Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìtọ́ni Ọlọrun
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè-ńlá Oluwa . . . , òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwà óò sì máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀.”—MIKA 4:2.
1. Gẹ́gẹ́ bí Mika ti sọ, kí ni Ọlọrun yóò ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
MIKA wòlíì Ọlọrun sọtẹ́lẹ̀ pé ní “ọjọ́ ìkẹyìn,” àkókò wa, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò fi aápọn wá Ọlọrun, láti jọ́sìn rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí yóò fún ẹnìkínní kejì níṣìírí pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè-ńlá Oluwa . . . , òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa ó sì máa rìn ní ipa-ọ̀nà rẹ̀.”—Mika 4:1, 2.
2, 3. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Paulu nípa jíjẹ́ tí àwọn ènìyàn jẹ́ olùfẹ́ owó ṣe ń ní ìmúṣẹ lónìí?
2 Ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nínú 2 Timoteu 3:1-5 lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ìyọrísí jíjẹ́ ẹni tí Ọlọrun fún ní ìtọ́ni ní àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn.” Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ àwọn ìbùkún tí ń dé bá àwọn tí wọ́n fi ìkìlọ̀ Paulu sọ́kàn láti máṣe jẹ́ “olùfẹ́ ti araawọn.” Paulu fikún-un pé ní àkókò wa àwọn ènìyàn yóò tún jẹ́ “olùfẹ́ owó.”
3 Ẹnìkan kò nílò oyè ilé-ẹ̀kọ́ gíga nínú ìtàn òde-òní láti mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ti bá àwọn àkókò wa mu tó. Ìwọ kò ha ti gbọ́ nípa àwọn ayánilówódókòwò àti àwọn olórí àjọ ilé-iṣẹ́ tí gbígba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ owó lọ́dọọdún kò tẹ́lọ́rùn? Àwọn olùfẹ́ owó wọ̀nyí ń fẹ́ púpọ̀ síi, àní lọ́nà tí kò bófinmu pàápàá. Ọ̀rọ̀ Paulu tún bá ọ̀pọ̀ mu lónìí, tí ó jẹ́ pé bí wọn kò tilẹ̀ lọ́rọ̀, wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò, wọn kò fìgbàkan nítẹ̀ẹ́lọ́rùn rí. Ìwọ lè mọ ọ̀pọ̀ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní agbègbè rẹ.
4-6. Báwo ni Bibeli ṣe ran àwọn Kristian lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi olùfẹ́ owó?
4 Ohun tí Paulu mẹ́nukàn ha wulẹ̀ jẹ́ apá aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀ nínú ìwà ẹ̀dá ènìyàn bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ bí a bá fi dá Òǹṣèwé Bibeli, ẹni tí ó ti sọ òtítọ́ yìí tipẹ́tipẹ́ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ìbìnújẹ́ púpọ̀ gún araawọn ní ọ̀kọ̀.” Ṣàkíyèsí pé, Ọlọrun kò sọ pé, ‘Owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo.’ Ó sọ pé “ìfẹ́ owó” ni.—1 Timoteu 6:10.
5 Ó dùnmọ́ni pé, àyíká ọ̀rọ̀ Paulu yẹn gbà pé àwọn Kristian rere kan ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, yálà wọ́n jogún ọ̀rọ̀ tàbí wọn ṣiṣẹ́ fún un. (1 Timoteu 6:17) Ó níláti hàn kedere, nígbà náà, pé ohun yòówù kí ipò ìdúró wa jẹ́ níti ìṣúná owó, Bibeli kìlọ̀ fún wa nípa ewu dídi olùfẹ́ owó. Bibeli ha fúnni ní ìtọ́ni èyíkéyìí síwájú síi nípa yíyẹra fún àléébù bíbaninínújẹ́ tí ó sì wọ́pọ̀ yìí bí? Dájúdájú ó ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú Ìwàásù Jesu Lórí Òkè. Ọgbọ́n rẹ̀ lókìkí kárí ayé. Fún àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ohun tí Jesu sọ nínú Matteu 6:26-33.
