Ẹ̀KỌ́ 15
Ìrísí Tó Dára
ÌRÍSÍ rẹ ń sọ ohun púpọ̀ nípa rẹ. Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà máa ń wo ohun tó wà lọ́kàn ẹni, “ohun tí ó fara hàn sí ojú” ni ẹ̀dá èèyàn ní gbogbo gbòò máa ń wo láti fi ṣèpinnu ní tiwọn. (1 Sám. 16:7) Bí o bá múra dáadáa lọ́nà tó mọ́ tónítóní, ńṣe làwọn èèyàn yóò gbà pé ẹni iyì ni ọ́, wọ́n á sì túbọ̀ fẹ́ láti tẹ́tí sí ọ. Wíwọṣọ tí o bá wọṣọ lọ́nà yíyẹ yóò tún jẹ́ kí àwọn èèyàn fojú tó dára wo ètò àjọ tí o wà, àwọn tó ń fetí sí ọ yóò sì ní èrò tó dára nípa Ọlọ́run tí ò ń sìn.
Àwọn Ìlànà Tí A Ní Láti Tẹ̀ Lé. Bíbélì kò to ọ̀pọ̀ òfin kalẹ̀ nípa ìrísí ẹni. Ṣùgbọ́n ó pèsè àwọn ìlànà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó yè kooro. Pàtàkì jù lọ nínú gbogbo wọn ni pé kí á “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Àwọn ìlànà wo ló jẹ mọ́ ìrísí wa?
Àkọ́kọ́, Bíbélì rọ̀ wá pé ká wà ní mímọ́, pé kí ara wa mọ́ kí aṣọ wa sì mọ́. Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àtijọ́, ó sọ àwọn ohun tí wọ́n ní láti máa ṣe kí wọ́n lè máa wà ní mímọ́ tónítóní. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn àlùfáà bá wà lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ wẹ̀ kí wọ́n sì fọ ẹ̀wù wọn ní àwọn àkókò tí Ọlọ́run pa láṣẹ. (Léf. 16:4, 24, 26, 28) Àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, ṣùgbọ́n àwọn ìlànà inú rẹ̀ ṣì wúlò. (Jòh. 13:10; Ìṣí. 19:8) Pàápàá nígbà tí a bá ń lọ sí ibi ìjọsìn tàbí tí a bá ń lọ sí òde ẹ̀rí, ara wa gbọ́dọ̀ mọ́, èémí wa gbọ́dọ̀ dára, aṣọ wa sì gbọ́dọ̀ mọ́ kó má di pé à ń rí àwọn ẹlòmíràn lára. Àwọn tí a máa ń yan ọ̀rọ̀ fún láti sọ tàbí tí wọ́n máa ń ṣe àwọn àṣefihàn níwájú ìjọ gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú èyí. Kíkíyèsí ìrísí wa ń fi ọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀.
Ìkejì, Bíbélì rọ̀ wá pé ká mẹ̀tọ́mọ̀wà, ká sì yè kooro ní èrò inú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni obìnrin láti máa “ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tím. 2:9, 10) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú ṣe pàtàkì nínú ìwọṣọ àti ìmúra àwọn ọkùnrin pẹ̀lú.
Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń ṣàníyàn nípa pé kí òun má mọ̀ọ́mọ̀ máa mú àwọn ẹlòmíràn bínú àti pé kí òun má ṣe pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara òun. Ẹni tí èrò inú rẹ̀ bá yè kooro á lè ní ìdánúṣe á sì lè máa lo làákàyè. Ẹni tó bá ń lo ànímọ́ wọ̀nyí ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Ọlọ́run, ìyẹn kò sì ní jẹ́ kó máa ṣi nǹkan ṣe. Bí èèyàn bá ń lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, ìyẹn kò ní kí èèyàn máà múra lọ́nà tó gbayì, ṣùgbọ́n ó máa ń jẹ́ kí ìrísí wa fi hàn pé a lo làákàyè á sì jẹ́ ká yẹra fún ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀. (1 Jòh. 2:16) A fẹ́ fi àwọn ìlànà wọ̀nyí sílò yálà a wà níbi ìjọsìn, a wà lóde ẹ̀rí, tàbí a ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn. Kódà aṣọ tí a fi ń gbatẹ́gùn gbọ́dọ̀ fi hàn pé a jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà àti ẹni tí èrò inú rẹ̀ yè kooro. Ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, àwọn àǹfààní yóò ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà. A lè ṣàìmúra bí ìgbà tí à ń lọ sí ìpàdé àti àpéjọ, síbẹ̀síbẹ̀, aṣọ wa gbọ́dọ̀ mọ́ kí ó má ṣe rún, kí ó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Lóòótọ́, gbogbo wa kì í múra bákan náà. A kò tilẹ̀ retí pé ká múra bákan náà. Ohun tó wù mí ò wù ọ́, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbà gbogbo.
Àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé aṣọ tó jẹ́ ti “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” tilẹ̀ ṣe pàtàkì gidigidi ju irú irun tí èèyàn ṣe àti irú aṣọ tí èèyàn wọ̀ lọ. (1 Pét. 3:3, 4) Nígbà tí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, inú rere, àti ìgbàgbọ́ tó lágbára bá kún inú ọkàn wa, wọn yóò di ẹ̀wù tẹ̀mí tí ń bọlá fún Ọlọ́run ní tòótọ́.
Ìkẹta, Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ṣàyẹ̀wò bóyá ìrísí wa wà létòletò. Ní 1 Tímótì 2:9, a sọ̀rọ̀ nípa “aṣọ tí ó wà létòletò.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ ọ̀ṣọ́ àwọn obìnrin ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ, ìlànà kan náà wúlò fún àwọn ọkùnrin. Ohun tó bá wà létòletò kò ní rún, kò sì ní rí wúruwùru. Bóyá a rí jájẹ tàbí a kò rí jájẹ, ìrísí wa ṣì lè bójú mu.
Ọ̀kan lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí àwọn ẹlòmíràn máa ń kíyè sí nípa ìrísí wa ni irun wa. Ó yẹ kí ó mọ́ tàbí kí ó wà létòletò. Àṣà ìbílẹ̀ àti àbùdá ẹni jẹ́ kókó méjì tó máa ń ní ipa lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣe irun wọn. Ní 1 Kọ́ríńtì 11:14, 15, a rí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa ọ̀nà ìgbàṣerun, èyí tí ẹ̀rí fi hàn pé ó gba ti kókó méjì yìí yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ọ̀nà tí ẹnì kan gbà ṣe irun rẹ̀ bá fi hàn pé ẹni ọ̀hún ń gbìyànjú láti dà bí ẹ̀yà òdìkejì, ìyẹn lòdì sí ìlànà Bíbélì.—Diu. 22:5.
Ní ti àwọn ọkùnrin, ó yẹ kí wọ́n gẹrun kí wọ́n sì fá irùngbọ̀n wọn láti lè ní ìrísí tó mọ́. Ní àgbègbè tí wọ́n bá ti ń ka irun imú sí nǹkan iyì, kí ẹni tó bá dá tiẹ̀ sí máa gé e kí ó bójú mu.
FÌkẹrin, kí ìrísí wa má dà bíi ti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ayé àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (1 Jòh. 2:15-17) Ńṣe ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kún inú ayé yìí. Ara ìwọ̀nyí ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ àti fífi ohun ìní ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími tí Jòhánù mẹ́nu kàn. Ìwé Mímọ́ tún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ tàbí ṣíṣe àìgbọràn sí àwọn aláṣẹ. (Òwe 17:11; Éfé. 2:2) Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwàkiwà wọ̀nyí sábà máa ń hàn nínú irú aṣọ tí àwọn èèyàn máa ń wọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń múra. Nítorí èyí, ìrísí wọn lè máà bójú mu, ó lè máa mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, ó lè jẹ́ ti ọ̀ṣọ́ àṣejù, ó lè rí wúruwùru, ó lè fi àìbìkítà hàn, tàbí kó rí jákujàku. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, a ó yẹra fún irú ìwọṣọ àti ìmúra tí kò bá àwọn ọ̀nà ti Kristẹni mu yìí.
Dípò fífarawé ayé yìí, o ò rí i pé ó sàn pé kí àpẹẹrẹ rere ti àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni máa nípa lórí irú aṣọ tí ò ń wọ̀ àti bí o ṣe ń múra! Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó bá ń retí pé lọ́jọ́ kan, àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn lè máa kíyè sí ìmúra àwọn tó ti tóótun láti máa sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Gbogbo wa lè máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ àwọn tó ti fi ìdúróṣinṣin kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.—1 Tím. 4:12; 1 Pét. 5:2, 3.
