Àwọn Òbí Ń kojú Pákáǹleke
Ó SÁBÀ máa ń jọ pé ayọ̀ tí àwọn òbí ń ní bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ máa ń mú kí wọ́n má mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ọmọ wọn tuntun ní ń ru wọ́n sókè. Wọ́n máa ń ka ẹ̀rín músẹ́ àkọ́kọ́, àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, àti àwọn ìṣísẹ̀ àkọ́kọ́ ọmọ náà sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Wọ́n máa ń fi àwọn ìtàn àti fọ́tò dá àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan wọn lára yá. Ní kedere, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn.
Síbẹ̀síbẹ̀, nínú àwọn ìdílé kan, ọ̀ràn ìbànújẹ́ ń yọjú bí ọdún ti ń gorí ọdún. Àwọn òbí náà ń bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ líle àti ọ̀rọ̀ ìmúnibínú rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́tù tí wọ́n fi ń báni ṣeré; wọ́n ń fi ìfìbínúluni tàbí àìsí ìfarakanra kankan rọ́pò ìgbánimọ́ra onífẹ̀ẹ́ni; ìbìnújẹ́ kíkorò ń rọ́pò ìmọ̀lára ìyangàn òbí. Ọ̀pọ̀ ń sọ pé: “Kò yẹ kí n bímọ kankan.” Nínú àwọn ìdílé mìíràn, ìṣòro náà tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ—àwọn òbí náà kùnà láti fi ìfẹ́ hàn kódà nígbà tí ọmọ náà ṣì jẹ́ ọmọ ọwọ́ jòjòló! Nínú èyí tó wù kó jẹ́ nínú ọ̀ràn méjèèjì, kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀? Níbo ni ìfẹ́ náà wà?
Dájúdájú, àwọn ọmọdé kò tóótun láti mọ ìdáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn kì yóò dí wọn lọ́wọ́ dídé orí èrò tiwọn. Nínú ọkàn àyà rẹ̀ lọ́hùn-ún, ó ṣeé ṣe kí ọmọdé kan parí èrò sí pé, ‘Bí Mọ́mì àti Dádì kò bá nífẹ̀ẹ́ mi, ó ní láti jẹ́ nítorí pé ohun kan ṣàìtọ́ nípa mi. Mo ní láti jẹ́ ọmọ burúkú gan-an ni.’ Èyí lè di ohun tí ó gbà gbọ́ gidigidi—ọ̀kan tí ó lè fa onírúurú ìbàjẹ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé.
Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí lè kùnà láti fi ìfẹ́ tí àwọn ọmọdé nílò hàn wọ́n nítorí onírúurú ìdí. A gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn òbí lóde òní ń kojú onírúurú pákáǹleke, tí àwọn kan lára wọn kò sì ṣẹlẹ̀ lọ́nà púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí. Ní ti àwọn òbí tí kò ṣe tán láti kojú àwọn pákáǹleke náà bí ó ti yẹ, àwọn pákáǹleke yìí lè nípa búburú gan-an lórí agbára wọn láti ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òbí. Ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n ìgbàanì kan polongo pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.”—Oníwàásù 7:7.
“Àwọn Àkókò Lílekoko Tí Ó Nira Láti Bá Lò”
Sànmánì Ìjẹ́pípé kan. Ìyẹn ni ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti retí láti rí nínú ọ̀rúndún yìí. Finú rò ó wò—kò sí pákáǹleke ọrọ̀ ajé, ìyàn, ọ̀dá, ogun mọ́! Ṣùgbọ́n irú àwọn ìrètí bẹ́ẹ̀ ti kọjá lọ láìṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ayé òde òní ti rí bí òǹkọ̀wé Bíbélì kan ṣe sọ tẹ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa lọ́hùn-ún. Ó kọ̀wé pé ní àwọn ọjọ́ wa, a óò máa kojú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Ọ̀pọ̀ jù lọ òbí yóò láti fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn láìjanpata.