6 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Luku 12:15-21, Jesu sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí kò dẹ́kun ìgbìyànjú láti kó ọrọ̀ púpọ̀ síi jọ ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ìwàláàyè rẹ̀. Kí ni kókó ọ̀rọ̀ Jesu? Ó sọ pé: “Kí ẹ sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí-ayé ènìyàn kìí dúró nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.” Papọ̀ pẹ̀lú fífúnni ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, Bibeli dẹ́bi fún ìwà ọ̀lẹ tí ó sì tẹnumọ́ ìníyelórí iṣẹ́ aláìlábòsí. (1 Tessalonika 4:11, 12) Óò, àwọn kan lè ṣàtakò pé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kò ṣe é lò ní àwọn àkókò wa—ṣùgbọ́n wọn ṣe é lò, wọ́n sì gbéṣẹ́.
A fún Wọn Ní Ìtọ́ni Wọ́n Sì Jàǹfààní
7. Ìdí wo ni a ní fún ìgbẹ́kẹ̀lé pé a lè lo ìmọ̀ràn Bibeli nípa ọrọ̀ lọ́nà yíyọrísírere?
7 Ní orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìwọ lè rí àwọn àpẹẹrẹ gidi nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin nínú onírúurú ìpele ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ti ètò ọrọ̀-ajé tí wọ́n ti lo ìlànà àtọ̀runwá náà nípa owó. Wọ́n ti ṣe araawọn àti ìdílé wọn láǹfààní, àní bí àwọn ará ìta ti lè ríi. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìwé náà Religious Movements in Contemporary America láti ọwọ́ òǹṣèwé fún Yunifásítì Princeton, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn kan kọ̀wé pé: “Nínú àwọn ìtẹ̀jáde àti àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé inú ìjọ [àwọn Ẹlẹ́rìí] a ń rán wọn létí pé wọn kò gbáralé àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ titun, aṣọ olówó iyebíye, tàbí gbígbé ìgbésí-ayé onínàákúnàá nítorí ipò àyè wọn. Bákan náà sì ni ẹlẹ́rìí kan níláti ṣe iṣẹ́-òòjọ́ yíyẹ wẹ́kú fún agbanisíṣẹ́ rẹ̀ [ó sì] níláti jẹ́ aláìlábòsí ní gbogbo ọ̀nà . . . Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ ń sọ ènìyàn kan tí kò ní òye iṣẹ́ púpọ̀ di òṣìṣẹ́ wíwúlò, àwọn Ẹlẹ́rìí mélòókan ní Àríwá Philadelphia [U.S.A.] ti gòkè dé ipò ẹrù-iṣẹ́ jíjọjú níbi iṣẹ́.” Ó ṣe kedere pé, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti tẹ́wọ́gba ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a ti mú wà lójúfò sí àwọn ìṣarasíhùwà tí ó mú kí ó ṣòro láti kojú àwọn ipò lọ́ọ́lọ́ọ́. Àwọn ìrírí wọn fihàn pé àwọn ìtọ́ni Bibeli ń ṣamọ̀nà sí ìgbésí-ayé dídára jù, tí ó túbọ̀ láyọ̀.
8. Èéṣe tí a fi lè so “ajọra-ẹni lójú,” “onírera,” àti “asọ̀rọ̀-òdì” pọ̀ mọ́ra, kí sì ni ìtumọ̀ àwọn èdè mẹ́ta wọ̀nyí?
8 A lè so àwọn nǹkan mẹ́ta tí ó tẹ̀lé e nínú àkọsílẹ̀ Paulu pọ̀ mọ́ra. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “ajọra-ẹni lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì.” Àwọn mẹ́ta wọ̀nyí kò jọra, ṣùgbọ́n gbogbo wọn tanmọ́ ìgbéraga. Àkọ́kọ́ ni “ìjọra-ẹni lójú.” Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ọ̀rọ̀ Griki ìpìlẹ̀ náà níhìn ín túmọ̀sí: “‘Ẹni tí ń pọ́n ara rẹ̀ ju bí òun fúnraarẹ̀ ṣe jẹ́ lọ’ tàbí ‘tí ń ṣèlérí ju ohun tí agbára rẹ̀ ká lọ.’” Ìwọ lè lóye ìdí tí àwọn Bibeli kan fi lo èdè náà “afúnnu.” Èyí tí ó tẹ̀lé e ni “onírera,” tàbí lóréfèé “afarahàn-bí-ẹni-lọ́lá jùlọ.” Èyí tí ó kẹ́yìn ni “asọ̀rọ̀-òdì.” Àwọn kan lè ronú nípa asọ̀rọ̀-òdì gẹ́gẹ́ bí àwọn wọnnì tí ń sọ̀rọ̀ láìlọ́wọ̀ nípa Ọlọrun, ṣùgbọ́n ìtumọ̀ fífarasin fún èdè náà ní nínú ọ̀rọ̀ apanilára, abanilórúkọjẹ́, tàbí eléèébú lòdìsí ènìyàn. Nítorí náà Paulu ń tọ́kasí ọ̀rọ̀-òdì tí a sọ sí Ọlọrun àti ènìyàn.
