“Ṣe Iṣẹ́ Ajíhìnrere”
“Pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, . . . ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.”—2 Tímótì 4:5.
1. Àṣẹ wo ni Jésù pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
A Ń POLONGO orúkọ Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé. Ìdí rẹ̀ ni pé àwọn èèyàn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àṣẹ tí Jésù Kristi pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.
2. Ìtọ́ni wo ni Tímótì tó jẹ́ alábòójútó rí gbà, kí sì ni ọ̀nà táwọn Kristẹni alábòójútó lè gbà ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?
2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní kò fojú kéré àṣẹ yẹn rárá. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni alábòójútó ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tímótì 4:5) Ọ̀nà tí alábòójútó kan lè gbà ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lónìí ni pé kó jẹ́ ẹni tó ń fi ìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó jẹ́ ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà déédéé. Bí àpẹẹrẹ, alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù kó sì máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn níṣẹ́ náà. Pọ́ọ̀lù ṣe ojúṣe rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere, ó sì tún ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa kíkọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—Ìṣe 20:20; 1 Kọ́ríńtì 9:16, 17.
Àwọn Ajíhìnrere Tó Jẹ́ Onítara Láyé Ọjọ́un
3, 4. Kí làwọn ìrírí tí Fílípì ní gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere?
3 Gbogbo èèyàn ló mọ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sí ajíhìnrere tó jẹ́ onítara. Gbé ọ̀ràn ti Fílípì ajíhìnrere yẹ̀ wò. Ó wà lára àwọn “ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè . . . tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n” tá a yàn láti ṣe iṣẹ́ pípín oúnjẹ ojoojúmọ́ láìṣojúsàájú fún àwọn Kristẹni opó tí ń sọ èdè Gíríìkì àtàwọn tó ń sọ èdè Hébérù ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 6:1-6) Lẹ́yìn tí iṣẹ́ tá a yàn fún wọn yìí parí tí inúnibíni sì fọ́n gbogbo wọn káàkiri tí ó ku àwọn àpọ́sítélì nìkan, Fílípì lọ sí Samáríà. Ibẹ̀ ló ti polongo ìhìn rere náà tí ẹ̀mí mímọ́ sì tún fún un lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde àti láti wo àwọn arọ àtàwọn tó ní àrùn ẹ̀gbà sàn. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà ló tẹ́wọ́ gba ìwàásù Ìjọba náà tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Nígbà táwọn àpọ́sítélì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ èyí, wọ́n rán àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù lọ sí Samáríà kí àwọn onígbàgbọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi yìí lè gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 8:4-17.
4 Ẹ̀yìn ìyẹn ni ẹ̀mí Ọlọ́run darí Fílípì láti lọ pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà ní ojú ọ̀nà tó lọ sí Gásà. Lẹ́yìn tí Fílípì ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà lọ́nà tó yéni yékéyéké, ọkùnrin “tí ó wà ní ipò agbára lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà” yìí gba Jésù Kristi gbọ́, a sì batisí rẹ̀. (Ìṣe 8:26-38) Lẹ́yìn ìyẹn ni Fílípì wá lọ sí Áṣídódì, ó tún lọ sí Kesaréà, ó sì ń “polongo ìhìn rere fún gbogbo àwọn ìlú ńlá” tó wà lójú ọ̀nà. (Ìṣe 8:39, 40) Ó dájú pé ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínu ṣíṣe iṣẹ́ ajíhìnrere!
5. Kí ni ohun náà gan-an táwọn èèyàn fi mọ àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí Fílípì bí?
5 Fílípì ṣì jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní Kesaréà ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn àkókò yẹn. Kódà ó ní “ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀” nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù wà nílé rẹ̀. (Ìṣe 21:8-10) Ó hàn gbangba pé wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ tó ye kooro nípa tẹ̀mí, wọ́n ní ìtara fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, wọ́n sì tún láǹfààní láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. Lóde òní, ìtara táwọn òbí ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ní ipa tó dára lórí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin wọn, tí yóò sì mú kí àwọn ọmọ náà sọ iṣẹ́ fífi ìtara wàásù di iṣẹ́ tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe.
Àwọn Ajíhìnrere Tó Jẹ́ Onítara Lónìí
6. Àṣeyọrí wo ni àwọn ajíhìnrere ọ̀rúndún kìíní ṣe?
