Ìfẹ́ Wo Ló Ń Mú Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀?
“Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—SM. 144:15.
1. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àkókò wa yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?
ÀKÓKÒ tá à ń gbé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an. Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ń kó àwọn èèyàn jọ, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Àwọn tá a kó jọ yìí ti di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè,” wọ́n ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” (Ìṣí. 7:9, 15; Aísá. 60:22) Kò tíì sí ìgbà kankan nínú ìtàn ẹ̀dá táwọn èèyàn tó pọ̀ tó báyìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bíi tiwọn.
2. Irú ìfẹ́ wo làwọn tí kò mọ Ọlọ́run ní? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
2 Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àsìkò wa yìí, àwọn tí kò mọ Ọlọ́run máa ní ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn . . . , àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tím. 3:1-4) Irú ìfẹ́ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi hàn síra wa, kódà òdìkejì rẹ̀ ni. Àwọn tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan kì í láyọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wọ́n pé kí wọ́n láyọ̀. Ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan yìí ló jẹ́ kí ayé di èyí “tí ó nira láti bá lò.”
3. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?
3 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan tó gbayé kan lè ran àwọn Kristẹni, torí náà ó kìlọ̀ pé kí wọ́n “yà kúrò” lọ́dọ̀ àwọn tó ní ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan. (2 Tím. 3:5) Síbẹ̀ kò sí bá a ṣe lè yẹra pátápátá fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Torí náà, kí la lè ṣe táwọn èèyàn inú ayé ò fi ní kéèràn ràn wá, tí àá sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́? Ẹ jẹ́ ká wo ìyàtọ̀ tó wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti irú ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Tímótì 3:2-4. Ìyẹn máa jẹ́ ká mọ irú ìfẹ́ tó yẹ ká ní, ìyẹn ìfẹ́ tó máa fún wa ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.
IRÚ ÌFẸ́ WO LÓ YẸ KÁ NÍ?
4. Ṣó burú téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀? Ṣàlàyé.
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé:“Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn.” Ṣó burú téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀? Rárá kò burú. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu, kódà ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀. Jésù náà sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Máàkù 12:31) Tá ò bá nífẹ̀ẹ́ ara wa, a ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn míì. Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Éfé. 5:28, 29) Torí náà, kò sóhun tó burú tá a bá nífẹ̀ẹ́ ara wa.
5. Kí la lè fi àwọn onímọtara-ẹni-nìkan wé?
5 Ìfẹ́ tí 2 Tímótì 3:2 sọ kì í ṣe irú ìfẹ́ tó yẹ ká ní. Irú ìfẹ́ yìí ò dáa, ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan sì ni. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. (Ka Róòmù 12:3.) Wọn ò mọ̀ ju tara wọn lọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, kàkà kí wọ́n gbà pé àwọn ṣàṣìṣe àwọn míì ni wọ́n máa ń dá lẹ́bi. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì fi wọ́n wé ‘irú ọ̀yà kan tó sábà máa ń ká, tí irun múlọ́múlọ́ tó wà láyà rẹ̀ máa wà nínú àmọ́ tó máa kó ẹ̀gún ara rẹ̀ síta fáwọn míì.’ Irú àwọn onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ kì í ní ojúlówó ayọ̀.
6. Àwọn ànímọ́ wo làwọn tó ní ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń ní, báwo ló sì ṣe máa ń rí lára wọn?
6 Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan gbà pé ìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ́kọ́ mẹ́nu kan ìfẹ́ ara ẹni ni pé òun ló ń bí àwọn ìwà tí kò dáa yòókù tó mẹ́nu kàn. Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó ní ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń ní àwọn ànímọ́ tó dáa. Bíbélì sọ pé àwọn tó ní ìfẹ́ Ọlọ́run máa ń ní àwọn ànímọ́ bí ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gál. 5:22, 23) Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!” (Sm. 144:15) Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà, báwọn èèyàn rẹ̀ sì ṣe rí nìyẹn. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn onímọtara-ẹni-nìkan tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa gba tọwọ́ àwọn míì ni wọ́n ń wá, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni torí pé wọ́n máa ń lo ara wọn fáwọn míì.—Ìṣe 20:35.
7. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ ara wa ju Ọlọ́run lọ?
7 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ ara wa ju Ọlọ́run lọ? Ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:3, 4. Ẹsẹ yìí ní ká má ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí a máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ, kí a má ṣe máa mójú tó ire ara wa nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò ní ìgbésí ayé mi? Ṣé lóòótọ́ ni mò ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Ṣé mo máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ yálà nínú ìjọ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?’ Kò rọrùn láti lo ara ẹni fáwọn míì, ó máa ń gba kéèyàn sapá gan-an, kó sì yááfì àwọn nǹkan kan. Àmọ́, kò sóhun tó lè múnú wa dùn tó mímọ̀ tá a mọ̀ pé inú Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ń dùn sí wa.
8. Kí ni ìfẹ́ táwọn kan ní fún Ọlọ́run ti mú kí wọ́n ṣe?
8 Ìfẹ́ táwọn kan ní sí Ọlọ́run ti mú kí wọ́n fi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé sílẹ̀ kí wọ́n lè gbájú mọ́ iṣẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, dókítà ni Arábìnrin Ericka tó ń gbé nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Kàkà kó máa lé bó ṣe máa dé ipò ńlá nídìí iṣẹ́ ìṣègùn, ṣe ló di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, òun àti ọkọ rẹ̀ sì ti sìn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Arábìnrin yẹn sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tá a ní àtàwọn ìrírí wa bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíì ti jẹ́ káyé wa túbọ̀ nítumọ̀. Mo ṣì ń ṣiṣẹ́ dókítà, àmọ́ bí mo ṣe ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tí mò ń wo àwọn èèyàn sàn nípa tẹ̀mí àti bí mo ṣe ń ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́ ló ń fún mi láyọ̀ jù.”
ṢÉ ỌRỌ̀ AYÉ LÒ Ń LÉ ÀBÍ ỌRỌ̀ TI Ọ̀RUN?
9. Kí nìdí tí ìfẹ́ owó kò fi lè fúnni láyọ̀?
9 Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn èèyàn máa jẹ́ “olùfẹ́ owó.” Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, aṣáájú-ọ̀nà kan bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ọkùnrin yẹn ṣe? Ó mú owó jáde nínú pọ́ọ̀sì rẹ̀, ó nà án sókè ó sì sọ pé, “ọlọ́run mi nìyí!” Lóòótọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa lè fi gbogbo ẹnu sọ pé nǹkan míì làwọn ń sìn, àmọ́ àwọn èèyàn tó fẹ́ràn owó àtàwọn nǹkan ìní tara ló kún inú ayé yìí. Bó ti wù kó rí, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníw. 5:10) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, bí wón ṣe máa ní owó púpọ̀ sí i ni wọ́n ń lépa, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora.”—1 Tím. 6:9, 10.
10. Kí ni Ágúrì sọ nípa ipò òṣì àti ọrọ̀?
10 Gbogbo wa la nílò owó, torí pé ó máa ń dáàbò boni déwọ̀n àyè kan. (Oníw. 7:12) Àmọ́ ṣé èèyàn á láyọ̀ lóòótọ́ tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba owó táá fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nìkan ló ní? Bẹ́è ni! (Ka Oníwàásù 5:12.) Ágúrì ọmọkùnrin Jákè sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.” A lóye ìdí tó fi bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kóun tòṣì. Ó sọ síwájú sí i pé òun ò fẹ́ jalè torí pé ìyẹn máa tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ kí nìdí tó fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run má ṣe fún òun ní ọrọ̀? Ó ní: “Kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́, kí n sì wí pé: ‘Ta ni Jèhófà?’ ” (Òwe 30:8, 9) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà mọ àwọn kan tó gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ dípò Ọlọ́run.