Ìkarùn-ún, láti pinnu ohun tó bójú mu, a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé “Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:3) Ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni ohun tó jẹ Jésù lógún jù lọ. Jésù tún fi ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ṣáájú ìrọ̀rùn ti ara rẹ̀. Ní ti aṣọ wíwọ̀ àti ọ̀nà ìgbàmúra, bí ohunkóhun yóò bá jẹ́ ìdènà láàárín àwa àti àwọn èèyàn tó wà níbi tá a ti ń sìn báyìí, kí ló yẹ ká ṣe? Fífarawé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Kristi fi hàn lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìlànà tí a ní láti tẹ̀ lé lélẹ̀, ó ní: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀.” (2 Kọ́r. 6:3) Nítorí ìdí yẹn, a lè yẹra fún àṣà irun tàbí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ara tó lè mú kí àwọn tí a fẹ́ wàásù fún máà fẹ́ láti tẹ́tí sí wa.
Ìdúró Ara. Ìrísí tó dára tún kan pé kí èèyàn gbé ara dúró bó ṣe yẹ. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe bákan náà ní ìdúró ara wa ṣe rí, a kì í sì í sapá láti mú ara wa bá irú ọ̀nà kan pàtó mu. Ṣùgbọ́n, ó yẹ fún àfiyèsí pé gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe lò ó, nínàró ṣánṣán máa ń buyì kúnni, ó sì máa ń fi hàn pé èèyàn ò sọ̀rètí nù. (Léf. 26:13; Lúùkù 21:28) Síbẹ̀, nítorí pé arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe iṣẹ́ tó gba pé kó tẹrí mọ́lẹ̀ tàbí nítorí ọjọ́ ogbó tàbí àìlera, ó lè má ṣeé ṣe fún un láti nàró ṣánṣán mọ́ tàbí ó lè gba pé kí ó fara ti nǹkan kó tó lè dúró. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tó bá lè nàró ṣánṣán, a dámọ̀ràn pé kí wọ́n nàró nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ kí ó má bàa dà bíi pé wọn kò bìkítà tàbí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú kí olùbánisọ̀rọ̀ gbé ọwọ́ lé orí tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwùjọ yóò túbọ̀ fojú iyì wo olùbánisọ̀rọ̀ tí kò bá fi ara ti tábìlì rárá.
Ohun Èlò Tó Wà ní Mímọ́. Kì í ṣe ìrísí wa nìkan ló yẹ kó mọ́ kí ó sì wà létòletò, ó yẹ kí àwọn ohun èlò tí à ń lò lóde ẹ̀rí pẹ̀lú mọ́ kí wọ́n sì bójú mu.
Ronú nípa Bíbélì rẹ. Kì í ṣe gbogbo wa là ń rí Bíbélì tuntun nígbà tí èyí tá a ní bá gbó. Síbẹ̀, bó ti wù kó pẹ́ tó tí a ti ń lo Bíbélì wa, ó yẹ kó hàn pé à ń tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
Lóòótọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà di àpò òde ẹ̀rí wa, ṣùgbọ́n kò yẹ kí ó rí wúruwùru. Ǹjẹ́ o ti rí i rí tí àwọn bébà já bọ́ látinú Bíbélì nígbà tí akéde kan fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ẹnì kan lóde ẹ̀rí tàbí bóyá nígbà tí arákùnrin kan ń sọ̀rọ̀ níwájú ìjọ? Ó pín ọkàn rẹ níyà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí bébà tí ẹnì kan fi sínú Bíbélì bá ń fa ìpínyà ọkàn, a jẹ́ pé onítọ̀hún yóò ní láti kó àwọn bébà yẹn sí ibòmíràn, kí ohun èlò rẹ̀ bàa lè wà létòletò. Tún kíyè sí i pé ní àwọn ilẹ̀ kan, ìwà àìlọ́wọ̀ ni wọ́n kà á sí béèyàn bá gbé Bíbélì tàbí àwọn ìwé mìíràn tó jẹ́ ti ìsìn sórí ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
Ó yẹ kí ìrísí tó dára jẹ wá lógún. Ó tún máa ń ní ipa lórí ojú tí àwọn èèyàn fi ń wò wá. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ní láti fún un ní àfiyèsí pàtàkì nítorí pé a fẹ́ láti “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.