9. Yàtọ̀ sí ìṣarasíhùwà pípanilára tí ó gbòdekan, ìṣarasíhùwà wo ni Bibeli fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti mú dàgbà?
9 Báwo ni ìmọ̀lára rẹ̀ ti ń rí nígbà tí o bá wà ní àyíká àwọn ènìyàn tí wọ́n bá àpèjúwe Paulu mu, yálà wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, tàbí ìbátan rẹ? Ó ha ń mú ìgbésí-ayé rọrùn síi bí? Tàbí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ha ń mú ìgbésí-ayé rẹ díjú síi ni bí, ní mímú kí ó ṣòro láti kojú àwọn àkókò lílekoko wa? Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, bí ó ti wù kí ó rí, kọ́ wa láti kọ àwọn ìṣarasíhùwà wọ̀nyí, ní fífúnni ní ìtọ́ni irú èyí ti a rí ní 1 Korinti 4:7; Kolosse 3:12, 13; àti Efesu 4:29.
10. Kí ni ó fihàn pé àwọn ènìyàn Jehofa ń jàǹfààní láti inú títẹ́wọ́gba ìtọ́ni Bibeli?
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristian jẹ́ aláìpé, fífi ìtọ́ni rere yìí sílò ń ràn wọ́n lọ́wọ́ púpọ̀ ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí. Ìwé ìròyìn Italy náà La Civiltà Cattolica sọ pé ìdí kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń báa nìṣó láti pọ̀ síi “ni pé àjọ ìgbòkègbodò náà ń fún àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ní ìdánimọ̀ lílágbára tí ó sì ṣe pàtó.” Ṣùgbọ́n, nípa “ìdánimọ̀ lílágbára,” òǹkọ̀wé náà ha ní “ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì” lọ́kàn bí? Yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ìwé ìròyìn àwọn onísìn Jesuit ṣàkíyèsí pé àjọ ìgbòkègbodò náà “fún àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ní ìdánimọ̀ lílágbára tí ó sì ṣe pàtó, ó sì jẹ́ ibìkan fún wọn níbi tí a ti gbà wọ́n pẹ̀lú ọ̀yàyà àti ìmọ̀lára jíjẹ́ ará àti wíwà ní ìṣọ̀kan.” Ǹjẹ́ kò ha hàn kedere pé àwọn ohun tí a ti kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń ràn wọn lọ́wọ́ bí?
Ìtọ́ni Ń Ṣàǹfààní fún Àwọn Mẹ́ḿbà Ìdílé
11, 12. Báwo ni Paulu ṣe fi bí ipò nǹkan yóò ṣe rí nínú ọ̀pọ̀ ìdílé hàn lọ́nà ṣíṣerẹ́gí?
11 A lè so àwọn nǹkan mẹ́rin tí ó tẹ̀lé e, tí wọ́n tanmọ́ra lọ́nà kan ṣáá papọ̀. Paulu sọtẹ́lẹ̀ pé nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ yóò jẹ́ “aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní-ìfẹ́ni-àdánidá.” Ìwọ mọ̀ pé méjì nínú àwọn àbùkù wọ̀nyí—jíjẹ́ aláìlọ́pẹ́, àti jíjẹ́ aláìdúróṣinṣin—wà yí wa ká. Síbẹ̀, a lè fi ìrọ̀rùn rí ìdí tí Paulu fi fi wọ́n sáàárín jíjẹ́ “aṣàìgbọ́ràn sí òbí” àti “aláìní-ìfẹ́ni-àdánidá.” Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wémọ́ra.