Ọ̀pọ̀ òbí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ń rí i pé owó ìgbọ́bùkátà ọmọ títọ́ nínú ayé òde òní pọ̀ jù lọ́nà tí ń ka àwọn láyà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí méjèèjì gbọ́dọ̀ jáde lọ ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Àwọn ìnáwó lórí ìlera, owó aṣọ, owó ilé ẹ̀kọ́, owó ìtọ́jú ojúmọ́, àti owó oúnjẹ òun ibùgbé pàápàá lè para pọ̀ di gbèsè tí ń mú kí ọ̀pọ̀ òbí nímọ̀lára bíi pé ìgbì ayé fẹ́ bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ipò ọrọ̀ ajé ń rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì létí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá tí ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí àwọn ènìyàn yóò fi gbogbo owó iṣẹ́ òòjọ́ kan ra kìkì ohun tí wọn yóò lò fún ọjọ́ kan ṣoṣo!—Ìṣípayá 6:6.
A kò lè retí pé kí àwọn ọmọdé lóye gbogbo pákáǹleke tí àwọn òbí wọn ń dojú kọ wọ̀nyí. Rárá, ní ti bí a ṣe dá wọn, àwọn ọmọdé ṣàìní, wọ́n nílò ìfẹ́ àti àfiyèsí. Agbára ìdarí tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ń ní lórí wọn láti ní àwọn ohun ìṣeré, aṣọ, àti ohun abánáṣiṣẹ́ tiwọn tí ó bágbà mu jù lọ sábà máa ń di ìkìmọ́lẹ̀ tí a ń gbé karí àwọn òbí láti pèsè àwọn ohun tí a fẹ́ tí ń pọ̀ sí i ṣáá.
Pákáǹleke mìíràn, tí ó jọ pé ó ń burú sí i lórí àwọn òbí lónìí, ni ìṣọ̀tẹ̀. Ó gbàfiyèsí pé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àìgbọràn àwọn ọmọ sí àwọn òbí lọ́nà gbígbòòrò gẹ́gẹ́ bí àmì míràn fún àwọn àkókò onídààmú wa. (Tímótì Kejì 3:2) Òtítọ́ ni pé ìṣòro bíbá àwọn ọmọ wí kì í ṣe tuntun. Kò sì sí òbí kan tí ó lè fi ẹ̀tọ́ di ẹ̀bi ṣíṣe ọmọ níṣekúṣe ru àṣìṣe ọmọ náà. Ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ha gbà pé àwọn òbí lónìí gbọ́dọ̀ kojú títọ́ àwọn ọmọ nínú àyíká tí ìṣọ̀tẹ̀ ti gbòde kan bí? Àwọn orin lílókìkí tí ń gbé ìrunú, ìṣọ̀tẹ̀, àti àìnírètí lárugẹ; àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí ń fi àwọn òbí hàn bí òmùgọ̀ tí ń fi àìmọ̀kan ṣàṣìṣe, tó sì ń fi àwọn ọmọdé hàn bí àwọn ọ̀jáfáfá ọlọgbọ́n títayọ jù wọ́n lọ; àwọn sinimá tí ń fògo fún híhùwà ipá láìrò ó wò—irú àwọn ipá bẹ́ẹ̀ ló ń bo àwọn ọmọdé mọ́lẹ̀ lóde òní. Àwọn ọmọdé tí ó bá gba irú ànímọ́ àti ìwà wíwọ́pọ̀ ti ìṣọ̀tẹ̀ yí mọ́ra lè gbé pákáǹleke lílekoko karí àwọn òbí wọn.
‘Àìní Ìfẹ́ni Àdánidá’
Síbẹ̀síbẹ̀, apá mìíràn nínú àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì kan náà yí tún wà, tí ó dá lórí ìṣòro púpọ̀ sí i fún ìdílé òde òní. Ó tọ́ka sí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (Tímótì Kejì 3:3) Ìfẹ́ni àdánidá ló so ìdílé pọ̀. Kódà, àwọn tí wọ́n ń ṣiyè méjì nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yóò ní láti gbà pé àwọn àkókò tiwa ti rí ìwólulẹ̀ amúnigbọ̀nrìrì nínú ìgbésí ayé ìdílé. Jákèjádò àgbáyé, iye ìkọ̀sílẹ̀ ti lọ sókè gan-an. Nínú àwọn àwùjọ púpọ̀, àwọn ìdílé olóbìí kan àti àwọn ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe wọ́pọ̀ ju àwọn ìdílé àbáláyé lọ. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ àti àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe ń kojú ìpèníjà àti pákáǹleke àrà ọ̀tọ̀ nígbà míràn, tí ó lè mú kí ó ṣòro fún wọn láti fi ìfẹ́ tí àwọn ọmọ nílò hàn sí wọn.
