Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì àti Hébérù
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù Kírétè lẹ́yìn tí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n lọ́dún 61 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ẹ̀wọ̀n àkọ́kọ́ tó ṣe ní Róòmù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ó yẹ káwọn ìjọ tó wà ní Kírétè túbọ̀ mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i, ó fi Títù sílẹ̀ níbẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù láti tọ́ ọ sọ́nà nípa bó ṣe máa ṣe ojúṣe rẹ̀ àti láti fi hàn pé òun ń tì í lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Makedóníà ni Pọ́ọ̀lù ti kọ lẹ́tà yìí.
Àmọ́ ìgbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lọ́dún 61 Sànmánì Kristẹni, ló kọ̀wé sí Fílémónì, arákùnrin kan tó ń gbé ní Kólósè. Ọ̀rọ̀ ìyànjú téèyàn lè bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ ló wà nínú lẹ́tà náà.
Ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ Hébérù tí wọ́n ń gbé ní Jùdíà, ó sì fi hàn pé ẹ̀sìn Kristẹni ló tọ̀nà kì í ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù. Àwọn ìwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Pọ́ọ̀lù kọ yìí ní ìmọ̀ràn tó ṣeyebíye fún gbogbo wa.—Héb. 4:12.
Ẹ JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ YÍN LÁGBÁRA
Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti pèsè ìtọ́sọ́nà fún Títù lórí bó ṣe máa “yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá,” ó tún fún un nímọ̀ràn pé kó “máa bá a nìṣó ní fífi ìbáwí tọ́ [àwọn ewèlè èèyàn] sọ́nà pẹ̀lú ìmúnájanjan, kí wọ́n lè jẹ́ onílera nínú ìgbàgbọ́.” Ó gba gbogbo àwọn tó wà ní ìjọ Kírétè níyànjú láti “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ . . . àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.”—Títù 1:5, 10-13; 2:12.
Pọ́ọ̀lù tún gba àwọn ará tó wà ní Kírétè nímọ̀ràn síwájú sí i pé kí wọ́n mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára sí i. Ó fún Títù nítọ̀ọ́ni pé kó “máa yẹ àwọn ìbéèrè òmùgọ̀ sílẹ̀ . . . àti àwọn ìjà lórí Òfin.”—Títù 3:9.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:15—Báwo ni “ohun gbogbo” ṣe lè “mọ́ fún àwọn tí ó mọ́,” tí ohun gbogbo sì jẹ́ ẹlẹ́gbin “fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́”? A ní láti lóye “ohun gbogbo” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí ká tó lè mọ ìdáhùn náà. Kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá lẹ́bi. Ohun tó ń sọ ni àwọn nǹkan tí Ìwé Mímọ́ gbà láyè kí onígbàgbọ́ kan fúnra rẹ̀ ṣèpinnu lé lórí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe gbà á láyè. Fún ẹni tí ìrònú rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ mọ́. Àmọ́ fún ẹni tí èrò rẹ̀ ti dìdàkudà tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sì ti di ẹlẹ́gbin, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò mọ́.a
3:5—Báwo ni a ṣe ‘gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró là nípasẹ̀ ìwẹ̀,’ tá a sì ‘sọ wọ́n di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́’? A ‘gbà wọ́n là nípasẹ̀ ìwẹ̀’ ní ti pé Ọlọ́run fi ẹ̀jẹ̀ Jésù wẹ̀ wọ́n, tàbí sọ wọ́n di mímọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. A sọ wọ́n di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ nítorí pé wọ́n di “ẹ̀dá tuntun” gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run tá a fi ẹ̀mí bí.—2 Kọ́r. 5:17.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:10-13; 2:15. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ alábòójútó ní láti ní ìgboyà láti lè ṣàtúnṣe àwọn ohun tí kò tọ́ nínú ìjọ.
2:3-5. Bíi ti ọ̀rúndún kìíní, àwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lóde òní ní láti “jẹ́ onífọkànsìn nínú ìhùwàsí, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì, kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.” Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè máa tọ́ “àwọn ọ̀dọ́bìnrin” sọ́nà nínú ìjọ.
3:8, 14. Gbígbé ‘èrò inú wa ka orí dídi àwọn iṣẹ́ àtàtà mú’ jẹ́ “ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì ṣàǹfààní fún ènìyàn” nítorí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, wọ́n sì ń mú ká yàtọ̀ nínú ayé búburú yìí.
MO Ń GBÀ Ọ́ NÍYÀNJÚ “NÍTORÍ ÌFẸ́”
Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún Fílémónì nítorí ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú “ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́.” Bí Fílémónì ṣe ń tu àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ nínú ti mú kí Pọ́ọ̀lù ní “ìdùnnú àti ìtùnú” púpọ̀.—Fílém. 4, 5, 7.
Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn alábòójútó, ó fẹ̀sọ̀ bójú tó ọ̀rọ̀ Ónẹ́símù nípa gbígbà Fílémónì níyànjú “nítorí ìfẹ́,” kò pàṣẹ fún un. Ó sọ́ fún Fílémónì pé: “Ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìfohùnṣọ̀kan rẹ, mo ń kọ̀wé sí ọ, ní mímọ̀ pé ìwọ yóò tilẹ̀ ṣe ju àwọn ohun tí mo wí.”—Fílém. 8, 9, 21.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
10, 11, 18—Báwo ni Ónẹ́símù tí “kò wúlò” tẹ́lẹ̀ rí ṣe wá di ẹni tó “wúlò”? Ónẹ́símù jẹ́ ẹrú aláìgbọràn kan tó sá kúrò lọ́dọ̀ Fílémónì ọ̀gá rẹ̀ ní Kólósè, ó sì lọ sí Róòmù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ja ọ̀gá rẹ̀ lólè láti lè rí owó tó máa fi rìnrìn àjò tó jìn tó egbèje [1,400] kìlómítà. Lóòótọ́, ẹrú yìí kò wúlò fún Fílémónì. Àmọ́, ní Róòmù, Pọ́ọ̀lù ran Ónẹ́símù lọ́wọ́, ó sì di Kristẹni. Ní báyìí tó ti wá di Kristẹni, ẹrú tí “kò wúlò” tẹ́lẹ̀ rí yìí ti wá dẹni tó “wúlò.”
15, 16—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù kò fi sọ fún Fílémónì pé kó sọ Ónẹ́símù dòmìnira? Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ìyẹn ‘wíwàásù ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ni láwọn ohun tó jẹ mọ́ Jésù Kristi Olúwa.’ Nítorí náà, kò fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ àárín ẹrú àti ọ̀gá rẹ̀ tàbí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 28:31.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
2. Fílémónì yọ̀ǹda ilé rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ìpàdé Kristẹni níbẹ̀. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé ká máa ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá nílé wa.—Róòmù 16:5; Kól. 4:15.
4-7. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́.
15, 16. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ipò tí kò bára dé nígbèésí ayé mú ká máa ṣàníyàn ju bó ti yẹ lọ. Èyí á ṣe wá láǹfààní gan-an bó ṣe rí nínú ọ̀rọ̀ ti Ónẹ́símù.
21. Pọ́ọ̀lù nírètí pé Fílémónì á dárí ji Ónẹ́símù. Bákan náà la retí pé ká dárí ji ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó ṣẹ̀ wá.—Mát. 6:14.
“TẸ̀ SÍWÁJÚ SÍ ÌDÀGBÀDÉNÚ”
Láti fi hàn pé ẹbọ Jésù dára ju iṣẹ́ Òfin lọ, Pọ́ọ̀lù sọ bí Ẹni tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ ṣe ta yọ lọ́lá tó, ó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀, ẹbọ rẹ̀, àti májẹ̀mú tuntun náà. (Héb. 3:1-3; 7:1-3, 22; 8:6; 9:11-14, 25, 26) Ìmọ̀ táwọn Hébérù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ní yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú inúnibíni táwọn Júù ń ṣe sí wọn. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Hébérù tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.”—Héb. 6:1.
Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ń kó nínú ẹ̀sìn Kristẹni? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ‘láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa.’ Ó gba àwọn Hébérù yẹn níyànjú pé: ‘Kí wọ́n fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wọn,’ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.—Héb. 11:6; 12:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:14, 15—Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ pé Sátánì “ní ọ̀nà àtimú ikú wá” fí hàn pé ó lè dá ẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ légbodò? Rárá, o kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, látìgbà tí Sátánì ti hùwà ibi láti inú ọgbà Édẹ́nì ni irọ́ tó pa ti fa ikú, nítorí Ádámù ṣẹ̀ ó sì ta àtaré ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sórí ìran èèyàn. (Róòmù 5:12) Síwájú sí i, àwọn èèyàn tó ń ṣe ìfẹ́ Sátánì lórí ilẹ̀ ayé ti ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run dójú ikú, bí wọ́n ti ṣe sí Jésù. Àmọ́ ìyẹn kò sọ pé Sátánì ní gbogbo agbára láti pa ẹnikẹ́ni tó bá wù ú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ì bá ti pa gbogbo àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tipẹ́tipẹ́. Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, kò sì gba Sátánì láyè láti pa wọ́n run. Àní bí Ọlọ́run bá tiẹ̀ yọ̀ǹda kí Sátánì pa àwọn kan lára wa, ìgbẹ́kẹ̀lé wa ni pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìpalára tó ti mú wá bá wa kúrò.