12 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n ní àfiyèsí, lọ́mọdé lágbà, ni yóò gbà pé àìgbọ́ràn sí òbí ti gbilẹ̀ lónìí, ó sì ń burú síi. Ọ̀pọ̀ òbí ń ṣàròyé pé ó dàbíi pé àwọn èwe ń di aláìmọpẹ́ẹ́dá fún gbogbo ohun tí a ń ṣe fún wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń fi ẹ̀hónú hàn pé àwọn òbí wọn kò jẹ́ adúróṣinṣin sí wọn (tàbí sí ìdílé ní gbogbogbòò) níti gidi ṣùgbọ́n wọ́n ti fi araawọn jin iṣẹ́ wọn, adùn, tàbí araawọn. Dípò kí á gbìyànjú láti pinnu ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ìyọrísí náà. Ìbáraṣọ̀tá láàárín àwọn àgbà àti èwe sábà máa ń sún àwọn ọ̀dọ́langba láti ṣe ìgbékalẹ̀ ọ̀pá-ìdiwọ̀n tiwọn nípa ìwàrere, tàbí ìwà pálapàla. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ìlọsókè iye oyún ọ̀dọ́langba, ìṣẹ́yún, àti àwọn àrùn ìbálòpọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àìtó ìfẹ́ni-àdánidá nínú ilé máa ń yọrísí ìwà ipá. Ó ṣeéṣe kí o lè sọ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ láti agbègbè rẹ, ẹ̀rí pé ìfẹ́ni-àdánidá ń pòórá.
13, 14. (a) Lójú bí nǹkan ṣe ń bàjẹ́ síi nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, èéṣe tí a fi níláti fiyèsí Bibeli? (b) Irú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni Ọlọrun fúnni nípa ìgbésí-ayé ìdílé?
13 Èyí lè ṣàlàyé ìdí tí àwọn ènìyàn púpọ̀ síi fi ń hùwà lòdìsí àwọn wọnnì tí wọ́n ti fi ìgbà kan rí dàbí apákan ẹbí wọn, àwọn tí wọ́n jọ wá láti ìran ìdílé, ẹ̀yà, tàbí àwùjọ orílẹ̀-èdè kan náà. Bí ó ti wù kí ó rí, fi sọ́kàn pé àwa kò fa àwọn nǹkan wọ̀nyí yọ láti tẹnumọ́ àwọn ohun tí kò dára nínú ìgbésí-ayé lónìí. Ọkàn-ìfẹ́ wa pàtàkì méjì náà ni: Àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli ha lè ṣèrànwọ́ fún wa láti yẹra fún jíjìyà lọ́wọ́ àwọn àbùkù tí Paulu kọsílẹ̀, àti pé a óò ha jàǹfààní láti inú lílo àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli nínú ìgbésí-ayé wa? Ìdáhùn náà lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, bí ó ti hàn níti àwọn kókó mẹ́rin wọnnì nínú àkọsílẹ̀ Paulu.
14 Gbólóhùn ọ̀rọ̀ gbogbogbòò kan tọ̀nà dáradára: Kò sí ẹ̀kọ́ kan tí ó tayọ ti Bibeli ní pípèsè ìgbésí-ayé ìdílé tí ń mù ọkàn yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń yọrísírere dáadáa. Èyí ni a jẹ́rìí sí nípa àpẹẹrẹ kan nínú àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ tí ó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé kìí ṣe láti yẹra fún àwọn ọ̀fìn nìkan ni bíkòṣe láti kẹ́sẹjárí. Kolosse 3:18-21 ṣàkàwé ìyẹn dáradára, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ ìwé gbígbéṣẹ́ mìíràn tí ó sì gbámúṣe wà tí a darí rẹ̀ sí àwọn ọkọ, aya, àti àwọn ọmọ. Àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ wa. Òótọ́ ni, àní nínú ìdílé àwọn Kristian pàápàá, àwọn ìṣòro dídíjú àti ìpènijà wà. Síbẹ̀, àwọn ìyọrísí ní gbogbogbòò fẹ̀ríhàn pé Bibeli ń pèsè àwọn ẹ̀kọ́ tí ń ran àwọn ìdílé lọ́wọ́.
15, 16. Ipò wo ni olùṣèwádìí kan rí nígbà tí ó ń ṣèwádìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Zambia?