11. Kí ni Jésù sọ nípa owó?
11 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó ò lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ó ti kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ kan ṣáájú èyí, ó ní: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.”—Mát. 6:19, 20, 24.
12. Báwo ni jíjẹ́ káwọn nǹkan díẹ̀ tẹ́ni lọ́rùn ṣe lè mú kó rọrùn láti sin Ọlọ́run? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé àwọn ń láyọ̀ àwọn sì túbọ̀ ń ráyè sin Jèhófà báwọn ṣe jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ àwọn lọ́rùn. Arákùnrin Jack tó ń gbé ní Amẹ́ríkà ta ilé àti ilé iṣẹ́ rẹ̀ kó lè ráyè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bíi ti ìyàwó rẹ̀. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún wa láti dórí ìpinnu pé ká ta ilé wa torí pé àwòṣífìlà nilé ọ̀hún, ó sì wà lágbègbè tó fini lọ́kàn balẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ọdún ló jẹ́ pé inú mi kì í dùn tí mo bá dé láti ibi iṣẹ́, nítorí àwọn ìṣòro tí mo máa ń kojú níbẹ̀. Àmọ́ ṣe ni inú ìyàwó mi tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń dùn ní tiẹ̀. Ó máa ń sọ fún mi pé, ‘Ọ̀gá tó dáa jù lọ ni mò ń bá ṣiṣẹ́!’ Ní báyìí témi náà ti di aṣáájú-ọ̀nà, a ti jọ wà lábẹ́ Ọ̀gá kan náà, ìyẹn Jèhófà.”
13. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ owó?
13 Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ owó, á dáa ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí, ká má sì tan ara wa jẹ. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ nípa owó, ṣé àwọn ìlànà yẹn ló sì ń darí mi? Ṣé bí mo ṣe máa lówó ló gbawájú láyé mi? Ṣé àwọn nǹkan tara ló jẹ mí lógún jù àbí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn? Ṣé mo gbà lóòótọ́ pé Jèhófà lè bójú tó àwọn ohun tí mo nílò?’ Ó dá wa lójú pé Jèhófà kò ní já àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ kulẹ̀, ó ṣe tán, adúró-ti-Olúwa kò ní jogún òfo.—Mát. 6:33.
OLÙFẸ́ ADÙN ÀBÍ OLÙFẸ́ ỌLỌ́RUN?
14. Kí ni Bíbélì sọ tó bá di pé kéèyàn gbádùn ara rẹ̀ tàbí kéèyàn ṣe fàájì?
14 Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “olùfẹ́ adùn” lásìkò wa yìí. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbádùn ara rẹ̀ tàbí kéèyàn ṣe fàájì níwọ̀ntúnwọ̀nsì, bó ṣe jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ tàbí kéèyàn lówó lọ́wọ́. Jèhófà ò fẹ́ ká máa fìyà jẹ ara wa, kò ní ká má gbádùn ara wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ká má ṣe fàájì. Bíbélì tiẹ̀ gba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níyànjú pé: “Máa lọ, máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó yá gágá mu wáìnì rẹ.”—Oníw. 9:7.
15. Irú adùn wo ni 2 Tímótì 3:4 ń sọ nípa rẹ̀?
15 Àwọn tí 2 Tímótì 3:4 pè ní olùfẹ́ adùn làwọn tí kò rí ti Ọlọ́run rò torí fàájì. Ẹ kíyè sí i pé ẹsẹ yìí ò sọ pé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ adùn ju Ọlọ́run lọ, bí ẹni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run déwọ̀n àyè kan. Ohun tó ń sọ ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ adùn ‘dípò Ọlọ́run.’ Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kò sọ pé àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run déwọ̀n àyè kan. Ohun tó ń sọ ni pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run rárá àti rárá.” Ẹ ò rí i pé ìkìlọ̀ ńlá lèyí jẹ́ fáwọn tí ìfẹ́ adùn ti gbà lọ́kàn, débi pé wọn ò ronú nǹkan míì ju bí wọ́n ṣe máa jayé orí wọn! Torí náà, gbólóhùn náà, “olùfẹ́ adùn” ṣàpèjúwe àwọn tí “adùn ìgbésí ayé yìí gbé lọ.”—Lúùkù 8:14.