6 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Jésù Kristi sọ nípa ọjọ́ wa àti nípa àkókò òpin, ó sọ pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Òpin náà yóò dé lẹ́yìn tá a bá ti wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Bí Pọ́ọ̀lù àtàwọn ajíhìnrere mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ń polongo ìhìn rere náà ni ọ̀pọ̀ ń di onígbàgbọ́, tí wọ́n ń dá àwọn ìjọ sílẹ̀ ní ibi púpọ̀ jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Àwọn alàgbà tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ nínú àwọn ìjọ wọ̀nyí bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn kópa nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere, wọ́n sì jẹ́ kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù náà dé ibi gbogbo. Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí nígbà yẹn lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lọ́jọ́ òní nítorí pé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere náà. (Ìṣe 19:20) Ǹjẹ́ o wà lára àwọn tó ń fi ayọ̀ yin Jèhófà?
7. Kí làwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe lónìí?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run lóde òní ló ń lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún wọn láti mú kí ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere náà túbọ̀ pọ̀ sí i. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ti wà nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ẹgbẹẹgbàárùn-ún ló sì ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ẹ sì wo iṣẹ́ àtàtà táwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí onítara akéde Ìjọba náà ń ṣe! Láìsí àní-àní, gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà ló ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ajíhìnrere.—Sefanáyà 3:9.
8. Iṣẹ́ sísàmì wo ló ń lọ lọ́wọ́ lónìí, àwọn wo ló sì ń ṣe é?
8 Ọlọ́run ti fún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù ní ẹrù iṣẹ́ láti pòkìkí ìhìn rere náà jákèjádò ayé. Àwọn tó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ti Kristi, tí iye wọn ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. (Jòhánù 10:16) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ kan wí, iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí la fi wé sísàmì síwájú orí àwọn tó ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí. A ó pa àwọn ẹni ibi run láìpẹ́. Ní báyìí ná, ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa mú òtítọ́ tí ń gba ẹ̀mí là lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn olùgbé ayé!—Ìsíkíẹ́lì 9:4-6, 11.
9. Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
9 Tó bá ti pẹ́ díẹ̀ tá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere náà, ó ṣeé ṣe ká lè ṣe nǹkan kan láti ran àwọn ẹni tuntun nínú ìjọ lọ́wọ́. A lè sọ pé kí wọ́n tẹ̀ lé wa lọ sóde ẹ̀rí nígbà mìíràn. Àwọn tó jẹ́ alàgbà yóò fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti gbé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ró nípa tẹ̀mí. Ìsapá àtàtà tí àwọn alábòójútó tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ń ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di ajíhìnrere to nítara tó sì ń ṣàṣeyọrí.—2 Pétérù 1:5-8.
Jíjẹ́rìí Láti Ilé Dé Ilé
10. Àpẹẹrẹ wo ni Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí fi lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
10 Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere. Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi àti ti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni pé: “Ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Lúùkù 8:1) Àwọn àpọ́sítélì fúnra wọn ńkọ́? Lẹ́yìn tá a tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, “ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:42.
11. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣe 20:20, 21?
11 Iṣẹ́ ìjíhìnrere tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìtara ṣe ló fi lè sọ fún àwọn Kristẹni alàgbà tó wà ní Éfésù pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ‘ń kọ́ni láti ilé dé ilé,’ ṣé ilé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà ló ń lọ káàkiri tó ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́? Rárá o, nítorí ó tún ṣàlàyé pé: “Mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” (Ìṣe 20:20, 21) Ó hàn gbangba pé àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kò nílò ìtọ́ni nípa “ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” Pọ́ọ̀lù dá àwọn Kristẹni alàgbà tó wà ní Éfésù lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé, bó ṣe ń fi ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ kọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Nípa ṣíṣe èyí, Pọ́ọ̀lù ń fara wé ọ̀nà tí Jésù fi lélẹ̀.
12, 13. Ní ìbámu pẹ̀lú Fílípì 1:7, kí làwọn èèyàn Jèhófà ti ṣe nípa ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti wàásù?