15 Fún ọdún kan àbọ̀, olùṣèwádìí kan láti Yunifásítì Lethbridge, Canada, wádìí ìgbésí-ayé ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ní Zambia. Obìnrin náà parí èrò sí pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ní ìrírí àṣeyọrísírere gígalọ́lá ju àwọn mẹ́ḿbà ètò-ìsìn mìíràn lọ níti níní ìrẹ́pọ̀ lọ́kọláya tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. . . . Àṣeyọrísírere wọn jẹ́ nítorí àjọṣepọ̀ tọ̀túntòsì tí a mú sunwọ̀n síi láàárín tọkọtaya lọ́nà tí wọ́n gbà ń bá araawọn lò lẹ́nìkínní kejì nínú ìsapá tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwárí rẹ̀ láti ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìhalẹ̀mọ́ni, nítorí tí wọ́n ti di olùjíhìn fún olórí titun kan, Ọlọrun. . . . Ọkọ kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kọ́ láti dàgbàdénú nínú gbígbé ẹrù-iṣẹ́ fún ire-àǹfààní aya àti àwọn ọmọ rẹ̀. . . . Ọkọ àti aya ni a fún níṣìírí láti jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan . . . Ìpàwàtítọ́mọ́ tí a béèrè fún jùlọ yìí ń so ìgbéyàwó pọ̀ ṣọ̀kan.”
16 Ìwádìí yẹn ni a gbéka ọ̀pọ̀ àwọn ìrírí gidi. Fún àpẹẹrẹ, olùṣèwádìí yìí sọ pé yàtọ̀ sí ohun tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀, “àwọn ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a máa ń rí lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn aya wọn nínú oko, kìí ṣe nígbà ṣíṣán oko nìkan ni, ṣùgbọ́n ní ìgbà gbígbìn àti títúlẹ̀ pẹ̀lú.” Ó farahàn nípa bẹ́ẹ̀ pé àìlóǹkà àwọn ìrírí kárí ayé fihàn pé ìtọ́ni Bibeli kan ìgbésí-ayé.
17, 18. Àbájáde yíyanilẹ́nu wo ni ó jáde nínú ìwádìí kan nípa ogún ìsìn àti ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó?
17 Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú mẹ́nukan àwọn àwárí inú ìwé ìròyìn Journal for the Scientific Study of Religion. Ní 1991 ó ní ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó ní àkòrí náà “Àwọn Ogún Ìsìn àti Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó: Ẹ̀rí Láti Inú Àpẹẹrẹ Àwọn Géńdé Ọ̀dọ́ Orílẹ̀-Èdè Kan.” Ó ṣeéṣe kí o mọ bí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ti wọ́pọ̀ tó. Nígbà ọ̀dọ́ ọ̀pọ̀ ti juwọ́sílẹ̀ fún ìfẹ́ ìbálòpọ̀, tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba sì ní ọ̀pọ̀ alájùmọ̀ ní ìbálòpọ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli ha lè yí àṣà wíwọ́pọ̀ yìí padà bí?
18 Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n mẹ́ta tí wọn ṣèwádìí ọ̀ràn náà ṣèrètí láti ríi ‘pé àwọn àgùnbánirọ̀ àti àwọn géńdé ọ̀dọ́ tí a tọ́ nínú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Kristian fífìdímúlẹ̀ ni kì yóò ṣeéṣe púpọ̀ fún láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.’ Ṣùgbọ́n kí ni àwọn òtítọ́ fihàn? Ní gbogbogbòò, láàárín ìpín 70 sí 82 nínú ọgọ́rùn-ún ti lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Fún àwọn kan “ogún ìrinkinkin mọ́ ìlànà [dín] ṣíṣeéṣe ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó [kù], ṣùgbọ́n kìí ṣe níti ọ̀ràn ‘ìbálòpọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba ṣáájú ìgbéyàwó.’” Àwọn olùṣèwádìí náà ṣàlàyé nípa àwọn ọ̀dọ́ kan láti inú ìdílé tí ó dàbíi pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí ìsìn tí wọ́n “ṣàfihàn ṣíṣeéṣe gíga tí ó hàn gbangba láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó bí a bá fiwéra pẹ̀lú àwọn Protẹstanti Ìjímìjí.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
19, 20. Báwo ni ìtọ́ni Ọlọrun ti ṣe ran ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ tí ó sì dáàbòbò wọ́n?
