Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ sí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ!
BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ kan? Tímótì náà gba irú lẹ́tà yìí látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, lẹ́tà yìí la wá mọ̀ sí Tímótì Kejì nínú Bíbélì. Ó dájú pé Tímótì máa wá ibi tó pa rọ́rọ́ kó lè ka lẹ́tà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí kọ sí i. Ó ṣeé ṣe kí Tímótì máa ronú pé: ‘Ṣé àlàáfíà ni Pọ́ọ̀lù wà ṣá? Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù máa fún mi lórí bí mo ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mi? Ṣé ìmọ̀ràn inú lẹ́tà yìí máa jẹ́ kí n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, kí n sì mọ̀ọ̀yàn kọ́?’ Kò sí àní-àní pé lẹ́tà yìí dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì tó ṣeé ṣe kí Tímótì ní. Àmọ́ ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó pàtàkì kan nínú lẹ́tà náà tó máa ran àwa náà lọ́wọ́.
‘MÒ Ń FARA DA OHUN GBOGBO’
Àtìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà náà ni Tímótì ti rí i pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Kódà, Pọ́ọ̀lù pè é ní “ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́.” (2 Tím. 1:2) Nǹkan bí ọdún 65 S.K. ni Tímótì gba lẹ́tà yìí. Kò tíì dàgbà púpọ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n (30) ọdún, síbẹ̀ alàgbà ni, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí. Ìdí ni pé ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tóun àti Pọ́ọ̀lù ti jọ ń ṣiṣẹ́, ó sì ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
Inú Tímótì máa dùn gan-an nígbà tó rí i pé Pọ́ọ̀lù ń fara dà á láìbọ́hùn, ó sì dájú pé ìyẹn máa fún un níṣìírí gan-an. Ìdí sì ni pé inú ẹ̀wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù wà ní Róòmù, wọ́n sì ti dájọ́ ikú fún un. (2 Tím. 1:15, 16; 4:6-8) Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mò ń fara da ohun gbogbo,’ ìyẹn sì jẹ́ kí Tímótì mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù nígboyà gan-an. (2 Tím. 2:8-13) Bíi ti Tímótì, àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lè fún àwa náà lókun láti fara dà á.
‘JẸ́ KÍ Ẹ̀BÙN ỌLỌ́RUN TÓ WÀ NÍNÚ RẸ MÁA JÓ BÍ INÁ’
Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ‘ẹ̀bùn Ọlọ́run tó wà nínú Tímótì máa jó bí iná.’ (2 Tím. 1:6) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún “ẹ̀bùn” ni khaʹri·sma. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí ẹ̀bùn téèyàn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí tàbí téèyàn ò ṣiṣẹ́ fún. Ìgbà tí wọ́n yan Tímótì fún iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ ló gba ẹ̀bùn yìí.—1 Tím. 4:14.
Kí ni Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì fi ẹ̀bùn yìí ṣe? Bí Tímótì ṣe ń ka ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé kó jẹ́ kí ẹ̀bùn Ọlọ́run tó wà nínú òun “máa jó bí iná,” ó ṣeé ṣe kó rántí pé iná igi máa ń jó lọlẹ̀ nígbà míì, tó sì máa gba pé kéèyàn koná mọ́ ọn. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò, ìyẹn a·na·zo·py·reʹo túmọ̀ sí pé kéèyàn “mú sọjí tàbí kó fẹ́ iná.” Ìyẹn ni pé kó “fìtara ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.” Lédè míì, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún Tímótì ni pé: ‘Fi gbogbo ọkàn rẹ sí iṣẹ́ ìsìn rẹ!’ Láìsí àní-àní, ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn, ìyẹn ni pé ká fìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
MÁA “ṢỌ́ OHUN RERE TÍ A FI SÍKÀÁWỌ́ RẸ”
Bí Tímótì ṣe ń ka lẹ́tà yìí lọ, ó rí ọ̀rọ̀ míì tí Pọ́ọ̀lù sọ tó máa jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeyanjú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Máa fi ẹ̀mí mímọ́ tó ń gbé inú wa ṣọ́ ohun rere tí a fi síkàáwọ́ rẹ.” (2 Tím. 1:14) Kí ni ohun rere tí wọ́n fi síkàáwọ́ Tímótì? Nínú ẹsẹ tó ṣáájú, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí “àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní,” ìyẹn òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 1:13) Tímótì ní láti kọ́ àwọn ará nínú ìjọ àtàwọn tí kì í ṣe Kristẹni ní òtítọ́. (2 Tím. 4:1-5) Bákan náà, torí pé alàgbà ni Tímótì, ó ní láti máa ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. (1 Pét. 5:2) Kí Tímótì tó lè ṣọ́ ohun rere tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, ìyẹn òtítọ́ tó fi ń kọ́ni, ó gbọ́dọ̀ gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Tím. 3:14-17.
Bákan náà lónìí, Jèhófà ti fi òtítọ́ yìí síkàáwọ́ wa ká lè fi kọ́ àwọn míì. (Mát. 28:19, 20) A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé bí òtítọ́ yìí ṣe ṣeyebíye tó. Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (Róòmù 12:11, 12; 1 Tím. 4:13, 15, 16) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe ká jẹ́ alàgbà nínú ìjọ tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ó yẹ kí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní yìí mú ká gbára lé Jèhófà, ká sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Torí náà, ká tó lè ṣọ́ ohun iyebíye tó wà ní ìkáwọ́ wa yìí, a gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà pátápátá kó lè ràn wá lọ́wọ́.
“ÀWỌN NǸKAN YÌÍ NI KÍ O FI SÍKÀÁWỌ́ ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́”
Ara iṣẹ́ Tímótì ni pé kó dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè ṣe iṣẹ́ tóun náà ń ṣe. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gba Tímótì níyànjú pé: “Àwọn nǹkan tí o sì gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . ni kí o fi síkàáwọ́ àwọn olóòótọ́, tí àwọn náà á sì wá kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti kọ́ àwọn ẹlòmíì.” (2 Tím. 2:2) Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará, kó sì kọ́ wọn láwọn ohun tó ti kọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn alàgbà náà sapá láti máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Alàgbà tó nírìírí kì í fi ohun tó mọ̀ pa mọ́ fáwọn míì. Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọṣẹ́ náà dáadáa. Kì í bẹ̀rù pé àwọn míì máa mọ iṣẹ́ náà ju òun lọ tàbí pé wọ́n á gbayì ju òun lọ. Torí náà, tìfuntẹ̀dọ̀ iṣẹ́ náà ló máa kọ́ wọn. Ìdí sì ni pé ó fẹ́ kí wọ́n ní ìrírí, kí òtítọ́ sì túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, “àwọn olóòótọ́” tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ máa túbọ̀ wúlò nínú ìjọ.
Kò sí àní-àní pé Tímótì mọyì lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí i. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Tímótì máa tún lẹ́tà náà kà, á sì máa ronú nípa bóun ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀ sílò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun.
Ó ṣe pàtàkì pé káwa náà fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá jẹ́ kí ẹ̀bùn Ọlọ́run tó wà nínú wa máa jó bí iná, tá à ń ṣọ́ ohun rere tí a fi síkàáwọ́ wa, tá a sì ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwa náà á lè “ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ [wa] láìkù síbì kan” bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún Tímótì.—2 Tím. 4:5.