4:9-11—Báwo la ṣe lè “wọnú ìsinmi Ọlọ́run”? Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀, ó sì mọ̀ pé ohun tóun ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé àti èèyàn yóò ṣẹ. (Jẹ́n. 1:28; 2:2, 3) A “wọnú ìsinmi” yẹn nípa jíjáwọ́ nínú òfin tó ń fi wá hàn gẹ́gẹ́ bí olódodo, ká sì tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè fún wa. Tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tá a sì ṣègbọràn sí Ọmọ rẹ̀, tí a ò máa lépa ìfẹ́ ti ara wa, ojoojúmọ́ la óò máa gbádùn ìtura àti ìbùkún tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.—Mát. 11:28-30.
9:16—Ta ni “ẹ̀dá ènìyàn olùdámájẹ̀mú” ti májẹ̀mú tuntun? Jèhófà ni Ẹni tó ṣe Májẹ̀mú tuntun náà, Jésù ni “ẹ̀dá ènìyàn olùdámájẹ̀mú.” Jésù ni Alárinà májẹ̀mú yẹn, ó sì tipasẹ̀ ikú rẹ̀ ṣe ìràpadà tá a nílò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.—Lúùkù 22:20; Héb. 9:15.
11:10, 13-16—“Ìlú” wo ni Ábúráhámù dúró dè? Ìlú ìṣàpẹẹrẹ ni ìlú náà, kì í ṣe èyí téèyàn lè fojú rí. Ábúráhámù ń dúró de “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run,” ìyẹn Jésù Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó máa bá a jọba. Àwọn tó máa bá Jésù jọba tí wọ́n wà nínú ògo wọn ni Bíbélì pè ní “ìlú ńlá mímọ́, Jerúsálẹ́mù Tuntun.” (Héb. 12:22; Ìṣí. 14:1; 21:2) Ábúráhámù ń fojú sọ́nà láti gbé lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run.
12:2—Kí ni “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú [Jésù]” tó tìtorí rẹ̀ “fara da òpó igi oró”? Ìdùnnú rírí tó máa rí ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yóò mú jáde ló mú kó fara da òpó igi oró, lára àwọn ohun náà ni: ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà, ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ìràpadà láti gba aráyé kúrò lọ́wọ́ ikú. Jésù tún ń fojú sọ́nà láti gba èrè ṣíṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba táá sì tún jẹ́ Àlùfáà Àgbà fún àǹfààní aráyé.
13:20—Kí nìdí tá a fi sọ pé májẹ̀mú tuntun jẹ́ ti “àìnípẹ̀kun”? Ìdí mẹ́ta tí ibí yìí fi sọ bẹ́ẹ̀ rèé: (1) A kò ní fi ohun mìíràn rọ́pò rẹ̀, (2) ohun tó máa gbéṣe yóò wà títí lọ, àti pé (3) “àwọn àgùntàn mìíràn” yóò máa gbádùn àǹfààní májẹ̀mú tuntun náà lọ lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì.—Jòh. 10:16.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
5:14. A ní láti jẹ́ ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọntaápọn, ká sì máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan la fi lè kọ́ “agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—1 Kọ́r. 2:10.
6:17-19. Gbígbé ìrètí wa ka ìlérí àti ìbúra rẹ̀ kó ní jẹ́ ká kúrò ní ọ̀nà òtítọ́.
12:3, 4. Dípò kí á jẹ́ ‘kó rẹ̀ wá, kí á sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wa’ nítorí àwọn ìdẹwò kéékèèké tàbí àtakò, ńṣe ló yẹ ká máa bá a nìṣó ní dídàgbà nípa tẹ̀mí ká sì túbọ̀ múra láti fara da ìdẹwò. Ó yẹ ká pinnu láti “dúró títí dé orí ẹ̀jẹ̀,” ìyẹn, títí dójú ikú.—Héb. 10:36-39.
12:13-15. A ò gbọ́dọ̀ fàyè gba “gbòǹgbò onímájèlé,” tàbí ẹnì kan tó ń ṣàríwísí ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan nínú ìjọ, tí kò ní jẹ́ ká ‘máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wa.’
12:26-28. “Àwọn ohun tí a ti ṣe” tí kò wá látọwọ́ Ọlọ́run, ìyẹn ètò nǹkan ìsinsìnyí lápapọ̀, tí í ṣe “ọ̀run” burúkú, la óò mì tí kò ní sí mọ́. Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, kìkì “àwọn ohun tí a ko mì” ìyẹn, Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn tó fara mọ́ Ìjọba náà ni yóò dúró. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì fún wa láti máa fìtara kéde Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa fi ìlànà Ìjọba náà sílò!
13:7, 17. Pípa àmọ̀ràn yìí mọ́ pé ká máa ṣègbọràn ká sì máa tẹrí ba fún àwọn alábòójútó nínú ìjọ yóò jẹ́ ká ní ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]