19 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà wulẹ̀ rí òdìkejì láàárín àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n wà lára “àwùjọ tí ó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn mìíràn.” Èéṣe? “Ìwọ̀n ìfarajìn àti ìdarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ìrírí, ìfojúlọ́nà, àti ìkópa nínú ìgbòkègbodò ìsìn pèsè . . . lè ṣokùnfà ìrọ̀mọ́ àwọn ìlànà ìgbàgbọ́ ní gbogbogbòò lọ́nà gíga.” Wọ́n fikún-un pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí ni a retí pé kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn níti ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ àti géńdé ọ̀dọ́.”
20 Nítorí náà, ìtọ́ni Bibeli ń nípalórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí rere nípa ṣíṣèrànwọ́ fún wọn láti yẹra fún ìwà pálapàla. Èyí ń yọrísí ààbò kúró lọ́wọ́ àrùn ìbálòpọ̀, díẹ̀ lára èyí tí kò ṣeé wòsàn tí àwọn mìíràn sì ń ṣekúpani. Ó túmọ̀sí pé kò sí ìkìmọ́lẹ̀ láti ṣẹ́yún, èyí ti Bibeli fi kọ́ni pé ó dọ́gba pẹ̀lú ìpànìyàn. Ó tún ń yọrísí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lè wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn mímọ́gaara. Ìyẹn túmọ̀sí ìgbéyàwó tí a kọ́ lé orí ìpìlẹ̀ lílágbára. Irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni ó lè ṣèrànwọ́ fún wa láti kojú ìṣòro, kí á jẹ́ aláyọ̀, àti onílera.
Ìtọ́ni Tí Ń Gbéniró
21. Àwọn nǹkan wo ni Paulu sọtẹ́lẹ̀ fún àkókò wa lọ́nà ṣíṣerẹ́gí?
21 Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a padà lọ sínú 2 Timoteu 3:3, 4, kí a sì kíyèsí ohun mìíràn tí Paulu sọ pé yóò mú kí àkókò wa lekoko fún ọ̀pọ̀ láti bálò—ṣùgbọ́n kìí ṣe fún gbogbo ènìyàn: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ aláìṣeé bá ṣe àdéhùn, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, àti olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.” Ẹ wo bí ó ṣe báamu gẹ́ẹ́! Síbẹ̀síbẹ̀, ìtọ́ni láti inú Bibeli lè dáàbòbò wá kí ó sì mú wa gbaradì láti kojú ìṣòro, kí a sì kẹ́sẹjárí.
22, 23. Ìgbaniníyànjú gbígbéniró wo ni Paulu fi parí àkọsílẹ̀ rẹ̀, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì rẹ̀?
22 Aposteli Paulu parí àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀nà tí ń gbéniró. Ó yí apá tí ó kẹ́yìn sí àṣẹ Ọlọrun tí ó lè mú ìbùkún aláìṣeédíwọ̀n wá fún wa. Paulu mẹ́nukan àwọn “tí wọn ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọrun ṣùgbọ́n tí wọn jásí èké níti agbára rẹ̀, yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí.” Ràntí pé àwọn ọ̀dọ́ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mélòókan ní iye ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó tí ó ju ìpíndọ́gba lọ níti gidi. Họ́wù, àní bí ìwà pálapàla àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì wọnnì bá tilẹ̀ wà ní ipele ìpíndọ́gba, ìyẹn kì yóò ha jẹ́ ẹ̀rí pé irú ìjọsìn wọn jẹ́ aláìlágbára? Síwájú síi, àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn ha ń mú ìyípadà bá bí àwọ̀n ènìyàn ṣe ń ṣe òwò wọn, bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ abẹ́ wọn lò, tàbí bí wọ́n ṣe ń bà àwọn ìbátan lò?
23 Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu fihàn pé a gbọ́dọ̀ fi àwọn ohun tí a ń kọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò, ní níní ọ̀nà ìjọsìn kan tí ó fi agbára Kristian gidi hàn. Nípa tí àwọn wọnnì tí irú ìjọsìn wọn jẹ́ aláìlágbára, Paulu sọ fún wa pé: “Yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí.” Èyí jẹ́ àṣẹ ṣíṣe kedere kan, tí yóò mú àwọn ìbùkún ṣíṣe pàtó wá fún wa.