16, 17. Kí la rí kọ́ lára Jésù tó bá di pé ká gbádùn ara wa tàbí kéèyàn ṣe fàájì?
16 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká gbádùn ara ẹni láìṣe àṣejù. Bí àpẹẹrẹ, ó lọ sí “àsè ìgbéyàwó kan,” ó sì tún lọ sí “àsè ìṣenilálejò” ńlá kan. (Jòh. 2:1-10; Lúùkù 5:29) Nígbà tó wà níbi ìgbéyàwó náà, ó sọ omi di ọtí wáìnì, èyí ló sì mú káwọn èèyàn rí wáìnì mu lẹ́yìn tí èyí tó wà tẹ́lẹ̀ ti tán. Kódà ìgbà kan wà táwọn kan bẹnu àtẹ́ lu Jésù pé ó ń jẹ ó sì ń mu, àmọ́ Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò wọn kò tọ̀nà.—Lúùkù 7:33-36.
17 Bó ti wù kó rí, kì í ṣe adùn tàbí fàájì ni Jésù fi gbogbo ayé rẹ̀ lé. Ìfẹ́ Jèhófà ló gbawájú láyé rẹ̀, ó sì lo gbogbo okun rẹ̀ torí àwọn míì. Kódà, ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀, ó sì kú ikú oró káwọn míì lè wà láàyè. Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.”—Mát. 5:11, 12.
18. Àwọn ìbéèrè wo láá jẹ́ ká mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ adùn?
18 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ adùn tàbí fàájì? Á dáa ká bi ara wa pé: ‘Ṣé ìpàdé àti òde ẹ̀rí ló máa ń gbawájú nínú ìgbòkègbodò mi àbí eré ìnàjú? Ṣé mo ṣe tán láti fàwọn nǹkan kan du ara mi kí n lè túbọ̀ sin Jèhófà? Ṣé mo máa ń ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan tí mo yàn láti fi gbádùn ara mi?’ Tó bá jẹ́ lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa bí Jèhófà nínú nìkan la máa yẹra fún, kódà a ò tún ní lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tá a fura sí pé inú rẹ̀ lè má dùn sí.—Ka Mátíù 22:37, 38.
BÁ A ṢE LÈ LÁYỌ̀
19. Àwọn wo ni kò lè ní ojúlówó ayọ̀?
19 Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà [6,000] tí ayé Èṣù yìí ti ń fojú pọ́n aráyé, àmọ́ ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin báyìí. Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, olùfẹ́ owó àtàwọn olùfẹ́ adùn ló kúnnú ayé yìí. Bọ́wọ́ wọn ṣe máa tẹ ohun tí wọ́n fẹ́ ló gbawájú nígbèésí ayé wọn, wọn kì í ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kò lè ní ojúlówó ayọ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Onísáàmù kan sọ béèyàn ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.”—Sm. 146:5.
20. Báwo ni ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ṣe ń mú kó o láyọ̀?
20 Ṣe ni ìfẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ ń jinlẹ̀ lọ́kàn àwa èèyàn Jèhófà, bẹ́ẹ̀ sì ni iye wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ẹ̀rí nìyẹn jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso àti pé ó máa tó rọ̀jò ìbùkún sórí ilẹ̀ ayé. Àá ní ojúlówó ayọ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Baba wa ọ̀run fẹ́, àá sì múnú rẹ̀ dùn. Yàtọ̀ síyẹn, títí ayé làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà á máa láyọ̀! Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, àá jíròrò ìwà táwọn onímọtara-ẹni-nìkan máa ń hù àti bíyẹn ṣe yàtọ̀ sáwọn ànímọ́ rere táwa èèyàn Jèhófà ní.