Síbẹ̀síbẹ̀, ipa tí ó tún jinlẹ̀ kan wà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn òbí òde òní fúnra wọn ti dàgbà nínú ilé tí “ìfẹ́ni àdánidá” ti kéré gan-an, tí ó bá wà rárá—àwọn ilé tí panṣágà àti ìkọ̀sílẹ̀ ti pín sí wẹ́wẹ́; tí àìlọ́yàyà àti ìkórìíra ti pa run; bóyá, àwọn ilé tí ìfọ̀rọ̀-jẹni-níyà, ìjẹniníyà ní ti ìmọ̀lára, ìlunibolẹ̀, tàbí ìbáni-ṣèṣekúṣe ti wọ́pọ̀ pàápàá. Kì í ṣe pé dídàgbà nínú irú ilé bẹ́ẹ̀ ń pa àwọn ọmọdé lára nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún lè ṣèpalára fún irú àgbà tí wọn yóò dà. Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò ń fi ipò búburú kan hàn—ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn òbí tí a jẹ níyà lọ́mọdé máa jẹ àwọn ọmọ tiwọn náà níyà. Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn Júù máa ń pa òwe kan pé: “Àwọn bàbá ti jẹ èso àjàrà kíkan, eyín àwọn ọmọ sì kan.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:2.
Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé ọ̀ràn kò ní láti rí bẹ́ẹ̀. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:3) Ó yẹ kí a sọ kókó pàtàkì kan níhìn-ín. Gbogbo pákáǹleke wọ̀nyí tí àwọn òbí ń kojú ha túmọ̀ sí pé kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe yàtọ̀ sí pé kí wọ́n máa fìyà jẹ àwọn ọmọ tiwọn bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́! Bí ìwọ bá jẹ́ òbí tí o sì bá ara rẹ tí o ń bá àwọn kan lára àwọn pákáǹleke tí a ti mẹ́nu bà sẹ́yìn fínra, tí o sì ń dààmú nípa bóyá ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti jẹ́ òbí rere láé, mọ́kàn! Ìwọ nìkan kọ́. Ipò rẹ àtẹ̀yìnwá kò fi dandan pinnu ọjọ́ ọ̀la rẹ.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìdánilójú tí Ìwé Mímọ́ fi fúnni pé ìmúsunwọ̀n ṣeé ṣe, ìwé náà, Healthy Parenting, ṣe àlàyé yìí pé: “Bí [ìwọ] kò bá gbé ìgbésẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀gbé láti hùwà lọ́nà yíyàtọ̀ sí ti àwọn òbí rẹ, àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé ọmọdé tìrẹ yóò tún fara hàn láìka bóyá ó fẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí o kò fẹ́ sí. Láti dínà ìyípoyípo ìṣẹ̀lẹ̀ yí, o gbọ́dọ̀ mọ àwọn ọ̀nà tí kò gbámúṣé tí o ń tọ̀ dunjú, kí o sì kọ́ láti yí wọn pa dà.”
Dájúdájú, bí ó bá pọn dandan, o lè dínà ìyípoyípo ìṣẹ̀lẹ̀ jíjẹ́ òbí afìyàjẹni! O sì lè kojú àwọn pákáǹleke tí ń mú kí jíjẹ́ òbí ṣòro bẹ́ẹ̀ lónìí. Ṣùgbọ́n báwo ni? Níbo ni o ti lè kọ́ nípa àwọn ìlànà tí ó dára jù lọ, tí ó ṣeé gbára lé jù lọ, ní ti jíjẹ́ òbí gbígbámúṣé? Àpilẹ̀kọ wa tí ó kàn yóò gbé ọ̀ràn yí yẹ̀ wò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Lábẹ́ pákáǹleke, àwọn òbí kan ń kùnà láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi ìfẹ́ tí àwọn ọmọ wọn nílò hàn