24. Báwo ni ìgbaniníyànjú tí ó wà nínú Ìfihàn orí 18 ṣe báradọ́gba pẹ̀lú ìmọ̀ràn Paulu?
24 Ní ọ̀nà wo? Ó dára, ìwé tí ó kẹ́yìn Bibeli ṣàpèjúwe obìnrin ìṣàpẹẹrẹ kan, aṣẹ́wó kan, tí a pè ní Babiloni Ńlá. Ẹ̀rí fihàn pé Babiloni Ńlá dúró fún ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé, tí Jehofa Ọlọrun ti gbéyẹ̀wò tí ó sì ti kọ̀sílẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò níláti wà lára wọn. Ìfihàn 18:4 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ẹ má baà ṣe alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ẹ má baà sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.” Ìyẹn kìí ha ṣe ìhìn-iṣẹ́ kan náà ti Paulu sọ, “yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí”? Ṣíṣègbọràn sí i jẹ́ ọ̀nà mìíràn nípasẹ̀ èyí tí ìtọ́ni Ọlọrun fi lè ṣàǹfààní fún wa.
25, 26. Ọjọ́-ọ̀la wo ni ó wà ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìtọ́ni Jehofa Ọlọrun nísinsìnyí tí wọ́n sì lò ó?
25 Láìpẹ́ Ọlọrun yóò dásí ọ̀ràn aráyé ní tààràtà. Òun yóò fòpin sí gbogbo ìsìn èké àti ìyókù ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ti ìsinsìnyí. Ìyẹn yóò jẹ́ ìdí kan fún ayọ̀, bí Ìfihàn 19:1, 2 ti fihàn. Àwọn tí wọ́n gbà tí wọ́n sì tẹ̀lé ìtọ́ni Ọlọrun ni a óò yọ̀ọ̀da fún láti máa báa nìṣó láti tẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbà tí àwọn ohun ìdìgbòlù ti àkókò lílekoko yìí bá kọjá lọ.—Ìfihàn 21:3, 4.
26 Gbígbé nínú Paradise ilẹ̀-ayé tí a dá padàbọ̀sípò yẹn dájúdájú yóò jẹ́ ìdùnnú tí ó rékọjá àfinúrò. Ọlọrun ṣèlérí pé ó ṣeéṣe fún wa, a sì lè gbọ́kànlé e pátápátá. Ó tipa báyìí fún wa ní ìdí púpọ̀ yanturu láti tẹ́wọ́gbà kí á sì tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ń rannilọ́wọ́. Nígbà wo? Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀ nísinsìnyí ní àwọn àkókò lílekoko wa títí wọnú Paradise tí ó ṣèlérí.—Mika 4:3, 4.
Àwọn Kókó Láti Ronú Lé
◻ Báwo ni àwọn ènìyàn Jehofa ti ṣe jàǹfààní láti inú ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa ọrọ̀?
◻ Àwọn àbájáde rere wo tí ń débá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nítorí lílo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ìwé ìròyìn onísìn Jesuit kan jẹ́rìí sí?
◻ Àwọn àǹfààní wo tí ń débá àwọn ìdílé tí ń lo ìtọ́ni àtọ̀runwá ni ìwádìí kan ní Zambia ṣípayá?
◻ Ààbò wo ni ìtọ́ni àtọ̀runwá pèsè fún àwọn ọ̀dọ́?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ WO BÍ Ó TI JẸ́ ÀDÁNÙ TÓ!
“Àwọn ọ̀dọ́langba dojúkọ ewu ńláǹlà ti kíkó àrùn AIDS nítorí tí wọ́n fẹ́ràn láti fi ìbálòpọ̀ àti oògùn dánrawò, láti farawewu kí wọ́n sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀, àti nítorí tí wọ́n ronú pé àwọn kò lè kú tí wọ́n sì ń ṣàìgbọràn sí òfin,” ni ìròyìn kan tí a gbékalẹ̀ níbi àpérò kan lórí àrùn AIDS àti àwọn ọ̀dọ́langba sọ.—Daily News ti New York, Sunday, March 7, 1993.
“Àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba tí ń ní ìbálòpọ̀ takọtabo nígbàgbogbo ń ṣẹ́yọ gẹ́gẹ́ bí ‘òléwájú’ nínú ìjìyà àjàkálẹ̀ àrùn AIDS, ni ìwádìí kan tí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè ṣe ní Europe, Africa ati Gúúsù-Ìlà-Oòrùn Asia ti ṣàwárí.”—The New York Times, Friday, July 30, 1993.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ìtọ́ni Bibeli ń ṣàǹfààní fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ìjọ àti nínú ilé