12 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé lè má rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, inú máa ń bí àwọn kan nígbà tá a bá wá sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì fún wọn. Kì í ṣe pé ó wù wá láti máa múnú bí àwọn èèyàn. Àmọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé tá a ń ṣe yìí bá Ìwé Mímọ́ mu, ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti fún àwọn aládùúgbò wa ló sì ń sún wa láti jẹ́rìí lọ́nà yìí. (Máàkù 12:28-31) A ti gbé àwọn ọ̀ràn kan lọ sílé ẹjọ́, títí kan Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kí á lè ‘gbèjà, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin’ pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti wàásù láti ilé dé ilé. (Fílípì 1:7) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwa ni ilé ẹjọ́ máa ń dá láre. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé:
13 “Pípín ìwé ìléwọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìsìn kiri ti jẹ́ ohun kan táwọn míṣọ́nnárì fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn láti ọjọ́ tó ti pẹ́, ká kúkú sọ pé látìgbà tí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti wà. Ó jẹ́ ohun tí onírúurú ìsìn ti ń lò láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Àwọn èèyàn ṣì ń lo ọ̀nà ìjẹ́rìí yìí lónìí, àwọn tó ń lò ó jù lọ ni àwọn onírúurú ìsìn tí àwọn apínwèé-ìsìn-kiri wọn máa ń mú Ìhìn Rere lọ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé tí wọ́n tún máa ń wá bí wọ́n ṣe máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè rí àwọn èèyàn tó máa fara mọ́ ìgbàgbọ́ wọn. . . . Ojú pàtàkì ti wọ́n fi wo jíjọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti wíwàásù lórí àga ìwàásù náà ni wọ́n fi wo irú ìgbòkègbodò ìsìn yìí nínú Àtúnṣe Kìíní [sí Òfin orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà].”—Ẹjọ́ Murdock pẹ̀lú Pennsylvania, 1943.
Kí Nìdí Tá Ò Fi Dáwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Náà Dúró?
14. Ipa tó lágbára wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè ní?
14 Ìdí tó fi yẹ ká máa wàásù láti ilé dé ilé pọ̀ rẹpẹtẹ. Gbogbo ìgbà tá a bá ti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ là ń gbìyànjú láti gbin èso òtítọ́ kan látinú Ìwé Mímọ́ sínú ọkàn onítọ̀hún. A sì ń bomi rin ín nígbà tá a bá ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ó sì lè ní ipa tó lágbára lórí onítọ̀hún, nítorí pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.” (1 Kọ́ríńtì 3:6) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní ‘gbígbìn àti bíbomi rin,’ kí ó sì dá wa lójú pé Jèhófà ‘yóò mú kí ó dàgbà.’
15, 16. Kí nìdí tá a fi ń lọ sílé àwọn èèyàn léraléra?
15 A ń ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere nítorí pé ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu. A lè tipa wíwàásù gba ara wa àti àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ wa là. (1 Tímótì 4:16) Tá a bá mọ̀ pé ẹ̀mí ẹnì kan wà nínú ewu, ṣe àá kàn sapá díẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ ni? Ó ti o! Níwọ̀n bí ọ̀ràn náà ti ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàlà, a ní láti máa kàn sí àwọn èèyàn nílé wọn ní gbogbo ìgbà. Ńṣe ni ipò nǹkan máa ń yí padà ṣáá. Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí débi pé kò ráyè gbọ́ wa nígbà kan lè ṣe tán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì nígbà mìíràn. Ó lè jẹ́ ẹlòmíràn lára ìdílé náà la máa bá nílé, ìyẹn sì lè yọrí sí ìjíròrò látinú Ìwé Mímọ́.
16 Kì í ṣe pé ipò àwọn onílé lè yí padà nìkan, àmọ́ ìṣarasíhùwà wọn tún lè yí padà pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, ìbànújẹ́ tí ẹnì kan ní nítorí èèyàn rẹ̀ tó kú ti lè mú kí onítọ̀hún fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. A óò fẹ́ láti tu onítọ̀hún nínú, a óò jẹ́ kó mọ̀ pé ó nílò nǹkan tẹ̀mí, a óò sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè rí i.—Mátíù 5:3, 4.
17. Kí ni ìdí pàtàkì jù lọ tá a fi ń wàásù?
17 Ìdì pàtàkì jù lọ tá a fi ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí tá a fi ń kópa nínú àwọn apá mìíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni pé ó wù wá láti kópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀. (Ẹ́kísódù 9:16; Sáàmù 83:18) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ nígbà tí iṣẹ́ ìjíhìnrere tá à ń ṣe bá ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ láti di olùyin Jèhófà! Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹ̀yin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin. Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé. Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.”—Sáàmù 148:12, 13.
Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Ṣe Àwa Fúnra Wa Láǹfààní
18. Ọ̀nà wo la gbà ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ ìjíhìnrere?
