàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yíká ayé ti forúkọ sílẹ̀ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, wọ́n sì ń lo nǹkan bíi wákàtí méjì lójúmọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún mìíràn lára wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, tí wọ́n sì ń lo nǹkan bíi wákàtí méjì àtààbọ̀ lójúmọ́ láti polongo ìhìn Ìjọba náà. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe àtàwọn míṣọ́nnárì tiẹ̀ ń lo àkókò tó jùyẹn lọ nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. A tún lè wá àwọn àǹfààní láti sọ ìrètí Ìjọba náà lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣe tán láti gbọ́. (Jòhánù 4:7-15) Ohun tó yẹ kó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa ni láti kópa nínú iṣẹ́ yẹn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ibi tí agbára wa bá lè ṣe é dé, nítorí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14; Éfésù 5:15-17.
15. Nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí ló mú ọ gbà pé ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:58 bọ́ sákòókò?
15 Pẹ̀lú ìṣọ̀kan, ní apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, láìka orílẹ̀-èdè yòówù kí wọ́n máa gbé sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa nínú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí. Wọ́n ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí náà sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Nígbà tí Jésù sọ pé ká máa “wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́,” kí ló ń tọ́ka sí pé ó yẹ ká fi sí ipò kejì?
• Ojú ìwòye wo ló yẹ ká ní nípa gbígbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa? Irú ìrànwọ́ wo ni Ọlọ́run máa ṣe fún wa?
• Inú àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà wo la ti lè kópa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 107]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ń wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè, kí òpin tóó dé