18 Ṣíṣe iṣẹ́ ajíhìnrere ń ṣe wá láǹfààní ní onírúurú ọ̀nà. Mímú ìhìn rere náà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti ilé dé ilé ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, àgàgà nígbà tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Tá a bá fẹ́ jẹ́ ajíhìnrere tó gbéṣẹ́, a ní láti dà bíi Pọ́ọ̀lù, tó ‘di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo kí ó lè gba àwọn kan là.’ (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Àwọn ìrírí tá a ń ní lóde ẹ̀rí lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo ọgbọ́n. Tá a bá gbára lé Jèhófà tá a sì ń ronú lórí ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ sọ kó tó ti ẹnu wa jáde, ìyẹn á jẹ́ ká lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.
19. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ran àwọn ajíhìnrere lọ́wọ́?
19 Iṣẹ́ ìjíhìnrere tún máa ń jẹ́ ká gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Sekaráyà 4:6) Lẹ́yìn náà, àwọn èso ti ẹ̀mí bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu” yóò fara hàn kedere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Gálátíà 5:22, 23) Ó máa ń nípa lórí bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn lò, nítorí pé títẹ̀lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́, láti kún fún ìdùnnú, láti ní ẹ̀mí àlàáfíà, ó ń jẹ́ ká ní ìpamọ́ra ká sì jẹ́ onínúure, ó ń jẹ́ ká fi ìwà rere àti ìgbàgbọ́ hàn, ká sì ní ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà tá a bá ń kéde ìhìn rere náà.
20, 21. Kí làwọn ìbùkún àti àǹfààní tá a lè ní tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere?
20 Ìbùkún mìíràn tí jíjẹ́ ajíhìnrere máa ń fúnni ni pé ó máa ń sọ wa di ẹni tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn. Nígbà táwọn èèyàn bá sọ ìṣòro tí wọ́n ní bí àìsàn, àìríṣẹ́ṣe, wàhálà inú ilé—a kì í sọ ara wa di agbaninímọ̀ràn, àmọ́ ńṣe la máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú àtàwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fún wọn. A máa ń ṣàníyàn nípa àwọn èèyàn tí ojú wọn ti fọ́ nípa tẹ̀mí, àmọ́ tó dà bíi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òdodo. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ìbùkún ńlá ló sì jẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”!—Ìṣe 13:48.
21 Kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí. (Lúùkù 11:34) Ó sì dájú pé ìyẹn á ṣe wá láǹfààní, nítorí pé bí a kò bá fọkàn sí ohun tẹ̀mí, a lè kó sínú ìdẹwò níní ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó wọ́pọ̀ nínú ayé yìí. Àpọ́sítélì Jòhánù rọ àwa Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) Jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere ká sì ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Ẹ To Ìṣúra Jọ sí Ọ̀run
22, 23. (a) Ìṣúra wo ni àwọn Kristẹni ajíhìnrere ń tò jọ? (b) Báwo ni àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́?
22 Fífi ìtara wàásù Ìjọba náà ń mú àǹfààní pípẹ́ títí wá. Jésù fi èyí hàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. Nítorí pé ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.”—Mátíù 6:19-21.
23 Ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní títo ìṣúra jọ sí ọ̀run, ní mímọ̀ pé kò sí àǹfààní tó tún lè ga ju kéèyàn jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń ṣojú fún Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ. (Aísáyà 43:10-12) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kí àwa náà máa ronú bíi ti Kristẹni obìnrin kan tó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, tó sọ nípa ọ̀pọ̀ ọdún tó ti fi ń sin Ọlọ́run pé: “Jálẹ̀ gbogbo rẹ̀, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó tẹ́wọ́ gbà mí nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìfi ìkùdíẹ̀-káàtó mi pè ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, mo sì gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí ó jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ fún mi títí láé.” Tí àwa náà bá mọyì àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run lọ́nà yìí, ó dájú pé a ó fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere náà láṣepé. Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere?
• Kí lo lè sọ nípa iṣẹ́ àwọn ajíhìnrere ayé ọjọ́un àtàwọn tòde òní?
• Kí nìdí tá a fi ń wàásù láti ilé dé ilé?
• Báwo ni ìwọ fúnra rẹ ṣe ń jàǹfààní látinú ṣíṣe iṣẹ́ ajíhìnrere?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn kan wà lóde òní tó jẹ́ pé tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń wàásù bíi ti Fílípì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ́ ajíhìnrere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Báwo ni ìwọ fúnra rẹ̀ ṣe ń jàǹfààní bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn?